Sámúẹ́lì Kìíní 28:1-25

  • Sọ́ọ̀lù lọ bá abẹ́mìílò ní Ẹ́ń-dórì (1-25)

28  Nígbà yẹn, àwọn Filísínì kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ láti bá Ísírẹ́lì jà.+ Nítorí náà, Ákíṣì sọ fún Dáfídì pé: “Ṣé o mọ̀ pé ìwọ àti àwọn ọkùnrin rẹ máa bá mi lọ jagun?”+  Dáfídì bá sọ fún Ákíṣì pé: “Ìwọ náà mọ ohun tí ìránṣẹ́ rẹ máa ṣe.” Ni Ákíṣì bá sọ fún Dáfídì pé: “Ìdí nìyẹn tí màá fi yàn ọ́ ṣe ẹ̀ṣọ́ tí á máa ṣọ́ mi nígbà gbogbo.”*+  Lákòókò yìí, Sámúẹ́lì ti kú, gbogbo Ísírẹ́lì ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rámà ìlú rẹ̀.+ Sọ́ọ̀lù sì ti mú àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ kúrò ní ilẹ̀ náà.+  Àwọn Filísínì kóra jọ, wọ́n lọ, wọ́n sì pabùdó sí Ṣúnémù.+ Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì pabùdó sí Gíbóà.+  Nígbà tí Sọ́ọ̀lù rí ibùdó àwọn Filísínì, ẹ̀rù bà á, àyà rẹ̀ sì já gan-an.+  Bí Sọ́ọ̀lù tilẹ̀ ń wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà,+ Jèhófà kò dá a lóhùn rárá, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ àlá tàbí nípasẹ̀ Úrímù  + tàbí àwọn wòlíì.  Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò,+ màá lọ wádìí lọ́wọ́ rẹ̀.” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Wò ó! Obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò wà ní Ẹ́ń-dórì.”+  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù pa ara dà, ó wọ aṣọ míì, ó sì lọ sọ́dọ̀ obìnrin náà ní òru pẹ̀lú méjì lára àwọn ọkùnrin rẹ̀. Ó ní: “Jọ̀wọ́, bá mi fi agbára ìbẹ́mìílò+ rẹ pe ẹni tí mo bá dárúkọ rẹ̀ fún ọ jáde.”  Ṣùgbọ́n, obìnrin náà sọ fún un pé: “Ó yẹ kí o mọ ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe dáadáa, bí ó ṣe mú àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ kúrò ní ilẹ̀ yìí.+ Kí wá nìdí tí o fi fẹ́ dẹkùn mú mi* kí wọ́n lè pa mí?”+ 10  Sọ́ọ̀lù wá fi Jèhófà búra fún un pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, o ò ní jẹ̀bi kankan lórí ọ̀rọ̀ yìí!” 11  Ni obìnrin náà bá sọ pé: “Ta ni kí n bá ọ pè jáde?” Ó fèsì pé: “Bá mi pe Sámúẹ́lì jáde.” 12  Nígbà tí obìnrin náà rí “Sámúẹ́lì,”*+ ó fi gbogbo agbára rẹ̀ ké jáde sí Sọ́ọ̀lù pé: “Kí ló dé tí o fi tàn mí? Ìwọ ni Sọ́ọ̀lù!” 13  Àmọ́ ọba sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, kí lo rí?” Obìnrin náà dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Mo rí ẹnì kan tó dà bí ọlọ́run tó ń jáde bọ̀ láti inú ilẹ̀.” 14  Ní kíá, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Báwo ló ṣe rí?” Ó fèsì pé: “Ọkùnrin arúgbó kan ló ń jáde bọ̀, ó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.”+ Sọ́ọ̀lù wá mọ̀ pé “Sámúẹ́lì” ni, ó tẹrí ba, ó sì dọ̀bálẹ̀. 15  Ìgbà náà ni “Sámúẹ́lì” sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Kí ló dé tí o fi ń yọ mí lẹ́nu, tí o ní kí wọ́n pè mí jáde?” Sọ́ọ̀lù fèsì pé: “Mo wà nínú wàhálà ńlá. Àwọn Filísínì ń bá mi jà, Ọlọ́run sì ti fi mí sílẹ̀, kò dá mi lóhùn mọ́, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ àwọn wòlíì tàbí nípasẹ̀ àlá;+ ìdí nìyẹn tí mo fi ń pè ọ́, kí o lè jẹ́ kí n mọ ohun tó yẹ kí n ṣe.”+ 16  “Sámúẹ́lì” bá sọ pé: “Kí nìdí tí o fi ń wádìí lọ́dọ̀ mi ní báyìí tí Jèhófà ti fi ọ́ sílẹ̀,+ tó sì ti wá di ọ̀tá rẹ? 17  Jèhófà yóò ṣe ohun tí ó ti gbẹnu mi sọ: Jèhófà máa fa ìjọba náà ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, á sì fún Dáfídì tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn rẹ.+ 18  Nítorí pé o kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, Ámálékì+ tó ń múnú bí i gan-an ni o kò sì pa run, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ọ lónìí. 19  Jèhófà tún máa fi ìwọ àti Ísírẹ́lì lé àwọn Filísínì lọ́wọ́.+ Ní ọ̀la, ìwọ+ àti àwọn ọmọ rẹ+ yóò wà pẹ̀lú mi. Jèhófà sì máa tún fi àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì lé àwọn Filísínì lọ́wọ́.”+ 20  Ní kíá, Sọ́ọ̀lù nà gbalaja sórí ilẹ̀, ẹ̀rù sì bà á gan-an nítorí ọ̀rọ̀ “Sámúẹ́lì.” Kò sì sí okun kankan nínú rẹ̀ mọ́, torí pé kò tíì jẹun ní gbogbo ọ̀sán àti ní gbogbo òru. 21  Nígbà tí obìnrin náà wá bá Sọ́ọ̀lù, tó sì rí i pé ìdààmú ti bá a gan-an, ó sọ fún un pé: “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ ti ṣe ohun tí o sọ, mo ti fi ẹ̀mí mi wewu,*+ mo sì ṣe ohun tí o ní kí n ṣe. 22  Ní báyìí, jọ̀wọ́ gbọ́ ohun tí ìránṣẹ́ rẹ fẹ́ sọ. Jẹ́ kí n gbé oúnjẹ díẹ̀ síwájú rẹ, kí o lè jẹun, kí o sì ní okun nígbà tí o bá ń lọ.” 23  Ṣùgbọ́n ó kọ̀, ó sì sọ pé: “Mi ò ní jẹun.” Àmọ́, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti obìnrin náà ń rọ̀ ọ́. Níkẹyìn, ó gbọ́ tiwọn, ó dìde nílẹ̀, ó sì jókòó sórí ibùsùn. 24  Obìnrin náà ní ọmọ màlúù àbọ́sanra kan nílé, torí náà ó sáré pa á,* ó bu ìyẹ̀fun, ó pò ó, ó sì fi ṣe búrẹ́dì aláìwú. 25  Ó wá gbé e fún Sọ́ọ̀lù àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì jẹun. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n gbéra, wọ́n sì lọ ní òru yẹn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “olùṣọ́ orí mi lọ́jọ́ gbogbo.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ohun tó fara jọ Sámúẹ́lì.”
Tàbí “ọkàn mi sí ọwọ́ mi.”
Tàbí “fi í rúbọ.”