Àkọsílẹ̀ Jòhánù 18:1-40

  • Júdásì da Jésù (1-9)

  • Pétérù lo idà (10, 11)

  • Wọ́n mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Ánásì (12-14)

  • Ìgbà àkọ́kọ́ tí Pétérù sẹ́ (15-18)

  • Jésù dé iwájú Ánásì (19-24)

  • Pétérù sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì àti lẹ́ẹ̀kẹta (25-27)

  • Jésù dé iwájú Pílátù (28-40)

    • “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí” (36)

18  Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí òdìkejì Àfonífojì Kídírónì,*+ níbi tí ọgbà kan wà, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wọnú ibẹ̀.+  Júdásì, ẹni tó dà á náà mọ ibẹ̀, torí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sábà máa ń pàdé níbẹ̀.  Torí náà, Júdásì kó àwùjọ àwọn ọmọ ogun àti àwọn òṣìṣẹ́ ti àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí, wọ́n sì wá síbẹ̀, tàwọn ti ògùṣọ̀, fìtílà àti ohun ìjà.+  Jésù mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i, torí náà, ó bọ́ síwájú, ó sì sọ fún wọn pé: “Ta lẹ̀ ń wá?”  Wọ́n dá a lóhùn pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.”+ Ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni.” Júdásì, ẹni tó dà á náà wà ní ìdúró pẹ̀lú wọn.+  Àmọ́ nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé, “Èmi ni,” wọ́n sún mọ́ ẹ̀yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.+  Torí náà, ó tún bi wọ́n pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” Wọ́n ní: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.”  Jésù dáhùn pé: “Mo ti sọ fún yín pé èmi ni. Torí náà, tó bá jẹ́ èmi lẹ̀ ń wá, ẹ fi àwọn yìí sílẹ̀.”  Èyí jẹ́ torí kí ohun tó sọ lè ṣẹ, pé: “Mi ò pàdánù ìkankan nínú àwọn tí o fún mi.”+ 10  Ni Símónì Pétérù tó ní idà bá fà á yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ ọ̀tún dà nù.+ Málíkọ́sì ni orúkọ ẹrú náà. 11  Àmọ́ Jésù sọ fún Pétérù pé: “Fi idà náà sínú àkọ̀ rẹ̀.+ Ṣé kò yẹ kí n mu ife tí Baba fún mi ni?”+ 12  Àwọn ọmọ ogun náà àti ọ̀gágun àti àwọn aláṣẹ àwọn Júù wá mú* Jésù, wọ́n sì dè é. 13  Wọ́n kọ́kọ́ mú un lọ sọ́dọ̀ Ánásì, torí òun ni bàbá ìyàwó Káyáfà,+ tó jẹ́ àlùfáà àgbà lọ́dún yẹn.+ 14  Ní tòótọ́, Káyáfà ló gba àwọn Júù nímọ̀ràn pé ó máa ṣe wọ́n láǹfààní kí ọkùnrin kan kú torí àwọn èèyàn.+ 15  Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn míì ń tẹ̀ lé Jésù.+ Àlùfáà àgbà mọ ọmọ ẹ̀yìn yẹn, ó sì bá Jésù lọ sínú àgbàlá àlùfáà àgbà, 16  àmọ́ Pétérù dúró síta níbi ilẹ̀kùn.* Torí náà, ọmọ ẹ̀yìn kejì, tí àlùfáà àgbà mọ̀, jáde lọ bá aṣọ́nà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé. 17  Ìránṣẹ́bìnrin tó jẹ́ aṣọ́nà wá sọ fún Pétérù pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yìí ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ó sọ pé: “Rárá o.”+ 18  Àwọn ẹrú àti àwọn òṣìṣẹ́ dúró yí ká iná èédú tí wọ́n dá, torí pé òtútù mú, wọ́n sì ń yáná. Pétérù náà dúró síbẹ̀, ó sì ń yáná. 19  Torí náà, olórí àlùfáà bi Jésù léèrè nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. 20  Jésù dá a lóhùn pé: “Mo ti bá ayé sọ̀rọ̀ ní gbangba. Gbogbo ìgbà ni mò ń kọ́ni nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì,+ níbi tí gbogbo àwọn Júù ń kóra jọ sí; mi ò sì sọ ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀. 21  Kí ló dé tí ò ń bi mí? Bi àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn. Wò ó! Àwọn yìí mọ ohun tí mo sọ.” 22  Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tó dúró nítòsí gbá Jésù létí,+ ó sì sọ pé: “Ṣé bí o ṣe máa dá olórí àlùfáà lóhùn nìyẹn?” 23  Jésù dá a lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ ohun tí kò tọ́ ni mo sọ, jẹ́rìí nípa* ohun tí kò tọ́ náà; àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tó tọ́ ni mo sọ, kí ló dé tí o fi gbá mi?” 24  Ánásì wá dè é, ó sì ní kí wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Káyáfà àlùfáà àgbà.+ 25  Símónì Pétérù wà lórí ìdúró níbẹ̀, ó ń yáná. Wọ́n wá sọ fún un pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ó sẹ́, ó sì sọ pé: “Rárá o.”+ 26  Ọ̀kan lára àwọn ẹrú àlùfáà àgbà, tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí ọkùnrin tí Pétérù gé etí rẹ̀ dà nù+ sọ pé: “Mo rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọgbà, àbí mi ò rí ọ?” 27  Àmọ́ Pétérù tún sẹ́, àkùkọ sì kọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+ 28  Wọ́n wá mú Jésù látọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ilé gómìnà.+ Àárọ̀ kùtù ni. Àmọ́ àwọn fúnra wọn ò wọnú ilé gómìnà, kí wọ́n má bàa sọ ara wọn di aláìmọ́,+ kí wọ́n lè jẹ Ìrékọjá. 29  Torí náà, Pílátù jáde wá bá wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀sùn wo lẹ fi kan ọkùnrin yìí?” 30  Wọ́n dáhùn pé: “Ká ní ọkùnrin yìí ò ṣe ohun tí kò dáa ni,* a ò ní fà á lé ọ lọ́wọ́.” 31  Pílátù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ sì fi òfin yín dá a lẹ́jọ́.”+ Àwọn Júù sọ fún un pé: “Kò bófin mu fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”+ 32  Èyí jẹ́ torí kí ọ̀rọ̀ Jésù lè ṣẹ, èyí tó sọ kí wọ́n lè mọ irú ikú tí òun máa tó kú.+ 33  Torí náà, Pílátù tún wọnú ilé gómìnà, ó pe Jésù, ó sì bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?”+ 34  Jésù dáhùn pé: “Ṣé ìwọ lo ronú ìbéèrè yìí fúnra rẹ, àbí àwọn míì ló sọ ọ̀rọ̀ mi fún ọ?” 35  Pílátù dáhùn pé: “Èmi kì í ṣe Júù, àbí Júù ni mí? Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ àti àwọn olórí àlùfáà ló fà ọ́ lé mi lọ́wọ́. Kí lo ṣe?” 36  Jésù dáhùn pé:+ “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.+ Ká ní Ìjọba mi jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ì bá ti jà kí wọ́n má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́.+ Àmọ́, bó ṣe rí yìí, Ìjọba mi ò wá láti orísun yìí.” 37  Pílátù wá bi í pé: “Ó dáa, ṣé ọba ni ọ́?” Jésù dáhùn pé: “Ìwọ fúnra rẹ ń sọ pé ọba ni mí.+ Torí èyí la ṣe bí mi, torí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.+ Gbogbo ẹni tó bá fara mọ́ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.” 38  Pílátù wá bí i pé: “Kí ni òtítọ́?” Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó tún jáde lọ bá àwọn Júù, ó sì sọ fún wọn pé: “Mi ò rí i pé ó jẹ̀bi kankan.+ 39  Àmọ́, ẹ ní àṣà kan, pé kí n máa tú ẹnì kan sílẹ̀ fún yín nígbà Ìrékọjá.+ Torí náà, ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?” 40  Wọ́n bá tún kígbe pé: “A ò fẹ́ ọkùnrin yìí, Bárábà la fẹ́!” Àmọ́ olè ni Bárábà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ojú ọ̀gbàrá Kídírónì ti ìgbà òtútù.”
Tàbí “fàṣẹ ọba mú.”
Tàbí “àbáwọlé.”
Tàbí “jẹ́rìí sí.”
Tàbí “kì í ṣe ọ̀daràn ni.”