Àkọsílẹ̀ Jòhánù 21:1-25

  • Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (1-14)

  • Pétérù fi dá Jésù lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ (15-19)

    • “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké” (17)

  • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù nífẹ̀ẹ́ (20-23)

  • Ọ̀rọ̀ ìparí (24, 25)

21  Lẹ́yìn èyí, Jésù tún fara han* àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní òkun Tìbéríà. Bó ṣe fara hàn wọ́n nìyí.  Símónì Pétérù, Tọ́másì (tí wọ́n ń pè ní Ìbejì),+ Nàtáníẹ́lì+ láti Kánà ti Gálílì, àwọn ọmọ Sébédè+ àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì míì jọ wà níbì kan náà.  Símónì Pétérù sọ fún wọn pé: “Mò ń lọ pẹja.” Wọ́n sọ fún un pé: “A máa tẹ̀ lé ọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọnú ọkọ̀ ojú omi, àmọ́ wọn ò rí nǹkan kan mú ní òru yẹn.+  Àmọ́ bí ilẹ̀ ṣe ń mọ́ bọ̀, Jésù dúró sí etíkun, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò mọ̀ pé Jésù ni.+  Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ ò ní nǹkan* tí ẹ máa jẹ, àbí ẹ ní?” Wọ́n dáhùn pé: “Rárá o!”  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ju àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ sì máa rí díẹ̀.” Torí náà, wọ́n jù ú, àmọ́ wọn ò lè fà á wọlé torí ẹja tí wọ́n kó pọ̀.+  Ni ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù nífẹ̀ẹ́+ bá sọ fún Pétérù pé: “Olúwa ni!” Bí Símónì Pétérù ṣe gbọ́ pé Olúwa ni, ó wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,* torí pé ìhòòhò ló wà,* ó sì bẹ́ sínú òkun.  Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù wọ ọkọ̀ ojú omi kékeré náà wá, wọ́n ń fa àwọ̀n tí ẹja kún inú rẹ̀, torí pé wọn ò jìnnà sí ilẹ̀, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ẹsẹ̀ bàtà* péré ni sórí ilẹ̀.  Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹja lórí iná èédú níbẹ̀, wọ́n sì rí búrẹ́dì. 10  Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ mú díẹ̀ wá lára ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa.” 11  Torí náà, Símónì Pétérù wọnú ọkọ̀, ó sì fa àwọ̀n tí ẹja ńlá kún inú rẹ̀ wá sórí ilẹ̀, ọgọ́rùn-ún kan àti mẹ́tàléláàádọ́ta (153) làwọn ẹja náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó pọ̀ gan-an, àwọ̀n náà ò ya. 12  Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ wá jẹ oúnjẹ àárọ̀.” Ìkankan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ò nígboyà láti bi í pé: “Ta ni ọ́?” torí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni. 13  Jésù wá, ó mú búrẹ́dì náà, ó sì fún wọn, ó ṣe bẹ́ẹ̀ náà sí ẹja. 14  Ìgbà kẹta nìyí+ tí Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn tó jíǹde. 15  Lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ àárọ̀ tán, Jésù sọ fún Símónì Pétérù pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ?” Ó sọ fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Ó sọ fún un pé: “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi.”+ 16  Ó tún sọ fún un lẹ́ẹ̀kejì pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o nífẹ̀ẹ́ mi?” Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Ó sọ fún un pé: “Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.”+ 17  Ó sọ fún un lẹ́ẹ̀kẹta pé: “Símónì ọmọ Jòhánù, ṣé o ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi?” Ẹ̀dùn ọkàn bá Pétérù torí ó bi í lẹ́ẹ̀kẹta pé: “Ṣé o ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi?” Torí náà, ó sọ fún un pé: “Olúwa, o mọ ohun gbogbo; o mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọ.” Jésù sọ fún un pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.+ 18  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́, o máa ń wọ aṣọ fúnra rẹ, o sì máa ń rìn káàkiri lọ síbi tí o fẹ́. Àmọ́ tí o bá darúgbó, o máa na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíì máa wọ aṣọ fún ọ, ó sì máa gbé ọ lọ síbi tó ò fẹ́.” 19  Ó sọ èyí láti fi tọ́ka sí irú ikú tó máa fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”+ 20  Pétérù yíjú pa dà, ó sì rí ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù nífẹ̀ẹ́+ tó ń tẹ̀ lé e, òun ló fẹ̀yìn ti àyà rẹ̀ níbi oúnjẹ alẹ́, tó sì sọ pé: “Olúwa, ta ló máa dà ọ́?” 21  Torí náà, nígbà tó tajú kán rí i, Pétérù sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ẹni yìí ńkọ́?” 22  Jésù sọ fún un pé: “Kí ló kàn ọ́ tí mo bá fẹ́ kó wà títí màá fi dé? Ìwọ ṣáà máa tẹ̀ lé mi.” 23  Torí náà, ọ̀rọ̀ yìí tàn kálẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin pé ọmọ ẹ̀yìn yẹn ò ní kú. Àmọ́, Jésù ò sọ fún un pé kò ní kú, ohun tó sọ ni pé: “Kí ló kàn ọ́ tí mo bá fẹ́ kó wà títí màá fi dé?” 24  Ọmọ ẹ̀yìn yìí+ ló jẹ́rìí yìí nípa àwọn nǹkan yìí, tó sì kọ àwọn nǹkan yìí, a sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀. 25  Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan míì wà tí Jésù ṣe, tó jẹ́ pé, tí a bá kọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn, mo wò ó pé, ayé pàápàá ò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ ọ́ sí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “fi ara rẹ̀ hàn kedere fún.”
Tàbí “ẹja kankan.”
Tàbí “fi aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ di ara rẹ̀ lámùrè.”
Tàbí “aṣọ jáńpé ló wà lára rẹ̀.”
Nǹkan bíi 90 mítà. Ní Grk., “nǹkan bíi 200 ìgbọ̀nwọ́.” Wo Àfikún B14.