Àkọsílẹ̀ Jòhánù 2:1-25

  • Ìgbéyàwó ní Kánà; omi di wáìnì (1-12)

  • Jésù fọ tẹ́ńpìlì mọ́ (13-22)

  • Jésù mọ ohun tó wà nínú èèyàn (23-25)

2  Ní ọjọ́ kẹta, àsè ìgbéyàwó kan wáyé ní Kánà ti Gálílì, ìyá Jésù sì wà níbẹ̀.  Wọ́n pe Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà síbi àsè ìgbéyàwó náà.  Nígbà tí wáìnì ò tó mọ́, ìyá Jésù sọ fún un pé: “Wọn ò ní wáìnì kankan.”  Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún un pé: “Obìnrin yìí, báwo ni ìyẹn ṣe kan èmi àti ìwọ?* Wákàtí mi ò tíì tó.”  Ìyá rẹ̀ sọ fún àwọn tó ń pín jíjẹ mímu pé: “Ẹ ṣe ohunkóhun tó bá ní kí ẹ ṣe.”  Ìṣà omi mẹ́fà tí wọ́n fi òkúta ṣe wà níbẹ̀, bí òfin ìwẹ̀mọ́ àwọn Júù+ ṣe sọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan lè gba òṣùwọ̀n méjì tàbí mẹ́ta tó jẹ́ ti nǹkan olómi.*  Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìṣà náà.” Torí náà, wọ́n pọn omi kún un dé ẹnu.  Ó wá sọ fún wọn pé: “Ó yá, ẹ bu díẹ̀, kí ẹ sì gbé e lọ fún alága àsè.” Ni wọ́n bá gbé e lọ.  Nígbà tí alága àsè tọ́ omi tí Jésù sọ di wáìnì wò, láìmọ ibi tó ti wá (bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ tó bu omi náà mọ̀), alága àsè pe ọkọ ìyàwó, 10  ó sì sọ fún un pé: “Wáìnì tó dáa ni gbogbo èèyàn máa ń kọ́kọ́ gbé jáde, tí àwọn èèyàn bá sì ti yó, wọ́n á gbé gbàrọgùdù jáde. Wáìnì tó dáa lo gbé pa mọ́ títí di àkókò yìí.” 11  Jésù ṣe èyí ní Kánà ti Gálílì láti fi bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀, ó sì mú kí ògo rẹ̀ hàn kedere,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. 12  Lẹ́yìn náà, òun, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀+ àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí Kápánáúmù,+ àmọ́ wọn ò pẹ́ níbẹ̀. 13  Ìrékọjá+ àwọn Júù ti sún mọ́lé, Jésù sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. 14  Ó rí àwọn tó ń ta màlúù, àgùntàn àti àdàbà+ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì rí àwọn tó ń pààrọ̀ owó lórí ìjókòó wọn. 15  Torí náà, ó fi okùn ṣe ẹgba, ó sì lé gbogbo àwọn tó ní àgùntàn àti màlúù jáde nínú tẹ́ńpìlì, ó da ẹyọ owó àwọn tó ń pààrọ̀ owó sílẹ̀, ó sì dojú àwọn tábìlì wọn dé.+ 16  Ó sọ fún àwọn tó ń ta àdàbà pé: “Ẹ kó àwọn nǹkan yìí kúrò níbí! Ẹ yéé sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!”*+ 17  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé a ti kọ ọ́ pé: “Ìtara ilé rẹ máa gbà mí lọ́kàn.”+ 18  Torí náà, àwọn Júù sọ fún un pé: “Àmì wo lo máa fi hàn wá,+ torí o ti ń ṣe àwọn nǹkan yìí?” 19  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ wó tẹ́ńpìlì yìí lulẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ.”+ 20  Àwọn Júù wá sọ pé: “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta (46) ni wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì yìí, ṣé ọjọ́ mẹ́ta lo máa wá fi kọ́ ọ?” 21  Àmọ́ tẹ́ńpìlì ti ara rẹ̀ ló ń sọ.+ 22  Nígbà tí a wá jí i dìde, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé ó máa ń sọ bẹ́ẹ̀,+ wọ́n sì gba ìwé mímọ́ àti ohun tí Jésù sọ gbọ́. 23  Nígbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà àjọyọ̀ Ìrékọjá, ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n rí àwọn iṣẹ́ àmì tó ń ṣe. 24  Àmọ́ Jésù ò gbára lé wọn, torí pé ó mọ gbogbo wọn, 25  kò sì nílò kí ẹnikẹ́ni jẹ́rìí nípa èèyàn, torí ó mọ ohun tó wà nínú èèyàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “Kí ló pa èmi àti ìwọ pọ̀, obìnrin?” Àkànlò èdè tí èèyàn fi ń sọ pé òun ò fara mọ́ nǹkan nìyí. Bó ṣe pè é ní “obìnrin” kò túmọ̀ sí pé kò bọ̀wọ̀ fún un.
Ó ṣeé ṣe kí òṣùwọ̀n nǹkan olómi náà jẹ́ báàtì tó jẹ́ Lítà 22 (gálọ́ọ̀nù 5.81). Wo Àfikún B14.
Tàbí “ọjà; ibi ìṣòwò.”