Àkọsílẹ̀ Jòhánù 3:1-36

  • Jésù àti Nikodémù (1-21)

    • Àtúnbí (3-8)

    • Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé (16)

  • Ẹ̀rí tí Jòhánù jẹ́ gbẹ̀yìn nípa Jésù (22-30)

  • Ẹni tó wá láti òkè (31-36)

3  Ọkùnrin kan wà tó jẹ́ Farisí, Nikodémù+ ni orúkọ rẹ̀, alákòóso àwọn Júù ni.  Ẹni yìí wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní òru,+ ó sì sọ fún un pé: “Rábì,+ a mọ̀ pé olùkọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ́, torí kò sẹ́ni tó lè ṣe àwọn iṣẹ́ àmì+ tí ò ń ṣe yìí, àfi tí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú rẹ̀.”+  Jésù dá a lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, tí a kò bá tún ẹnikẹ́ni bí,*+ kò lè rí Ìjọba Ọlọ́run.”+  Nikodémù sọ fún un pé: “Báwo ni wọ́n ṣe lè bí èèyàn nígbà tó ti dàgbà? Kò lè wọnú ikùn ìyá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, kí ìyá rẹ̀ sì bí i, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?”  Jésù dáhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, tí a kò bá bí ẹnì kan látinú omi+ àti ẹ̀mí,+ kò lè wọ Ìjọba Ọlọ́run.  Ẹran ara ni ohun tí a bí látinú ẹran ara, ẹ̀mí sì ni ohun tí a bí látinú ẹ̀mí.  Má ṣe jẹ́ kí ẹnu yà ọ́ torí mo sọ fún ọ pé: A gbọ́dọ̀ tún yín bí.  Ibi tó bá wu atẹ́gùn ló máa ń fẹ́ sí, o sì máa ń gbọ́ ìró rẹ̀, àmọ́ o ò mọ ibi tó ti wá àti ibi tó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ẹni tí a bí látinú ẹ̀mí.”+  Nikodémù fèsì pé: “Báwo ni àwọn nǹkan yìí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?” 10  Jésù dá a lóhùn pé: “Ṣebí olùkọ́ ni ọ́ ní Ísírẹ́lì, kí ló dé tí o ò mọ àwọn nǹkan yìí? 11  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, ohun tí a mọ̀ là ń sọ, ohun tí a sì rí là ń jẹ́rìí sí, àmọ́ ẹ̀yin ò gba ẹ̀rí tí a jẹ́. 12  Tí mo bá sọ àwọn nǹkan ti ayé fún yín, síbẹ̀ tí ẹ ò gbà gbọ́, báwo lẹ ṣe máa gbà gbọ́ tí mo bá sọ àwọn nǹkan ti ọ̀run fún yín? 13  Bákan náà, kò sí èèyàn kankan tó tíì gòkè lọ sọ́run+ àfi ẹni tó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run,+ ìyẹn Ọmọ èèyàn. 14  Àti pé bí Mósè ṣe gbé ejò sókè ní aginjù,+ bẹ́ẹ̀ náà la gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ èèyàn sókè,+ 15  kí gbogbo ẹni tó bá gbà á gbọ́ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 16  “Torí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni,+ kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 17  Torí Ọlọ́run ò rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé kó lè ṣèdájọ́ ayé, àmọ́ ó rán an kí ayé lè rí ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀.+ 18  A ò ní dá ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lẹ́jọ́.+ Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní ìgbàgbọ́, a ti dá a lẹ́jọ́ ná, torí pé kò ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.+ 19  Ohun tí a máa gbé ìdájọ́ kà nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ti wá sí ayé,+ àmọ́ àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, torí pé oníṣẹ́ ibi ni wọ́n. 20  Torí ẹnikẹ́ni tó bá ń hùwà burúkú kórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a má bàa dá àwọn iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́bi.* 21  Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ohun tó tọ́ máa ń wá sínú ìmọ́lẹ̀,+ ká lè fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn kedere pé ó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.” 22  Lẹ́yìn èyí, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ìgbèríko Jùdíà, ó lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi.+ 23  Àmọ́ Jòhánù náà ń ṣèrìbọmi ní Áínónì nítòsí Sálímù, torí pé omi púpọ̀ wà níbẹ̀,+ àwọn èèyàn ń wá ṣáá, ó sì ń ṣèrìbọmi fún wọn;+ 24  wọn ò tíì fi Jòhánù sẹ́wọ̀n+ nígbà yẹn. 25  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù ń bá Júù kan fa ọ̀rọ̀ ìwẹ̀mọ́. 26  Torí náà, wọ́n wá sọ́dọ̀ Jòhánù, wọ́n sì sọ fún un pé: “Rábì, ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ rẹ ní òdìkejì Jọ́dánì, ẹni tí o jẹ́rìí nípa rẹ̀,+ wò ó, ẹni yìí ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn, gbogbo èèyàn sì ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” 27  Jòhánù dá wọn lóhùn pé: “Èèyàn ò lè rí nǹkan kan gbà àfi tí a bá fún un láti ọ̀run. 28  Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí sí i pé mo sọ pé, ‘Èmi kọ́ ni Kristi,+ àmọ́ a ti rán mi jáde ṣáájú ẹni yẹn.’+ 29  Ẹnikẹ́ni tó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó.+ Àmọ́ tí ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó bá dúró, tó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, inú rẹ̀ máa dùn gan-an torí ohùn ọkọ ìyàwó. Torí náà, ayọ̀ mi ti kún rẹ́rẹ́. 30  Ẹni yẹn gbọ́dọ̀ máa pọ̀ sí i, àmọ́ èmi gbọ́dọ̀ máa dín kù.” 31  Ẹni tó wá láti òkè+ ga ju gbogbo àwọn yòókù lọ. Ẹni tó wá láti ayé, ará ayé ni, àwọn nǹkan ti ayé ló sì ń sọ. Ẹni tó wá láti ọ̀run ga ju gbogbo àwọn yòókù lọ.+ 32  Ó ń jẹ́rìí sí ohun tó ti rí, tó sì ti gbọ́,+ àmọ́ èèyàn kankan ò gba ẹ̀rí rẹ̀.+ 33  Ẹnikẹ́ni tó bá gba ẹ̀rí rẹ̀ ti gbé èdìdì rẹ̀ lé e pé* olóòótọ́ ni Ọlọ́run.+ 34  Torí ẹni tí Ọlọ́run rán ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ torí pé Òun kì í fúnni ní ẹ̀mí tí kò pọ̀ tó.* 35  Baba nífẹ̀ẹ́ Ọmọ,+ ó sì ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.+ 36  Ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun;+ ẹni tó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè,+ àmọ́ ìbínú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “bí ẹnikẹ́ni láti òkè.”
Tàbí “tú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ fó.”
Tàbí “rí i dájú pé.”
Tàbí “kì í díwọ̀n ẹ̀mí fúnni.”