Àkọsílẹ̀ Jòhánù 7:1-52

  • Jésù lọ síbi Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn (1-13)

  • Jésù ń kọ́ni níbi àjọyọ̀ náà (14-24)

  • Oríṣiríṣi ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nípa Kristi (25-52)

7  Lẹ́yìn náà, Jésù ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ káàkiri* Gálílì, kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ní Jùdíà, torí àwọn Júù ń wá bí wọ́n á ṣe pa á.+  Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn*+ tí àwọn Júù máa ń ṣe ti sún mọ́lé.  Torí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀+ sọ fún un pé: “Kúrò níbí, kí o sì lọ sí Jùdíà, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ náà lè rí àwọn iṣẹ́ tí ò ń ṣe.  Torí kò sí ẹni tí á máa ṣe ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀ tó bá fẹ́ kí wọ́n mọ òun ní gbangba. Tí o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, fi ara rẹ han ayé.”  Ní tòótọ́, àwọn arákùnrin rẹ̀ ò gbà á gbọ́.+  Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Àkókò mi ò tíì tó,+ àmọ́ gbogbo ìgbà ni àkókò wọ̀ fún yín.  Ayé ò ní ìdí kankan láti kórìíra yín, àmọ́ ó kórìíra mi, torí mò ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú.+  Ẹ̀yin ẹ máa lọ síbi àjọyọ̀ náà; kò tíì yá fún mi láti lọ síbi àjọyọ̀ yìí, torí àkókò mi ò tíì tó ní kíkún.”+  Torí náà, lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí fún wọn, ó dúró sí Gálílì. 10  Àmọ́ nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ ti lọ síbi àjọyọ̀ náà, òun náà wá lọ, àmọ́ kò lọ ní gbangba, ṣe ló yọ́ lọ. 11  Àwọn Júù wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá a níbi àjọyọ̀ náà, wọ́n ń sọ pé: “Ọkùnrin yẹn dà?” 12  Ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nípa rẹ̀ láàárín èrò. Àwọn kan á sọ pé: “Èèyàn dáadáa ni.” Àwọn míì á sọ pé: “Irọ́ ni. Ṣe ló ń tan àwọn èèyàn jẹ.”+ 13  Àmọ́ kò sí ẹni tó lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba torí wọ́n ń bẹ̀rù àwọn Júù.+ 14  Nígbà tí wọ́n bá àjọyọ̀ náà dé ìdajì, Jésù gòkè lọ sínú tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni. 15  Ẹnu ya àwọn Júù, wọ́n sọ pé: “Báwo ni ọkùnrin yìí ṣe mọ Ìwé Mímọ́*+ tó báyìí láìjẹ́ pé ó lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́?”*+ 16  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, àmọ́ ó jẹ́ ti ẹni tó rán mi.+ 17  Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, ó máa mọ̀ bóyá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ náà ti wá+ àbí èrò ara mi ni mò ń sọ. 18  Ẹnikẹ́ni tó bá ń sọ èrò ara rẹ̀, ògo ara rẹ̀ ló ń wá; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń wá ògo ẹni tó rán an,+ olóòótọ́ ni ẹni yìí, kò sì sí àìṣòdodo kankan nínú rẹ̀. 19  Mósè fún yín ní Òfin,+ àbí kò fún yín? Àmọ́ kò sí ìkankan nínú yín tó ń ṣègbọràn sí Òfin náà. Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa pa mí?”+ 20  Àwọn èèyàn dáhùn pé: “Ẹlẹ́mìí èṣù ni ọ́. Ta ló fẹ́ pa ọ́?” 21  Jésù sọ fún wọn pé: “Iṣẹ́ kan ni mo ṣe tó ń ya gbogbo yín lẹ́nu. 22  Ìdí nìyí tí Mósè fi sọ pé kí ẹ máa dádọ̀dọ́*+—kì í ṣe pé ó wá látọ̀dọ̀ Mósè, àmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá ló ti wá+—ẹ sì ń dádọ̀dọ́ ọkùnrin ní sábáàtì. 23  Tí ọkùnrin kan bá dádọ̀dọ́ ní sábáàtì torí kó má bàa rú Òfin Mósè, ṣé ẹ wá ń bínú gidigidi sí mi ni, torí pé mo wo ọkùnrin kan sàn pátápátá ní sábáàtì?+ 24  Ẹ yéé fi ìrísí òde ṣe ìdájọ́, àmọ́ ẹ máa dá ẹjọ́ òdodo.”+ 25  Àwọn kan lára àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ọkùnrin tí wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe fẹ́ pa nìyí, àbí òun kọ́?+ 26  Ẹ wò ó! òun ló ń sọ̀rọ̀ ní gbangba yìí, wọn ò sì sọ nǹkan kan sí i. Ṣé ó ti dá àwọn alákòóso lójú pé Kristi nìyí ni? 27  Ní tiwa, a mọ ibi tí ọkùnrin yìí ti wá;+ àmọ́ tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tó máa mọ ibi tó ti wá.” 28  Bí Jésù ṣe ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì, ó gbóhùn sókè, ó ní: “Ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Èmi kọ́ ni mo rán ara mi,+ àmọ́ ẹni gidi ni Ẹni tó rán mi, ẹ ò sì mọ̀ ọ́n.+ 29  Èmi mọ̀ ọ́n,+ torí pé aṣojú látọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mí, Ẹni yẹn ló sì rán mi jáde.” 30  Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa mú un,+ àmọ́ ẹnì kankan ò fọwọ́ kàn án, torí pé wákàtí rẹ̀ ò tíì tó.+ 31  Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn náà gbà á gbọ́,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Tí Kristi bá dé, ṣé ó máa ṣe iṣẹ́ àmì tó ju èyí tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ ni?” 32  Àwọn Farisí gbọ́ tí àwọn èrò ń sọ àwọn nǹkan yìí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí sì rán àwọn òṣìṣẹ́ pé kí wọ́n lọ mú un.* 33  Jésù wá sọ pé: “Màá ṣì wà pẹ̀lú yín fúngbà díẹ̀ sí i, kí n tó lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó rán mi.+ 34  Ẹ máa wá mi, àmọ́ ẹ ò ní rí mi, ẹ ò sì ní lè wá sí ibi tí mo wà.”+ 35  Torí náà, àwọn Júù sọ láàárín ara wọn pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí fẹ́ lọ, tí a ò fi ní rí i? Kì í ṣe ọ̀dọ̀ àwọn Júù tó fọ́n ká sáàárín àwọn Gíríìkì ló fẹ́ lọ, kó sì máa kọ́ àwọn Gíríìkì, àbí ohun tó fẹ́ ṣe nìyẹn ni? 36  Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé, ‘Ẹ máa wá mi, àmọ́ ẹ ò ní rí mi, ẹ ò sì ní lè wá sí ibi tí mo wà’?” 37  Ní ọjọ́ tó kẹ́yìn, ọjọ́ ńlá àjọyọ̀ náà,+ Jésù dìde, ó sì gbóhùn sókè, ó ní: “Tí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kó wá sọ́dọ̀ mi, kó sì mu.+ 38  Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ìwé mímọ́ ṣe sọ pé: ‘Láti inú rẹ̀ lọ́hùn-ún, omi ìyè máa ṣàn jáde.’”+ 39  Àmọ́ ó sọ èyí nípa ẹ̀mí tí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ máa tó gbà, torí kò tíì sí ẹ̀mí nígbà yẹn,+ torí pé a ò tíì ṣe Jésù lógo.+ 40  Àwọn kan láàárín èrò tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Wòlíì náà nìyí lóòótọ́.”+ 41  Àwọn míì ń sọ pé: “Kristi náà nìyí.”+ Àmọ́ àwọn kan ń sọ pé: “Gálílì kọ́ ni Kristi ti máa jáde wá, àbí ibẹ̀ ni?+ 42  Ṣebí ìwé mímọ́ sọ pé látinú ọmọ Dáfídì ni Kristi ti máa wá,+ ó sì máa wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ abúlé tí Dáfídì wà tẹ́lẹ̀?”+ 43  Àwọn èrò náà wá pínyà síra wọn nítorí rẹ̀. 44  Àwọn kan nínú wọn tiẹ̀ fẹ́ mú un,* àmọ́ ẹnì kankan ò fọwọ́ kàn án. 45  Àwọn òṣìṣẹ́ náà wá pa dà lọ bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí, wọ́n sì bi àwọn òṣìṣẹ́ náà pé: “Kí ló dé tí ẹ ò mú un wá?” 46  Àwọn òṣìṣẹ́ náà fèsì pé: “Èèyàn kankan ò sọ̀rọ̀ báyìí rí.”+ 47  Àwọn Farisí náà wá sọ pé: “Àbí wọ́n ti tan ẹ̀yin náà jẹ ni? 48  Kò sí ìkankan nínú àwọn alákòóso tàbí àwọn Farisí tó gbà á gbọ́, àbí ó wà?+ 49  Àmọ́ ẹni ègún ni àwọn èèyàn yìí tí wọn ò mọ Òfin.” 50  Nikodémù, ẹni tó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, tó sì wà lára wọn, sọ fún wọn pé: 51  “Òfin wa kì í ṣèdájọ́ èèyàn láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ gbọ́ tẹnu rẹ̀, kó sì mọ ohun tó ń ṣe, àbí ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?”+ 52  Wọ́n dá a lóhùn pé: “Kì í ṣe Gálílì ni ìwọ náà ti wá, àbí ibẹ̀ ni? Wádìí, kí o sì rí i pé a ò ní mú wòlíì kankan wá láti Gálílì.”*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “rìn káàkiri.”
Tàbí “Àwọn Àtíbàbà.”
Ní Grk., “àwọn àkọsílẹ̀.”
Ìyẹn, ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì.
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”
Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”
Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ kan tó ṣeé gbára lé kò fi ẹsẹ 53 sí orí 8, ẹsẹ 11 kún un.