Àkọsílẹ̀ Jòhánù 8:12-59

  • Baba ń jẹ́rìí nípa Jésù (12-30)

    • Jésù ni “ìmọ́lẹ̀ ayé” (12)

  • Àwọn ọmọ Ábúráhámù (31-41)

    • ‘Òtítọ́ máa sọ yín di òmìnira’ (32)

  • Àwọn ọmọ Èṣù (42-47)

  • Jésù àti Ábúráhámù (48-59)

8  12  Jésù tún sọ fún wọn pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.+ Ó dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá ń tẹ̀ lé mi kò ní rìn nínú òkùnkùn, àmọ́ ó máa ní ìmọ́lẹ̀+ ìyè.” 13  Torí náà, àwọn Farisí sọ fún un pé: “Ò ń jẹ́rìí nípa ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òótọ́.” 14  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Tí mo bá tiẹ̀ jẹ́rìí nípa ara mi, òótọ́ ni ẹ̀rí mi, torí mo mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mò ń lọ.+ Àmọ́ ẹ̀yin ò mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mò ń lọ. 15  Ẹ̀ ń dáni lẹ́jọ́ lọ́nà ti ẹran ara;*+ èmi kì í dá èèyàn kankan lẹ́jọ́. 16  Síbẹ̀, tí mo bá tiẹ̀ dáni lẹ́jọ́, òótọ́ ni ìdájọ́ mi, torí mi ò dá wà, àmọ́ Baba tó rán mi wà pẹ̀lú mi.+ 17  Bákan náà, a kọ ọ́ sínú Òfin yín pé: ‘Òótọ́ ni ẹ̀rí ẹni méjì.’+ 18  Mò ń jẹ́rìí nípa ara mi, Baba tó rán mi sì ń jẹ́rìí nípa mi.”+ 19  Wọ́n wá bi í pé: “Ibo ni Baba rẹ wà?” Jésù dáhùn pé: “Ẹ ò mọ̀ mí, ẹ ò sì mọ Baba mi.+ Ká ní ẹ mọ̀ mí ni, ẹ̀ bá mọ Baba mi náà.”+ 20  Ibi ìṣúra+ ló ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́ kò sẹ́ni tó mú un, torí wákàtí rẹ̀ ò tíì tó.+ 21  Ó tún sọ fún wọn pé: “Mò ń lọ, ẹ sì máa wá mi, síbẹ̀ inú ẹ̀ṣẹ̀ yín lẹ máa kú sí.+ Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ.”+ 22  Àwọn Júù wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Kò ní pa ara rẹ̀, àbí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀? Torí ó sọ pé, ‘Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ.’” 23  Ó wá sọ fún wọn pé: “Ìsàlẹ̀ ni ẹ̀yin ti wá; èmi wá láti òkè.+ Inú ayé yìí lẹ ti wá; èmi ò wá látinú ayé yìí. 24  Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún yín pé: Inú ẹ̀ṣẹ̀ yín lẹ máa kú sí. Torí tí ẹ ò bá gbà gbọ́ pé èmi ni ẹni náà, inú ẹ̀ṣẹ̀ yín lẹ máa kú sí.” 25  Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “Ta ni ọ́?” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Kí ni mo tiẹ̀ ń bá yín sọ̀rọ̀ fún? 26  Mo ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo fẹ́ sọ nípa yín, tí mo sì fẹ́ ṣèdájọ́ rẹ̀. Ní tòótọ́, olóòótọ́ ni Ẹni tó rán mi, àwọn ohun tí mo sì gbọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mò ń sọ nínú ayé.”+ 27  Wọn ò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa Baba ló ń sọ fún wọn. 28  Torí náà, Jésù sọ pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti gbé Ọmọ èèyàn sókè,+ ìgbà yẹn lẹ máa wá mọ̀ pé èmi ni+ àti pé mi ò dá ṣe nǹkan kan lérò ara mi;+ àmọ́ bí Baba ṣe kọ́ mi gẹ́lẹ́ ni mò ń sọ àwọn nǹkan yìí. 29  Ẹni tó rán mi wà pẹ̀lú mi; kò pa mí tì lémi nìkan, torí gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe ohun tó wù ú.”+ 30  Bó ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. 31  Jésù wá sọ fún àwọn Júù tó gbà á gbọ́ pé: “Tí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín lóòótọ́, 32  ẹ ó mọ òtítọ́,+ òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.”+ 33  Wọ́n sọ fún un pé: “Ọmọ Ábúráhámù ni wá, a ò sì ṣe ẹrú ẹnikẹ́ni rí. Kí ló dé tí o wá sọ pé, ‘Ẹ máa di òmìnira’?” 34  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀+ ni gbogbo ẹni tó bá ń dẹ́ṣẹ̀. 35  Bákan náà, ẹrú kì í wà nínú ilé títí láé, àmọ́ ọmọ máa ń wà níbẹ̀ títí láé. 36  Torí náà, tí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ máa di òmìnira lóòótọ́. 37  Mo mọ̀ pé ọmọ Ábúráhámù ni yín. Àmọ́ ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa pa mí, torí pé ọ̀rọ̀ mi ò ṣe yín láǹfààní kankan. 38  Mò ń sọ àwọn ohun tí mo ti rí nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ Baba mi,+ àmọ́ ohun tí ẹ̀yin gbọ́ látọ̀dọ̀ bàbá yín lẹ̀ ń ṣe.” 39  Wọ́n dá a lóhùn pé: “Ábúráhámù ni bàbá wa.” Jésù sọ fún wọn pé: “Tó bá jẹ́ pé ọmọ Ábúráhámù ni yín,+ àwọn iṣẹ́ Ábúráhámù lẹ̀ bá máa ṣe. 40  Àmọ́ ní báyìí, ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa pa mí, èmi tí mo sọ òtítọ́ tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ fún yín. Ábúráhámù ò ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. 41  Àwọn iṣẹ́ bàbá yín lẹ̀ ń ṣe.” Wọ́n sọ fún un pé: “Ìṣekúṣe* kọ́ ni wọ́n fi bí wa; Baba kan la ní, Ọlọ́run ni.” 42  Jésù sọ fún wọn pé: “Tó bá jẹ́ Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ mi,+ torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo ti wá, mo sì wà níbí. Èmi kọ́ ni mo rán ara mi wá, àmọ́ Ẹni yẹn ló rán mi.+ 43  Kí ló dé tí ohun tí mò ń sọ ò yé yín? Torí pé ẹ ò lè fetí sí ọ̀rọ̀ mi. 44  Ọ̀dọ̀ Èṣù bàbá yín lẹ ti wá, ẹ sì fẹ́ ṣe àwọn ìfẹ́ ọkàn bàbá yín.+ Apààyàn ni ẹni yẹn nígbà tó bẹ̀rẹ̀,*+ kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, torí pé òtítọ́ ò sí nínú rẹ̀. Tó bá ń pa irọ́, ṣe ló ń sọ irú ẹni tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́, torí pé òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́.+ 45  Àmọ́ torí pé èmi ń sọ òtítọ́, ẹ ò gbà mí gbọ́. 46  Èwo nínú yín ló dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Tó bá jẹ́ òtítọ́ ni mò ń sọ, kí ló dé tí ẹ ò gbà mí gbọ́? 47  Ẹni tó bá wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run máa ń fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.+ Ìdí nìyí tí ẹ ò fi fetí sílẹ̀, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ lẹ ti wá.”+ 48  Àwọn Júù dá a lóhùn pé: “Ṣebí a ti sọ pé, ‘Ará Samáríà ni ọ́,+ ẹlẹ́mìí èṣù sì ni ọ́’?”+ 49  Jésù fèsì pé: “Mi ò ní ẹ̀mí èṣù, àmọ́ mò ń bọlá fún Baba mi, ẹ̀yin sì ń kàn mí lábùkù. 50  Ṣùgbọ́n mi ò wá ògo fún ara mi;+ Ẹnì kan wà tó ń wá a, tó sì ń ṣèdájọ́. 51  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹnikẹ́ni bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ mi, kò ní rí ikú láé.”+ 52  Àwọn Júù sọ fún un pé: “A ti wá mọ̀ báyìí pé ẹlẹ́mìí èṣù ni ọ́. Ábúráhámù kú, àwọn wòlíì náà kú, àmọ́ ìwọ sọ pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ mi, kò ní tọ́ ikú wò láé.’ 53  O ò tóbi ju Ábúráhámù bàbá wa tó kú lọ, àbí o tóbi jù ú lọ? Àwọn wòlíì náà kú. Ta lò ń fi ara rẹ pè?” 54  Jésù dáhùn pé: “Tí mo bá ń ṣe ara mi lógo, ògo mi ò já mọ́ nǹkan kan. Baba mi ló ń ṣe mí lógo,+ ẹni tí ẹ sọ pé ó jẹ́ Ọlọ́run yín. 55  Síbẹ̀, ẹ ò tíì mọ̀ ọ́n,+ àmọ́ èmi mọ̀ ọ́n.+ Tí mo bá sì sọ pé mi ò mọ̀ ọ́n, ṣe ni màá dà bíi yín, ẹ̀yin òpùrọ́. Àmọ́ mo mọ̀ ọ́n, mo sì ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀. 56  Ábúráhámù bàbá yín yọ̀ gidigidi bó ṣe ń retí láti rí ọjọ́ mi, ó rí i, ó sì yọ̀.”+ 57  Àwọn Júù wá sọ fún un pé: “O ò tíì tó ẹni àádọ́ta (50) ọdún, síbẹ̀ o ti rí Ábúráhámù, àbí?” 58  Jésù sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kí Ábúráhámù tó wà, èmi ti wà.”+ 59  Ni wọ́n bá ṣa òkúta kí wọ́n lè sọ ọ́ lù ú, àmọ́ Jésù fara pa mọ́, ó sì kúrò nínú tẹ́ńpìlì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “lọ́nà ti èèyàn.”
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “láti ìbẹ̀rẹ̀.”