Àkọsílẹ̀ Jòhánù 5:1-47

  • Ó wo ọkùnrin kan sàn ní Bẹtisátà (1-18)

  • Jésù gba àṣẹ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ (19-24)

  • Àwọn òkú máa gbọ́ ohùn Jésù (25-30)

  • Àwọn ẹ̀rí nípa Jésù (31-47)

5  Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, àjọyọ̀ kan + tí àwọn Júù máa ń ṣe wáyé, Jésù sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù.  Adágún omi kan wà ní Jerúsálẹ́mù níbi Ibodè Àgùntàn+ tí wọ́n ń pè ní Bẹtisátà lédè Hébérù, ó ní ọ̀dẹ̀dẹ̀* márùn-ún.  Inú ibẹ̀ ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn aláìsàn, afọ́jú, arọ àti àwọn tó rọ lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀ dùbúlẹ̀ sí. 4 * ——  Àmọ́ ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìdínlógójì (38).  Jésù rí ọkùnrin yìí tó dùbúlẹ̀ síbẹ̀, ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tó ti ń ṣàìsàn, ó wá sọ fún ọkùnrin náà pé: “Ṣé o fẹ́ kí ara rẹ yá?”+  Ọkùnrin aláìsàn náà dá a lóhùn pé: “Ọ̀gá, mi ò lẹ́ni tó lè gbé mi sínú adágún omi náà tó bá ti rú, torí tí n bá ti ń lọ síbẹ̀, ẹlòmíì á ti sọ̀ kalẹ̀ ṣáájú mi.”  Jésù sọ fún un pé: “Dìde! Gbé ẹní* rẹ, kí o sì máa rìn.”+  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ara ọkùnrin náà yá, ó gbé ẹní* rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn. Ọjọ́ Sábáàtì ni. 10  Torí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọkùnrin tó wò sàn náà pé: “Sábáàtì nìyí, kò sì bófin mu fún ọ láti gbé ẹní* náà.”+ 11  Àmọ́ ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹni tó wò mí sàn náà ló sọ fún mi pé, ‘Gbé ẹní* rẹ, kí o sì máa rìn.’” 12  Wọ́n bi í pé: “Ta lẹni tó sọ fún ọ pé, ‘Gbé e, kí o sì máa rìn’?” 13  Àmọ́ ọkùnrin tí ara rẹ̀ ti yá náà ò mọ ẹni náà, torí Jésù ti wọ àárín àwọn èrò tó wà níbẹ̀. 14  Lẹ́yìn náà, Jésù rí i nínú tẹ́ńpìlì, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó, ara rẹ ti yá. Má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí nǹkan tó burú ju ti tẹ́lẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀ sí ọ.” 15  Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé Jésù ló wo òun sàn. 16  Torí èyí, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí Jésù, torí pé ó ń ṣe àwọn nǹkan yìí lọ́jọ́ Sábáàtì. 17  Àmọ́, ó dá wọn lóhùn pé: “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di báyìí, èmi náà ṣì ń ṣiṣẹ́.”+ 18  Ìdí nìyí tí àwọn Júù fi túbọ̀ ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á, torí kì í ṣe pé kò pa Sábáàtì mọ́ nìkan ni, àmọ́ ó tún ń pe Ọlọ́run ní Baba rẹ̀,+ ó ń sọ pé òun àti Ọlọ́run dọ́gba.+ 19  Torí náà, Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, Ọmọ ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara rẹ̀, àfi ohun tó bá rí tí Baba ń ṣe nìkan.+ Torí ohunkóhun tí Ẹni yẹn bá ṣe, àwọn nǹkan yìí ni Ọmọ náà ń ṣe lọ́nà kan náà. 20  Torí Baba ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọmọ,+ ó sì ń fi gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe hàn án, ó sì máa fi àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju èyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín.+ 21  Torí bí Baba ṣe ń jí àwọn òkú dìde gẹ́lẹ́, tó sì ń mú kí wọ́n wà láàyè,+ bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ń sọ àwọn tí òun bá fẹ́ di alààyè.+ 22  Torí Baba kì í ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni, àmọ́ ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́,+ 23  kí gbogbo ẹ̀dá lè máa bọlá fún Ọmọ bí wọ́n ṣe ń bọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá bọlá fún Ọmọ, kò bọlá fún Baba tó rán an.+ 24  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tó sì gba Ẹni tó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ a ò sì ní dá a lẹ́jọ́, àmọ́ ó ti tinú ikú bọ́ sínú ìyè.+ 25  “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn òkú máa gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọ́run, tí àwọn tó fiyè sílẹ̀ sì máa yè. 26  Torí bí Baba ṣe ní ìyè nínú ara rẹ̀,*+ bẹ́ẹ̀ náà ló yọ̀ǹda fún Ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀.+ 27  Ó sì ti fún un ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́,+ torí òun ni Ọmọ èèyàn.+ 28  Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, torí wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀,+ 29  tí wọ́n á sì jáde wá, àwọn tó ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.+ 30  Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara mi. Ohun tí mò ń gbọ́ ni mo fi ń ṣèdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi,+ torí kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mò ń wá, ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni.+ 31  “Tí èmi nìkan bá jẹ́rìí nípa ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òótọ́.+ 32  Ẹlòmíì wà tó ń jẹ́rìí nípa mi, mo sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí tó ń jẹ́ nípa mi.+ 33  Ẹ ti rán àwọn èèyàn sí Jòhánù, ó sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.+ 34  Àmọ́ mi ò gba ẹ̀rí látọ̀dọ̀ èèyàn, ṣùgbọ́n mo sọ àwọn nǹkan yìí kí ẹ lè rígbàlà. 35  Fìtílà tó ń jó, tó sì ń tàn yòò ni ọkùnrin yẹn, ó sì wù yín pé kí ẹ yọ̀ gidigidi nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ fúngbà díẹ̀.+ 36  Àmọ́ mo ní ẹ̀rí tó tóbi ju ti Jòhánù lọ, torí àwọn iṣẹ́ tí Baba mi yàn fún mi pé kí n ṣe, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí, ń jẹ́rìí sí i pé Baba ló rán mi.+ 37  Baba tó sì rán mi ti fúnra rẹ̀ jẹ́rìí nípa mi.+ Ẹ ò tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí, ẹ ò sì fojú rí bó ṣe rí,+ 38  ẹ ò sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé inú yín, torí pé ẹ ò gba ẹni tó rán gbọ́. 39  “Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́,+ torí ẹ rò pé ó máa jẹ́ kí ẹ ní ìyè àìnípẹ̀kun; àwọn yìí* gan-an ló sì ń jẹ́rìí nípa mi.+ 40  Síbẹ̀, ẹ ò fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi+ kí ẹ lè ní ìyè. 41  Èmi kì í gba ògo látọ̀dọ̀ èèyàn, 42  àmọ́ mo mọ̀ dáadáa pé ẹ ò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín. 43  Mo wá ní orúkọ Baba mi, àmọ́ ẹ ò gbà mí. Tí ẹlòmíì bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ máa gba ẹni yẹn. 44  Báwo lẹ ṣe máa gbà gbọ́, nígbà tó jẹ́ pé ẹ̀ ń gba ògo látọ̀dọ̀ ara yín, ẹ ò sì wá ògo tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ kan ṣoṣo náà? 45  Ẹ má rò pé màá fẹ̀sùn kàn yín lọ́dọ̀ Baba; ẹnì kan wà tó ń fẹ̀sùn kàn yín, Mósè ni,+ ẹni tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé. 46  Àní, tí ẹ bá gba Mósè gbọ́, ẹ máa gbà mí gbọ́, torí ó kọ̀wé nípa mi.+ 47  Àmọ́ tí ẹ ò bá gba ohun tó kọ gbọ́, báwo lẹ ṣe máa gba ohun tí mo sọ gbọ́?”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìloro.”
Tàbí “ibùsùn.”
Tàbí “ibùsùn.”
Tàbí “ibùsùn.”
Tàbí “ibùsùn.”
Tàbí “ṣe ní ẹ̀bùn ìwàláàyè nínú ara rẹ̀.”
Ìyẹn, Ìwé Mímọ́.