Àkọsílẹ̀ Jòhánù 16:1-33
16 “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kí ẹ má bàa kọsẹ̀.
2 Àwọn èèyàn máa lé yín kúrò nínú sínágọ́gù.+ Kódà, wákàtí náà ń bọ̀, nígbà tí ẹnikẹ́ni tó bá pa yín+ máa rò pé ṣe lòun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run.
3 Àmọ́ wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan yìí torí pé wọn ò tíì wá mọ Baba, wọn ò sì tíì wá mọ̀ mí.+
4 Síbẹ̀, mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kó lè jẹ́ pé tí wákàtí tí wọ́n máa ṣẹlẹ̀ bá dé, ẹ máa rántí pé mo sọ fún yín.+
“Mi ò kọ́kọ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, torí mo wà pẹ̀lú yín.
5 Àmọ́ ní báyìí, mò ń lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó rán mi;+ síbẹ̀ ìkankan nínú yín ò bi mí pé, ‘Ibo lò ń lọ?’
6 Àmọ́ torí pé mo sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, ẹ̀dùn ọkàn ti bá yín gidigidi.+
7 Síbẹ̀, òótọ́ ni mò ń sọ fún yín, torí yín ni mo ṣe ń lọ. Ìdí ni pé tí mi ò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà+ ò ní wá sọ́dọ̀ yín; àmọ́ tí mo bá lọ, màá rán an sí yín.
8 Tí ìyẹn bá sì dé, ó máa fún ayé ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀, nípa òdodo àti nípa ìdájọ́:
9 lákọ̀ọ́kọ́, nípa ẹ̀ṣẹ̀,+ torí pé wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú mi;+
10 lẹ́yìn náà, nípa òdodo, torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ ò sì ní rí mi mọ́;
11 lẹ́yìn náà, nípa ìdájọ́, torí pé a ti dá alákòóso ayé yìí lẹ́jọ́.+
12 “Mo ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo fẹ́ sọ fún yín, àmọ́ ẹ ò ní lè gbà á báyìí.
13 Àmọ́ tí ìyẹn* bá dé, ẹ̀mí òtítọ́,+ ó máa darí yín sínú gbogbo òtítọ́, torí kì í ṣe èrò ara rẹ̀ ló máa sọ, àmọ́ ohun tó gbọ́ ló máa sọ, ó sì máa kéde àwọn nǹkan tó ń bọ̀ fún yín.+
14 Ó máa yìn mí lógo,+ torí pé ó máa gbà lára ohun tó jẹ́ tèmi, ó sì máa kéde rẹ̀ fún yín.+
15 Gbogbo ohun tí Baba ní jẹ́ tèmi.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé ó máa gbà lára ohun tó jẹ́ tèmi, ó sì máa kéde rẹ̀ fún yín.
16 Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi mọ́,+ bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi.”
17 Ni àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá sọ fún ara wọn pé: “Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún wa pé, ‘Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi’ àti pé, ‘torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?”
18 Torí náà, wọ́n ń sọ pé: “Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé, ‘ní ìgbà díẹ̀ sí i’? A ò mọ ohun tó ń sọ.”
19 Jésù mọ̀ pé wọ́n fẹ́ bi òun ní ìbéèrè, torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ṣé torí mo sọ pé: ‘Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi,’ lẹ ṣe ń bi ara yín lọ́rọ̀ yìí?
20 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa sunkún, ẹ sì máa pohùn réré ẹkún, àmọ́ ayé máa yọ̀; ẹ̀dùn ọkàn máa bá yín, àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn yín máa di ayọ̀.+
21 Tí obìnrin kan bá fẹ́ bímọ, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá a torí pé wákàtí rẹ̀ ti tó, àmọ́ tó bá ti bí ọmọ náà, kò ní rántí ìpọ́njú náà mọ́ torí inú rẹ̀ máa dùn pé a ti bí èèyàn kan sí ayé.
22 Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, ẹ̀dùn ọkàn bá yín báyìí; àmọ́ màá tún rí yín, inú yín sì máa dùn,+ ẹnì kankan ò sì ní gba ayọ̀ yín mọ́ yín lọ́wọ́.
23 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ ò ní bi mí ní ìbéèrè kankan rárá. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba,+ ó máa fún yín ní orúkọ mi.+
24 Títí di báyìí, ẹ ò tíì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi. Ẹ béèrè, ẹ sì máa rí gbà, kí ayọ̀ yín lè kún rẹ́rẹ́.
25 “Àfiwé ni mo fi sọ àwọn nǹkan yìí fún yín. Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí mi ò ní lo àfiwé láti bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, àmọ́ màá sọ fún yín nípa Baba lọ́nà tó ṣe kedere.
26 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa béèrè nǹkan lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi; ohun tí mo sọ yìí ò túmọ̀ sí pé màá bá yín béèrè.
27 Torí Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi,+ ẹ sì ti gbà gbọ́ pé mo wá bí aṣojú Ọlọ́run.+
28 Mo wá bí aṣojú Baba, mo sì ti wá sí ayé. Mo ti wá ń kúrò ní ayé báyìí, mo sì ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”+
29 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé: “Wò ó! Ọ̀rọ̀ rẹ ti ṣe kedere báyìí, o ò lo àfiwé.
30 A ti wá mọ̀ báyìí pé o mọ ohun gbogbo, o ò sì nílò kí ẹnikẹ́ni bi ọ́ ní ìbéèrè. Èyí mú ká gbà gbọ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lo ti wá.”
31 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ ti gbà gbọ́ báyìí?
32 Ẹ wò ó! Wákàtí náà ń bọ̀, ní tòótọ́, ó ti dé, nígbà tí wọ́n máa tú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ká sí ilé rẹ̀, ẹ sì máa fi èmi nìkan sílẹ̀.+ Àmọ́ mi ò dá wà, torí pé Baba wà pẹ̀lú mi.+
33 Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi.+ Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ọ̀rọ̀ náà “ìyẹn” àti “ó” tó wà ní ẹsẹ 13 àti 14 ń tọ́ka sí “olùrànlọ́wọ́” tó wà ní ẹsẹ 7. Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “olùrànlọ́wọ́” (tí wọ́n ń lò fún ọkùnrin lédè Gíríìkì) bí àkànlò èdè tó ń tọ́ka sí ẹ̀mí mímọ́ bíi pé ó jẹ́ ẹnì kan. Agbára ni ẹ̀mí yìí, kì í ṣe ẹnì kan, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún un lédè Gíríìkì kò tọ́ka sí ọkùnrin tàbí obìnrin.