Àkọsílẹ̀ Jòhánù 20:1-31

  • Ibojì ṣófo (1-10)

  • Jésù fara han Màríà Magidalénì (11-18)

  • Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (19-23)

  • Tọ́másì ṣiyèméjì, àmọ́ ó pa dà dá a lójú (24-29)

  • Ìdí tí wọ́n fi kọ àkájọ ìwé yìí (30, 31)

20  Ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, Màríà Magidalénì wá síbi ibojì* náà ní àárọ̀ kùtù,+ nígbà tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, ó sì rí i pé wọ́n ti gbé òkúta náà kúrò níbi ibojì* náà.+  Ló bá sáré wá bá Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn kejì, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́ gan-an,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì,+ a ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”  Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn kejì wá gbéra lọ síbi ibojì náà.  Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ sáré, àmọ́ ọmọ ẹ̀yìn kejì yára ju Pétérù lọ, òun ló sì kọ́kọ́ dé ibojì náà.  Ó wá bẹ̀rẹ̀ wo iwájú, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀* nílẹ̀ níbẹ̀,+ àmọ́ kò wọlé.  Símónì Pétérù náà dé lẹ́yìn rẹ̀, ó sì wọnú ibojì náà. Ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ nílẹ̀ níbẹ̀.  Aṣọ tó wà ní orí rẹ̀ kò sí níbi tí aṣọ yòókù tí wọ́n fi dì í wà, àmọ́ ó dá wà níbì kan, ní kíká jọ.  Ọmọ ẹ̀yìn kejì tó kọ́kọ́ dé ibojì náà wá wọlé, ó rí i, ó sì gbà gbọ́.  Torí ìwé mímọ́ ò tíì yé wọn pé ó gbọ́dọ̀ jíǹde.+ 10  Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà pa dà sí ilé wọn. 11  Àmọ́ Màríà ò kúrò níbi tó dúró sí níta nítòsí ibojì náà, ó ń sunkún. Bó ṣe ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ wo inú ibojì náà, 12  ó sì rí áńgẹ́lì méjì+ tó wọ aṣọ funfun tí wọ́n jókòó síbi tí wọ́n tẹ́ Jésù sí tẹ́lẹ̀, ọ̀kan níbi orí, ọ̀kan níbi ẹsẹ̀. 13  Wọ́n sọ fún un pé: “Obìnrin yìí, kí ló dé tó ò ń sunkún?” Ó sọ fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa mi lọ, mi ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” 14  Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó yíjú pa dà, ó sì rí Jésù tó dúró síbẹ̀, àmọ́ kò mọ̀ pé Jésù ni.+ 15  Jésù sọ fún un pé: “Obìnrin yìí, kí ló dé tí o fi ń sunkún? Ta lò ń wá?” Obìnrin náà rò pé ẹni tó ń tọ́jú ọgbà ni, ló bá sọ fún un pé: “Ọ̀gá, tó bá jẹ́ ìwọ lo gbé e kúrò, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, màá sì gbé e lọ.” 16  Jésù sọ fún un pé: “Màríà!” Ló bá yíjú pa dà, ó sì sọ fún un ní èdè Hébérù pé: “Rábónì!” (tó túmọ̀ sí “Olùkọ́!”) 17  Jésù sọ fún un pé: “Má rọ̀ mọ́ mi mọ́, torí mi ò tíì gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba. Àmọ́ lọ bá àwọn arákùnrin mi,+ kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi+ àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi+ àti Ọlọ́run yín.’” 18  Màríà Magidalénì wá ròyìn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Mo ti rí Olúwa!” Ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó sọ fún òun.+ 19  Nígbà tí ọjọ́ ti lọ lọ́jọ́ yẹn, ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, tí ilẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn wà sì wà ní títì pa torí pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn Júù, Jésù wá, ó dúró ní àárín wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 20  Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó fi ọwọ́ rẹ̀ àti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀+ hàn wọ́n. Inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì dùn pé wọ́n rí Olúwa.+ 21  Jésù tún sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.+ Bí Baba ṣe rán mi gẹ́lẹ́+ ni èmi náà ń rán yín.”+ 22  Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó fẹ́ atẹ́gùn sí wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ẹ̀mí mímọ́.+ 23  Tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ẹnikẹ́ni, wọ́n á rí ìdáríjì; tí ẹ bá ní kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni ṣì wà, wọ́n ṣì máa wà.” 24  Àmọ́ Tọ́másì,+ ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà, tí wọ́n ń pè ní Ìbejì, kò sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí Jésù wá. 25  Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù ń sọ fún un pé: “A ti rí Olúwa!” Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Láìjẹ́ pé mo rí àpá* ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀, tí mo ki ìka mi bọ àpá ìṣó náà, tí mo sì ki ọwọ́ mi bọ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ mi ò ní gbà gbọ́ láé.” 26  Ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tún wà nínú ilé, Tọ́másì sì wà pẹ̀lú wọn. Jésù wá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ilẹ̀kùn pa, ó dúró ní àárín wọn, ó sì sọ pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 27  Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Tọ́másì pé: “Fi ìka rẹ síbí, kí o sì wo ọwọ́ mi, ki ọwọ́ rẹ bọ ẹ̀gbẹ́ mi, kí o má sì ṣiyèméjì* mọ́, àmọ́ kí o gbà gbọ́.” 28  Tọ́másì dá a lóhùn pé: “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!” 29  Jésù sọ fún un pé: “Ṣé o ti wá gbà gbọ́ torí pé o rí mi? Aláyọ̀ ni àwọn tí kò rí, síbẹ̀ tí wọ́n gbà gbọ́.” 30  Ó dájú pé Jésù tún ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì míì níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn, tí a ò kọ sínú àkájọ ìwé yìí.+ 31  Àmọ́ a kọ àwọn yìí sílẹ̀ kí ẹ lè gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, kí ẹ sì lè ní ìyè nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀ tí ẹ bá gbà gbọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “àmì.”
Ní Grk., “jẹ́ aláìnígbàgbọ́.”