Sí Àwọn Hébérù 1:1-14

  • Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ (1-4)

  • Ọmọ ju àwọn áńgẹ́lì lọ (5-14)

1  Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì lọ́pọ̀ ìgbà àti lọ́pọ̀ ọ̀nà.+  Ní báyìí, ní òpin àwọn ọjọ́ yìí, ó ti bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ+ tó yàn ṣe ajogún ohun gbogbo,+ nípasẹ̀ ẹni tó dá àwọn ètò àwọn nǹkan.*+  Ó ń gbé ògo Ọlọ́run yọ,+ òun ni àwòrán irú ẹni tó jẹ́ gẹ́lẹ́,+ ó sì ń fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó lágbára gbé ohun gbogbo ró. Lẹ́yìn tó ti wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́,+ ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọba Ọlọ́lá ní ibi gíga.+  Torí náà, ó ti wá sàn ju àwọn áńgẹ́lì lọ,+ débi pé ó ti jogún orúkọ tó lọ́lá ju tiwọn lọ.+  Bí àpẹẹrẹ, èwo nínú àwọn áńgẹ́lì ni Ọlọ́run sọ fún rí pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni mo di bàbá rẹ”?+ Tó sì tún sọ fún pé: “Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi”?+  Àmọ́ nígbà tó tún mú Àkọ́bí rẹ̀+ wá sí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, ó sọ pé: “Kí gbogbo áńgẹ́lì Ọlọ́run tẹrí ba* fún un.”  Bákan náà, ó sọ nípa àwọn áńgẹ́lì pé: “Ó dá àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mí, ó sì dá àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀*+ ní ọwọ́ iná.”+  Àmọ́, ó sọ nípa Ọmọ pé: “Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ+ títí láé àti láéláé, ọ̀pá àṣẹ Ìjọba rẹ sì jẹ́ ọ̀pá àṣẹ ìdúróṣinṣin.*  O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+ 10  Àti pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Olúwa, o fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 11  Wọ́n á ṣègbé, àmọ́ ìwọ á máa wà nìṣó; gbogbo wọn á sì gbó bí aṣọ, 12  o máa ká wọn jọ bí aṣọ àwọ̀lékè, a sì máa pààrọ̀ wọn bí aṣọ. Àmọ́ ìwọ ò yí pa dà, àwọn ọdún rẹ ò sì ní dópin láé.”+ 13  Àmọ́ èwo nínú àwọn áńgẹ́lì ló sọ nípa rẹ̀ rí pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?+ 14  Ṣebí ẹ̀mí tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́*+ ni gbogbo wọn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tó máa rí ìgbàlà?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn àsìkò.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “forí balẹ̀.”
Tàbí “ìránṣẹ́ rẹ̀ sí gbogbo èèyàn.”
Tàbí “ìdájọ́ òdodo.”
Tàbí “iṣẹ́ ìsìn gbogbo èèyàn.”