Sí Àwọn Hébérù 13:1-25

  • Ọ̀rọ̀ ìyànjú àti ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (1-25)

    • Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe aájò àlejò (2)

    • Kí ìgbéyàwó ní ọlá (4)

    • Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú (7, 17)

    • Ẹ máa rú ẹbọ ìyìn (15, 16)

13  Ẹ túbọ̀ máa ní ìfẹ́ ará.+  Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe aájò àlejò,*+ torí àwọn kan ti tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò láìmọ̀.+  Ẹ máa rántí àwọn tó wà nínú ẹ̀wọ̀n,*+ bí ẹni pé ẹ jọ wà lẹ́wọ̀n+ àti àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ, torí pé ẹ̀yin fúnra yín náà wà nínú ara.*  Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo èèyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó má sì ní ẹ̀gbin,+ torí Ọlọ́run máa dá àwọn oníṣekúṣe* àti àwọn alágbèrè lẹ́jọ́.+  Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín,+ bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.+ Torí ó ti sọ pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.”+  Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: “Jèhófà* ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”+  Ẹ máa rántí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín,+ tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, bí ẹ sì ṣe ń ṣàyẹ̀wò bí ìwà wọn ṣe rí, ẹ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn.+  Ọ̀kan náà ni Jésù Kristi lánàá, lónìí àti títí láé.  Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n fi oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ àtàwọn ẹ̀kọ́ tó ṣàjèjì ṣì yín lọ́nà, torí ó sàn kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ọkàn lókun ju oúnjẹ* lọ, èyí tí kì í ṣàǹfààní fún àwọn tó gbà lọ́kàn.+ 10  A ní pẹpẹ kan, tí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ níbi àgọ́ kò láṣẹ láti jẹ níbẹ̀.+ 11  Torí wọ́n máa ń sun ara àwọn ẹran tí àlùfáà àgbà máa ń mú ẹ̀jẹ̀ wọn wọnú ibi mímọ́ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn ibùdó.+ 12  Torí náà, Jésù náà jìyà lẹ́yìn odi* ìlú+ kó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn èèyàn di mímọ́.+ 13  Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká lọ bá a lẹ́yìn ibùdó, ká ru ẹ̀gàn tó rù,+ 14  torí a ò ní ìlú kan níbí tó ṣì máa wà, àmọ́ à ń fi gbogbo ọkàn wá èyí tó ń bọ̀.+ 15  Ẹ jẹ́ ká máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo,+ ìyẹn èso ètè wa+ tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.+ 16  Bákan náà, ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì,+ torí inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.+ 17  Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín,+ kí ẹ sì máa tẹrí ba,+ torí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí yín* bí àwọn tó máa jíhìn,+ kí wọ́n lè ṣe é tayọ̀tayọ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, torí èyí máa pa yín lára. 18  Ẹ túbọ̀ máa gbàdúrà fún wa, torí ó dá wa lójú pé a ní ẹ̀rí ọkàn rere,* bó ṣe ń wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.+ 19  Àmọ́ ní pàtàkì, mo rọ̀ yín pé kí ẹ máa gbàdúrà, kí n lè tètè pa dà sọ́dọ̀ yín. 20  Kí Ọlọ́run àlàáfíà, tó jí Jésù Olúwa wa dìde, olùṣọ́ àgùntàn ńlá+ fún àwọn àgùntàn, pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, 21  fi gbogbo ohun rere mú yín gbára dì láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣe ohun tó dáa gan-an nínú wa lójú rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi, ẹni tí ògo jẹ́ tiẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín. 22  Ẹ̀yin ará, mò ń rọ̀ yín pé kí ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí, torí lẹ́tà kúkúrú ni mo kọ sí yín. 23  Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé wọ́n ti tú Tímótì arákùnrin wa sílẹ̀. Tó bá tètè dé, a jọ máa wá nígbà tí mo bá fẹ́ wá rí yín. 24  Ẹ bá mi kí gbogbo àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín àti gbogbo àwọn ẹni mímọ́. Àwọn tó wà ní Ítálì+ kí yín. 25  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ṣe inúure sí àwọn àjèjì.”
Ní Grk., “àwọn tí a dè; àwọn tó wà nínú ìdè.”
Tàbí kó jẹ́, “bí ẹni pé ẹ jọ ń jìyà.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
Ìyẹn, àwọn òfin nípa oúnjẹ.
Tàbí “nítòsí ẹnubodè.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “aláìlábòsí.”