Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bẹ̀rù Jèhófà, Kí o Sì Pa Àwọn Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́

Bẹ̀rù Jèhófà, Kí o Sì Pa Àwọn Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́

Bẹ̀rù Jèhófà, Kí o Sì Pa Àwọn Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́

“Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—ONÍWÀÁSÙ 12:13.

1, 2. (a) Báwo ni ìbẹ̀rù ṣe lè dáàbò bò wá? (b) Kí nìdí táwọn òbí tó gbọ́n fi ń gbin ìbẹ̀rù tó dáa sọ́kàn àwọn ọmọ wọn?

 LEONARDO da Vinci sọ pé: “Bí ìgboyà ṣe máa ń fi ìwàláàyè sínú ewu gan-an ni ìbẹ̀rù ṣe máa ń dáàbò bo ìwàláàyè.” Ṣíṣàyàgbàǹgbà tàbí gbígbékútà lè máà jẹ́ kí ẹnì kan mọ̀ pé ewu ńbẹ, nígbà tó sì jẹ́ pé ńṣe ni ìbẹ̀rù yóò máa rán onítọ̀hún létí pé kí ó ṣọ́ra. Fún àpẹẹrẹ, tá a bá sún mọ́ etí ọ̀gbun kan, tá a sì rí ibi tá a ti máa balẹ̀ nísàlẹ̀ lọ́hùn-ún tó bá ṣẹlẹ̀ pé a já sínú rẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló máa sá padà sẹ́yìn láìsí pé ẹnikẹ́ni sọ fún wa. Bákan náà, kì í ṣe pé ìbẹ̀rù àtọkànwá wulẹ̀ ń gbé ìbátan rere tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run lárugẹ bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nìkan ni, àmọ́ ó tún ń dáàbò bò wá kí a má bàa fara pa.

2 Àmọ́, a gbọ́dọ̀ kọ́ bá a ṣe máa bẹ̀rù ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tí ń ṣe jàǹbá lóde òní. Níwọ̀n báwọn ọmọdé ò ti mọ̀ nípa ewu tí iná mànàmáná tàbí àwọn ọkọ̀ tó wà láàárín ìlú lè fà, wọ́n lè tètè kó sínú jàǹbá bíburú jáì. a Àwọn òbí tó gbọ́n sábà máa ń gbìyànjú láti gbin ìbẹ̀rù tó dáa sọ́kàn ọmọ wọn, wọ́n á máa kìlọ̀ fún wọn léraléra nípa ewu tó wà láyìíká wọn. Àwọn òbí mọ̀ pé ìbẹ̀rù yìí lè gba ẹ̀mí àwọn ọmọ wọn là.

3. Èé ṣe tí Jèhófà fi ń kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ewu tẹ̀mí, ọ̀nà wo ló sì gbà ń ṣe é?

3 Jèhófà ń ṣe àníyàn kan náà nípa ire wa. Gẹ́gẹ́ bí Baba onífẹ̀ẹ́, ó ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀ kọ́ wa kí a lè ṣe ara wa láǹfààní. (Aísáyà 48:17) Kíkìlọ̀ nípa àwọn ọ̀fìn tẹ̀mí fún wa “léraléra” wà lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yìí, kí a lè ní ìbẹ̀rù àtọkànwá fún irú àwọn ewu bẹ́ẹ̀. (2 Kíróníkà 36:15; 2 Pétérù 3:1) Jálẹ̀ ìtàn, ọ̀pọ̀ àgbákò nípa tẹ̀mí là bá ti yẹra fún, ọ̀pọ̀ ìyà ni ì bá sì ti fò wá dá ‘ká ní àwọn èèyàn ti mú ọkàn-àyà wọn dàgbà láti bẹ̀rù Ọlọ́run, kí wọ́n sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.’ (Diutarónómì 5:29) Ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí, báwo la ṣe lè mú ọkàn-àyà wa dàgbà láti bẹ̀rù Ọlọ́run, kí a sì yẹra fún ewu nípa tẹ̀mí?—2 Tímótì 3:1.

Ẹ Yà Kúrò Nínú Ohun Búburú

4. (a) Irú ìkórìíra wo ló yẹ kí Kristẹni ní? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìwà ẹ̀ṣẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

4 Bíbélì ṣàlàyé pé “ìbẹ̀rù Jèhófà túmọ̀ sí kíkórìíra ohun búburú.” (Òwe 8:13) Ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì kan ṣàpèjúwe ìkórìíra yìí gẹ́gẹ́ bí “irú ẹ̀mí téèyàn máa ń ní sáwọn aṣòdìsíni àtàwọn nǹkan mìíràn tí ń ṣọwọ́ òdì síni, àwọn nǹkan tó kóni nírìíra, tá a ń fojú ẹ̀gàn wò, téèyàn ò sì ní fẹ́ kí ohunkóhun da òun àtàwọn pọ tàbí kí àjọṣe kankan wà láàárín òun àtàwọn.” Nítorí náà, ìbẹ̀rù Ọlọ́run wé mọ́ sísá fún gbogbo ohun tó burú lójú Jèhófà tàbí kéèyàn kà wọ́n sí ohun ìríra. b (Sáàmù 97:10) Ìbẹ̀rù yìí ń jẹ́ kí a yà kúrò nínú ohun búburú, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa sá kúrò létí bèbè ọ̀gbun kan nígbà tí ìbẹ̀rù tá a dá mọ́ wa bá ta wá lólobó. Bíbélì sọ pé: “Nípa ìbẹ̀rù Jèhófà, ènìyàn a yí padà kúrò nínú ohun búburú.”—Òwe 16:6.

5. (a) Báwo la se lè fún ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti bí a ṣe kórìíra ohun búburú lókun? (b) Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi kọ́ni nípa ọ̀ràn yìí?

5 A lè fún ìbẹ̀rù àtọkànwá yìí àti ìkórìíra tá a ní sí ohun búburú lókun nípa ríronú lórí àwọn àbájáde búburú tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń mú wá. Bíbélì mú un dá wa lójú pé ohun tá a bá gbìn ni a óò ká—yálà a ń fúnrúgbìn sípa ti ara ni tàbí sípa ti ẹ̀mí. (Gálátíà 6:7, 8) Nítorí ìdí èyí, Jèhófà sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde ṣíṣàì ka àwọn àṣẹ òun sí àti pípa ìjọsìn tòótọ́ tì. Tí kò bá sí ti ààbò Ọlọ́run ni, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kékeré tí kò lè gbèjà ara rẹ̀, ì bá bọ́ sọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn tó lágbára tí wọ́n sì jẹ́ òǹrorò. (Diutarónómì 28:15, 45-48) Àbájáde búburú tó tẹ̀yìn àìgbọràn Ísírẹ́lì jáde la kọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ sínú Bíbélì “kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀” fún wa, ká lè fi tiwọn ṣàríkọ́gbọ́n, ká sì ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 10:11.

6. Kí làwọn àpẹẹrẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan tá a lè gbé yẹ̀ wò bá a ṣe ń kọ́ ìbẹ̀rù Ọlọ́run? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

6 Yàtọ̀ sí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lódindi, ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn tí owú, ìwà pálapàla, ìwọra, àti ìgbéraga lé bá tún wà nínú Bíbélì. c Àwọn kan lára àwọn èèyàn wọ̀nyí ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ ní àkókò kan nínú ìgbésí ayé wọn, ìbẹ̀rù tí wọ́n ní fún Ọlọ́run kò lágbára mọ́, àtúbọ̀tán rẹ̀ sì burú jáì. Ríronú lórí irú àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ bẹ́ẹ̀ lè fún ìpinnu wa lókun pé a ò ní ṣe irú àṣìṣe kan náà. Yóó mà burú jáì o tó bá jẹ́ pé ńṣe la fẹ́ dúró dìgbà tí ohun búburú bá ṣẹlẹ̀ sí wa ká tó fi ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò! Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ, pé bí ò ṣeni a kì í gbọ́n—àgàgà tó bá jẹ́ àfọwọ́fà ni—kò yẹ kí ó ṣeni ká tó gbọ́n o.—Sáàmù 19:7.

7. Ta ni Jèhófà ń pè wá sínú àgọ́ ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀?

7 Ìdí lílágbára mìíràn tá a fi gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni fífẹ́ tá a fẹ́ pa àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́. A ń bẹ̀rù pé kí a má ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ nítorí pé a mọyì ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú rẹ̀. Ta ni Ọlọ́run kà sí ọ̀rẹ́, tí yóò pè wá sí àgọ́ ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀? Kìkì ẹni tó bá “ń rìn láìlálèébù, tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù” ni. (Sáàmù 15:1, 2) Tá a bá mọyì àjọṣe tá a láǹfààní láti ní pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa yìí, a ó sapá láti rìn láìlálèébù ní ojú rẹ̀.

8. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣe fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn pẹ̀lú Ọlọ́run nígbà ayé Málákì?

8 Ó ṣeni láàánú pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run nígbà ayé Málákì. Dípò tí wọn ì bá fi máa bẹ̀rù Jèhófà, kí wọ́n sì máa bọlá fún un, wọ́n ń fi ẹran tó ń ṣàìsàn àti èyí tó yarọ rúbọ lórí pẹpẹ rẹ̀. Àìbẹ̀rù Ọlọ́run tún hàn gbangba nínú ọwọ́ tí wọ́n fi mú ìgbéyàwó. Wọ́n ń já àwọn aya ìgbà èwe wọn sílẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, kí wọ́n lè fẹ́ àwọn obìnrin tó kéré lọ́jọ́ orí. Málákì sọ fún wọn pé Jèhófà kórìíra “ìkọ̀sílẹ̀,” àti pé ẹ̀mí aládàkàdekè wọn ti sọ wọ́n di àjèjì sí Ọlọ́run. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ fojú tó dára wo ẹbọ wọn, nígbà tí pẹpẹ wọ́n kún fún omijé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ—ìyẹn omijé ìbànújẹ́ tó ń dà lójú àwọn aya tí wọ́n pa tì? Irú àìbọ̀wọ̀ fún ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà bẹ́ẹ̀ ló mú kó béèrè pé: “Ẹ̀rù mi dà?”—Málákì 1:6-8; 2:13-16.

9, 10. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Jèhófà?

9 Lóde òní pẹ̀lú, Jèhófà tún ń rí ìbànújẹ́ ọ̀pọ̀ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ọkọ tàbí aya àtàwọn ọmọ tí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwà pálapàla àwọn ọkọ àti baba tàbí àwọn aya àti ìyá pàápàá ti dà lọ́kàn rú. Dájúdájú, ó ń bà á nínú jẹ́. Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run yóò rí àwọn ọ̀ràn ní ọ̀nà tí Jèhófà gbà rí i, yóò sì ṣe iṣẹ́ àṣekára láti fún ìgbéyàwó rẹ̀ lókun, yóò kọ ìrònú ti ayé tó ń fojú yẹpẹrẹ wo ìdè ìgbéyàwó sílẹ̀, yóò sì “sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.

10 Nínú ìgbéyàwó àti nínú àwọn apá mìíràn nínú ìgbésí ayé wa, kíkórìíra gbogbo ohun tó burú lójú Jèhófà, pa pọ̀ pẹ̀lú níní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú rẹ̀, yóò jẹ́ kí a rí ojú rere àti ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Àpọ́sítélì Pétérù là á mọ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Àwọn àpẹẹrẹ pọ̀ nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn bí ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe sún àwọn kan ṣe ohun tí ó tọ́ nínú onírúurú ipò líle koko.

Àwọn Mẹ́ta Tó Bẹ̀rù Ọlọ́run

11. Ipò wo ni Ábúráhámù wà nígbà tá a pè é ní “olùbẹ̀rù Ọlọ́run”?

11 Ọkùnrin kan wà nínú Bíbélì tí Jèhófà fúnra rẹ̀ pè ní ọ̀rẹ́ òun—Ábúráhámù, baba ńlá náà ni. (Aísáyà 41:8) A dán ìbẹ̀rù tí Ábúráhámù ní fún Ọlọ́run wò nígbà tí Ọlọ́run sọ pé kó fi Ísákì, rúbọ. Èyí tí í ṣe ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ rẹ̀ mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, pé àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù yóò di orílẹ̀-èdè ńlá. (Jẹ́nẹ́sísì 12:2, 3; 17:19) Ṣé “ọ̀rẹ́ Jèhófà” máa yege àdánwò líle koko yìí? (Jákọ́bù 2:23) Àkókò tí Ábúráhámù gbé ọ̀bẹ rẹ̀ sókè láti pa Ísákì gan-an ni áńgẹ́lì Jèhófà sọ pé: “Má ṣe na ọwọ́ rẹ jáde lòdì sí ọmọdékùnrin náà, má sì ṣe ohunkóhun sí i rárá, nítorí nísinsìnyí ni mo mọ̀ pé olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìwọ ní ti pé ìwọ kò fawọ́ ọmọkùnrin rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní, sẹ́yìn fún mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:10-12.

12. Kí ló mú kí Ábúráhámù ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, báwo la sì ṣe lè fi irú ẹ̀mí kan náà hàn?

12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù ti kọ́kọ́ fẹ̀rí hàn pé òun bẹ̀rù Jèhófà, síbẹ̀ ó fi ìbẹ̀rù tó ní fún Ọlọ́run hàn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ní àkókò yẹn. Mímúra tó múra tán láti fi Ísákì rúbọ ré kọjá wíwulẹ̀ fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣègbọràn. Ohun tó sún Ábúráhámù ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé Baba òun ọ̀run yóò mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ nípa jíjí Ísákì dìde tó bá pọn dandan. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ, Ábúráhámù “gbà gbọ́ ní kíkún pé ohun tí [Ọlọ́run] ti ṣèlérí ni ó lè ṣe pẹ̀lú.” (Róòmù 4:16-21) Ǹjẹ́ a múra tán láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kódà nígbà tó bá béèrè pé kí a fi ohun pàtàkì du ara wa? Ǹjẹ́ a ní ìgbọ́kànlé pátápátá pé irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀ yóò mú àwọn àǹfààní pípẹ́ títí wá, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé Jèhófà ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a”? (Hébérù 11:6) Ìbẹ̀rù tòótọ́ fún Ọlọ́run nìyẹn.—Sáàmù 115:11.

13. Èé ṣe tí Jósẹ́fù fi lẹ́tọ̀ọ́ láti pe ara rẹ̀ ní ẹni tó “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́”?

13 Ẹ jẹ́ ká tún ṣàyẹ̀wò àpẹẹrẹ ẹlòmíràn tó fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn—ìyẹn ni àpẹẹrẹ ti Jósẹ́fù. Gẹ́gẹ́ bí ẹrú nínú agbo ilé Pọ́tífárì, ojoojúmọ́ ni Jósẹ́fù ń dojú kọ ewu ṣíṣe àgbèrè. Ó hàn gbangba pé kò sí ọ̀nà tó lè gbà yẹra fún aya ọ̀gá rẹ̀ tó ń fi ìwà pálapàla lọ̀ ọ́ láìsinmi. Níkẹyìn, nígbà tí obìnrin náà “dì í ní ẹ̀wù mú,” ó “fẹsẹ̀ fẹ, ó sì bọ́ síta.” Kí ló sún un láti sá fún ohun búburú lójú ẹsẹ̀? Láìsí àní-àní, ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni olórí ohun tó mú un ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ni pé ó fẹ́ yàgò fún híhu ‘ìwà búburú ńlá yìí, kí ó sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi.’ (Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12) Nítorí náà, Jósẹ́fù lẹ́tọ̀ọ́ láti pe ara rẹ̀ ní ẹni tó “bẹ̀rù Ọlọ́rùn tòótọ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 42:18.

14. Báwo ni àánú Jósẹ́fù ṣe fi hàn pé ó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́?

14 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ni Jósẹ́fù tún rí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní ojúkoojú, ìyẹn àwọn tí wọ́n fi ìwà ìkà tà á sí oko ẹrú. Ì bá kàn rọra lo àǹfààní wíwá tí wọ́n ń wá oúnjẹ lójú méjèèjì yẹn láti gbẹ̀san ìwà ibi tí wọn hù sí i ni. Àmọ́ híhu ìwà ìkà sáwọn èèyàn kò fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn. (Léfítíkù 25:43) Nítorí náà, nígbà tí Jósẹ́fù rí ẹ̀rí tí ó tó láti fi hàn pé ọkàn àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti yí padà, ó fi tàánútàánú dárí jì wọ́n. Bíi ti Jósẹ́fù, ìbẹ̀rù tá a ní fún Ọlọ́run yóò mú ká fi rere ṣẹ́gun búburú, kò sì ní jẹ́ ká ṣubú sínú àdánwò.—Jẹ́nẹ́sísì 45:1-11; Sáàmù 130:3, 4; Róòmù 12:17-21.

15. Èé ṣe tí ìwà Jóòbù fi mú ọkàn Jèhófà yọ̀?

15 Jóòbù náà jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí àpẹẹrẹ tirẹ̀ náà tayọ lọ́lá. Jèhófà sọ fún Èṣù pé: “Ìwọ ha ti fi ọkàn-àyà rẹ sí ìránṣẹ́ mi Jóòbù, pé kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé, ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú?” (Jóòbù 1:8) Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni ìwà aláìlẹ́bi tí Jóòbù ń hù fi ń mú ọkàn Baba rẹ̀ ọ̀run yọ̀. Jóòbù bẹ̀rù Ọlọ́run nítorí ó mọ̀ pé ohun tí ó tọ́ láti ṣe nìyẹn, àti pé ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ. Jóòbù polongo pé: “Wò ó! Ìbẹ̀rù Jèhófà—ìyẹn ni ọgbọ́n, yíyípadà kúrò nínú ìwà búburú sì ni òye.” (Jóòbù 28:28) Gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tó ti gbéyàwó, Jóòbù kì í wo àwọn ọ̀dọ́bìnrin ní ìwòkuwò, bẹ́ẹ̀ náà ni kì í gbèrò àtiṣe panṣágà nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni, síbẹ̀, ó kọ̀ láti gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀, ó sì sá fún ìbọ̀rìṣà èyíkéyìí.—Jóòbù 31:1, 9-11, 24-28.

16. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jóòbù gbà fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn? (b) Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé òun kò fawọ́ ìdáríjì sẹ́yìn?

16 Bí ó ti wù kó rí, ìbẹ̀rù Ọlọ́run túmọ̀ sí ṣíṣe ohun tó dára àti sísá fún ohun tó burú. Nípa bẹ́ẹ̀, Jóòbù ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí àwọn afọ́jú, àwọn arọ, àtàwọn òtòṣì. (Léfítíkù 19:14; Jóòbù 29:15, 16) Jóòbù mọ̀ pé “ẹnikẹ́ni tí ó fawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ọmọnìkejì rẹ̀, òun yóò pa àní ìbẹ̀rù Olódùmarè tì pẹ̀lú.” (Jóòbù 6:14) Fífawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sẹ́yìn tún lè kan fífawọ́ ìdáríjì sẹ́yìn tàbí dídi kùnrùngbùn sínú. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe darí rẹ̀, Jóòbù gbàdúrà fún àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, tí wọ́n ti kó ẹ̀dùn ọkàn ńláǹlà bá a. (Jóòbù 42:7-10) Ǹjẹ́ a lè fi irú ẹ̀mí ìdáríjì kan náà hàn sí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tó ti lè múnú bí wa láwọn ọ̀nà kan? Àdúrà àtọkànwá tá a gbà fún ẹni tó ṣẹ̀ wá lè ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti borí ìkórìíra. Àwọn ìbùkún tí Jóòbù gbádùn nítorí pé ó bẹ̀rù Ọlọ́run lè jẹ́ ká mọ ‘ọ̀pọ̀ yanturu oore tí Jèhófà ti tò pa mọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.’—Sáàmù 31:19; Jákọ́bù 5:11.

Ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti Ìbẹ̀rù Ènìyàn

17. Kí ni ìbẹ̀rù èèyàn lè ṣe fún wa, àmọ́ èé ṣe tí irú ẹ̀rù bẹ́ẹ̀ kò fi gba ti ọjọ́ ọ̀la rò?

17 Nígbà tó jẹ́ pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run lè sún wa ṣe ohun tí ó tọ́, ńṣe ni ìbẹ̀rù ènìyàn máa ń sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ. Nítorí ìdí èyí, nígbà tí Jésù ń rọ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ láti jẹ́ ẹni tó ń fìtara wàásù ìhìn rere náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má . . . bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ọkàn; ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lè pa àti ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.” (Mátíù 10:28) Jésù ṣàlàyé pé ìbẹ̀rù èèyàn kò gba ti ọjọ́ ọ̀la rò, nítorí pé àwọn èèyàn ò lè pa ìwàláàyè tá a ń retí lọ́jọ́ iwájú run. Síwájú sí i, a ń bẹ̀rù Ọlọ́run nítorí a mọ̀ pé alágbára gbogbo ni, àti pé agbára gbogbo orílẹ̀-èdè kò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbára rẹ̀. (Aísáyà 40:15) Bíi ti Ábúráhámù, a ní ìgbọ́kànlé tí ó dájú nínú agbára Jèhófà láti jí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ dìde. (Ìṣípayá 2:10) Nítorí náà, a ń fi ìdánilójú sọ pé: “Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa?”—Róòmù 8:31.

18. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń san ẹ̀san fáwọn tó bẹ̀rù rẹ̀?

18 Ì báà jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé wa lẹni tó ń ṣàtakò sí wa, tàbí ẹnì kan tó ń bú mọ́ wa nílé ìwé, a óò rí i pé “inú ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìgbọ́kànlé lílágbára wà.” (Òwe 14:26) A lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa lókun, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé yóò gbọ́ wa. (Sáàmù 145:19) Jèhófà kò jẹ́ gbàgbé àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ láé. Ó tipasẹ̀ Málákì, wòlíì rẹ̀ mú un dá wa lójú pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.”—Málákì 3:16.

19. Irú ìbẹ̀rù wo ni yóò dópin, àmọ́ irú èwo ni yóò wà títí láé?

19 Àkókò náà ti sún mọ́lé, nígbà tí gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé yóò jọ́sìn Jèhófà, tí ìbẹ̀rù ènìyàn yóò sì pòórá. (Aísáyà 11:9) Ìbẹ̀rù ebi, àrùn, ìwà ọ̀daràn àti ogun yóò kọjá lọ. Àmọ́ ìbẹ̀rù Ọlọ́run yóò wà títí ayérayé bí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ti ń bá a lọ láti bọ̀wọ̀ fún un, tí wọ́n ń ṣe ìgbọràn sí i, tí wọ́n ń bọlá fún un bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. (Ìṣípayá 15:4) Ní báyìí ná, ǹjẹ́ kí gbogbo wa fi ìmọ̀ràn tí Sólómọ́nì fúnni lábẹ́ ìmísí sọ́kàn pé: “Má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí o bẹ̀rù Jèhófà láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Nítorí bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ọjọ́ ọ̀la yóò wà, a kì yóò sì ké ìrètí rẹ kúrò.”—Òwe 23:17, 18.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn àgbàlagbà kan kì í bẹ̀rù ewu mọ́, nígbà tíṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe jẹ́ èyí tó máa ń wu wọ́n léwu ní gbogbo ìgbà. Nígbà tá a béèrè ìdí tí ọ̀pọ̀ káfíńtà fi di oníka mẹ́sàn-án, ohun tí oníṣẹ́ ọnà kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rọra fi fèsì ni pé: “Wọn ò bẹ̀rù àwọn ayùn ayára bí àṣá tó ń lo iná mànàmáná wọ̀nyẹn mọ́.”

b Ohun ìríra ni nǹkan wọ̀nyí jẹ́ sí Jèhófà fúnra rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Éfésù 4:29 pe ọ̀rọ̀ ìríra ní “àsọjáde jíjẹrà.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò fún “jíjẹrà” ń tọ́ka ní tààràtà sí èso, ẹja, tàbí ẹran tó ti rà. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ń ṣàgbéyọ bí ọ̀rọ̀ èébú tàbí ọ̀rọ̀ àlùfààṣá ṣe gbọ́dọ̀ kó wa nírìíra. Bákan náà, a sábà máa ń pe àwọn òrìṣà ní “ẹlẹ́bọ́tọ” nínú Ìwé Mímọ́. (Diutarónómì 29:17; Ìsíkíẹ́lì 6:9) Bá a ṣe máa ń sá fún ẹlẹ́bọ́tọ, tàbí ìgbẹ́, ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bí irú ìbọ̀rìṣà èyíkéyìí ṣe máa kó Ọlọ́run nírìíra tó.

c Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, gbé àwọn ìtàn inú Ìwé Mímọ́ yẹ̀ wò nípa Kéènì (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-12); Dáfídì (2 Sámúẹ́lì 11:2–12:14); Géhásì (2 Àwọn Ọba 5:20-27); àti Ùsáyà (2 Kíróníkà 26:16-21).

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo la ṣe ń kọ́ bá a ṣe ń kórìíra ohun búburú?

• Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣe fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Jèhófà nígbà ayé Málákì?

• Kí la lè kọ́ lára Ábúráhámù, Jósẹ́fù, àti Jóòbù nípa ìbẹ̀rù Ọlọ́run?

• Ìbẹ̀rù wo ni kò ní kásẹ̀ nílẹ̀ láé, èé sì ti ṣe?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń gbin ìbẹ̀rù tó dáa sọ́kàn àwọn ọmọ wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Bí ìbẹ̀rù ṣe máa ń jẹ́ ká sá fún ewu, bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe máa ń jẹ́ ká sá fún ohun búburú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Jóòbù kò jáwọ́ nínú bíbẹ̀rù Ọlọ́run, kódà nígbà táwọn ọ̀rẹ́ èké mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pin ín lẹ́mìí

[Credit Line]

Látinú ìtumọ̀ Bíbélì ti Vulgata Latina, 1795