Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 10:1-48

  • Ìran tí Kọ̀nílíù rí (1-8)

  • Pétérù rí àwọn ẹranko tí a ti sọ di mímọ́ nínú ìran (9-16)

  • Pétérù wá sílé Kọ̀nílíù (17-33)

  • Pétérù kéde ìhìn rere fún àwọn Kèfèrí (34-43)

    • “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú” (34, 35)

  • Àwọn Kèfèrí gba ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi (44-48)

10  Ọkùnrin kan wà ní Kesaríà tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù, ọ̀gá ọmọ ogun* kan nínú àwùjọ tí wọ́n ń pè ní àwùjọ Ítálì.*  Onífọkànsìn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀, ó ń fún àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ ọrẹ àánú, ó sì máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà gbogbo.  Ní nǹkan bí wákàtí kẹsàn-án+ ọjọ́,* ó rí áńgẹ́lì Ọlọ́run kedere nínú ìran, tí ó wọlé wá bá a, ó sì sọ pé: “Kọ̀nílíù!”  Kọ̀nílíù tẹjú mọ́ ọn, ẹ̀rù ń bà á, ó sì bi í pé: “Ṣé kò sí o, Olúwa?” Ó sọ fún un pé: “Àwọn àdúrà àti àwọn ọrẹ àánú rẹ ti dé iwájú Ọlọ́run, ó sì ti mú kó rántí rẹ.+  Nítorí náà, rán àwọn èèyàn sí Jópà, kí o sì ní kí wọ́n pe ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Símónì, tí wọ́n tún ń pè ní Pétérù wá.  Ọkùnrin yìí ni àlejò tó wà* lọ́dọ̀ Símónì, oníṣẹ́ awọ, tó ní ilé sétí òkun.”  Gbàrà tí áńgẹ́lì tó bá a sọ̀rọ̀ lọ, ó pe méjì lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ọmọ ogun kan tó jẹ́ onífọkànsìn lára àwọn tó ń ṣèránṣẹ́ fún un,  ó sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ó sì rán wọn lọ sí Jópà.  Lọ́jọ́ kejì, bí wọ́n ṣe ń bá ìrìn àjò wọn lọ, tí wọ́n sì ń sún mọ́ ìlú náà, Pétérù lọ sórí ilé ní nǹkan bíi wákàtí kẹfà* láti gbàdúrà. 10  Àmọ́ ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á gan-an, ó sì fẹ́ jẹun. Bí wọ́n ṣe ń ṣe oúnjẹ lọ́wọ́, ó bọ́ sójú ìran,+ 11  ó rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, ohun kan* sì ń sọ̀ kalẹ̀ tó dà bí aṣọ ọ̀gbọ̀ fífẹ̀ tí wọ́n ń fi àwọn igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí ayé; 12  oríṣiríṣi ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti àwọn ẹran tó ń fàyà fà* lórí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ló wà nínú rẹ̀. 13  Lẹ́yìn náà, ohùn kan sọ fún un pé: “Dìde, Pétérù, máa pa, kí o sì máa jẹ!” 14  Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Rárá o, Olúwa, mi ò jẹ ohunkóhun tó jẹ́ ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́ rí.”+ 15  Ohùn náà tún sọ fún un lẹ́ẹ̀kejì pé: “Yéé pe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” 16  Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà kẹta, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a gbé e* lọ sí ọ̀run. 17  Nígbà tí Pétérù ṣì ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìran tó rí túmọ̀ sí, àwọn ọkùnrin tí Kọ̀nílíù rán níṣẹ́ wá béèrè ibi tí ilé Símónì wà, wọ́n sì dúró sí ẹnubodè.+ 18  Wọ́n nahùn sókè, wọ́n sì béèrè bóyá wọ́n gba Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù lálejò níbẹ̀. 19  Bí Pétérù ṣe ń ronú nípa ìran náà lọ́wọ́, ẹ̀mí+ sọ fún un pé: “Wò ó! Àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń béèrè rẹ. 20  Torí náà, dìde, sọ̀ kalẹ̀, kí o sì bá wọn lọ, má ṣiyèméjì rárá, nítorí èmi ni mo rán wọn wá.” 21  Pétérù bá sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn ọkùnrin náà, ó sì sọ pé: “Èmi ni ẹni tí ẹ̀ ń wá. Kí lẹ bá wá o?” 22  Wọ́n sọ pé: “Kọ̀nílíù,+ ọ̀gá ọmọ ogun, ọkùnrin kan tó jẹ́ olódodo, tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí gbogbo orílẹ̀-èdè Júù sì ń ròyìn rẹ̀ dáadáa, ni áńgẹ́lì mímọ́ kan fún ní àṣẹ àtọ̀runwá pé kó ránṣẹ́ pè ọ́ láti wá sí ilé òun, kí ó lè gbọ́ ohun tí o ní láti sọ.” 23  Nítorí náà, ó ní kí wọ́n wọlé, ó sì gbà wọ́n lálejò. Lọ́jọ́ kejì, ó dìde, ó sì bá wọn lọ, lára àwọn arákùnrin tó wá láti Jópà náà bá a lọ. 24  Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, ó wọ Kesaríà. Ní ti tòótọ́, Kọ̀nílíù ti ń retí wọn, ó sì ti pe àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. 25  Bí Pétérù ṣe wọlé, Kọ̀nílíù pàdé rẹ̀, ó kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì tẹrí ba* fún un. 26  Àmọ́ Pétérù gbé e dìde, ó sọ pé: “Dìde; èèyàn lèmi náà.”+ 27  Bí ó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé, ó sì rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n pé jọ. 28  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin náà mọ̀ dáadáa pé kò bófin mu rárá fún Júù láti dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ ẹ̀yà míì tàbí kó wá sọ́dọ̀ rẹ̀,+ síbẹ̀ Ọlọ́run fi hàn mí pé kí n má ṣe pe èèyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́.+ 29  Nítorí náà, mo wá láìjanpata nígbà tí wọ́n ránṣẹ́ pè mí. Ní báyìí, mo fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi ránṣẹ́ pè mí.” 30  Kọ̀nílíù wá sọ pé: “Ọjọ́ mẹ́rin sẹ́yìn, tí a bá kà á láti wákàtí yìí, mò ń gbàdúrà nínú ilé mi ní wákàtí kẹsàn-án;* ni ọkùnrin kan tó wọ aṣọ títàn yòò bá dúró síwájú mi, 31  ó sì sọ pé: ‘Kọ̀nílíù, àdúrà rẹ ti gbà, a sì ti rántí àwọn ọrẹ àánú rẹ níwájú Ọlọ́run. 32  Torí náà, ránṣẹ́ sí Jópà, kí o sì pe Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù wá. Ọkùnrin yìí jẹ́ àlejò ní ilé Símónì, oníṣẹ́ awọ, létí òkun.’+ 33  Nítorí náà, mo ránṣẹ́ sí ọ ní kíá, o sì ṣe dáadáa bí o ṣe wá síbí. Ní báyìí, gbogbo wa wà níwájú Ọlọ́run láti gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà* ti pàṣẹ pé kí o sọ.” 34  Ni Pétérù bá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, ó ní: “Ní báyìí, ó ti wá yé mi dáadáa pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,+ 35  àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.+ 36  Ó ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lè kéde ìhìn rere àlàáfíà+ fún wọn nípasẹ̀ Jésù Kristi, ẹni yìí ni Olúwa gbogbo èèyàn.+ 37  Ẹ mọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀ káàkiri gbogbo Jùdíà, bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì+ lẹ́yìn ìrìbọmi tí Jòhánù wàásù: 38  nípa Jésù tó wá láti Násárẹ́tì, bí Ọlọ́run ṣe fi ẹ̀mí mímọ́+ àti agbára yàn án, tí ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, tí ó ń ṣe rere, tí ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn,+ torí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 39  Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Júù àti ní Jerúsálẹ́mù; àmọ́ wọ́n pa á bí wọ́n ṣe gbé e kọ́ sórí òpó igi.* 40  Ọlọ́run jí ẹni yìí dìde ní ọjọ́ kẹta,+ ó sì jẹ́ kó fara hàn kedere,* 41  kì í ṣe fún gbogbo èèyàn, bí kò ṣe fún àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọ́run ti yàn ṣáájú, fún àwa, tí a bá a jẹ, tí a sì bá a mu lẹ́yìn tí ó dìde kúrò nínú ikú.+ 42  Bákan náà, ó pàṣẹ fún wa pé ká wàásù fún àwọn èèyàn ká sì jẹ́rìí kúnnákúnná+ pé ẹni yìí ni Ọlọ́run pàṣẹ pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.+ 43  Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sí,+ pé gbogbo ẹni tó bá gbà á gbọ́ máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀.”+ 44  Nígbà tí Pétérù ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ nípa nǹkan yìí, ẹ̀mí mímọ́ bà lé gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.+ 45  Ẹnu ya àwọn onígbàgbọ́* tó ti dádọ̀dọ́* tí wọ́n bá Pétérù wá, torí pé ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ tú jáde sórí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú. 46  Nítorí wọ́n gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn èdè àjèjì,* tí wọ́n sì ń gbé Ọlọ́run ga.+ Nígbà náà, Pétérù dáhùn pé: 47  “Ṣé ẹnikẹ́ni lè sọ pé ká má fi omi batisí àwọn èèyàn yìí,+ àwọn tó ti gba ẹ̀mí mímọ́ bí àwa náà ṣe gbà á?” 48  Nítorí náà, ó pàṣẹ pé kí a batisí wọn ní orúkọ Jésù Kristi.+ Lẹ́yìn náà, wọ́n ní kó lo ọjọ́ díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “balógun ọ̀rún,” tó ń darí 100 ọmọ ogun.
Tàbí “àwùjọ ọmọ ogun,” ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù tó ní 600 ọmọ ogun.
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.
Tàbí “Wọ́n ń ṣe ọkùnrin yìí lálejò.”
Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.
Ní Grk., “oríṣi ohun èlò kan.”
Tàbí “àwọn ohun tó ń rákò.”
Ní Grk., “ohun èlò náà.”
Tàbí “forí balẹ̀.”
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.
Tàbí “igi.”
Tàbí “ó sì jẹ́ kó ṣeé fojú rí.”
Tàbí “àwọn olóòótọ́.”
Tàbí “kọlà.”
Ní Grk., “fi ahọ́n sọ̀rọ̀.”