Ìsíkíẹ́lì 6:1-14

  • Ọlọ́run yóò bá àwọn òkè Ísírẹ́lì jà (1-14)

    • Ọlọ́run máa rẹ àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wálẹ̀ (4-6)

    • ‘Ẹ ó wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà’ (7)

6  Jèhófà tún sọ fún mi pé:  “Ọmọ èèyàn, yíjú sí àwọn òkè Ísírẹ́lì, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn.  Kí o sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ: Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, fún àwọn odò àti àwọn àfonífojì nìyí: “Wò ó! Èmi yóò fi idà bá yín jà, èmi yóò sì run àwọn ibi gíga yín.  Màá wó àwọn pẹpẹ yín, màá fọ́ àwọn ohun tí ẹ fi ń sun tùràrí,+ màá sì ju òkú àwọn èèyàn yín síwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín.*+  Èmi yóò ju òkú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì síwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun yín ká sí àyíká àwọn pẹpẹ yín.+  Ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé, àwọn ìlú yóò di ahoro,+ wọ́n á wó àwọn ibi gíga, yóò sì di ahoro.+ Wọ́n á wó àwọn pẹpẹ yín, wọ́n á sì tú u ká, àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín máa pa run, wọ́n á wó àwọn ohun tí ẹ fi ń sun tùràrí, iṣẹ́ yín á sì pa rẹ́.  Òkú á sùn lọ bẹẹrẹbẹ láàárín yín,+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+  “‘“Àmọ́ màá mú kí àwọn kan ṣẹ́ kù, torí àwọn kan lára yín á bọ́ lọ́wọ́ idà àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí ẹ bá fọ́n ká sí àwọn ilẹ̀.+  Àwọn tó bá yè bọ́ yóò rántí mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó kó wọn lẹ́rú.+ Wọ́n á rí i pé ó dùn mí gan-an bí ọkàn àìṣòótọ́* wọn ṣe mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí mi+ àti bí ojú wọn ṣe mú kí ọkàn wọn fà sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.*+ Gbogbo iṣẹ́ ibi àtàwọn ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe yóò kó ìtìjú bá wọn, wọ́n á sì kórìíra rẹ̀ gidigidi.+ 10  Wọ́n á sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà àti pé àjálù yìí tí mo sọ pé màá mú bá wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán.”’+ 11  “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Pàtẹ́wọ́, kí o fẹsẹ̀ kilẹ̀, kí o sì kẹ́dùn torí gbogbo ìwà ibi àti ohun tó ń ríni lára tí ilé Ísírẹ́lì ṣe, torí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa wọ́n.+ 12  Àjàkálẹ̀ àrùn yóò pa ẹni tó wà lọ́nà jíjìn, idà yóò pa ẹni tó wà nítòsí, ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù, tó sì bọ́ lọ́wọ́ ìwọ̀nyí ni ìyàn yóò pa; bí mo ṣe máa bínú sí wọn gidigidi nìyẹn.+ 13  Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nígbà tí òkú wọn bá sùn lọ bẹẹrẹbẹ níbi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn, tí àwọn òkú náà yí àwọn pẹpẹ wọn ká,+ lórí gbogbo òkè kékeré àti òkè gíga, lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ àti lábẹ́ àwọn ẹ̀ka igi ńláńlá tí wọ́n ti rú àwọn ẹbọ olóòórùn dídùn* láti fi wá ojúure gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+ 14  Èmi yóò na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ wọ́n, màá sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro, ibi tí wọ́n ń gbé máa di ahoro ju aginjù tó wà nítòsí Díbílà lọ. Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “mú kí wọ́n bá àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn ṣèṣekúṣe.”
Tàbí “oníṣekúṣe; aṣẹ́wó.”
Tàbí “ẹbọ tí òórùn rẹ̀ ń tuni lára.”