Oníwàásù 12:1-14

  • Rántí Ẹlẹ́dàá kí ọjọ́ ogbó tó dé (1-8)

  • Ìparí ọ̀rọ̀ akónijọ (9-14)

    • Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù (11)

    • Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ (13)

12  Nítorí náà, rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nígbà ọ̀dọ́ rẹ,+ kí àwọn ọjọ́ wàhálà* tó dé,+ kí àwọn ọdún náà tó dé nígbà tí wàá sọ pé: “Wọn ò mú inú mi dùn”;  kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,+ tí ojú ọ̀run á sì tún ṣú lẹ́yìn tí òjò ti rọ̀;*  ní ọjọ́ tí àwọn ẹ̀ṣọ́* ilé ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀,* tí àwọn ọkùnrin alágbára sì tẹ̀, tí àwọn obìnrin tó ń lọ nǹkan dáwọ́ dúró nítorí pé wọn ò pọ̀ mọ́, tí àwọn ọmọge tó ń wo ìta lójú fèrèsé* sì rí i pé òkùnkùn ṣú;+  nígbà tí àwọn ilẹ̀kùn tó jáde sí ojú ọ̀nà ti wà ní títì, nígbà tí ìró ọlọ ti lọ sílẹ̀, nígbà tí èèyàn á jí nítorí ìró ẹyẹ, tí ohùn gbogbo àwọn ọmọbìnrin tó ń kọrin kò sì dún sókè mọ́.+  Bákan náà, èèyàn á máa bẹ̀rù ibi tó ga, ẹ̀rù á sì wà lójú ọ̀nà. Igi álímọ́ńdì ń yọ ìtànná,+ tata ń wọ́ ara rẹ̀ lọ, àgbáyun kápérì sì bẹ́, torí pé èèyàn ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé,+ àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ sì ń rìn kiri ní ojú ọ̀nà;+  kí okùn fàdákà tó yọ, kí àwo wúrà tó fọ́ sí wẹ́wẹ́, kí ìṣà tó wà níbi ìsun omi tó fọ́, kí kẹ̀kẹ́ ìfami tó wà níbi kòtò omi tó kán.  Nígbà náà, erùpẹ̀ á pa dà sí ilẹ̀,+ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ẹ̀mí* á sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tó fúnni.+  “Asán* pátápátá gbáà!” ni akónijọ+ wí. “Asán ni gbogbo rẹ̀.”+  Kì í ṣe pé akónijọ di ọlọ́gbọ́n nìkan ni, ó tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó mọ̀,+ ó ronú jinlẹ̀, ó sì wádìí fínnífínní, kí ó lè kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe jọ.*+ 10  Akónijọ wá bó ṣe máa rí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára,+ kó sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó péye tó sì jẹ́ òtítọ́. 11  Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù,+ àkójọ ọ̀rọ̀ wọn sì dà bí ìṣó tó wọlé ṣinṣin; ọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan ni wọ́n ti wá. 12  Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan yìí, ọmọ mi, ṣọ́ra: Kò sí òpin nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, fífi àkókò tó pọ̀ jù kà wọ́n sì ń kó àárẹ̀ bá ara.+ 13  Òpin ọ̀rọ̀ náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́,+ kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ nítorí èyí ni gbogbo ojúṣe èèyàn.+ 14  Nítorí Ọlọ́run tòótọ́ yóò dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ lórí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe, títí kan gbogbo ohun tó fara pa mọ́, bóyá ó dára tàbí ó burú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àjálù.”
Tàbí kó jẹ́, “pẹ̀lú òjò tó ń rọ̀.”
Tàbí “àwọn olùtọ́jú.”
Tàbí “wárìrì.”
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “ohun tó mú kí ẹ̀dá wà láàyè.”
Tàbí “Òtúbáńtẹ́.”
Tàbí “to ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe jọ lẹ́sẹẹsẹ.”