Jẹ́nẹ́sísì 45:1-28

  • Jósẹ́fù jẹ́ kí wọ́n mọ òun (1-15)

  • Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù pa dà lọ mú Jékọ́bù wá (16-28)

45  Jósẹ́fù ò lè mú un mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀. Ló bá pariwo pé: “Kí gbogbo èèyàn kúrò lọ́dọ̀ mi!” Kò sẹ́nì kankan lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí Jósẹ́fù sọ bí òun ṣe jẹ́ fún àwọn arákùnrin+ rẹ̀.  Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, ohùn rẹ̀ sì lọ sókè débi pé àwọn ará Íjíbítì gbọ́, ilé Fáráò sì gbọ́.  Níkẹyìn, Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Èmi ni Jósẹ́fù. Ṣé bàbá mi ṣì wà láàyè?” Àmọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ ò lè dá a lóhùn rárá, torí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu.  Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sún mọ́ mi.” Ni wọ́n bá sún mọ́ ọn. Ó sọ pé: “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín, tí ẹ tà sí Íjíbítì.+  Àmọ́ ẹ má banú jẹ́, ẹ má sì bínú sí ara yín torí pé ẹ tà mí síbí; torí Ọlọ́run ti rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là.+  Ọdún kejì tí ìyàn náà ti mú káàkiri nìyí,+ ó ṣì ku ọdún márùn-ún tí wọn ò ní túlẹ̀, tí wọn ò sì ní kórè.  Àmọ́ Ọlọ́run ti rán mi ṣáájú yín, kó lè mú kí ẹ ní àṣẹ́kù+ ní ayé,* kó sì gba ẹ̀mí yín là lọ́nà ìyanu.  Torí náà, ẹ̀yin kọ́ lẹ rán mi wá síbí, Ọlọ́run tòótọ́ ni, torí kó lè fi mí ṣe olórí agbani-nímọ̀ràn* fún Fáráò, kó sì fi mí ṣe olúwa lórí gbogbo ilé rẹ̀ àti olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+  “Ẹ tètè pa dà sọ́dọ̀ bàbá mi, kí ẹ sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jósẹ́fù ọmọ rẹ sọ nìyí: “Ọlọ́run ti fi mí ṣe olúwa lórí gbogbo Íjíbítì.+ Máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi. Tètè máa bọ̀.+ 10  Kí o máa gbé ilẹ̀ Góṣénì,+ kí o lè wà nítòsí mi, ìwọ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ, àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti gbogbo ohun tí o ní. 11  Èmi yóò máa fún ọ ní oúnjẹ níbẹ̀, torí ó ṣì ku ọdún márùn-ún tí ìyàn+ á fi mú. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ àti ilé rẹ máa di aláìní àti gbogbo ohun tí o ní.”’ 12  Ẹ̀yin àti Bẹ́ńjámínì àbúrò mi ti wá fojú ara yín rí i pé èmi gan-an ni mò ń bá yín sọ̀rọ̀.+ 13  Torí náà, kí ẹ sọ fún bàbá mi nípa gbogbo ògo tí mo ní nílẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo ohun tí ẹ rí. Ó yá, ẹ tètè lọ mú bàbá mi wá síbí.” 14  Ó wá dì mọ́* Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, ó sì bú sẹ́kún, Bẹ́ńjámínì náà dì mọ́ ọn lọ́rùn,+ ó sì sunkún. 15  Ó wá fi ẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ń sunkún bó ṣe ń dì mọ́ wọn, lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ bá a sọ̀rọ̀. 16  Ìròyìn dé ilé Fáráò pé: “Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù ti dé!” Èyí dùn mọ́ Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú. 17  Fáráò wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ẹ di ẹrù lé àwọn ẹran tí ẹ fi ń kẹ́rù, kí ẹ lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, 18  kí ẹ sì mú bàbá yín àti agbo ilé yín wá sọ́dọ̀ mi níbí. Màá fún yín ní àwọn ohun rere ilẹ̀ Íjíbítì, ẹ ó sì jẹ ohun tó dára jù* ní ilẹ̀ yìí.’+ 19  Mo sì pàṣẹ pé kí o sọ fún wọn pé:+ ‘Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ẹ kó àwọn kẹ̀kẹ́+ láti ilẹ̀ Íjíbítì torí àwọn ọmọ yín àti ìyàwó yín, kí ẹ sì fi ọ̀kan lára rẹ̀ gbé bàbá yín wá síbí.+ 20  Ẹ má da ara yín láàmú torí àwọn ohun ìní+ yín, torí ẹ̀yin lẹ ni gbogbo ohun tó dáa jù ní ilẹ̀ Íjíbítì.’” 21  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀, Jósẹ́fù fún wọn ní àwọn kẹ̀kẹ́ bí Fáráò ṣe pàṣẹ, ó tún fún wọn ní ohun tí wọ́n á jẹ lójú ọ̀nà. 22  Ó fún kálukú wọn ní aṣọ tuntun, àmọ́ ó fún Bẹ́ńjámínì ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ẹyọ fàdákà àti aṣọ+ tuntun márùn-ún. 23  Àwọn ohun tó fi ránṣẹ́ sí bàbá rẹ̀ nìyí: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tó gbé àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ Íjíbítì àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tó gbé ọkà àti búrẹ́dì àti ohun tí bàbá rẹ̀ máa jẹ lẹ́nu ìrìn àjò. 24  Ó wá ní kí àwọn arákùnrin rẹ̀ máa lọ, nígbà tí wọ́n sì ń lọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe bá ara yín jà lójú ọ̀nà.”+ 25  Wọ́n kúrò ní Íjíbítì, wọ́n sì dé ilẹ̀ Kénáánì lọ́dọ̀ Jékọ́bù bàbá wọn. 26  Wọ́n ròyìn fún un pé: “Jósẹ́fù ò tíì kú, ó ti di olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì!”+ Àmọ́ ohun tí wọ́n sọ kò wọ Jékọ́bù lọ́kàn, torí kò gbà wọ́n gbọ́.+ 27  Nígbà tí wọ́n wá ń sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jósẹ́fù sọ fún wọn, tí Jékọ́bù sì wá rí àwọn kẹ̀kẹ́ tí Jósẹ́fù fi ránṣẹ́ pé kí wọ́n fi gbé e, ara Jékọ́bù bàbá wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yá gágá. 28  Ísírẹ́lì sọ pé: “Ó tó! Jósẹ́fù ọmọ mi ò tíì kú! Mo gbọ́dọ̀ lọ rí i kí n tó kú!”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ní ilẹ̀ náà.”
Ní Héb., “baba.”
Ní Héb., “rọ̀ mọ́ ọrùn.”
Tàbí “gbára lé ibi tó lọ́ràá jù.”