Léfítíkù 19:1-37

  • Onírúurú òfin nípa ìjẹ́mímọ́ (1-37)

    • Kíkórè bó ṣe tọ́ (9, 10)

    • Híhu ìwà tó yẹ sí adití àti afọ́jú (14)

    • Bíbani lórúkọ jẹ́ (16)

    • Má ṣe di ẹnikẹ́ni sínú (18)

    • Ẹ ò gbọ́dọ̀ pidán, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ bá ẹ̀mí lò (26, 31)

    • Ẹ ò gbọ́dọ̀ fín àmì sára yín (28)

    • Máa bọ̀wọ̀ fún àgbàlagbà (32)

    • Bó ṣe yẹ kí ẹ ṣe sí àjèjì (33, 34)

19  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:  “Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Kí ẹ jẹ́ mímọ́, torí èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.+  “‘Kí kálukú yín máa bọ̀wọ̀ fún* ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀,+ kí ẹ sì máa pa àwọn sábáàtì+ mi mọ́. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.  Ẹ má ṣe yíjú sí àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí+ tàbí kí ẹ fi irin rọ àwọn ọlọ́run+ fún ara yín. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.  “‘Tí ẹ bá rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ sí Jèhófà,+ kí ẹ rú ẹbọ náà lọ́nà tí ẹ ó fi rí ìtẹ́wọ́gbà.+  Kí ẹ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ tí ẹ bá rúbọ àti ní ọjọ́ kejì, àmọ́ kí ẹ fi iná sun+ èyí tó bá ṣẹ́ kù di ọjọ́ kẹta.  Tí ẹ bá jẹ èyíkéyìí nínú rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, ohun tí kò tọ́ lẹ ṣe, kò sì ní rí ìtẹ́wọ́gbà.  Ẹni tó bá jẹ ẹ́ yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, torí ó ti sọ ohun mímọ́ Jèhófà di aláìmọ́, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.  “‘Tí ẹ bá ń kórè oko yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ kárúgbìn eteetí oko yín tán, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ pèéṣẹ́* irè oko yín.+ 10  Bákan náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín tàbí kí ẹ ṣa àwọn èso àjàrà tó fọ́n ká sínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi í sílẹ̀ fún àwọn aláìní*+ àti àjèjì. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 11  “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jalè,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ tanni jẹ,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ hùwà àìṣòótọ́ sí ara yín. 12  Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi orúkọ mi búra èké,+ kí ẹ má bàa sọ orúkọ Ọlọ́run yín di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà. 13  Ẹ ò gbọ́dọ̀ lu ọmọnìkejì yín ní jìbìtì,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ jalè.+ Owó iṣẹ́ alágbàṣe ò gbọ́dọ̀ wà lọ́wọ́ yín di àárọ̀ ọjọ́ kejì.+ 14  “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣépè fún* adití tàbí kí ẹ fi ohun ìdènà síwájú afọ́jú,+ ẹ sì gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù Ọlọ́run yín.+ Èmi ni Jèhófà. 15  “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ yí ìdájọ́ po. Ẹ ò gbọ́dọ̀ rẹ́ aláìní jẹ tàbí kí ẹ ṣe ojúsàájú sí ọlọ́rọ̀.+ Máa ṣe ìdájọ́ òdodo tí o bá ń dá ẹjọ́ ẹnì kejì rẹ. 16  “‘O ò gbọ́dọ̀ máa bani lórúkọ jẹ́ káàkiri láàárín àwọn èèyàn rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ dìde lòdì sí ẹ̀mí* ẹnì kejì rẹ.*+ Èmi ni Jèhófà. 17  “‘O ò gbọ́dọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ nínú ọkàn rẹ.+ Kí o rí i pé o bá ẹnì kejì rẹ wí,+ kí o má bàa jẹ nínú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 18  “‘O ò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san+ tàbí kí o di ọmọ àwọn èèyàn rẹ sínú, kí o sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.+ Èmi ni Jèhófà. 19  “‘Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́: Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú kí oríṣi ẹran ọ̀sìn yín méjì bá ara wọn lò pọ̀. Ẹ ò gbọ́dọ̀ gbin oríṣi irúgbìn méjì sínú oko yín,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ wọ aṣọ tó ní oríṣi òwú méjì tí wọ́n hun pọ̀.+ 20  “‘Tí ọkùnrin kan bá dùbúlẹ̀ ti obìnrin kan, tó sì bá a lò pọ̀, tó sì jẹ́ pé ìránṣẹ́ ọkùnrin míì ni obìnrin náà, àmọ́ tí wọn ò tíì rà á pa dà tàbí dá a sílẹ̀, ẹ gbọ́dọ̀ fìyà jẹ wọ́n. Àmọ́, ẹ má pa wọ́n, torí wọn ò tíì dá obìnrin náà sílẹ̀. 21  Kí ọkùnrin náà mú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ wá fún Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àgbò kan fún ẹbọ ẹ̀bi.+ 22  Kí àlùfáà fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbà. 23  “‘Tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, tí ẹ sì gbin igi èyíkéyìí fún oúnjẹ, kí ẹ ka èso rẹ̀ sí ohun àìmọ́ àti èèwọ̀.* Ọdún mẹ́ta ni yóò fi jẹ́ èèwọ̀* fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. 24  Àmọ́ ní ọdún kẹrin, gbogbo èso rẹ̀ yóò di ohun mímọ́ láti fi yọ̀ níwájú Jèhófà.+ 25  Tó bá di ọdún karùn-ún, ẹ lè jẹ èso rẹ̀, kí ohun tí ẹ máa kórè lè pọ̀ sí i. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 26  “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tòun ti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+ “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ woṣẹ́, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ pidán.+ 27  “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ fá* irun ẹ̀gbẹ́ orí yín tàbí kí ẹ ba eteetí irùngbọ̀n yín jẹ́.+ 28  “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ kọ ara yín lábẹ torí ẹni tó kú,*+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fín àmì sí ara yín. Èmi ni Jèhófà. 29  “‘Má ba ọmọbìnrin rẹ jẹ́ nípa sísọ ọ́ di aṣẹ́wó,+ kí ilẹ̀ náà má bàa ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó, kí ìwà ìbàjẹ́+ sì kún ibẹ̀. 30  “‘Ẹ gbọ́dọ̀ máa pa àwọn sábáàtì mi mọ́,+ kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún* ibi mímọ́ mi. Èmi ni Jèhófà. 31  “‘Ẹ má tọ àwọn abẹ́mìílò lọ.+ Ẹ má sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn woṣẹ́woṣẹ́,+ kí wọ́n má bàa sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 32  “‘Kí o dìde níwájú orí ewú,+ kí o máa bọlá fún àgbàlagbà,+ kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run+ rẹ. Èmi ni Jèhófà. 33  “‘Tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ẹ́.+ 34  Kí ẹ máa ṣe àjèjì tó ń bá yín gbé bí ọmọ ìbílẹ̀;+ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara yín, torí àjèjì lẹ jẹ́ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 35  “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ lo ìwọ̀n èké tí ẹ bá ń díwọ̀n bí ohun kan ṣe gùn tó, bó ṣe wúwo tó tàbí bó ṣe pọ̀ tó.+ 36  Kí ẹ máa lo òṣùwọ̀n tó péye, ìwọ̀n tó péye, òṣùwọ̀n tó péye fún ohun tí kò lómi* àti òṣùwọ̀n tó péye fún nǹkan olómi.*+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹni tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. 37  Torí náà, kí ẹ máa pa gbogbo àṣẹ mi àti gbogbo ìdájọ́ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn.+ Èmi ni Jèhófà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “kó ohun tó bá ṣẹ́ kù lára.”
Tàbí “àwọn tí ìyà ń jẹ.”
Tàbí “pe ibi wá sórí.”
Ní Héb., “ẹ̀jẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “O ò gbọ́dọ̀ máa wò tí ẹ̀mí ọmọnìkejì rẹ bá wà nínú ewu.”
Ní Héb., “tó jẹ́ aláìkọlà.”
Ní Héb., “aláìkọlà.”
Tàbí “gé.”
Tàbí “torí ọkàn kan.” Ní ẹsẹ yìí, ọ̀rọ̀ Hébérù náà neʹphesh ń tọ́ka sí ẹni tó ti kú.
Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Ní Héb., “òṣùwọ̀n eéfà tó péye.” Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “òṣùwọ̀n hínì tó péye.” Wo Àfikún B14.