Sí Àwọn Ará Róòmù 12:1-21

  • Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè (1, 2)

  • Ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ ara kan náà (3-8)

  • Ìmọ̀ràn lórí ìgbé ayé Kristẹni tòótọ́ (9-21)

12  Nítorí náà, mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ fi ara yín+ fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, tó jẹ́ mímọ́,+ tó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, kí ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ pẹ̀lú agbára ìrònú yín.+  Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí* máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà,+ kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí+ ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.  Torí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún mi, mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ,+ àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe fún kálukú ní ìwọ̀n ìgbàgbọ́.*+  Nítorí bí ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara ṣe wà nínú ara kan,+ àmọ́ tí gbogbo ẹ̀yà ara kì í ṣe iṣẹ́ kan náà,  bẹ́ẹ̀ ni àwa, bí a tiẹ̀ pọ̀, a jẹ́ ara kan ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, àmọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a jẹ́ ẹ̀yà ara fún ẹnì kejì wa.+  Nígbà tí a sì ti ní àwọn ẹ̀bùn tó yàtọ̀ síra nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún wa,+ tó bá jẹ́ ti àsọtẹ́lẹ̀ ni, ẹ jẹ́ ká máa sọ tẹ́lẹ̀ bí ìgbàgbọ́ wa ṣe tó;  tó bá jẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni, ẹ jẹ́ kí a wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí; tàbí ẹni tó ń kọ́ni, kó wà lẹ́nu kíkọ́ni rẹ̀;+  tàbí ẹni tó ń fúnni níṣìírí,* kó máa fúnni níṣìírí;*+ ẹni tó ń pín nǹkan fúnni,* kó máa ṣe é tinútinú;+ ẹni tó ń ṣe àbójútó,* kó máa ṣe é kárakára;*+ ẹni tó ń ṣàánú, kó máa fi ọ̀yàyà ṣe é.+  Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí ẹ̀tàn.*+ Ẹ kórìíra ohun búburú;+ ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere. 10  Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín. Nínú bíbu ọlá fún ara yín, ẹ mú ipò iwájú.*+ 11  Ẹ máa ṣiṣẹ́ kára,* ẹ má ṣọ̀lẹ.*+ Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín.+ Ẹ máa ṣẹrú fún Jèhófà.*+ 12  Ẹ jẹ́ kí ìrètí tí ẹ ní máa fún yín láyọ̀. Ẹ máa fara da ìpọ́njú.+ Ẹ máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà.+ 13  Ẹ máa ṣàjọpín nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n nílò.+ Ẹ máa ṣe aájò àlejò.+ 14  Ẹ máa súre fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni;+ ẹ máa súre, ẹ má sì máa ṣépè.+ 15  Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún. 16  Bí ẹ ṣe ń ṣe sí ara yín ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹlòmíì; ẹ má ṣe máa ronú nípa àwọn ohun ńláńlá,* àmọ́ ẹ máa ronú nípa àwọn ohun tó rẹlẹ̀.+ Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín.+ 17  Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni.+ Ẹ jẹ́ kí ìrònú yín dá lé ohun tó dára lójú gbogbo èèyàn. 18  Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.+ 19  Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́, àmọ́ ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìrunú;*+ nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san, ni Jèhófà* wí.”+ 20  Àmọ́ “tí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; tí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní nǹkan mu; torí bí o ṣe ń ṣe èyí, wàá máa kó ẹyin iná jọ lé e lórí.”*+ 21  Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, àmọ́ máa fi ire ṣẹ́gun ibi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “yan ìgbàgbọ́ fún kálukú; pín ìgbàgbọ́ fún kálukú.”
Tàbí “lójú méjèèjì.”
Tàbí “mú ipò iwájú.”
Tàbí “fúnni ní nǹkan.”
Tàbí “gbani níyànjú.”
Tàbí “gbani níyànjú.”
Tàbí “àgàbàgebè.”
Tàbí “ẹ máa lo ìdánúṣe.”
Tàbí “Ẹ jẹ́ aláápọn; Ẹ jẹ́ onítara.”
Tàbí “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yín.”
Tàbí “ní èrò gíga.”
Ìyẹn, ìrunú Ọlọ́run.
Ìyẹn, láti mú kí ọkàn ẹni náà rọ̀, kí inú rẹ̀ sì yọ́.