Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 10:1-33

  • Àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ látinú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (1-13)

  • Àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ nípa ìbọ̀rìṣà (14-22)

    • Tábìlì Jèhófà àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù (21)

  • Òmìnira àti gbígba tàwọn ẹlòmíì rò (23-33)

    • “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run” (31)

10  Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn baba ńlá wa wà lábẹ́ ìkùukùu,*+ gbogbo wọn gba inú òkun kọjá,+  a sì batisí gbogbo wọn láti jẹ́ ọmọlẹ́yìn Mósè nípasẹ̀ ìkùukùu* àti òkun,  gbogbo wọn jẹ oúnjẹ tẹ̀mí+ kan náà,  gbogbo wọn sì mu ohun mímu tẹ̀mí+ kan náà. Torí wọ́n ti máa ń mu látinú àpáta tẹ̀mí tó ń tẹ̀ lé wọn, àpáta náà sì dúró fún* Kristi.+  Síbẹ̀, a pa wọ́n nínú aginjù+ nítorí inú Ọlọ́run kò dùn sí èyí tó pọ̀ jù lára wọn.  Àwọn nǹkan yìí di àpẹẹrẹ fún wa, kí àwọn ohun tó ń ṣeni léṣe má bàa máa wu àwa náà, bó ṣe wù wọ́n.+  Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe di abọ̀rìṣà, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe; gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Àwọn èèyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu. Wọ́n sì dìde láti gbádùn ara wọn.”+  Bákan náà, kí a má ṣe ìṣekúṣe,* bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe ìṣekúṣe,* tí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún (23,000) lára wọn fi kú ní ọjọ́ kan ṣoṣo.+  Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe dán Jèhófà* wò,+ bí àwọn kan nínú wọn ṣe dán an wò, tí ejò sì ṣán wọn pa.+ 10  Bákan náà, kí ẹ má ṣe máa kùn, bí àwọn kan nínú wọn ṣe kùn,+ tí apanirun sì pa wọ́n.+ 11  Àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí wọn kí ó lè jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa,+ wọ́n sì wà lákọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá. 12  Nítorí náà, kí ẹni tó bá rò pé òun dúró kíyè sára kó má bàa ṣubú.+ 13  Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.+ Àmọ́ Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra,+ ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.+ 14  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.+ 15  Mo mọ̀ pé ẹ ní òye; ẹ fúnra yín pinnu lórí ohun tí mo sọ bóyá òótọ́ ni àbí irọ́. 16  Ife ìbùkún tí a súre sí, ṣebí láti pín nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi ni?+ Ìṣù búrẹ́dì tí a bù, ṣebí láti pín nínú ara Kristi ni?+ 17  Nítorí pé ìṣù búrẹ́dì kan ló wà, àwa, bí a tilẹ̀ pọ̀, a jẹ́ ara kan,+ torí gbogbo wa ló ń jẹ nínú ìṣù búrẹ́dì kan yẹn. 18  Ẹ wo Ísírẹ́lì lọ́nà ti ara: Ǹjẹ́ àwọn tó ń jẹ ohun tí a fi rúbọ kì í ṣe alájọpín pẹ̀lú pẹpẹ?+ 19  Kí ni mo wá ń sọ? Ṣé pé ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan ni? 20  Bẹ́ẹ̀ kọ́; àmọ́ ohun tí mò ń sọ ni pé àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ, àwọn ẹ̀mí èṣù ni wọ́n fi ń rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọ́run;+ mi ò sì fẹ́ kí ẹ di alájọpín pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù.+ 21  Ẹ ò lè máa mu nínú ife Jèhófà* àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù; ẹ ò lè máa jẹun lórí “tábìlì Jèhófà”*+ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù. 22  Àbí ‘ṣé a fẹ́ máa mú Jèhófà* jowú ni’?+ A ò lágbára jù ú lọ, àbí a ní? 23  Ohun gbogbo ló bófin mu,* àmọ́ kì í ṣe ohun gbogbo ló ṣàǹfààní. Ohun gbogbo ló bófin mu, àmọ́ kì í ṣe ohun gbogbo ló ń gbéni ró.+ 24  Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.+ 25  Ẹ máa jẹ ohunkóhun tí wọ́n ń tà ní ọjà ẹran, láìṣe ìwádìí kankan kí ẹ̀rí ọkàn yín má bàa dà yín láàmú, 26  nítorí pé “Jèhófà* ló ni ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀.”+ 27  Tí aláìgbàgbọ́ bá pè yín, tí ẹ sì fẹ́ lọ, ẹ jẹ ohunkóhun tó bá gbé síwájú yín, láìṣe ìwádìí kankan kí ẹ̀rí ọkàn yín má bàa dà yín láàmú. 28  Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, “Ohun tí a fi rúbọ ni,” ẹ má ṣe jẹ ẹ́ nítorí ẹni tó sọ fún yín àti nítorí ẹ̀rí ọkàn.+ 29  Kì í ṣe ẹ̀rí ọkàn yín ni mò ń sọ, ti ẹni yẹn ni. Kí nìdí tí màá fi jẹ́ kí ẹnì kan fi ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ dá mi lẹ́jọ́ lórí ohun tí mo lómìnira láti ṣe?+ 30  Tí mo bá ń jẹ ẹ́, tí mo sì ń dúpẹ́, kí nìdí tí a ó fi máa sọ̀rọ̀ mi láìdáa nítorí ohun tí mo dúpẹ́ lé lórí?+ 31  Nítorí náà, bóyá ẹ̀ ń jẹ tàbí ẹ̀ ń mu tàbí ẹ̀ ń ṣe ohunkóhun míì, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.+ 32  Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹ má bàa di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì àti fún ìjọ Ọlọ́run,+ 33  bí mo ṣe ń gbìyànjú láti wu gbogbo èèyàn nínú ohun gbogbo, láìmáa wá ire ti ara mi+ bí kò ṣe ti ọ̀pọ̀ èèyàn, kí wọ́n lè rí ìgbàlà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “sì ni.”
Tàbí “làyè gbà.”