Málákì 3:1-18

 • Olúwa tòótọ́ wá fọ tẹ́ńpìlì rẹ̀ mọ́ (1-5)

  • Ìránṣẹ́ májẹ̀mú náà (1)

 • Jèhófà rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun (6-12)

  • Jèhófà kì í yí pa dà (6)

  • “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín” (7)

  • ‘Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá, Jèhófà yóò sì tú ìbùkún sórí yín’ (10)

 • Olódodo àti ẹni burúkú (13-18)

  • Wọ́n kọ ìwé ìrántí kan níwájú Ọlọ́run (16)

  • Ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú (18)

3  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi, á sì tún ọ̀nà ṣe* dè mí.+ Lójijì, Olúwa tòótọ́, ẹni tí ẹ̀ ń wá yóò wá sí tẹ́ńpìlì rẹ̀;+ ìránṣẹ́ májẹ̀mú yóò sì wá, ẹni tí inú yín dùn sí. Wò ó! Ó dájú pé ó máa wá.  “Àmọ́ ta ló máa lè fara da ọjọ́ tó máa wá, ta ló sì máa lè dúró nígbà tó bá fara hàn? Torí òun yóò dà bí iná ẹni tó ń yọ́ nǹkan mọ́ àti bí ọṣẹ+ alágbàfọ̀.  Ó máa jókòó bí ẹni tó ń yọ́ fàdákà, tó sì ń fọ̀ ọ́ mọ́,+ ó sì máa fọ àwọn ọmọ Léfì mọ́; á sì yọ́ wọn mọ́* bíi wúrà àti fàdákà, ó sì dájú pé wọ́n á fi ọkàn òdodo mú ọrẹ wá fún Jèhófà.  Ní tòótọ́, ọrẹ tí Júdà àti Jerúsálẹ́mù bá mú wá yóò mú inú Jèhófà dùn,* bíi ti àtijọ́ àti àwọn ọdún láéláé.+  “Èmi yóò sún mọ́ yín láti dá yín lẹ́jọ́, èmi yóò sì ta ko àwọn oníṣẹ́ oṣó láìjáfara,+ èmi yóò ta ko àwọn alágbèrè, àwọn tó ń búra èké,+ àwọn tó ń lu òṣìṣẹ́ àti opó àti ọmọ aláìníbaba* ní jìbìtì,+ títí kan àwọn tó kọ̀ láti ran àwọn àjèjì lọ́wọ́.*+ Wọn ò bẹ̀rù mi,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.  “Torí èmi ni Jèhófà; èmi kì í yí pa dà.*+ Ẹ̀yin sì ni ọmọ Jékọ́bù; ẹ kò tíì pa run.  Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti kẹ̀yìn sí àwọn ìlànà mi, ẹ kò sì tẹ̀ lé wọn.+ Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. Àmọ́, ẹ sọ pé: “Báwo la ṣe máa pa dà?”  “Ṣé èèyàn lásán lè ja Ọlọ́run lólè? Àmọ́ ẹ̀ ń jà mí lólè.” Ẹ sì sọ pé: “Ọ̀nà wo ni a gbà jà ọ́ lólè?” “Nínú ìdá mẹ́wàá àti ọrẹ ni.  Ó dájú pé ègún wà lórí yín* torí ẹ̀ ń jà mí lólè, àní gbogbo orílẹ̀-èdè yìí ló ń ṣe bẹ́ẹ̀. 10  Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá sínú ilé ìkẹ́rùsí,+ kí oúnjẹ lè wà nínú ilé mi.+ Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi èyí dán mi wò,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “kí ẹ lè rí i bóyá mi ò ní ṣí ibú omi ọ̀run,+ kí n sì tú* ìbùkún sórí yín títí ẹ kò fi ní ṣaláìní ohunkóhun.”+ 11  “Èmi yóò sì bá ẹni tó ń jẹ nǹkan run* wí torí yín, kò ní run èso ilẹ̀ yín, àjàrà inú oko yín yóò sì so èso,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 12  “Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò pè yín ní aláyọ̀,+ torí ẹ ó di ilẹ̀ tó ń múnú ẹni dùn,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 13  Jèhófà sọ pé: “Ọ̀rọ̀ líle lẹ sọ sí mi.” Ẹ sì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ líle wo la sọ sí ọ?”+ 14  “Ẹ sọ pé, ‘Kò sí àǹfààní kankan nínú sísin Ọlọ́run.+ Èrè wo la rí gbà bí a ti ń ṣe ojúṣe wa sí i, tí a sì ń kárí sọ níwájú Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun? 15  Ní báyìí, àwọn agbéraga* ni à ń pè ní aláyọ̀. Bákan náà, àwọn tó ń hùwà burúkú ń ṣàṣeyọrí.+ Àyà kò wọ́n láti dán Ọlọ́run wò, wọ́n sì ń mú un jẹ.’” 16  Ní àkókò yẹn, àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀, kálukú pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Wọ́n sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀+ torí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà àti àwọn tó ń ṣe àṣàrò lórí orúkọ rẹ̀.*+ 17  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Wọn yóò di tèmi+ ní ọjọ́ tí mo bá sọ wọ́n di ohun ìní mi pàtàkì.*+ Èmi yóò ṣàánú wọn, bí èèyàn ṣe máa ń ṣàánú ọmọ rẹ̀ tó ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu.+ 18  Ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú,+ láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “palẹ̀ ọ̀nà mọ́.”
Tàbí “mú kí wọ́n mọ́ kedere.”
Tàbí “yóò tẹ́ Jèhófà lọ́rùn.”
Tàbí “tó ń fi ẹ̀tọ́ àwọn àjèjì dù wọ́n.”
Tàbí “ọmọ aláìlóbìí.”
Tàbí “èmi kò yí pa dà.”
Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀ ń gégùn-ún fún mi.”
Ní Héb., “da.”
Ó lè jẹ́ àwọn kòkòrò tó ń ba nǹkan jẹ́ ló ń sọ.
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
Tàbí “ronú lórí orúkọ rẹ̀.” Tàbí kó jẹ́, “ka orúkọ rẹ̀ sí pàtàkì.”
Tàbí “tó ṣeyebíye.”