Diutarónómì 5:1-33

  • Jèhófà bá wọn dá májẹ̀mú ní Hórébù (1-5)

  • Wọ́n tún Òfin Mẹ́wàá sọ (6-22)

  • Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn náà ní Òkè Sínáì (23-33)

5  Mósè wá pe gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì jọ, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń kéde fún yín lónìí, kí ẹ mọ̀ wọ́n, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń pa wọ́n mọ́.  Jèhófà Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú kan ní Hórébù.+  Àwọn baba ńlá wa kọ́ ni Jèhófà bá dá májẹ̀mú yìí, àwa ni, gbogbo àwa tí a wà láàyè níbí lónìí.  Ojúkojú ni Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní òkè náà látinú iná.+  Mo dúró láàárín Jèhófà àti ẹ̀yin nígbà yẹn+ kí n lè sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún yín, torí iná náà ń dẹ́rù bà yín, ẹ ò sì lè gun òkè náà lọ.+ Ó sọ pé:  “‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.+  O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.*+  “‘O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ+ tàbí kí o ṣe ohun* kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé tàbí nínú omi nísàlẹ̀.  O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n sún ọ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi,+ 10  àmọ́ tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀* hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi títí dé ẹgbẹ̀rún ìran wọn, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́. 11  “‘O ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò tọ́,+ torí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́.+ 12  “‘Máa pa ọjọ́ Sábáàtì mọ́, kí o lè yà á sí mímọ́, bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́.+ 13  Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi ṣiṣẹ́, kí o sì fi ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,+ 14  àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti akọ màlúù rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ àti èyíkéyìí nínú ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tó ń gbé nínú àwọn ìlú* rẹ,+ kí ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ lè sinmi bíi tìẹ.+ 15  Rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì àti pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi ọwọ́ agbára àti apá rẹ̀ tó nà jáde mú ọ kúrò níbẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi pàṣẹ fún ọ pé kí o máa pa ọjọ́ Sábáàtì mọ́. 16  “‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,+ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn, kí nǹkan sì lè máa lọ dáadáa fún ọ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.+ 17  “‘O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.+ 18  “‘O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.+ 19  “‘O ò gbọ́dọ̀ jalè.+ 20  “‘O ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ.+ 21  “‘O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyàwó ọmọnìkejì rẹ wọ̀ ọ́ lójú.+ O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò ilé ọmọnìkejì rẹ tàbí oko rẹ̀ tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.’+ 22  “Àwọn àṣẹ* yìí ni Jèhófà pa fún gbogbo ìjọ yín lórí òkè náà, látinú iná àti ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà+ pẹ̀lú ohùn rara, kò sì fi ohunkóhun kún un; ó wá kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì, ó sì kó o fún mi.+ 23  “Àmọ́ gbàrà tí ẹ gbọ́ ohùn tó ń tinú òkùnkùn náà jáde, nígbà tí iná ń jó ní òkè náà,+ gbogbo olórí ẹ̀yà yín àti àwọn àgbààgbà wá sọ́dọ̀ mi. 24  Ẹ wá sọ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ àti títóbi rẹ̀ hàn wá, a sì ti gbọ́ ohùn rẹ̀ látinú iná.+ Òní la rí i pé Ọlọ́run lè bá èèyàn sọ̀rọ̀ kí onítọ̀hún má sì kú.+ 25  Ṣé ó wá yẹ ká kú ni? Iná ńlá yìí lè jó wa run. Tí a bá ṣì ń gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa, ó dájú pé a máa kú. 26  Nínú gbogbo aráyé,* ta ló tíì gbọ́ ohùn Ọlọ́run alààyè tó ń sọ̀rọ̀ látinú iná bí a ṣe gbọ́ ọ, tí onítọ̀hún ò sì kú? 27  Ìwọ fúnra rẹ ni kí o sún mọ́ ibẹ̀, kí o lè gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa máa sọ, ìwọ lo sì máa sọ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá bá ọ sọ fún wa, a máa gbọ́, a sì máa ṣe é.’+ 28  “Jèhófà gbọ́ ohun tí ẹ sọ fún mi, Jèhófà sì sọ fún mi pé, ‘Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn èèyàn yìí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ ló dáa.+ 29  Ì bá mà dáa o, tí wọ́n bá mú kí ọkàn wọn máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo,+ tí wọ́n ń pa gbogbo àṣẹ mi mọ́,+ nǹkan á máa lọ dáadáa fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn títí láé!+ 30  Lọ sọ fún wọn pé: “Ẹ pa dà sínú àwọn àgọ́ yín.” 31  Àmọ́ kí ìwọ dúró sọ́dọ̀ mi, kí n lè sọ gbogbo àṣẹ, ìlànà àti ìdájọ́ tí o máa kọ́ wọn fún ọ, èyí tí wọ́n á máa tẹ̀ lé ní ilẹ̀ tí màá fún wọn pé kó di tiwọn.’ 32  Kí ẹ rí i pé ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ fún yín gẹ́lẹ́ lẹ̀ ń ṣe.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+ 33  Gbogbo ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ máa rìn,+ kí ẹ lè máa wà láàyè, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín, kí ẹ sì lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ máa gbà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “láti fojú di mí.” Ní Héb., “níṣojú mi.”
Tàbí “àwòrán.”
Tàbí “inú rere onífẹ̀ẹ́.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Ní Héb., “ọ̀rọ̀.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”