Jẹ́nẹ́sísì 17:1-27

  • Ábúráhámù yóò di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè (1-8)

    • Orúkọ Ábúrámù yí pa dà sí Ábúráhámù (5)

  • Májẹ̀mú nípa ìdádọ̀dọ́ (9-14)

  • Orúkọ Sáráì yí pa dà sí Sérà (15-17)

  • Ọlọ́run ṣèlérí pé yóò bí Ísákì (18-27)

17  Nígbà tí Ábúrámù pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99), Jèhófà fara han Ábúrámù, ó sì sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè. Máa bá mi rìn,* kí o sì fi hàn pé o jẹ́ aláìlẹ́bi.*  Màá fìdí májẹ̀mú mi tí mo bá ọ dá+ múlẹ̀, màá sì mú kí o di púpọ̀ gan-an.”+  Ni Ábúrámù bá dojú bolẹ̀, Ọlọ́run tún sọ fún un pé:  “Wò ó! Ní tèmi, mo ti bá ọ dá májẹ̀mú,+ ó sì dájú pé wàá di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.+  O ò ní jẹ́ Ábúrámù* mọ́; orúkọ rẹ yóò di Ábúráhámù,* torí màá mú kí o di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.  Màá mú kí o bímọ tó pọ̀ gan-an, màá mú kí o di àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba yóò sì tinú rẹ jáde.+  “Màá mú májẹ̀mú mi ṣẹ, tí mo bá ìwọ+ àti ọmọ* rẹ dá jálẹ̀ gbogbo ìran wọn, pé màá jẹ́ Ọlọ́run fún ọ àti fún ọmọ* rẹ.  Màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ ní ilẹ̀ tí o gbé nígbà tí o jẹ́ àjèjì,+ ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Kénáánì, yóò jẹ́ ohun ìní wọn títí láé, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run+ wọn.”  Ọlọ́run tún sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní tìrẹ, kí o pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ jálẹ̀ àwọn ìran wọn. 10  Májẹ̀mú tí mo bá ọ dá nìyí, òun sì ni ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò máa pa mọ́: Gbogbo ọkùnrin tó wà láàárín yín gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́.*+ 11  Kí ẹ dá adọ̀dọ́ yín,* yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú tó wà láàárín èmi àti ẹ̀yin.+ 12  Jálẹ̀ àwọn ìran yín, gbogbo ọmọkùnrin tó wà láàárín yín tó jẹ́ ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́,*+ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá bí nínú ilé àti ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ* yín àmọ́ tí ẹ fi owó yín rà lọ́wọ́ àjèjì. 13  Gbogbo ọkùnrin tí wọ́n bí ní ilé rẹ àti gbogbo ọkùnrin tí o fi owó rẹ rà gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́,*+ májẹ̀mú mi tó wà nínú ẹran ara yín gbọ́dọ̀ jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. 14  Tí ọkùnrin èyíkéyìí ò bá dá adọ̀dọ́ rẹ̀, kí wọ́n pa ẹni* náà, kí wọ́n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Ó ti da májẹ̀mú mi.” 15  Ọlọ́run wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní ti Sáráì*+ ìyàwó rẹ, má pè é ní Sáráì mọ́, torí Sérà* ni yóò máa jẹ́. 16  Èmi yóò bù kún un, màá sì mú kí ó+ bí ọmọkùnrin kan fún ọ; èmi yóò bù kún un, ó máa di àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ọba àwọn èèyàn yóò sì tinú rẹ̀ jáde.” 17  Ni Ábúráhámù bá dojú bolẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, ó sì ń sọ lọ́kàn rẹ̀+ pé: “Ṣé ọkùnrin ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún lè di bàbá ọmọ? Ṣé Sérà, obìnrin ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún sì lè bímọ?”+ 18  Ábúráhámù wá sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí Íṣímáẹ́lì wà láàyè níwájú rẹ!”+ 19  Ọlọ́run fèsì pé: “Ó dájú pé Sérà ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o sì sọ ọ́ ní Ísákì.*+ Màá sì fìdí májẹ̀mú mi tí mo bá a dá múlẹ̀, ó máa jẹ́ májẹ̀mú ayérayé fún àtọmọdọ́mọ* rẹ̀.+ 20  Ní ti ohun tó o sọ nípa Íṣímáẹ́lì, mo ti gbọ́. Wò ó! Èmi yóò bù kún un, màá mú kó bímọ, màá sì mú kí ó di púpọ̀ gan-an. Ó máa bí ìjòyè méjìlá (12), màá sì mú kí ó di orílẹ̀-èdè ńlá.+ 21  Àmọ́, èmi yóò fìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Ísákì,+ ọmọ tí Sérà máa bí fún ọ ní àkókò yìí lọ́dún tó ń bọ̀.”+ 22  Nígbà tí Ọlọ́run bá a sọ̀rọ̀ tán, ó kúrò lọ́dọ̀ Ábúráhámù. 23  Ábúráhámù wá mú Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin tí wọ́n bí nínú ilé rẹ̀ àti gbogbo ẹni tó fi owó rà, gbogbo ọkùnrin inú agbo ilé Ábúráhámù, ó sì dá adọ̀dọ́ wọn* ní ọjọ́ yẹn gan-an, bí Ọlọ́run ṣe sọ fún un.+ 24  Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) ni Ábúráhámù nígbà tó dádọ̀dọ́.+ 25  Ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13) sì ni Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ nígbà tó dádọ̀dọ́.  + 26  Ní ọjọ́ yẹn gan-an, Ábúráhámù àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ dádọ̀dọ́. 27  Gbogbo ọkùnrin agbo ilé rẹ̀, gbogbo ẹni tí wọ́n bí nínú ilé náà àti ẹni tí wọ́n fi owó rà láti ọwọ́ àjèjì ló dádọ̀dọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Máa rìn níwájú mi.”
Tàbí “aláìlábùkù.”
Ó túmọ̀ sí “Bàbá Ga (Di Ẹni Àgbéga).”
Ó túmọ̀ sí “Bàbá Èèyàn Rẹpẹtẹ (Ogunlọ́gọ̀); Bàbá Ọ̀pọ̀ Èèyàn.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “kọ ara yín nílà.”
Tàbí “kọlà.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “ọkàn.”
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Alárìíyànjiyàn.”
Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí Yóò Di Ìyá Àwọn Ọba.”
Ó túmọ̀ sí “Ẹ̀rín.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “ó sì kọ wọ́n nílà.”