Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ohun tí Ọlọ́run sọ nínú Jeremáyà 7:16 túmọ̀ sí pé kí àwọn Kristẹni má gbàdúrà nípa ẹnì kan tá a yọ nínú ìjọ Kristẹni nítorí pé kò ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

Lẹ́yìn tí Jèhófà dá Júdà aláìṣòótọ́ lẹ́jọ́, ó sọ fún Jeremáyà pé: “Ní tìrẹ, má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn ènìyàn yìí, má sì ṣe gbé ohùn igbe ìpàrọwà sókè tàbí àdúrà tàbí kí o fi taratara bẹ̀ mí nítorí wọn, nítorí èmi kì yóò fetí sí ọ.”—Jeremáyà 7:16.

Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí Jeremáyà má gbàdúrà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Dájúdájú, nítorí pé wọ́n ń dìídì tẹ Òfin rẹ̀ lójú ni. Láìfi bò, láìnítìjú rárá, wọ́n ‘ń jalè, wọ́n ń ṣìkà pànìyàn, wọ́n ń ṣe panṣágà, wọ́n ń búra lọ́nà èké, wọ́n ń rú èéfín ẹbọ sí Báálì, wọ́n sì ń tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.’ Ìyẹn ló jẹ́ kí Jèhófà sọ fáwọn Júù aláìnígbàgbọ́ pé: “Èmi yóò sọ yín síta kúrò níwájú mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ gbogbo àwọn arákùnrin yín síta, gbogbo àwọn ọmọ Éfúráímù.” Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, kò ní bójú mu kí Jeremáyà, tàbí ẹnikẹ́ni, gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó yí ìdájọ́ Rẹ̀ padà.—Jeremáyà 7:9, 15.

Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé nípa irú àdúrà tí Ọlọ́run ń gbọ́. Ó kọ́kọ́ fi àwọn Kristẹni lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Nígbà tí Jòhánù wá ń sọ̀rọ̀ nípa gbígbàdúrà fáwọn ẹlòmíràn, ó fi kún un pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá tajú kán rí arákùnrin rẹ̀ tí ń ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í fa ikú wá báni, yóò béèrè, yóò sì fi ìyè fún un, bẹ́ẹ̀ ni, fún àwọn tí kì í dẹ́ṣẹ̀ tí yóò fa ikú wá báni. Ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí ń fa ikú wá báni ní tòótọ́. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ni èmi kò sọ fún un láti ṣe ìbéèrè.” (1 Jòhánù 5:16) Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ ‘tí kò ní ìdáríjì,’ èyíinì ni ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí ẹ̀mí mímọ́.—Mátíù 12:31, 32.

Ṣé ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé gbogbo àwọn tá a bá yọ nínú ìjọ Kristẹni nítorí pé wọn kò ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni wọ́n ti dá ẹ̀ṣẹ̀ “tí ń fa ikú wá báni,” tí a kò sì gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé nínú àwọn ọ̀ràn kan, irú àṣemáṣe bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni. A ò tilẹ̀ lè sọ pàtó pé ẹ̀ṣẹ̀ báyìí-báyìí ló wà ní ìsọ̀rí yẹn. Àpẹẹrẹ kan tó gba àfiyèsí ni ti Mánásè Ọba Júdà. Ó mọ pẹpẹ fáwọn èké ọlọ́run, ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ, ó bẹ́mìí lò, ó sì gbé ère fífín kan sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. Kódà, Bíbélì sọ pé Mánásè àtàwọn èèyàn náà “ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa rẹ́ ráúráú kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” Jèhófà fìyà jẹ Mánásè fún ohun tó ṣe yìí. Ó jẹ́ kí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é nígbèkùn lọ sí Bábílónì.—2 Àwọn Ọba 21:1-9; 2 Kíróníkà 33:1-11.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Mánásè burú jáì, ǹjẹ́ ó la ikú lọ? Kò jọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé ìtàn náà sọ síwájú sí i nípa Mánásè pé: “Gbàrà tí ó . . . fa wàhálà bá a, ó tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú, ó sì ń bá a nìṣó ní rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi nítorí Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀. Ó sì ń gbàdúrà sí I ṣáá, tí ó fi jẹ́ pé Ó jẹ́ kí ó pàrọwà sí òun, Ó sì gbọ́ ìbéèrè rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba rẹ̀; Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.”—2 Kíróníkà 33:12, 13.

Nípa báyìí, kò yẹ ká fi ìkánjú parí èrò sí pé ẹnikẹ́ni tá a bá yọ nínú ìjọ ti jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni nìyẹn. Ó lè gba àkókò kí ohun tó wà nínú ọkàn onítọ̀hún tó hàn síta. A sáà máa ń sọ pé ọ̀kan lára ìdí fún ìyọnilẹ́gbẹ́ ni láti mú kí orí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà wálé, bóyá á jẹ́ ronú pìwà dà, kí ó sì yí padà.

Níwọ̀n bí onítọ̀hún kì í ti í ṣe mẹ́ńbà ìjọ mọ́, bó bá ronú pìwà dà, àwọn tó sún mọ́ ọn, bí ọkọ tàbí aya rẹ̀, tàbí àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀, ló máa kọ́kọ́ mọ̀. Àwọn tó bá rí irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ lè parí èrò sí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ náà kò dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni. Ọkàn wọn lè sún wọn láti gbàdúrà pé kírú ẹni bẹ́ẹ̀ jèrè okun nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí, kí Jèhófà sì ṣe ohun tó bá bá ìfẹ́ Rẹ̀ mu sí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà.—Sáàmù 44:21; Oníwàásù 12:14.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè ní àǹfààní láti rí ẹ̀rí kíkún tó mú kí wọ́n gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ti ronú pìwà dà, ìjọ ní gbogbo gbòò lè máà rí irú ẹ̀rí yẹn. Nítorí náà, ó lè rú wọn lójú, kí ọkàn wọn dà rú, tàbí kí ó tilẹ̀ mú wọn kọsẹ̀ pàápàá, bí wọ́n bá gbọ́, tí ẹnì kan lọ ń gbàdúrà fún ẹlẹ́ṣẹ̀ náà níwájú àwùjọ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn tí ọkàn wọn bá sún wọn láti gbàdúrà nípa ẹlẹ́ṣẹ̀ náà gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ kìkì nínú àdúrà tí wọ́n ń dá gbà, kí wọ́n sì fi ìyókù sílẹ̀ fún àwọn alàgbà tí ń bójú tó ìjọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì tí Mánásè ṣẹ̀ jì í nígbà tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

A tún àwòrán yìí yà látinú Illustrierte Pracht - Bibel/Heilige Schrift des Alten und Neuen Testaments, nach der deutschen Uebersetzung D. Martin Luther’s