Kíróníkà Kejì 33:1-25

  • Mánásè di ọba Júdà (1-9)

  • Mánásè ronú pìwà dà ìwà búburú rẹ̀ (10-17)

  • Ikú Mánásè (18-20)

  • Ámọ́nì di ọba Júdà (21-25)

33  Ọmọ ọdún méjìlá (12) ni Mánásè+ nígbà tó jọba, ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+  Ó ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, torí pé ó ń ṣe àwọn ohun ìríra bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+  Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ ti wó lulẹ̀,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe àwọn òpó òrìṣà.* Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+  Ó tún mọ àwọn pẹpẹ sí ilé Jèhófà,+ níbi tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Inú Jerúsálẹ́mù ni orúkọ mi yóò máa wà títí láé.”+  Ó mọ àwọn pẹpẹ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sí àgbàlá méjì nínú ilé Jèhófà.+  Ó sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná+ ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù;+ ó ń pidán,+ ó ń woṣẹ́, ó ń ṣe oṣó, ó sì yan àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+ Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.  Ó gbé ère gbígbẹ́ tó ṣe wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ ilé tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ fún Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Inú ilé yìí àti ní Jerúsálẹ́mù, tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ni màá fi orúkọ mi sí títí láé.+  Mi ò tún ní ṣí ẹsẹ̀ Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo yàn fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọ́n bá ṣáà ti rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn, ìyẹn gbogbo Òfin, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ látọwọ́ Mósè.”  Mánásè ń ṣi Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù lọ́nà nìṣó, ó ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa run kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 10  Jèhófà bá Mánásè àti àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ títí, àmọ́ wọn ò gbọ́.+ 11  Nítorí náà, Jèhófà mú kí àwọn olórí ọmọ ogun ọba Ásíríà wá gbéjà kò wọ́n, wọ́n fi ìwọ̀ mú Mánásè,* wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é, wọ́n sì mú un lọ sí Bábílónì. 12  Nínú ìdààmú tó bá a, ó bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pé kó ṣíjú àánú wo òun,* ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀. 13  Ó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sì mú kí àánú ṣe Ọlọ́run, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un pa dà sí Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba rẹ̀.+ Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+ 14  Lẹ́yìn náà, ó mọ ògiri ẹ̀yìn òde sí Ìlú Dáfídì+ lápá ìwọ̀ oòrùn Gíhónì+ ní àfonífojì títí dé Ẹnubodè Ẹja,+ ó mọ ọ́n yí ká dé Ófélì,+ ó sì mú kí ó ga gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ó yan àwọn olórí ọmọ ogun sí gbogbo àwọn ìlú olódi ní Júdà. 15  Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú àwọn ọlọ́run àjèjì àti ère òrìṣà kúrò ní ilé Jèhófà + àti gbogbo àwọn pẹpẹ tó mọ sí òkè ilé Jèhófà+ àti sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ní kí wọ́n kó wọn dà nù sí ẹ̀yìn òde ìlú. 16  Ó tún ṣètò pẹpẹ Jèhófà,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́+ lórí rẹ̀, ó sì sọ fún Júdà pé kí wọ́n máa sin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 17  Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ lórí àwọn ibi gíga, àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run wọn nìkan ni wọ́n ń rúbọ sí. 18  Ní ti ìyókù ìtàn Mánásè àti àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwọn aríran tí wọ́n bá a sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ìtàn àwọn ọba Ísírẹ́lì. 19  Bákan náà, àdúrà rẹ̀+ àti bí Ọlọ́run ṣe gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀,+ àwọn ibi tó kọ́ ibi gíga sí, tó sì gbé àwọn òpó òrìṣà*+ àti àwọn ère gbígbẹ́ sí kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àwọn aríran rẹ̀. 20  Níkẹyìn, Mánásè sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí ilé rẹ̀; Ámọ́nì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+ 21  Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ámọ́nì+ nígbà tó jọba, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 22  Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, bí Mánásè bàbá rẹ̀ ti ṣe;+ Ámọ́nì rúbọ sí gbogbo àwọn ère gbígbẹ́ tí Mánásè bàbá rẹ̀ ṣe,+ ó sì ń sìn wọ́n. 23  Àmọ́ kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà+ bí Mánásè bàbá rẹ̀ ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;+ kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Ámọ́nì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀. 24  Níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn,+ wọ́n sì pa á nínú ilé rẹ̀. 25  Àmọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tó dìtẹ̀ mọ́ Ọba Ámọ́nì,+ wọ́n sì fi Jòsáyà+ ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “wọ́n mú Mánásè ní ibi tó jin kòtò.”
Tàbí “ó tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú.”