Jeremáyà 7:1-34

  • Ìgbẹ́kẹ̀lé asán nípa tẹ́ńpìlì Jèhófà (1-11)

  • Tẹ́ńpìlì náà yóò dà bíi Ṣílò (12-15)

  • Ọlọ́run kọ ìjọsìn wọn (16-34)

    • Wọ́n jọ́sìn “Ọbabìnrin Ọ̀run” (18)

    • Wọ́n ń fi ọmọ rúbọ ní Hínómù (31)

7  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, ó ní:  “Dúró sí ẹnubodè ilé Jèhófà, kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀ pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin èèyàn Júdà tó ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé láti wá forí balẹ̀ fún Jèhófà.  Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe, màá sì jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí.+  Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Èyí ni* tẹ́ńpìlì Jèhófà, tẹ́ńpìlì Jèhófà, tẹ́ńpìlì Jèhófà!’+  Tí ẹ bá tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe lóòótọ́, tó bá sì jẹ́ pé òótọ́ lẹ ṣe ìdájọ́ òdodo láàárín èèyàn kan àti ọmọnìkejì rẹ̀,+  bí ẹ kò bá ni àjèjì lára àti ọmọ aláìlóbìí,* pẹ̀lú àwọn opó,+ tí ẹ kò ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì tó máa yọrí sí ìṣeléṣe yín; +  nígbà náà, màá jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí, ní ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé.”’”*  “Àmọ́, ẹ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,+ kò ní ṣe yín láǹfààní kankan.  Ṣé ẹ lè máa jalè+ tàbí kí ẹ máa pa èèyàn, kí ẹ máa ṣe àgbèrè tàbí kí ẹ máa búra èké,+ kí ẹ máa rú ẹbọ* sí Báálì,+ kí ẹ sì máa tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì tí ẹ kò mọ̀, 10  kí ẹ wá dúró níwájú mi nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, kí ẹ sì sọ pé, ‘A ó rí ìgbàlà,’ pẹ̀lú gbogbo ohun ìríra tí ẹ ti ṣe yìí? 11  Ṣé ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè ti wá di ihò tí àwọn olè ń fara pa mọ́ sí lójú yín ni?+ Èmi fúnra mi ti rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe,” ni Jèhófà wí. 12  “‘Àmọ́, ní báyìí ẹ lọ sí àyè mi ní Ṣílò,+ níbi tí mo mú kí orúkọ mi wà ní ìbẹ̀rẹ̀,+ kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì.+ 13  Ṣùgbọ́n ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí,’ ni Jèhófà wí, ‘àní bí mo tiẹ̀ bá yín sọ̀rọ̀ léraléra,* ẹ kò fetí sílẹ̀.+ Mo sì ń pè yín ṣáá, ṣùgbọ́n ẹ kò dá mi lóhùn.+ 14  Bí mo ti ṣe sí Ṣílò, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe sí ilé tí a fi orúkọ mi pè,+ èyí tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé+ àti sí ibi tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.+ 15  Màá lé yín síta kúrò níwájú mi, bí mo ṣe lé gbogbo àwọn arákùnrin yín síta, gbogbo àwọn ọmọ Éfúrémù.’+ 16  “Ní tìrẹ, má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn èèyàn yìí. Má ṣe sunkún tàbí kí o gbàdúrà tàbí kí o bẹ̀ mí nítorí wọn,+ torí mi ò ní fetí sí ọ.+ 17  Ṣé o ò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù ni? 18  Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn bàbá ń dá iná, àwọn ìyàwó sì ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà ìrúbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run,*+ wọ́n sì ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì láti mú mi bínú.+ 19  ‘Àmọ́ ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú?’* ni Jèhófà wí. ‘Ǹjẹ́ kì í ṣe ara wọn ni wọn ń ṣe, tí wọ́n ń dójú ti ara wọn?’+ 20  Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Wò ó! Ìbínú mi àti ìrunú mi yóò dà sórí ibí yìí,+ sórí èèyàn àti ẹranko, sórí igi oko àti èso ilẹ̀. Ìbínú mi yóò máa jó bí iná tí kò ṣeé pa.’+ 21  “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ lọ, kí ẹ fi odindi ẹbọ sísun yín kún àwọn ẹbọ yín yòókù, kí ẹ sì jẹ ẹran rẹ̀.+ 22  Torí láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mi ò bá wọn sọ̀rọ̀ tàbí kí n pàṣẹ fún wọn lórí àwọn odindi ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ.+ 23  Ṣùgbọ́n, mo pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, màá sì di Ọlọ́run yín, ẹ ó sì di èèyàn mi.+ Kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún yín, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín.”’+ 24  Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sílẹ̀,+ kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń rìn nínú ètekéte* wọn, wọ́n ya alágídí, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ,+ ńṣe ni wọ́n ń pa dà sẹ́yìn, wọn ò lọ síwájú, 25  láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì títí di òní.+ Torí náà, mò ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mò ń rán wọn lójoojúmọ́, mo sì ń rán wọn léraléra.*+ 26  Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, wọn kò sì fetí sílẹ̀.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ya alágídí,* wọ́n sì ṣe ohun tó burú ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ! 27  “Wàá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún wọn,+ ṣùgbọ́n wọn ò ní fetí sí ọ. Wàá pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn ò ní dá ọ lóhùn. 28  Wàá sì sọ fún wọn pé, ‘Orílẹ̀-èdè tí kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ nìyí, kò sì gba ìbáwí. Kò sí òtítọ́ mọ́, a ò tiẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàárín wọn mọ́.’*+ 29  “Fá irun gígùn* rẹ, kí o dà á nù, kí o sì kọ orin arò* lórí àwọn òkè, nítorí pé Jèhófà ti kọ ìran àwọn èèyàn tó mú un bínú yìí, yóò sì pa á tì. 30  ‘Nítorí àwọn èèyàn Júdà ti ṣe ohun tó burú ní ojú mi,’ ni Jèhófà wí. ‘Wọ́n ti gbé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn kalẹ̀ sínú ilé tí a fi orúkọ mi pè, láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin.+ 31  Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga Tófétì, èyí tó wà ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,*+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí.’*+ 32  “‘Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘tí a kò ní pè é ní Tófétì tàbí Àfonífojì Ọmọ Hínómù mọ́,* àmọ́ Àfonífojì Ìpànìyàn la ó máa pè é. Wọ́n á sin òkú ní Tófétì títí kò fi ní sí àyè mọ́.+ 33  Òkú àwọn èèyàn yìí á di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀, láìsí ẹnikẹ́ni tó máa lé wọn dà nù.+ 34  Màá fòpin sí ìró ayọ̀ àti ìró ìdùnnú, ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó+ ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù, nítorí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Wọ́n jẹ́,” ìyẹn gbogbo àwọn ilé tó wà ní tẹ́ńpìlì náà.
Tàbí “àwọn ọmọ aláìníbaba.”
Tàbí “láti ayérayé dé ayérayé.”
Tàbí “mú ẹbọ rú èéfín.”
Ní Héb., “dìde ní kùtùkùtù láti bá yín sọ̀rọ̀.”
Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
Tàbí “ṣẹ̀ sí?”
Tàbí “ìmọ̀ràn.”
Ní Héb., “mò ń jí ní kùtùkùtù lójoojúmọ́, mo sì ń rán wọn.”
Ní Héb., “wọ́n mú ọrùn wọn le.”
Ní Héb., “a ti gé e kúrò ní ẹnu wọn.”
Tàbí “irun ìyàsọ́tọ̀.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”
Tàbí “ohun tí èmi kò ronú rẹ̀ rí.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”