Jẹ́nẹ́sísì 39:1-23

  • Jósẹ́fù ní ilé Pọ́tífárì (1-6)

  • Jósẹ́fù ò gbà fún ìyàwó Pọ́tífárì (7-20)

  • Jósẹ́fù ṣẹ̀wọ̀n (21-23)

39  Wọ́n wá mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì,+ Pọ́tífárì+ ará Íjíbítì tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò àti olórí ẹ̀ṣọ́ sì rà á lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì+ tó mú un lọ síbẹ̀.  Àmọ́ Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù.+ Ìyẹn mú kó ṣàṣeyọrí, ọ̀gá rẹ̀ tó jẹ́ ará Íjíbítì sì fi ṣe alábòójútó ilé rẹ̀.  Ọ̀gá rẹ̀ sì rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀ àti pé Jèhófà ń mú kí gbogbo ohun tó ń ṣe yọrí sí rere.  Jósẹ́fù máa ń rí ojúure rẹ̀, ó sì di ìránṣẹ́ Pọ́tífárì fúnra rẹ̀. Ó wá fi ṣe olórí ilé rẹ̀, ó sì ní kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní òun.  Látìgbà tí ọ̀gá rẹ̀ ti fi ṣe olórí ilé rẹ̀, tó sì ń bójú tó gbogbo ohun tó ní, Jèhófà ń bù kún ilé ará Íjíbítì náà torí Jósẹ́fù. Jèhófà sì bù kún gbogbo ohun ìní Pọ́tífárì nílé lóko.+  Nígbà tó yá, ó fi gbogbo ohun tó ní sí ìkáwọ́ Jósẹ́fù, kò sì da ara rẹ̀ láàmú nípa ohunkóhun àfi oúnjẹ tó ń jẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Jósẹ́fù taagun, ó sì rẹwà.  Lẹ́yìn náà, ojú ìyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù kò kúrò lára rẹ̀, ó sì ń sọ fún un pé: “Wá bá mi sùn.”  Àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà, ó sì sọ fún ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ọ̀gá mi kì í yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò nínú ilé, ó sì ti fa gbogbo ohun tó ní lé mi lọ́wọ́.  Kò sẹ́ni tó tóbi jù mí lọ nínú ilé yìí, kò sì fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn fún mi àyàfi ìwọ, torí pé ìwọ ni ìyàwó rẹ̀. Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?”+ 10  Ojoojúmọ́ ló ń bá Jósẹ́fù sọ ọ́, àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà rárá láti bá a sùn tàbí kó wà pẹ̀lú rẹ̀. 11  Lọ́jọ́ kan tí Jósẹ́fù wọnú ilé lọ ṣiṣẹ́ rẹ̀, kò sí ìránṣẹ́ ilé kankan nínú ilé. 12  Obìnrin náà di aṣọ rẹ̀ mú, ó sì sọ pé: “Wá bá mi sùn!” Àmọ́ Jósẹ́fù fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì sá jáde. 13  Bí obìnrin náà ṣe rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, tó sì ti sá jáde, 14  ó bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe àwọn èèyàn tó wà nílé, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Ó mú ọkùnrin Hébérù yìí wá sọ́dọ̀ wa kó lè fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wá bá mi, ó fẹ́ bá mi sùn, àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í ké tantan. 15  Bó ṣe wá rí i pé mò ń pariwo, tí mo sì ń kígbe, ó fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sá jáde.” 16  Lẹ́yìn náà, obìnrin náà fi aṣọ Jósẹ́fù sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ títí ọ̀gá rẹ̀ fi dé sí ilé. 17  Ó sọ ohun kan náà fún un, ó ní: “Ìránṣẹ́ Hébérù tí o mú wá sọ́dọ̀ wa wá bá mi kó lè fi mí ṣe ẹlẹ́yà. 18  Àmọ́ gbàrà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, tí mo sì kígbe, ó fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sá jáde.” 19  Gbàrà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ohun tí ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Ohun tí ìránṣẹ́ rẹ ṣe sí mi nìyí,” inú bí i gan-an. 20  Ni ọ̀gá Jósẹ́fù bá ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí wọ́n ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí, ó sì wà níbẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n.+ 21  Àmọ́ Jèhófà ò fi Jósẹ́fù sílẹ̀, ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí i, ó sì ń mú kó rí ojúure ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n+ náà. 22  Ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wá fi Jósẹ́fù ṣe olórí gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú ẹ̀wọ̀n, òun ló sì máa ń rí sí i pé wọ́n ṣe gbogbo iṣẹ́ tó wà níbẹ̀.+ 23  Ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ò yẹ Jósẹ́fù lọ́wọ́ wò rárá, torí Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, Jèhófà sì ń mú kí gbogbo ohun tó bá ṣe yọrí sí rere.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé