Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú

Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú

Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú

“Jèhófà ti fòróró yàn mí . . . láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.”—AÍSÁYÀ 61:1, 2.

1, 2. Àwọn wo ló yẹ ká tù nínú, kí sì nìdí?

 JÈHÓFÀ tí í ṣe Ọlọ́run ìtùnú gbogbo ń kọ́ wa láti lẹ́mìí aájò nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ búburú bá ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹlòmíràn. Ó kọ́ wa pé ká “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́” ká sì máa tu gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú. (1 Tẹsalóníkà 5:14) A máa ń ṣe irú ìrànlọ́wọ́ yìí fáwọn olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ wa nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Bákan náà la tún ń fìfẹ́ hàn sáwọn tí kì í ṣe ará, títí dórí àwọn tó kórìíra wa tẹ́lẹ̀.—Mátíù 5:43-48; Gálátíà 6:10.

2 Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ka iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ kan ó sì sọ pé ó ṣẹ sí òun lára, èyí tó kà pé: “Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ń bẹ lára mi, nítorí ìdí náà pé Jèhófà ti fòróró yàn mí láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Ó ti rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn, . . . láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.” (Aísáyà 61:1, 2; Lúùkù 4:16-19) Kì í ṣòní kì í ṣàná táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró òde òní ti mọ̀ pé iṣẹ́ yìí kan àwọn náà, tayọ̀tayọ̀ sì làwọn “àgùntàn mìíràn” fi ń dara pọ̀ mọ́ wọn nínú iṣẹ́ náà.—Jòhánù 10:16.

3. Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá béèrè pé, “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbà pé kí ìṣẹ̀lẹ̀ búburú máa ṣẹlẹ̀?”

3 Tí ìṣẹ̀lẹ̀ búburú bá ṣẹlẹ̀ tí ìbànújẹ́ sì dorí àwọn èèyàn kodò, ìbéèrè tí wọ́n sábà máa ń béèrè ni pé, “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbà pé kí ìṣẹ̀lẹ̀ búburú máa ṣẹlẹ̀?” Bíbélì dáhùn ìbéèrè náà ní kedere. Àmọ́ ó lè gba àkókò díẹ̀ kí ẹnì kan tí ò tíì di akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lè lóye ìdáhùn náà ní kíkún. A lè rí ìrànlọ́wọ́ nípa èyí nínú àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. a Àmọ́ rírí táwọn kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ rí àwọn ẹsẹ Bíbélì bí irú èyí tó wà nínú Aísáyà 61:1, 2 ti tù wọ́n nínú gan-an, níwọ̀n bó ti sọ pé Ọlọ́run fẹ́ kí ẹ̀dá èèyàn rí ìtùnú gbà.

4. Báwo ni Ẹlẹ́rìí kan ní Poland ṣe ran ọmọbìnrin kan tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò lọ́wọ́, báwo sì ní ìrírí yìí ṣe lè mú kó o ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?

4 Àtọmọdé àtàgbà ló nílò ìtùnú o. Ọmọbìnrin kan tí ò tíì pé ọmọ ogún ọdún ní Poland, tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò lọ bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan pé kó dákun kó gba òun nímọ̀ràn. Ọ̀rẹ́ yìí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ̀sọ̀ béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ ọmọbìnrin náà, èyí jẹ́ kó rí i pé àwọn ìbéèrè kan wà tó ń gbé ọmọbìnrin náà lọ́kàn àti pé ó tún ń ṣiyèméjì lórí: “Kí ló fà á táwọn nǹkan búburú fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Kí ló dé táwọn èèyàn fi ń jìyà? Kí nìdí tí àbúrò mi tó ya abirùn fi ń jìyà? Kí nìdí tí àrùn ọkàn fi ń yọ mí lẹ́nu? Ohun tí wọ́n ń sọ fún mi ní Ṣọ́ọ̀ṣì ni pé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí nìyẹn. Àmọ́ tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí lóòótọ́, mi ò ní sin Ọlọ́run mọ́!” Ẹlẹ́rìí náà kọ́kọ́ gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Jèhófà, ó wá sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé o bi mí láwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Màá sì gbìyànjú láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.” Ó wá sọ fún ọmọbìnrin náà pé òun pẹ̀lú ṣiyèméjì gan-an nígbà tóun wà lọ́mọdé, àti pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ran òun lọ́wọ́ nígbà náà. Ó ní: “Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe Ọlọ́run ló ń mú káwọn èèyàn jìyà. Ó fẹ́ràn wọn, kìkì ohun tó dára ló sì ń fẹ́ fún wọn, àti pé ó máa ṣe àwọn àtúnṣe tó ṣe pàtàkì lórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́. Àìsàn, ìṣòro ọjọ́ ogbó àti ikú ò ní sí mọ́, àwọn onígbọràn èèyàn á wà láàyè títí láé—lórí ilẹ̀ ayé ńbí.” Ó ka Ìṣípayá 21:3, 4; Jóòbù 33:25; Aísáyà 35:5-7 àti Aísáyà 65:21-25, fún ọmọbìnrin náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ dáadáa, ọmọbìnrin náà tí ọkàn rẹ̀ ti balẹ̀ wá sọ pé: “Mo ti wá mọ ìdí tí mo fi wà láyé báyìí. Ṣé mo tún lè padà wá sọ́dọ̀ rẹ?” Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń bá ọmọbìnrin yìí ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Lo Ìtùnú Tó Ń Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

5. Kí ló lè fún àwọn èèyàn ní ojúlówó ìtùnú nígbà tá a bá ń bá wọn kẹ́dùn?

5 Sísọ àwọn ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn nígbà tá a bá ń tu àwọn ẹlòmíràn nínú dára lọ́pọ̀lọpọ̀. A máa ń gbìyànjú láti jẹ́ káwọn ọ̀rọ̀ tá à ń sọ àti ọ̀nà tá a gbà ń sọ ọ́ mú un dá àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn bá lójú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn ká wa lára gan-an. Àmọ́ èyí ò lè ṣeé ṣe tí àwọn ọ̀rọ̀ tá à ń sọ ò bá dénú. Bíbélì sọ fún wa pé “nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, . . . a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Bá a bá fi èyí sọ́kàn, àá lè ṣàlàyé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí lákòókò tó yẹ, àá sì tún lè fi hàn wọ́n látinú Bíbélì bó ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro lọ́ọ́lọ́ọ́. Nígbà náà, àá lè bá wọn fèrò wérò nípa bó ṣe jẹ́ ìrètí tó ṣe é gbọ́kàn lé. Lọ́nà yìí, àá lè fún àwọn èèyàn ní ìtùnú.

6. Kí la gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ kí wọ́n bàa lè jàǹfààní ìtùnú tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?

6 Káwọn èèyàn tó lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú ìtùnú tá à ń fún wọn, wọ́n ní láti mọ Ọlọ́run òtítọ́ náà, kí wọ́n mọ irú Ẹni tó jẹ́ àti bí àwọn ìlérí rẹ̀ ṣe ṣeé gbíyè lé tó. Nígbà tá a bá ń ran ẹnì kan tí kò tí ì di olùjọ́sìn Jèhófà lọ́wọ́, ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká ṣàlàyé àwọn kókó wọ̀nyí fún un (1) Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ náà ni ìtùnú tó wà nínú Bíbélì ti wá; (2) Jèhófà ni Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá ayé àti ọ̀run. Ọlọ́run ìfẹ́ ni, inú rere onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀. (3) A lè rí okun gbà láti fara da àwọn ipò tí ò fara rọ tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run nípa níní ìmọ̀ pípéye látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (4) Àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tó jẹ mọ́ oríṣi àwọn àdánwò kan pàtó táwọn èèyàn lónírúurú ń kojú wà nínú Bíbélì.

7. (a) Kí lohun tá a lè ṣe láṣeyọrí tá a bá ń fi yé àwọn èèyàn pé ìtùnú tí Ọlọ́run ń pèsè “nípasẹ̀ Kristi pọ̀ gidigidi”? (b) Báwo lo ṣe lè fún ẹnì kan tó ń kábàámọ̀ nítorí ìwàkiwà tó hù sẹ́yìn ní ìtùnú?

7 Àwọn kan ti fún àwọn tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò àmọ́ tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní ìtùnú nípa kíka 2 Kọ́ríńtì 1:3-7 fún wọn. Bí wọ́n ṣe ń kà á, wọ́n tẹnu mọ́ gbólóhùn náà “ìtùnú tí a ń rí gbà nípasẹ̀ Kristi pọ̀ gidigidi pẹ̀lú.” Ẹsẹ Bíbélì yìí lè jẹ́ kéèyàn mọ̀ pé Bíbélì ni orísun ìtùnú tó yẹ kóun túbọ̀ gbé yẹ̀ wò. Kódà, ẹ tún lè jíròrò síwájú sí i nínú rẹ̀ pàápàá bóyá láwọn àkókò mìíràn. Bí ẹnì kan bá sì ronú pé àwọn nǹkan burúkú tóun ti ṣe sẹ́yìn lòun ń jìyà rẹ̀ báyìí, kì í ṣe tiwa láti máa ṣe lámèyítọ́, a lè sọ fún un pé ó lè rí ìtùnú nínú àkọsílẹ̀ tó wà ní 1 Jòhánù 2:1, 2 àti Sáàmù 103:11-14. Láwọn ọ̀nà wọ̀nyí, ńṣe là ń fi ìtùnú tí Ọlọ́run ń pèsè tu àwọn ẹlòmíràn nínú.

Tu Àwọn Tí Ìwà Ipá Tàbí Ìṣòro Ìṣúnná Owó Ti Sọ Ìgbésí Ayé Wọn Dìdàkudà Nínú

8, 9. Báwo la ṣe lè fún àwọn tá a hùwà ipá sí ní ìtùnú lọ́nà tó tọ́ tó sì yẹ?

8 Àìmọye èèyàn ni ìwà ipá—yálà èyí tó ṣẹlẹ̀ lágbègbè kan tàbí ogun—ti sọ ìgbésí ayé wọn dìdàkudà. Báwo la ṣe lè tù wọ́n nínú?

9 Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń lo ìṣọ́ra gan-an kí wọ́n má bàa ṣètìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ kan tàbí òmíràn nínú rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. (Jòhánù 17:16) Ṣùgbọ́n wọ́n ń lo Bíbélì bó ṣe yẹ láti fi hàn pé ipò àwọn nǹkan tó le koko bí ojú ẹja yìí ò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí ayé. Wọ́n lè ka Sáàmù 11:5 láti jẹ́ káwọn èèyàn rí irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn tó fẹ́ràn ìwà ipá tàbí kí wọ́n ka Sáàmù 37:1-4 láti fi hàn bí Ọlọ́run ṣe gbà wá nímọ̀ràn láti má ṣe gbẹ̀san kàkà bẹ́ẹ̀ ká gbọ́kàn lé Ọlọ́run. Àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 72:12-14, fi bí ọ̀ràn àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tá a ń hùwà ipá sí ṣe rí lára Sólómọ́nì Gíga Jù Lọ, ìyẹn Jésù Kristi, tó ti di Ọba lókè ọ̀run báyìí.

10. Ká ní kìkì ogun ṣáá lò ń rí láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí wọ̀nyí ṣe lè tù ọ́ nínú?

10 Àwọn kan wà tó jẹ́ pé látìgbà tá a ti bí wọn ni wọ́n ti ń rí báwọn èèyàn ṣe ń jagun lóríṣiríṣi kí agbára lè bọ́ sí wọn lọ́wọ́. Irú àwọn èèyàn yìí ti gba kámú pé ara nǹkan téèyàn wá rí nílé ayé ni ogun àti wàhálà tó ń tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. Ìrètí kan ṣoṣo tí wọ́n ní ni pé ó ṣeé ṣe kí ipò àwọn nǹkan rọjú díẹ̀ táwọn bá káńgárá àwọn táwọn sì mú ọ̀nà orílẹ̀-èdè mìíràn pọ̀n. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ni kì í rọ́nà àtiṣe èyí, ọ̀pọ̀ tó sì ti gbìyànjú rẹ̀ ló ti ṣòfò ẹ̀mí. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó rọ́nà sá lọ sórílẹ̀-èdè mìíràn sọ pé ìṣòro làwọn tún lọ ń bá yí níbi táwọn sá lọ. A lè fi Sáàmù 146:3-6, ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ pé kí wọ́n ní ìrètí nínú ohun kan tó ṣeé gbíyè lé ju ṣíṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn lọ. Àsọtẹ́lẹ̀ inú Mátíù 24:3, 7, 14 tàbí 2 Tímótì 3:1-5, lè mú kí wọ́n túbọ̀ lóye bí gbogbo ọ̀ràn náà ṣe rí lápapọ̀ kí wọ́n sì mọ bí ọ̀ràn ipò àwọn nǹkan tí wọ́n ń fara dà ṣe jẹ́, ìyẹn ni pé àkókò òpin ètò ògbólógbòó náà la wà yìí. Àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi Sáàmù 46:1-3, 8, 9 àti Aísáyà 2:2-4, á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ní ti tòótọ́ ìrètí wà pé ọjọ́ ọ̀la á dára.

11. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló fún obìnrin kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ní ìtùnú, èé sì ti ṣe?

11 Lákòókò kan tí ogun ń jà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, obìnrin kan sá kúrò nílé rẹ̀ lákòókò tí òjò ọta ìbọn ń rọ̀ lọ́tùn-ún lósì. Ìbẹ̀rù, ìbànújẹ́, ìjákulẹ̀ ńláǹlà ò jẹ́ kí obìnrin yìí gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀. Nígbà tó yá, tóun àti ìdílé rẹ̀ ń gbé orílẹ̀-èdè mìíràn, ọkọ rẹ̀ sọ pé òun máa dáná sun ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó wọn, pé òun á lé obìnrin yìí jáde toyúntoyún àti ọmọ wọn tí ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́wàá lọ, pé òun á wá di àlùfáà. Nígbà tí wọ́n ka Fílípì 4:6, 7 àti Sáàmù 55:22, fun obìnrin yìí, àtàwọn àpilẹ̀kọ tá a gbé karí Ìwé Mímọ́ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, ó wá rí ìtùnú ó sì wá rí i pé òun ò kàn wà láàyè lásán.

12. (a) Ìtùnú wo ni Ìwé Mímọ́ fún àwọn tí ètò ọrọ̀ ajé ń hàn léèmọ̀? (b) Báwo ni obìnrin kan ní ilẹ̀ Éṣíà ṣe ran oníbàárà rẹ̀ lọ́wọ́?

12 Àìmọye èèyàn ni ètò ọrọ̀ ajé tó ń dẹnu kọlẹ̀ ti ṣe ìgbésí ayé wọn báṣubàṣu. Ogun àtàwọn nǹkan mìíràn tó ń tẹ̀yìn rẹ̀ jáde ló sì ń fa èyí náà nígbà mìíràn. Láwọn àkókò kan, àwọn ìlànà tí ò lọ́gbọ́n nínú tí ìjọba gbé kalẹ̀, ìwà ìwọra àti ìwà àìṣòótọ́ àwọn aláṣẹ ti mú kí wọ́n ṣe gbogbo owó táwọn èèyàn fi pa mọ́ báṣubàṣu, èyí sì ti mú káwọn èèyàn pàdánù àwọn ohun ìní wọn. Àwọn míì sì wà tí wọn ò fìgbà kan rí ní ọ̀pọ̀ àwọn ohun èlò téèyàn fi ń gbádùn ayé. Irú àwọn èèyàn wọ̀nyí lè rí ìtùnú nínú mímọ̀ pé Ọlọ́run ti mú un dáni lójú pé òun á mú ayé rọ gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé òun lọ́rùn gbẹ̀dẹ̀gbẹdẹ àti pé ayé òdodo kan ń bọ̀ níbi táwọn èèyàn á ti gbádùn iṣẹ́ tí wọ́n bá ń ṣe. (Sáàmù 146:6, 7; Aísáyà 65:17, 21-23; 2 Pétérù 3:13) Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan ní orílẹ̀-èdè kan tó wà ní ilẹ̀ Éṣíà gbọ́ tí oníbàárà rẹ̀ ń ṣàròyé pé ọkàn òun ò balẹ̀ nítorí ètò ọrọ̀ ajé tí kò dúró sójú kan níbẹ̀, Ẹlẹ́rìí náà sọ fún obìnrin yìí pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri àgbáyé. Wọ́n jọ jíròrò Mátíù 24:3-14 àti Sáàmù 37:9-11, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé sì tipa báyìí bẹ̀rẹ̀.

13. (a) Nígbà tí ìlérí asán bá ti mú kí nǹkan tojú sú àwọn èèyàn, báwo la ṣe lè fi Bíbélì ràn wọ́n lọ́wọ́? (b) Bí àwọn èèyàn bá ronú pé bí ipò àwọn nǹkan ṣe dìdàkudà yìí jẹ́ ẹ̀rí pé kò sí Ọlọ́run, báwo lo ṣe lè tún èrò wọn ṣe?

13 Tó bá ti pẹ́ tójú àwọn èèyàn ti ń rí màbo tàbí tó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti ń ṣe ìlérí asán fún wọn, wọ́n lè dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Íjíbítì tí wọn ò fetí sílẹ̀ mọ́ nítorí “ìrẹ̀wẹ̀sì” tó bá wọn. (Ẹ́kísódù 6:9) Tí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣàǹfààní láti mẹ́nu ba àwọn ọ̀nà tí Bíbélì lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro òde òní kí wọ́n sì yẹra fún àwọn ọ̀fìn tó ń ba ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́. (1 Tímótì 4:8b) Àwọn mìíràn lè sọ pé bí ipò àwọn nǹkan ti ṣe dìdàkudà yìí jẹ́ ẹ̀rí pé kò sí Ọlọ́run tàbí pé ńṣe ni kò bìkítà nípa àwọn. O lè ronú nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o lè lò láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ti pèsè ìrànlọ́wọ́, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò tíì gba ìrànlọ́wọ́ náà.—Aísáyà 48:17, 18.

Fún Àwọn Tó Kàgbákò Ìjì Líle àti Ilẹ̀ Ríri Ní Ìtùnú

14, 15. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi hàn pé àwọn bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn lákòókò kan tí àjálù ńlá kó jìnnìjìnnì bá ọ̀pọ̀ èèyàn?

14 Ìjì líle, ilẹ̀ ríri, iná tàbí kí nǹkan bú gbàù lè mú káwọn èèyàn kàgbákò. Ọ̀pọ̀ èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀. Báwo la ṣe lè tu àwọn tó bá rù ú là nínú?

15 Ohun táwọn èèyàn ń fẹ́ ni pé kí wọ́n rí i pé àwọn ẹlòmíràn bìkítà nípa àwọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni jìnnìjìnnì bò nígbà tí àwọn apániláyà fa àjálù ńlá ní orílẹ̀-èdè kan báyìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni mọ̀lẹ́bí wọn, ẹni tó ń gbọ́ bùkátà wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn ṣòfò ẹ̀mí. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn mìíràn, àwọn míì sì pàdánù àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tí wọ́n ní. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran àwọn tó wà lágbègbè wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣèbẹ̀wò kára-ó-le sọ́dọ̀ wọn, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn látinú Bíbélì. Ọ̀pọ̀ èèyàn mọrírì ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn yìí gan-an.

16. Nígbà tí àjálù ṣẹlẹ̀ lágbègbè kan ní orílẹ̀-èdè El Salvador, kí nìdí tí òde ẹ̀rí táwọn Ẹlẹ́rìí ibẹ̀ lọ fi so èso rere?

16 Kété tí ilẹ̀ ríri lílágbára ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè El Salvador lọ́dún 2001 ni omíyalé náà tún kó tiẹ̀ dé, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló sì bá a rìn. Ẹlẹ́rìí kan ní ọmọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ẹ̀mí ọmọkùnrin yìí àti tàwọn méjì mìíràn tí wọ́n jẹ́ àbúrò àfẹ́sọ́nà rẹ̀ lọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kíá ni ìyá ọmọkùnrin yìí àti àfẹ́sọ́nà ọmọkùnrin náà ṣara gírí tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ fún wọn pé Ọlọ́run ló mú àwọn tó kú náà lọ sọ́run tàbí pé àmúwá Ọlọ́run ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ka Òwe 10:22 láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa ní ìrora. Wọ́n ka Róòmù 5:12 láti fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀dá èèyàn dá ló fa ikú, pé Ọlọ́run kọ́ ló fà á. Bákan náà ni wọ́n tún jẹ́ káwọn èèyàn rí ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Sáàmù 34:18; Sáàmù 37:29; Aísáyà 25:8 àti Ìṣípayá 21:3, 4. Àwọn èèyàn tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí wọn, àgàgà nítorí pé àwọn obìnrin méjèèjì yìí lèèyàn wọn kú nínú ìjábá náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

17. Irú ìrànlọ́wọ́ wo la lè ṣe fáwọn èèyàn nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?

17 Nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, o lè rí ẹnì kan tó nílò ìrànlọ́wọ́ ojú ẹsẹ̀. Èyí lè ní kíkàn sí dókítà nínú, gbígbé ẹni náà lọ sílé ìwòsàn tàbí ṣíṣe ohun tó bá ṣeé ṣe láti pèsè oúnjẹ tàbí ibùgbé fún onítọ̀hún. Nígbà tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí wáyé ní Ítálì lọ́dún 1998, akọ̀ròyìn kan sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “ṣe gudugudu méje. Gbogbo àwọn tí wàhálà náà kàn ni wọ́n ràn lọ́wọ́, láìfi ti ẹ̀sìn táwọn èèyàn yìí ń ṣe pè.” Àwọn ibì kan wà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá a sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n á wáyé lákòókò òpin ti ń fa ìjìyà ńláǹlà. Láwọn ibi tí èyí ti ń ṣẹlẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wọ̀nyí fáwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń fi ìdánilójú tí Bíbélì fúnni pé Ìjọba Ọlọ́run á mú ààbò tó péye wá fún ẹ̀dá èèyàn tu àwọn èèyàn nínú.—Òwe 1:33; Míkà 4:4.

Fún Àwọn Téèyàn Wọn Kú Ní Ìtùnú

18-20. Bí ẹnì kan bá ṣaláìsí nínú ìdílé kan, kí lo lè sọ tàbí tó o lè ṣe láti tù wọ́n nínú?

18 Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń ṣọ̀fọ̀ lójoojúmọ́ nítorí èèyàn wọn tó kú. O lè bá àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ pàdé bó o ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tàbí bó o ṣe ń bá àtijẹ àtimu kiri. Kí lo lè ṣe láti tù wọ́n nínú?

19 Ṣé ìbànújẹ́ ti dorí ẹni náà kodò? Ṣé gbogbo mọ̀lẹ́bí tó wà nínú ilé náà ló ń ṣọ̀fọ̀? Ọ̀rọ̀ lè pọ̀ nínú ẹ tó o fẹ́ sọ, àmọ́ ó gba ìṣọ́ra gan-an o. (Oníwàásù 3:1, 7) Ó lè jẹ́ pé ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe ni pé kó o bá wọn kẹ́dùn, kó o fún wọn ní ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì tó bá ohun tó ṣẹlẹ̀ náà mu (yálà ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìròyìn tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú), kó o sì padà bẹ̀ wọ́n wò ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà láti mọ̀ bóyá ìrànlọ́wọ́ kan wà tó o tún lè ṣe fún wọn. Nígbà tó o bá rí i pé ọwọ́ wọn dilẹ̀, sọ àwọn ọ̀rọ̀ afúnniníṣìírí látinú Bíbélì fún wọn. Èyí lè mú kí ọkàn wọn wálẹ̀ kára sì rọ̀ wọ́n. (Òwe 16:24; 25:11) O ò lè jí ẹni tó ti kú dìde bíi ti Jésù. Ṣùgbọ́n o lè jẹ́ kí wọ́n rí ohun tí Bíbélì sọ nípa ipò táwọn òkú wà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò yẹn lè máà jẹ́ èyí tó bọ́gbọ́n mu láti bẹ̀rẹ̀ sí tako èrò òdì táwọn èèyàn ní nípa àwọn òkú. (Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4) O lè ka ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa àjíǹde fún wọn. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) O lè ṣàlàyé ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wọn, o tiẹ̀ lè ka àkọsílẹ̀ kan nínú Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde kan tó wáyé nígbà kan rí. (Lúùkù 8:49-56; Jòhánù 11:39-44) Bákan náà, tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó fún wa ní ìrètí yìí. (Jóòbù 14:14, 15; Jòhánù 3:16) Ṣàlàyé ọ̀nà táwọn ẹ̀kọ́ yìí ti gbà ran ìwọ alára lọ́wọ́ àti ìdí tó o fi ní ìgbọ́kànlé nínú wọn.

20 Kíké sí àwọn èèyàn wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tún lè ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́ láti mọ irú àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn dénú tí wọ́n sì mọ béèyàn ṣe ń gbé ọmọnìkejì rẹ̀ ró. Obìnrin kan nílẹ̀ Sweden sọ pé nǹkan tóun ti ń wọ̀nà fún ní gbogbo ìgbésí ayé òun gan-an rèé.—Jòhánù 13:35; 1 Tẹsalóníkà 5:11.

21, 22. (a) Ki la ní láti ṣe tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìtùnú? (b) Báwo lo ṣe lè tu ẹnì kan tó mọ Ìwé Mímọ́ lámọ̀dunjú nínú?

21 Tó o bá rí i pé ẹnì kan ń ṣọ̀fọ̀, yálà nínú ìjọ Kristẹni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ǹjẹ́ ó máa ń dà bí ẹni pé o ò mọ nǹkan tó o lè sọ tàbí tó o lè ṣe nígbà mìíràn? Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìtùnú” nínú Bíbélì, ní ṣáńgílítí ni “fífa ẹnì kan mọ́ra.” Láti jẹ́ olùtùnú tòótọ́, o ní láti dúró gbágbáágbá ti àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀.—Òwe 17:17.

22 Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ẹni tó o fẹ́ tù nínú náà ti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú, ìràpadà àti àjíǹde ńkọ́? Pé ìwọ tó o jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tiẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lásán ti tó láti tù ú nínú. Tó bá fẹ́ sọ̀rọ̀, tẹ́tí sóhun tó fẹ́ sọ dáadáa. Má ṣe ronú pé dandan ni kí ìwọ náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Tẹ́ ẹ bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́, ńṣe ni kó o kà wọ́n sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń fún ọkàn ẹ̀yin méjèèjì lókun. Sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe dá ẹ̀yìn méjèèjì lójú pé òtítọ́ pọ́ńbélé làwọn ìlérí náà. Nípa níní ìyọ́nú bíi ti Ọlọ́run àti nípa ṣíṣàjọpín òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá tún lè ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́ láti rí ìtùnú àti okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́ríńtì 1:3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, orí 8; àti ìwé pẹlẹbẹ Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

• Ta ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé ó fa ìṣẹ̀lẹ̀ búburú, báwo la sì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

• Kí la lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní kíkún látinú ìtùnú tí Bíbélì ń fúnni?

• Àwọn nǹkan wo ló ń kó ìbànújẹ́ bá àwọn èèyàn lágbègbè rẹ, báwo lo sì ṣe lè tù wọ́n nínú?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Sísọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn èèyàn lákòókò ìṣòro

Credit Line]

Àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi: FỌ́TÒ UN 186811/J. Isaac

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Pé ọ̀rẹ́ kan tiẹ̀ wà lọ́dọ̀ èèyàn máa ń tuni nínú