Àkọsílẹ̀ Lúùkù 8:1-56

  • Àwọn obìnrin tó ń tẹ̀ lé Jésù (1-3)

  • Àpèjúwe afúnrúgbìn (4-8)

  • Ìdí tí Jésù fi ń lo àwọn àpèjúwe (9, 10)

  • Ó ṣàlàyé àpèjúwe afúnrúgbìn (11-15)

  • A kì í bo fìtílà mọ́lẹ̀ (16-18)

  • Ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ (19-21)

  • Jésù mú kí ìjì dáwọ́ dúró (22-25)

  • Jésù lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde sínú ẹlẹ́dẹ̀ (26-39)

  • Ọmọbìnrin Jáírù; obìnrin kan fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè Jésù (40-56)

8  Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó ń rin ìrìn àjò láti ìlú dé ìlú àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.+ Àwọn Méjìlá náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀,  bákan náà ni àwọn obìnrin kan tó ti lé ẹ̀mí burúkú kúrò lára wọn, tó sì ti wo àìsàn wọn sàn: Màríà tí wọ́n ń pè ní Magidalénì, tí ẹ̀mí èṣù méje jáde lára rẹ̀;  Jòánà+ ìyàwó Kúsà, ọkùnrin tí Hẹ́rọ́dù fi ṣe alábòójútó; Sùsánà; àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin míì, tí wọ́n ń fi àwọn ohun ìní wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.+  Nígbà tí èrò rẹpẹtẹ ti kóra jọ pẹ̀lú àwọn tó ń lọ bá a láti ìlú dé ìlú, ó fi àpèjúwe kan sọ̀rọ̀,+ ó ní:  “Afúnrúgbìn kan jáde lọ fún irúgbìn rẹ̀. Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ lára rẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, wọ́n tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ.+  Àwọn kan já bọ́ sórí àpáta, lẹ́yìn tí wọ́n sì rú jáde, wọ́n gbẹ dà nù torí pé omi ò rin ibẹ̀.+  Àwọn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún tí wọ́n sì jọ dàgbà fún wọn pa.+  Àmọ́ àwọn míì já bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, lẹ́yìn tí wọ́n sì rú jáde, wọ́n so èso ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100).”+ Bó ṣe sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbóhùn sókè, ó ní: “Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+  Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í ní ohun tí àpèjúwe yìí túmọ̀ sí.+ 10  Ó sọ pé: “Ẹ̀yin la yọ̀ǹda fún pé kí ẹ lóye àwọn àṣírí mímọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ àpèjúwe+ ló jẹ́ fún àwọn yòókù, kó lè jẹ́ pé, bí wọ́n tiẹ̀ ń wò, lásán ni wọ́n á máa wò àti pé bí wọ́n tiẹ̀ ń gbọ́, kó má ṣe yé wọn.+ 11  Ìtumọ̀ àpèjúwe náà nìyí: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni irúgbìn náà.+ 12  Àwọn ti etí ọ̀nà ni àwọn tó gbọ́, tí Èṣù wá lẹ́yìn náà, tó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò nínú ọkàn wọn, kí wọ́n má bàa gbà gbọ́, kí wọ́n sì rí ìgbàlà.+ 13  Àwọn ti orí àpáta ni àwọn tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á, àmọ́ àwọn yìí kò ní gbòǹgbò. Wọ́n gbà gbọ́ fúngbà díẹ̀, àmọ́ ní àsìkò ìdánwò, wọ́n yẹsẹ̀.+ 14  Ní ti àwọn tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, àwọn yìí ló gbọ́, àmọ́ torí pé àníyàn, ọrọ̀+ àti adùn ayé yìí + pín ọkàn wọn níyà, a fún wọn pa pátápátá, wọn ò sì mú kí ohunkóhun dàgbà.+ 15  Ní ti èyí tó wà lórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, àwọn yìí ló jẹ́ pé, lẹ́yìn tí wọ́n fi ọkàn tó tọ́, tó sì dáa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà,+ wọ́n fi sọ́kàn, wọ́n sì ń fi ìfaradà so èso.+ 16  “Kò sí ẹni tó máa tan fìtílà, tó máa wá fi nǹkan bò ó tàbí kó gbé e sábẹ́ ibùsùn, àmọ́ orí ọ̀pá fìtílà ló máa gbé e sí, kí àwọn tó bá wọlé lè rí ìmọ́lẹ̀.+ 17  Torí kò sí nǹkan tí a fi pa mọ́ tí kò ní hàn kedere, kò sí ohun tí a rọra tọ́jú tí a ò ṣì ní mọ̀, tí kò sì ní hàn sí gbangba.+ 18  Torí náà, ẹ kíyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀, torí ẹnikẹ́ni tó bá ní, a máa fi kún ohun tó ní,+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tí kò bá ní, a máa gba ohun tó rò pé òun ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”+ 19  Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ wá a wá, àmọ́ wọn ò ráyè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ torí èrò wà níbẹ̀.+ 20  Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró níta, wọ́n fẹ́ rí ọ.” 21  Ó dá wọn lóhùn pé: “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn yìí tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”+ 22  Lọ́jọ́ kan, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká sọdá sí òdìkejì adágún.” Torí náà, wọ́n ṣíkọ̀.+ 23  Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ lórí omi, ó sùn lọ. Ìjì líle kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í jà lórí adágún náà, omi wá ń rọ́ wọnú ọkọ̀ wọn, wọ́n sì wà nínú ewu.+ 24  Torí náà, wọ́n lọ jí i, wọ́n ní: “Olùkọ́, Olùkọ́, a ti fẹ́ ṣègbé!” Ló bá dìde, ó bá ìjì àti omi tó ń ru gùdù náà wí, wọ́n sì rọlẹ̀, wọ́n pa rọ́rọ́.+ 25  Ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò nígbàgbọ́ ni?” Àmọ́ ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n ń sọ fúnra wọn pé: “Ta lẹni yìí gan-an? Torí ó ń pàṣẹ fún ìjì àti omi pàápàá, wọ́n sì ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.”+ 26  Wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté tó wà ní agbègbè àwọn ará Gérásà,+ èyí tó wà ní òdìkejì Gálílì. 27  Bí Jésù ṣe sọ̀ kalẹ̀, ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu pàdé rẹ̀ látinú ìlú náà. Ó pẹ́ tí kò ti wọṣọ, kì í sì í gbé inú ilé, àárín àwọn ibojì* ló ń gbé.+ 28  Bó ṣe rí Jésù, ó kígbe, ó sì wólẹ̀ síwájú rẹ̀, ó wá ké jáde pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Mo bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.”+ 29  (Torí Jésù ti ń pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé kó jáde lára ọkùnrin náà. Ẹ̀mí náà ti gbá ọkùnrin náà mú lọ́pọ̀ ìgbà,*+ léraléra sì ni wọ́n fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, tí wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, àmọ́ ó máa ń já àwọn ìdè náà, ẹ̀mí èṣù náà á sì mú kó lọ sí àwọn ibi tó dá.) 30  Jésù bi í pé: “Kí lorúkọ rẹ?” Ó sọ pé: “Líjíónì,” torí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí èṣù ti wọ inú rẹ̀. 31  Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kó má pàṣẹ fún àwọn láti lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.+ 32  Ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀+ tó pọ̀ ń jẹun níbẹ̀ lórí òkè náà, torí náà, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó gba àwọn láyè láti wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ó sì gbà wọ́n láyè.+ 33  Ni àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá jáde lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú adágún, wọ́n sì kú sínú omi. 34  Àmọ́ nígbà tí àwọn darandaran rí ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ nínú ìlú àti ní ìgbèríko. 35  Torí náà, àwọn èèyàn jáde lọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì rí ọkùnrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde lára rẹ̀, ó ti wọṣọ, orí rẹ̀ sì ti wálé, ó jókòó síbi ẹsẹ̀ Jésù, ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. 36  Àwọn tí wọ́n rí i ròyìn fún wọn nípa bí ara ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà ṣe yá. 37  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti agbègbè àwọn ará Gérásà ní àyíká ibẹ̀ wá sọ fún Jésù pé kó kúrò lọ́dọ̀ àwọn, torí pé ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Torí náà, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kó lè máa lọ. 38  Àmọ́ ọkùnrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde lára rẹ̀ ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá pé òun fẹ́ bá a lọ, ṣùgbọ́n ó ní kí ọkùnrin náà máa lọ, ó ní:+ 39  “Pa dà sílé, kí o sì máa ròyìn ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ.” Torí náà, ó lọ, ó ń kéde ohun tí Jésù ṣe fún un káàkiri gbogbo ìlú náà. 40  Nígbà tí Jésù pa dà dé, àwọn èrò náà tẹ́wọ́ gbà á tinútinú, torí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.+ 41  Àmọ́ wò ó! ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jáírù wá; ọkùnrin yìí ni alága sínágọ́gù. Ó wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ Jésù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó wá sí ilé òun,+ 42  torí pé ọmọbìnrin kan ṣoṣo tó bí,* tó jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá (12), ń kú lọ. Bí Jésù ṣe ń lọ, àwọn èrò ń fún mọ́ ọn. 43  Obìnrin kan wà tó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá (12), kò sì tíì rí ìwòsàn lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni.+ 44  Obìnrin náà sún mọ́ ọn láti ẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì dáwọ́ dúró lójú ẹsẹ̀. 45  Jésù wá sọ pé: “Ta ló fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn ń sọ pé àwọn kọ́, Pétérù sọ pé: “Olùkọ́, àwọn èrò ń há ọ mọ́, wọ́n sì ń fún mọ́ ọ.”+ 46  Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹnì kan fọwọ́ kàn mí, torí mo mọ̀ pé agbára+ jáde lára mi.” 47  Nígbà tí obìnrin náà rí i pé òun ò lè fara pa mọ́ mọ́, ó wá, jìnnìjìnnì bò ó, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sọ ohun tó mú kí òun fọwọ́ kàn án níwájú gbogbo èèyàn àti bí ara òun ṣe yá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 48  Àmọ́ ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà.”+ 49  Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, aṣojú alága sínágọ́gù wá, ó ní: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú; má yọ Olùkọ́ lẹ́nu mọ́.”+ 50  Nígbà tí Jésù gbọ́ èyí, ó dá a lóhùn pé: “Má bẹ̀rù, ṣáà ti ní ìgbàgbọ́, ara ọmọ náà sì máa yá.”+ 51  Nígbà tó dé ilé náà, kò jẹ́ kí ẹnì kankan bá òun wọlé àfi Pétérù, Jòhánù, Jémíìsì pẹ̀lú bàbá àti ìyá ọmọ náà. 52  Àmọ́ gbogbo èèyàn ń sunkún, wọ́n sì ń lu ara wọn bí wọ́n ṣe ń dárò torí ọmọ náà. Torí náà, ó sọ pé: “Ẹ má sunkún mọ́,+ torí kò kú, ó ń sùn ni.”+ 53  Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi ṣẹlẹ́yà, torí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú. 54  Àmọ́ ó dì í lọ́wọ́ mú, ó sì pè é, ó ní: “Ọmọ, dìde!”+ 55  Ẹ̀mí rẹ̀*+ sì pa dà, ó dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,+ ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n fún un ní nǹkan tó máa jẹ. 56  Àwọn òbí rẹ̀ ò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, àmọ́ ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ẹnì kankan.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn ibojì ìrántí.”
Tàbí kó jẹ́, “Ó ti pẹ́ gan-an tó ti wà lára rẹ̀, tí kò lọ.”
Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.”
Ní Grk., “ọmọbìnrin bíbí kan ṣoṣo rẹ̀.”
Tàbí “Agbára ìwàláàyè rẹ̀.”