Àkọsílẹ̀ Lúùkù 4:1-44

  • Èṣù dán Jésù wò (1-13)

  • Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní Gálílì (14, 15)

  • Wọn ò tẹ́wọ́ gba Jésù ní Násárẹ́tì (16-30)

  • Nínú sínágọ́gù ní Kápánáúmù (31-37)

  • Ó wo ìyá ìyàwó Símónì àtàwọn míì sàn (38-41)

  • Àwọn èrò rí Jésù ní ibi tó dá (42-44)

4  Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ kún inú Jésù, ó sì kúrò ní Jọ́dánì, ẹ̀mí wá darí rẹ̀ káàkiri nínú aginjù+  fún ogójì (40) ọjọ́, Èṣù sì dán an wò.+ Kò jẹ nǹkan kan láwọn ọjọ́ yẹn, torí náà, lẹ́yìn àwọn ọjọ́ náà, ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á.  Ni Èṣù bá sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún òkúta yìí pé kó di búrẹ́dì.”  Àmọ́ Jésù dá a lóhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè.’”+  Ó wá mú un gòkè, ó sì fi gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí à ń gbé hàn án lójú ẹsẹ̀.+  Èṣù wá sọ fún un pé: “Gbogbo àṣẹ yìí àti ògo wọn ni màá fún ọ, torí a ti fi lé mi lọ́wọ́,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì wù mí ni màá fún.  Torí náà, tí o bá jọ́sìn níwájú mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, gbogbo rẹ̀ máa jẹ́ tìẹ.”  Jésù dá a lóhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+  Lẹ́yìn náà, ó mú un lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó mú un dúró lórí ògiri orí òrùlé* tẹ́ńpìlì, ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ láti ibí yìí,+ 10  torí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, pé kí wọ́n pa ọ́ mọ́’ 11  àti pé, ‘Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ, kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.’”+ 12  Jésù dá a lóhùn pé: “A sọ ọ́ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà* Ọlọ́run rẹ wò.’”+ 13  Torí náà, lẹ́yìn tí Èṣù dán an wò tán, ó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí di ìgbà míì tó wọ̀.+ 14  Jésù wá pa dà sí Gálílì+ nínú agbára ẹ̀mí. Ìròyìn rere nípa rẹ̀ sì tàn káàkiri gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká. 15  Bákan náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, gbogbo èèyàn sì ń bọlá fún un. 16  Lẹ́yìn náà, ó lọ sí Násárẹ́tì,+ níbi tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, ó wọnú sínágọ́gù,+ ó sì dìde dúró láti kàwé, bó ṣe máa ń ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì. 17  Torí náà, wọ́n fún un ní àkájọ ìwé wòlíì Àìsáyà, ó ṣí àkájọ ìwé náà, ó sì rí ibi tí wọ́n kọ ọ́ sí pé: 18  “Ẹ̀mí Jèhófà* wà lára mi, torí ó ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn aláìní. Ó rán mi láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú, pé àwọn afọ́jú máa pa dà ríran, láti mú kí àwọn tí wọ́n tẹ̀ rẹ́ máa lọ lómìnira,+ 19  láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.”*+ 20  Ló bá ká àkájọ ìwé náà, ó dá a pa dà fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó; gbogbo àwọn tó wà nínú sínágọ́gù sì tẹjú mọ́ ọn. 21  Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún wọn pé: “Òní ni ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ yìí ṣẹ.”+ 22  Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí rẹ̀ ní rere, ẹnu ń yà wọ́n torí àwọn ọ̀rọ̀ tó tuni lára tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Ọmọ Jósẹ́fù nìyí, àbí òun kọ́?”+ 23  Ló bá sọ fún wọn pé: “Ó dájú pé ẹ máa fi ọ̀rọ̀ yìí bá mi wí pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn. Tún ṣe àwọn ohun tí a gbọ́ pé ó wáyé ní Kápánáúmù ní ìlú rẹ níbí.’”+ 24  Torí náà, ó sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé kò sí wòlíì tí wọ́n máa ń tẹ́wọ́ gbà ní ìlú rẹ̀.+ 25  Bí àpẹẹrẹ, mò ń sọ fún yín ní tòótọ́ pé: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ opó ló wà ní Ísírẹ́lì nígbà ayé Èlíjà, nígbà tí a sé ọ̀run pa fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà, tí ìyàn sì mú gidigidi ní gbogbo ilẹ̀ náà.+ 26  Síbẹ̀, a kò rán Èlíjà sí ìkankan nínú àwọn obìnrin yẹn, àfi opó tó wà ní Sáréfátì nílẹ̀ Sídónì nìkan.+ 27  Bákan náà, ọ̀pọ̀ adẹ́tẹ̀ ló wà ní Ísírẹ́lì nígbà ayé wòlíì Èlíṣà; síbẹ̀ a ò wẹ ìkankan nínú wọn mọ́,* àfi Náámánì ará Síríà.”+ 28  Ni inú bá bí gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nínú sínágọ́gù gan-an,+ 29  wọ́n dìde, wọ́n yára mú un lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì mú un lọ sí téńté òkè tí wọ́n kọ́ ìlú wọn sí, kí wọ́n lè taari rẹ̀ sísàlẹ̀. 30  Àmọ́ ó kọjá láàárín wọn, ó sì ń bá tirẹ̀ lọ.+ 31  Ó wá sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Kápánáúmù, ìlú kan ní Gálílì. Ó ń kọ́ wọn ní ọjọ́ Sábáàtì,+ 32  bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sì yà wọ́n lẹ́nu,+ torí pé ó ń sọ̀rọ̀ tàṣẹtàṣẹ. 33  Ọkùnrin kan wà nínú sínágọ́gù náà tó ní ẹ̀mí kan, ẹ̀mí èṣù àìmọ́, ó sì kígbe pé:+ 34  “Áà! Kí ló pa wá pọ̀, Jésù ará Násárẹ́tì?+ Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́ gan-an, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run ni ọ́.”+ 35  Àmọ́ Jésù bá a wí, ó ní: “Dákẹ́, kí o sì jáde kúrò nínú rẹ̀.” Torí náà, lẹ́yìn tí ẹ̀mí èṣù náà gbé ọkùnrin náà ṣánlẹ̀ láàárín wọn, ó jáde kúrò nínú rẹ̀ láìṣe é léṣe. 36  Ni ẹnu bá ya gbogbo wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara wọn pé: “Irú ọ̀rọ̀ wo nìyí? Torí ó ń fi àṣẹ àti agbára lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́, wọ́n sì ń jáde!” 37  Ìròyìn rẹ̀ wá ń tàn káàkiri ṣáá dé gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká. 38  Lẹ́yìn tó kúrò nínú sínágọ́gù, ó wọ ilé Símónì. Akọ ibà ń ṣe ìyá ìyàwó Símónì, wọ́n sì ní kó ràn án lọ́wọ́.+ 39  Torí náà, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin náà, ó sì bá ibà náà wí, ibà náà sì lọ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin náà dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 40  Àmọ́ nígbà tí oòrùn ń wọ̀, gbogbo àwọn tí èèyàn wọn ń ṣàìsàn, tí wọ́n ní oríṣiríṣi àrùn, mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó ń wò wọ́n sàn.+ 41  Àwọn ẹ̀mí èṣù tún jáde lára ọ̀pọ̀ èèyàn, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì ń sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”+ Àmọ́ ó bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀,+ torí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi.+ 42  Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó kúrò lọ sí ibì kan tó dá.+ Àmọ́ àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí í wá a,* wọ́n dé ibi tó wà, wọ́n sì gbìyànjú láti dá a dúró kó má bàa kúrò lọ́dọ̀ wọn. 43  Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Mo tún gbọ́dọ̀ kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú míì, torí pé nítorí èyí la ṣe rán mi.”+ 44  Torí náà, ó ń wàásù nínú àwọn sínágọ́gù Jùdíà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìgbátí; ibi tó ga jù ní.”
Tàbí “wo ìkankan nínú wọn sàn.”
Tàbí “wá a kiri.”