Àkọsílẹ̀ Mátíù 24:1-51

 • ÀMÌ PÉ JÉSÙ TI WÀ NÍHÌN-ÍN (1-51)

  • Ogun, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ (7)

  • A máa wàásù ìhìn rere (14)

  • Ìpọ́njú ńlá (21, 22)

  • Àmì Ọmọ èèyàn (30)

  • Igi ọ̀pọ̀tọ́ (32-34)

  • Bí ọjọ́ Nóà ṣe rí (37-39)

  • Ẹ máa ṣọ́nà (42-44)

  • Ẹrú olóòótọ́ àti ẹrú burúkú (45-51)

24  Bí Jésù ṣe ń kúrò ní tẹ́ńpìlì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá láti fi àwọn ilé tẹ́ńpìlì hàn án.  Ó sọ fún wọn pé: “Ṣebí ẹ rí gbogbo nǹkan yìí? Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì níbí, láìwó o palẹ̀.”+  Nígbà tó jókòó sórí Òkè Ólífì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá a ní òun nìkan, wọ́n sọ pé: “Sọ fún wa, ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín*+ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”*+  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnì kankan má ṣì yín lọ́nà,+  torí ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ní orúkọ mi, wọ́n á sọ pé, ‘Èmi ni Kristi,’ wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà.+  Ẹ máa gbọ́ nípa àwọn ogun, ẹ sì máa gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun. Kí ẹ rí i pé ẹ ò bẹ̀rù, torí àwọn nǹkan yìí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, àmọ́ òpin ò tíì dé.+  “Torí orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba,+ àìtó oúnjẹ+ àti ìmìtìtì ilẹ̀ sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.+  Gbogbo nǹkan yìí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ wàhálà tó ń fa ìrora.  “Nígbà náà, àwọn èèyàn máa fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́,+ wọ́n á sì pa yín,+ gbogbo orílẹ̀-èdè sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.+ 10  Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa kọsẹ̀ nígbà yẹn, wọ́n máa dalẹ̀ ara wọn, wọ́n á sì kórìíra ara wọn. 11  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì èké máa dìde, wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà;+ 12  torí pé ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ máa tutù. 13  Àmọ́ ẹni tó bá fara dà á* dé òpin máa rí ìgbàlà.+ 14  A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè,+ nígbà náà ni òpin yóò dé. 15  “Torí náà, tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro, tó dúró ní ibi mímọ́, bí wòlíì Dáníẹ́lì ṣe sọ ọ́+ (kí òǹkàwé lo òye), 16  nígbà náà, kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.+ 17  Kí ẹni tó wà lórí ilé má sọ̀ kalẹ̀ wá kó ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀, 18  kí ẹni tó wà ní pápá má sì pa dà wá mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀. 19  Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o! 20  Ẹ máa gbàdúrà kí ìgbà tí ẹ máa sá má lọ bọ́ sí ìgbà òtútù tàbí ọjọ́ Sábáàtì; 21  torí ìpọ́njú ńlá máa wà nígbà náà,+ irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di báyìí, àní, irú rẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.+ 22  Kódà, ẹran ara kankan ò ní là á já, àfi tí a bá dín àwọn ọjọ́ yẹn kù; àmọ́ nítorí àwọn àyànfẹ́, a máa dín àwọn ọjọ́ yẹn kù.+ 23  “Nígbà yẹn, tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wò ó! Kristi wà níbí’+ tàbí ‘Lọ́hùn-ún!’ ẹ má gbà á gbọ́.+ 24  Torí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké+ máa dìde, wọ́n sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tó lágbára, láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà,+ tó bá ṣeé ṣe. 25  Ẹ wò ó! Mò ń kìlọ̀ fún yín ṣáájú. 26  Torí náà, tí àwọn èèyàn bá sọ fún yín pé, ‘Ẹ wò ó! Ó wà nínú aginjù,’ ẹ má lọ; ‘Ẹ wò ó! Ó wà nínú àwọn yàrá inú,’ ẹ má gbà á gbọ́.+ 27  Torí bí mànàmáná ṣe ń kọ láti ìlà oòrùn, tó sì ń mọ́lẹ̀ dé ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín.*+ 28  Ibikíbi tí òkú bá wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ idì máa kóra jọ sí.+ 29  “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú àwọn ọjọ́ yẹn, oòrùn máa ṣókùnkùn,+ òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀, àwọn ìràwọ̀ máa já bọ́ láti ọ̀run, a sì máa mi àwọn agbára ọ̀run.+ 30  Nígbà náà, àmì Ọmọ èèyàn máa fara hàn ní ọ̀run, ìbànújẹ́ máa mú kí gbogbo àwọn ẹ̀yà tó wà ní ayé lu ara wọn,+ wọ́n sì máa rí Ọmọ èèyàn+ tó ń bọ̀ lórí àwọsánmà* ojú ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+ 31  Ó máa rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú ìró kàkàkí tó rinlẹ̀, wọ́n sì máa kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ látinú atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun kan ọ̀run títí dé ìkángun kejì.+ 32  “Ní báyìí, ẹ kọ́ àpèjúwe yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ọ̀mùnú, tó sì rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti sún mọ́lé.+ 33  Bákan náà, tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan yìí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ ẹnu ọ̀nà.+ 34  Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó dájú pé ìran yìí ò ní kọjá lọ títí gbogbo nǹkan yìí fi máa ṣẹlẹ̀. 35  Ọ̀run àti ayé máa kọjá lọ, àmọ́ ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ mi ò ní kọjá lọ.+ 36  “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n,+ àwọn áńgẹ́lì ọ̀run àti Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan.+ 37  Torí bí àwọn ọjọ́ Nóà ṣe rí gẹ́lẹ́+ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín.*+ 38  Torí bó ṣe rí ní àwọn ọjọ́ yẹn ṣáájú Ìkún Omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fa àwọn obìnrin fún ọkọ, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì,+ 39  wọn ò fiyè sí i títí Ìkún Omi fi dé, tó sì gbá gbogbo wọn lọ,+ bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ èèyàn máa rí. 40  Nígbà yẹn, ọkùnrin méjì máa wà nínú pápá; a máa mú ọ̀kan lọ, a sì máa pa ìkejì tì. 41  Obìnrin méjì á máa lọ nǹkan lórí ọlọ; a máa mú ọ̀kan lọ, a sì máa pa ìkejì tì.+ 42  Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà, torí pé ẹ ò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.+ 43  “Ṣùgbọ́n ẹ mọ ohun kan: Ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀* ni,+ ì bá má sùn, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n ráyè wọ ilé òun.+ 44  Torí èyí, kí ẹ̀yin náà múra sílẹ̀,+ torí wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó máa jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀. 45  “Ní tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye* tí ọ̀gá rẹ̀ yàn pé kó máa bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀, kó máa fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ?+ 46  Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn tí ọ̀gá rẹ̀ bá dé, tó sì rí i tó ń ṣe bẹ́ẹ̀!+ 47  Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó máa yàn án pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀. 48  “Àmọ́ tí ẹrú burúkú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi ń pẹ́,’+ 49  tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú, tó ń jẹ, tó sì ń mu pẹ̀lú àwọn ọ̀mùtí paraku, 50  ọ̀gá ẹrú yẹn máa dé ní ọjọ́ tí kò retí àti wákàtí tí kò mọ̀,+ 51  ó máa fi ìyà tó le jù lọ jẹ ẹ́, ó sì máa fi í sí àárín àwọn alágàbàgebè. Ibẹ̀ ni á ti máa sunkún, tí á sì ti máa payín keke.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wíwàníhìn-ín.”
Tàbí “àsìkò náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “tó fara dà á.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wíwàníhìn-ín.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wíwàníhìn-ín.”
Tàbí “àkókò tí olè ń bọ̀ ní òru.”
Tàbí “ọlọ́gbọ́n.”