Àkọsílẹ̀ Mátíù 5:1-48

 • ÌWÀÁSÙ ORÍ ÒKÈ (1-48)

  • Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni lórí òkè (1, 2)

  • Ohun mẹ́sàn-án tó ń múni láyọ̀ (3-12)

  • Iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀ (13-16)

  • Jésù máa mú Òfin ṣẹ (17-20)

  • Ìmọ̀ràn lórí ìbínú (21-26), àgbèrè (27-30), ìkọ̀sílẹ̀ (31, 32), ìbúra (33-37), ẹ̀san (38-42), nínífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá (43-48)

5  Nígbà tó rí ọ̀pọ̀ èèyàn, ó lọ sórí òkè; lẹ́yìn tó jókòó, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀.  Ó wá la ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn, ó sọ pé:  “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run,*+ torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn.  “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, torí a máa tù wọ́n nínú.+  “Aláyọ̀ ni àwọn oníwà tútù,*+ torí wọ́n máa jogún ayé.+  “Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi òdodo ń pa,+ tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, torí wọ́n máa yó.*+  “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú,+ torí a máa ṣàánú wọn.  “Aláyọ̀ ni àwọn tí ọkàn wọn mọ́,+ torí wọ́n máa rí Ọlọ́run.  “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá àlàáfíà,*+ torí a máa pè wọ́n ní ọmọ Ọlọ́run. 10  “Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo,+ torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn. 11  “Aláyọ̀ ni yín tí àwọn èèyàn bá pẹ̀gàn yín,+ tí wọ́n ṣe inúnibíni sí yín,+ tí wọ́n sì parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́ yín nítorí mi.+ 12  Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì dùn gidigidi,+ torí èrè yín+ pọ̀ ní ọ̀run, torí bí wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tó wà ṣáájú yín nìyẹn.+ 13  “Ẹ̀yin ni iyọ̀+ ayé, àmọ́ tí iyọ̀ ò bá lágbára mọ́, báwo ló ṣe máa pa dà ní adùn rẹ̀? Kò ṣeé lò fún ohunkóhun mọ́, àfi ká dà á síta,+ kí àwọn èèyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. 14  “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.+ Ìlú tó bá wà lórí òkè ò lè fara sin. 15  Tí àwọn èèyàn bá tan fìtílà, wọn kì í gbé e sábẹ́ apẹ̀rẹ̀,* orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e sí, á sì tàn sára gbogbo àwọn tó wà nínú ilé.+ 16  Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn,+ kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín,+ kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.+ 17  “Ẹ má rò pé mo wá láti pa Òfin tàbí àwọn Wòlíì run. Mi ò wá láti pa á run, àmọ́ láti mú un ṣẹ.+ 18  Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, tí ọ̀run àti ayé bá tiẹ̀ yára kọjá lọ, lẹ́tà tó kéré jù tàbí ìlà kan lára lẹ́tà kò ní kúrò nínú Òfin títí gbogbo nǹkan fi máa ṣẹlẹ̀.+ 19  Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá tẹ ọ̀kan nínú àwọn àṣẹ tó kéré jù yìí lójú, tó sì ń kọ́ àwọn míì pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, a máa pè é ní ẹni tó kéré jù lọ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run. Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń pa á mọ́, tó sì ń fi kọ́ni, a máa pè é ní ẹni ńlá ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run. 20  Torí mò ń sọ fún yín pé tí òdodo yín ò bá ju ti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí lọ,+ ó dájú pé ẹ ò ní wọ Ìjọba ọ̀run.+ 21  “Ẹ gbọ́ pé a sọ fún àwọn èèyàn àtijọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pààyàn máa jíhìn fún ilé ẹjọ́.’+ 22  Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tí kò bá yéé bínú+ sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún ilé ẹjọ́; ẹnikẹ́ni tó bá sì sọ̀rọ̀ àbùkù tí kò ṣeé gbọ́ sétí sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé, ‘Ìwọ òpònú aláìníláárí!’ Gẹ̀hẹ́nà* oníná ló máa tọ́ sí i.+ 23  “Tí o bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ,+ tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, 24  fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ. Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ, lẹ́yìn náà, kí o pa dà wá fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.+ 25  “Tètè yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni tó fẹ̀sùn kàn ọ́ lábẹ́ òfin, nígbà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ lójú ọ̀nà ibẹ̀, kí ẹni tó fẹ̀sùn kàn ọ́ má bàa fi ọ́ lé adájọ́ lọ́wọ́ lọ́nà kan ṣáá, kí adájọ́ sì fi ọ́ lé òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi ọ́ sẹ́wọ̀n.+ 26  Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ pé, ó dájú pé o ò ní kúrò níbẹ̀ títí wàá fi san ẹyọ owó kékeré tó kù* tí o jẹ. 27  “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.’+ 28  Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá tẹjú mọ́ obìnrin+ kan lọ́nà tí á fi wù ú láti bá a ṣe ìṣekúṣe, ó ti bá a ṣe àgbèrè nínú ọkàn rẹ̀.+ 29  Tí ojú ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ Torí ó sàn kí o má ní ẹ̀yà ara kan ju kí a ju gbogbo ara rẹ sínú Gẹ̀hẹ́nà.*+ 30  Bákan náà, tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, gé e, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ Torí ó sàn kí o má ní ẹ̀yà ara kan ju kí o bá gbogbo ara rẹ nínú Gẹ̀hẹ́nà.*+ 31  “A tún sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, kó fún un ní ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.’+ 32  Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tí kò bá jẹ́ torí ìṣekúṣe,* lè mú kí obìnrin náà ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ obìnrin tí wọ́n ti kọ̀ sílẹ̀ ti ṣe àgbèrè.+ 33  “Ẹ tún gbọ́ pé a sọ fún àwọn èèyàn àtijọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ búra láìṣe é,+ àmọ́ o gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.’*+ 34  Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Má ṣe búra rárá,+ ì báà jẹ́ ọ̀run lo fi búra, torí ìtẹ́ Ọlọ́run ni; 35  tàbí ayé, torí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ni;+ tàbí Jerúsálẹ́mù, torí ìlú Ọba ńlá náà ni.+ 36  O ò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ búra, torí o ò lè sọ irun kan di funfun tàbí dúdú. 37  Ẹ ṣáà ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́,+ torí ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà ni ohun tó bá ju èyí lọ ti wá.+ 38  “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘Ojú dípò ojú àti eyín dípò eyín.’+ 39  Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ẹ má ṣe ta ko ẹni burúkú, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá gbá yín ní etí* ọ̀tún, ẹ yí èkejì sí i.+ 40  Tí ẹnì kan bá fẹ́ mú ọ lọ sí ilé ẹjọ́, kó sì gba aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kó gba aṣọ àwọ̀lékè rẹ pẹ̀lú;+ 41  tí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ bá sì fipá mú ọ láti ṣiṣẹ́ dé máìlì* kan, bá a dé máìlì méjì. 42  Tí ẹnì kan bá ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ, fún un, má sì yíjú kúrò lọ́dọ̀ ẹni tó fẹ́ yá nǹkan* lọ́wọ́ rẹ.+ 43  “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ,+ kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ 44  Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín,+ kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín,+ 45  kí ẹ lè fi hàn pé ọmọ Baba yín tó wà ní ọ̀run lẹ jẹ́,+ torí ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.+ 46  Torí tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ yín, kí ni èrè yín?+ Ṣebí ohun tí àwọn agbowó orí ń ṣe náà nìyẹn? 47  Tí ẹ bá sì ń kí àwọn arákùnrin yín nìkan, ohun àrà ọ̀tọ̀ wo lẹ̀ ń ṣe? Ṣebí ohun tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ń ṣe náà nìyẹn? 48  Kí ẹ jẹ́ pípé gẹ́lẹ́,* bí Baba yín ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn tí àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn; àwọn alágbe nípa tẹ̀mí.”
Tàbí “oníwà pẹ̀lẹ́.”
Tàbí “torí a máa tẹ́ wọn lọ́rùn.”
Tàbí “àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.”
Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n.”
Ibi tí wọ́n ti ń sun pàǹtírí lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “kúádíránì tó kù.” Wo Àfikún B14.
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “ẹ̀rẹ̀kẹ́.”
Ìyẹn, ẹni tó fẹ́ yá nǹkan láìsan èlé.
Tàbí “Kí ẹ pé pérépéré.”