Oníwàásù 9:1-18

  • Ohun kan náà ló ń gbẹ̀yìn gbogbo wọn (1-3)

  • Gbádùn ayé rẹ bí ikú tiẹ̀ máa dé (4-12)

    • Àwọn òkú ò mọ nǹkan kan (5)

    • Èèyàn ò lè ṣe nǹkan kan nínú Isà Òkú (10)

    • Ìgbà àti èèṣì (11)

  • Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn èèyàn máa ń mọyì ọgbọ́n (13-18)

9  Nítorí náà, mo fọkàn sí gbogbo èyí, mo sì gbà pé ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ni àwọn olódodo àti àwọn ọlọ́gbọ́n wà pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.+ Àwọn èèyàn kò mọ ìfẹ́ àti ìkórìíra tó ti wà ṣáájú wọn.  Ohun kan náà ló ń gbẹ̀yìn* gbogbo wọn,+ àti olódodo àti ẹni burúkú,+ ẹni rere pẹ̀lú ẹni tó mọ́ àti ẹni tí ò mọ́, àwọn tó ń rúbọ àti àwọn tí kì í rúbọ. Ìkan náà ni ẹni rere àti ẹlẹ́ṣẹ̀; bákan náà ni ẹni tó búra rí pẹ̀lú ẹni tó ń bẹ̀rù láti búra.  Ohun kan ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run* tó ń kó ìdààmú báni: Nítorí ohun* kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn,+ aburú ló kún ọkàn àwọn ọmọ èèyàn; ìwà wèrè wà lọ́kàn wọn ní ọjọ́ ayé wọn, lẹ́yìn náà wọ́n á kú!*  Ìrètí wà fún ẹni tó bá ṣì wà láàyè, nítorí ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.+  Nítorí àwọn alààyè mọ̀* pé àwọn máa kú,+ àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá,+ wọn kò sì ní èrè* kankan mọ́, nítorí pé wọ́n ti di ẹni ìgbàgbé.+  Bákan náà, ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn pẹ̀lú owú wọn ti ṣègbé, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ nínú ohun tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.*+  Máa lọ, máa fi ayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, kí o sì máa fi ìdùnnú mu wáìnì rẹ,+ nítorí inú Ọlọ́run tòótọ́ ti dùn sí àwọn iṣẹ́ rẹ.+  Kí aṣọ rẹ máa funfun* ní gbogbo ìgbà, kí o sì máa fi òróró pa orí rẹ.+  Máa gbádùn ayé rẹ pẹ̀lú aya rẹ ọ̀wọ́n+ ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, tí Ó fún ọ lábẹ́ ọ̀run,* ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, torí ìyẹn ni ìpín rẹ nígbèésí ayé àti nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ, èyí tí ò ń fi gbogbo agbára rẹ ṣe lábẹ́ ọ̀run.+ 10  Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú,*+ ibi tí ìwọ ń lọ. 11  Mo tún ti rí nǹkan míì lábẹ́ ọ̀run,* pé ìgbà gbogbo kọ́ ni ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá máa ń mókè nínú eré ìje, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn alágbára máa ń borí lójú ogun,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọlọ́gbọ́n kì í fìgbà gbogbo rí oúnjẹ jẹ, ìgbà gbogbo kọ́ sì ni àwọn olórí pípé máa ń ní ọrọ̀,+ bákan náà àwọn tó ní ìmọ̀ kì í fìgbà gbogbo ṣe àṣeyọrí,+ nítorí ìgbà àti èèṣì* ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. 12  Èèyàn kò mọ ìgbà tirẹ̀.+ Bí ẹja ṣe ń kó sínú àwọ̀n ikú, tí àwọn ẹyẹ sì ń kó sínú pańpẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èèyàn ṣe ń kó sínú ìdẹkùn ní àkókò àjálù, nígbà tó bá dé bá wọn lójijì. 13  Mo tún kíyè sí nǹkan kan nípa ọgbọ́n lábẹ́ ọ̀run,* ó sì wú mi lórí: 14  Ìlú kékeré kan wà tí èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí; ọba alágbára kan wá gbéjà kò ó, ó yí i ká, ó sì ṣe àwọn nǹkan ńlá tí á fi gbógun ti ìlú náà. 15  Ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó ní ọgbọ́n, ó sì fi ọgbọ́n rẹ̀ gba ìlú náà sílẹ̀. Àmọ́ kò sẹ́ni tó rántí ọkùnrin aláìní náà.+ 16  Mo wá sọ fún ara mi pé: ‘Ọgbọ́n sàn ju agbára lọ;+ síbẹ̀ àwọn èèyàn kì í ka ọgbọ́n aláìní sí, wọn kì í sì í ṣe ohun tó bá sọ.’+ 17  Ó sàn kéèyàn tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ọlọ́gbọ́n sọ ju kéèyàn máa fetí sí ariwo ẹni tó ń ṣàkóso láàárín àwọn òmùgọ̀. 18  Ọgbọ́n sàn ju àwọn ohun ìjà ogun lọ, àmọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ṣoṣo lè ba ọ̀pọ̀ ohun rere jẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Àtúbọ̀tán kan náà ló wà fún.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “àtúbọ̀tán.”
Ní Héb., “lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ àwọn òkú yá!”
Tàbí “mọ̀ dáadáa.”
Tàbí “owó iṣẹ́.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ìyẹn, aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ń tàn tó fi hàn pé inú èèyàn ń dùn, kì í ṣe aṣọ ọ̀fọ̀.
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”