Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé O Mọ Jèhófà Dáadáa Bíi Ti Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù?

Ṣé O Mọ Jèhófà Dáadáa Bíi Ti Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù?

“Àwọn ènìyàn tí wọ́n kúndùn ìwà búburú kò lè lóye ìdájọ́, ṣùgbọ́n àwọn tí ń wá Jèhófà lè lóye ohun gbogbo.”​ÒWE 28:5.

ORIN: 126, 150

1-3. (a) Kí ló máa jẹ́ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

BÍ ÀWỌN ọjọ́ ìkẹyìn yìí ṣe ń lọ sópin, bẹ́ẹ̀ làwọn ẹni ibi túbọ̀ ń “rú jáde bí ewéko.” (Sm. 92:7) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ni ò hùwà ọmọlúàbí mọ́. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé inú ayé yìí làwa náà ń gbé, báwo la ṣe lè “jẹ́ ìkókó ní ti ìwà búburú; síbẹ̀, [ká] dàgbà di géńdé nínú agbára òye”?​—1 Kọ́r. 14:20.

2 Ìdáhùn ìbéèrè yẹn wà nínú ẹsẹ Bíbélì tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà. Apá kan níbẹ̀ kà pé: “Àwọn tí ń wá Jèhófà lè lóye ohun gbogbo,” ìyẹn túmọ̀ sí pé wọ́n lóye gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti múnú Jèhófà dùn. (Òwe 28:5) Òwe 2:​7, 9 náà tún sọ pé Jèhófà máa ń “to ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣánṣán.” Ìyẹn ló ń jẹ́ káwọn adúróṣánṣán “lóye òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.”

3 Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù ní irú ọgbọ́n yẹn. (Ìsík. 14:14) Bó sì ṣe rí fáwa èèyàn Ọlọ́run lónìí náà nìyẹn. Ìwọ ńkọ́? Ṣé o “lóye ohun gbogbo” tó yẹ kó o mọ̀ kó o lè múnú Jèhófà dùn? Ohun táá jẹ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o ní ìmọ̀ tó péye nípa Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò (1) bí Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù ṣe di ẹni tó mọ Ọlọ́run, (2) bí ìmọ̀ tí wọ́n ní ṣe ṣe wọ́n láǹfààní, àti (3) bá a ṣe lè ní ìgbàgbọ́ bíi tiwọn.

NÓÀ BÁ ỌLỌ́RUN RÌN NÍNÚ AYÉ BURÚKÚ

4. Báwo ni Nóà ṣe mọ Jèhófà, báwo sì ni ìmọ̀ tó ní ṣe ràn án lọ́wọ́?

4 Bí Nóà Ṣe Mọ Jèhófà. Látìgbà tí Ọlọ́run ti dá àwọn èèyàn, ọ̀nà mẹ́ta pàtàkì làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni pé wọ́n máa ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Ọ̀nà kejì, wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ àwọn míì tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ọ̀nà kẹta sì ni bí wọ́n ṣe ń rí ìbùkún Ọlọ́run torí pé wọ́n ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. (Aísá. 48:18) Bí Nóà ṣe ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa mọ̀. Kì í ṣe pé ó máa gbà pé Ọlọ́run wà nìkan ni, ó tún máa mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tá ò lè rí bí “agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.” (Róòmù 1:20) Torí náà, ó ṣe kedere pé kì í ṣe pé Nóà kàn gbà pé Ọlọ́run wà nìkan ni, ó tún nígbàgbọ́ tó lágbára nínú rẹ̀.

5. Báwo ni Nóà ṣe mọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé?

5 Bíbélì sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Àmọ́, báwo ni Nóà ṣe gbọ́ nípa Jèhófà? Ó dájú pé ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ló ti máa gbọ́ nípa Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Lámékì bàbá Nóà nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì bá Ádámù láyé. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) Àwọn míì tó tún jẹ́ mọ̀lẹ́bí Nóà ni Mètúsélà bàbá rẹ̀ àgbà àti baba ńlá rẹ̀ tó ń jẹ́ Járédì, kódà ẹni ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́rìndínláàádọ́rin [366] ọdún ni Nóà nígbà tí Járédì kú. * (Lúùkù 3:​36, 37) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin yìí àtàwọn ìyàwó wọn ni Nóà ti gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá èèyàn, ó sì fẹ́ kí wọ́n fi àwọn ọmọ wọn kún ilẹ̀ ayé kí wọ́n sì máa jọ́sìn òun. Ó ṣeé ṣe kí Nóà gbọ́ nípa bí Ádámù àti Éfà ṣe tàpá sófin Ọlọ́run nínú ọgbà Édẹ́nì, ó sì dájú pé Nóà fúnra rẹ̀ rí ohun tíyẹn yọrí sí. (Jẹ́n. 1:28; 3:​16-19, 24) Bó ti wù kó rí, àwọn ohun tí Nóà kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ó sì pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn.​—Jẹ́n. 6:9.

6, 7. Ìrètí wo ló mú kí ìgbàgbọ́ Nóà túbọ̀ lágbára?

6 Ìrètí máa ń jẹ́ kóhun téèyàn gbà gbọ́ dá a lójú. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Nóà nígbà tó mọ ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀. Ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “Ìsinmi” tàbí “Ìtùnú,” tó fi hàn pé ìrètí ṣì wà. (Jẹ́n. 5:29) Lábẹ́ ìmísí, Lámékì sọ pé: “Ẹni yìí [Nóà] ni yóò mú ìtùnú wá fún wa nínú . . . ìrora ọwọ́ wa tí ó jẹ́ àbáyọrí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.” Nóà ní ìrètí nínú Ọlọ́run. Bíi ti Ébẹ́lì àti Énọ́kù tó gbé láyé ṣáájú rẹ̀, Nóà nígbàgbọ́ pé “irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí máa fọ́ ejò náà lórí.​—Jẹ́n. 3:15.

7 Ó ṣeé ṣe kí Nóà má mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣe máa nímùúṣẹ, àmọ́ ó dá a lójú pé nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá nímùúṣẹ, aráyé máa rí ìgbàlà. Yàtọ̀ síyẹn, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì bá ìkéde ìdájọ́ tí Énọ́kù ṣe mu pé Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn búburú run. (Júúdà 14, 15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà ogun Amágẹ́dọ́nì ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn máa nímùúṣẹ ní kíkún, ó dájú pé ìkéde tí Énọ́kù ṣe mú kí Nóà ní ìrètí, ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì túbọ̀ lágbára!

8. Báwo ni ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run ṣe ṣe Nóà láǹfààní?

8 Bí ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run ṣe ṣe Nóà láǹfààní. Ìmọ̀ tó péye tí Nóà ní mú kó nígbàgbọ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run. Ìmọ̀ tó ní yìí ni kò jẹ́ kó ṣe ohun tó máa múnú bí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Nóà “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” Ìdí nìyẹn tí kò fi bá àwọn èèyàn búburú rìn tí kò sì bá wọn kẹ́gbẹ́. Kò jẹ́ káwọn áńgẹ́lì burúkú tó sọ ara wọn di èèyàn yẹn tan òun jẹ bí wọ́n ṣe tan àwọn aláìgbọ́n jẹ. Ṣe làwọn èèyàn ń kan sárá sáwọn áńgẹ́lì yẹn torí agbára wọn àtohun tí wọ́n ń ṣe, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n máa jọ́sìn wọn. (Jẹ́n. 6:​1-4, 9) Yàtọ̀ síyẹn, Nóà mọ̀ pé àwọn èèyàn ni Ọlọ́run súre fún pé kí wọ́n bímọ kí wọ́n sì kún ilẹ̀ ayé kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì. (Jẹ́n. 1:​27, 28) Torí náà, ó mọ̀ pé ìbálòpọ̀ láàárín àwọn áńgẹ́lì tó sọ ara wọn di èèyàn àtàwọn obìnrin ò tọ̀nà, kò sì bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Èyí túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ. Nígbà tó yá, Ọlọ́run sọ fún Nóà pé òun máa mú Ìkún Omi wá sórí ilẹ̀ ayé. Ìgbàgbọ́ tí Nóà ní pé ohun tí Ọlọ́run sọ máa ṣẹ mú kó kan ọkọ̀ áàkì, òun àti ìdílé rẹ̀ sì la Ìkún Omi yẹn já.​—Héb. 11:7.

9, 10. Báwo la ṣe lè ní ìgbàgbọ́ bíi ti Nóà?

9 Bá a ṣe lè ní ìgbàgbọ́ bíi ti Nóà. Ohun tá a lè ṣe ni pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká máa fi àwọn nǹkan tá a kọ́ sílò, ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà, kó sì sọ wá di irú ẹni tí Ọlọ́run fẹ́. (1 Pét. 1:​13-15) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run máa dáàbò bò wá káwọn ètekéte Èṣù àti ẹ̀mí ayé yìí má bàa ràn wá. (2 Kọ́r. 2:11) Ẹ̀mí ayé yìí ló ń mú káwọn èèyàn máa ṣe ìṣekúṣe kí wọ́n sì máa hùwà ipá, ó sì tún ń mú kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbà wọ́n lọ́kàn. (1 Jòh. 2:​15, 16) Kódà, ó lè mú káwọn tí iná ẹ̀mí wọn ti ń jó rẹ̀yìn máa ronú pé á pẹ́ kí Ìjọba Ọlọ́run tó dé. Ẹ kíyè sí i pé nígbà tí Jésù ń fi àkókò wa yìí wé ìgbà ayé Nóà, kì í ṣe ìwà ipá àti ìṣekúṣe àwọn èèyàn náà ló tẹnu mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ bí wọn ò ṣe wà lójúfò nípa tẹ̀mí ló tẹnu mọ́.​—Ka Mátíù 24:​36-39.

10 Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi fi hàn pé lóòótọ́ ni mo mọ Jèhófà? Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ mi máa ń jẹ́ kí n fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò, ṣé mo sì máa ń fi kọ́ àwọn míì?’ Ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ìwọ náà ń “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn” bíi ti Nóà.

DÁNÍẸ́LÌ FI HÀN PÉ ÒUN NÍ ỌGBỌ́N ỌLỌ́RUN LÁÀÁRÍN ÀWỌN ABỌ̀RÌṢÀ

11. (a) Kí ni ìfẹ́ tí Dáníẹ́lì ní fún Ọlọ́run nígbà tó wà ní ọ̀dọ́ jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn òbí rẹ̀? (b) Àwọn ànímọ́ Dáníẹ́lì wo ni wàá fẹ́ máa fi ṣèwà hù?

11 Bí Dáníẹ́lì ṣe mọ Jèhófà. Ó ṣe kedere pé àwọn òbí Dáníẹ́lì kọ́ ọ pé kó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí Dáníẹ́lì sì ṣe ń dàgbà, kò gbàgbé ohun tí wọ́n kọ́ ọ, jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ ló fi sin Jèhófà. Kódà nígbà tó darúgbó, ó ṣì ń fara balẹ̀ ka Ìwé Mímọ́. (Dán. 9:​1, 2) Ohun tí Dáníẹ́lì mọ̀ nípa Jèhófà àti bí Jèhófà ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò ṣe kedere nínú àdúrà tó gbà nínú Dáníẹ́lì 9:​3-19. O ò ṣe wáyè ka àdúrà yẹn, kó o sì ṣàṣàrò lé e. Wá bi ara rẹ pé, ‘Kí ni àdúrà yìí kọ́ mi nípa Dáníẹ́lì?’

12-14. (a) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe fi hàn pé òun ní ọgbọ́n Ọlọ́run? (b) Torí pé Dáníẹ́lì lo ìgboyà ó sì jẹ́ adúróṣinṣin, báwo ni Ọlọ́run ṣe san án lẹ́san?

12 Bí ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run ṣe ṣe Dáníẹ́lì láǹfààní. Kò rọrùn fáwọn Júù olóòótọ́ tó ń gbé nílùú Bábílónì láti sin Ọlọ́run láàárín àwọn abọ̀rìṣà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fáwọn Júù pé: “Ẹ wá àlàáfíà ìlú ńlá tí mo mú kí a kó yín lọ ní ìgbèkùn.” (Jer. 29:7) Ìyẹn ò wá ní kí wọ́n máa jọ́sìn àwọn òrìṣà wọn torí Jèhófà sọ pé òun nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ jọ́sìn. (Ẹ́kís. 34:14) Kí ló ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti pa àṣẹ méjèèjì yìí mọ́? Ọgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ kó mọ̀ pé ó níbi téèyàn lè bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ mọ. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká fìyàtọ̀ sóhun tá à ń fún Ọlọ́run àtohun tó tọ́ sáwọn aláṣẹ.​—Lúùkù 20:25.

13 Àpẹẹrẹ kan lohun tí Dáníẹ́lì ṣe nígbà tí wọ́n ṣe òfin pé fún ọgbọ̀n [30] ọjọ́, ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí ẹnikẹ́ni tàbí ọlọ́run míì yàtọ̀ sí ọba. (Ka Dáníẹ́lì 6:​7-10.) Dáníẹ́lì lè sọ pé: ‘Ṣebí ọgbọ̀n ọjọ́ péré ni, kì í ṣe títí láé!’ Àmọ́ kò jẹ́ kí àṣẹ ọba mú kóun pa ìjọsìn Ọlọ́run tì. Ó lè pinnu pé òun á máa dọ́gbọ́n gbàdúrà kí wọ́n má bàa rí òun. Ó mọ̀ pé àwọn èèyàn mọ̀ pé ojoojúmọ́ lòun máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Bí Dáníẹ́lì tiẹ̀ mọ̀ pé ẹ̀mí òun wà nínú ewu, ó pinnu pé òun á ṣì máa gbàdúrà bí òun ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ kí wọ́n má bàa rò pé òun ò sin Jèhófà mọ́.

14 Dáníẹ́lì lo ìgboyà ó sì jẹ́ adúróṣinṣin, torí náà Jèhófà san án lẹ́san nígbà tó gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú oró. Kódà, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ káwọn èèyàn ní gbogbo Ilẹ̀ Ọba Mídíà àti Páṣíà mọ̀ pé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́.​—Dán. 6:​25-27.

15. Báwo la ṣe lè nígbàgbọ́ bíi ti Dáníẹ́lì?

15 Bá a ṣe lè nígbàgbọ́ bíi ti Dáníẹ́lì. Tá a bá fẹ́ nígbàgbọ́ tó lágbára, kì í ṣe pé ká kàn máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ni, ó yẹ kí òye ohun tá à ń kà yé wa. (Mát. 13:23) A fẹ́ mọ èrò Jèhófà nípa ohun tá a fẹ́ ṣe, ìyẹn sì gba pé ká lóye àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ dáadáa. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tá à ń kà. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà àtọkànwá nígbà gbogbo pàápàá tá a bá níṣòro tàbí tá a kojú àdánwò. Tá a bá bẹ Jèhófà pé kó fún wa lọ́gbọ́n àti agbára láti kojú àwọn ìṣòro náà, tá a sì nígbàgbọ́, ó dájú pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà wa.​—Ják. 1:5.

JÓÒBÙ LO ỌGBỌ́N ỌLỌ́RUN NÍGBÀ DÍDÙN ÀTI NÍGBÀ KÍKAN

16, 17. Báwo ni Jóòbù ṣe ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run?

16 Bí Jóòbù ṣe mọ Jèhófà. Jóòbù kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́ ìbátan Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ni, Jèhófà sì ti jẹ́ kí àwọn yìí mọ̀ nípa òun àti ohun tóun fẹ́ ṣe fún aráyé. Jóòbù náà mọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ bó ṣe mọ̀. (Jóòbù 23:12) Jóòbù sọ pé: “Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ.” (Jóòbù 42:5) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ pé Jóòbù sọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa òun.​—Jóòbù 42:​7, 8.

Ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára tá a bá ń kíyè sí àwọn ànímọ́ Jèhófà látinú àwọn nǹkan tó dá (Wo ìpínrọ̀ 17)

17 Jóòbù tún rí bí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ. (Jóòbù 12:​7-9, 13) Nígbà tó yá, Élíhù àti Jèhófà tọ́ka sáwọn ìṣẹ̀dá láti jẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé èèyàn ò jẹ́ nǹkan kan ní ìfiwéra pẹ̀lú Ọlọ́run. (Jóòbù 37:14; 38:​1-4) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jóòbù sọ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an débi pé ó fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: ‘Mo ti wá mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo, kò sì sí èrò-ọkàn kankan tí ó jẹ́ aláìṣeélébá fún ọ. Mo ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.’​—Jóòbù 42:​2, 6.

18, 19. Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé òun mọ Jèhófà lóòótọ́?

18 Bí ìmọ̀ tó péye ṣe ṣe Jóòbù láǹfààní. Jóòbù lóye àwọn ìlànà Ọlọ́run dáadáa. Ó mọ Jèhófà lóòótọ́, ohun tó sì mọ̀ nípa Jèhófà jẹ́ kó ṣe ohun tó tọ́. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan. Jóòbù mọ̀ pé òun ò lè sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kóun sì tún máa hùwà ìkà sáwọn èèyàn. (Jóòbù 6:14) Kò gbé ara rẹ̀ ga ju àwọn míì lọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ó máa ń fàánú hàn sí gbogbo èèyàn yálà olówó ni wọ́n tàbí tálákà. Jóòbù tiẹ̀ sọ pé: “Kì í ha ṣe Ẹni tí ó ṣẹ̀dá mi nínú ikùn ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀”? (Jóòbù 31:​13-22) Ó ṣe kedere pé nígbà tí Jóòbù lówó tó sì lẹ́nu láwùjọ, kò fojú pa àwọn míì rẹ́. Ẹ ò rí i pé ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí ìwà táwọn olówó àtàwọn gbajúmọ̀ òde òní máa ń hù!

19 Jóòbù ò jẹ́ kí nǹkan míì ṣe pàtàkì sóun ju Jèhófà lọ, títí kan àwọn ohun ìní tara. Ó mọ̀ pé tí òun bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ti sẹ́ “Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wà lókè” nìyẹn. (Ka Jóòbù 31:​24-28.) Jóòbù mọ̀ pé ohun mímọ́ ni ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó tó wà láàárín ọkọ àti ìyàwó. Kódà, ó bá ojú rẹ̀ dá májẹ̀mú pé òun ò ní tẹjú mọ́ obìnrin míì. (Jóòbù 31:1) Síbẹ̀, ẹ má gbàgbé pé lásìkò tá à ń sọ yìí, Ọlọ́run ṣì fàyè gba pé kí ọkùnrin ní ju ìyàwó kan lọ. Torí náà, Jóòbù lè ní ju ìyàwó kan lọ tó bá fẹ́, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó mọ̀ pé ìyàwó kan ṣoṣo ni Ọlọ́run fún Ádámù nínú ọgbà Édẹ́nì, àpẹẹrẹ yẹn lòun náà sì tẹ̀ lé. * (Jẹ́n. 2:​18, 24) Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [1,600] ọdún lẹ́yìn náà, Jésù Kristi fi ìlànà kan náà kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ọkọ kan tàbí aya kan ló yẹ kéèyàn ní, àárín àwọn méjèèjì nìkan ló sì yẹ kí ìbálòpọ̀ mọ.​—Mát. 5:28; 19:​4, 5.

20. Tá a bá ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run, báwo nìyẹn ṣe máa mú ká yan àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa àti eré ìnàjú tó gbámúṣé?

20 Bá a ṣe lè nígbàgbọ́ bíi ti Jóòbù. Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ohun tá a máa ṣe ni pé ká ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run, ká sì jẹ́ kí ìmọ̀ náà máa darí gbogbo ohun tá à ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé Jèhófà “kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá,” Dáfídì sì tún kìlọ̀ pé ká má ṣe kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn “tí kì í sọ òtítọ́.” (Ka Sáàmù 11:5; 26:4.) Torí náà, bi ara rẹ pé: ‘Kí làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan? Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan tí mo kà sí pàtàkì jù, bí mo ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn tí mò ń bá kẹ́gbẹ́ títí kan irú eré ìnàjú tí mo nífẹ̀ẹ́ sí?’ Ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo mọ Jèhófà. Tá a bá máa jẹ́ olódodo nínú ayé burúkú tó ti di ìdàkudà yìí, a gbọ́dọ̀ kọ́ “agbára ìwòye” wa ká lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, títí kan ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó bọ́gbọ́n mu àtohun tí kò bọ́gbọ́n mu.​—Héb. 5:14; Éfé. 5:15.

21. Kí ló máa mú ká “lóye ohun gbogbo” tó yẹ ká mọ̀ ká lè múnú Baba wa ọ̀run dùn?

21 Torí pé Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù wá Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n rí òun. Ó jẹ́ kí wọ́n “lóye ohun gbogbo” tó yẹ kí wọ́n mọ̀ kí wọ́n lè múnú òun dùn. Àpẹẹrẹ wọn fi hàn pé téèyàn bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, èèyàn á láyọ̀ á sì ṣàṣeyọrí. (Sm. 1:​1-3) Wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo mọ Jèhófà dáadáa bíi ti Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù?’ Ní báyìí tí òye wa ti túbọ̀ jinlẹ̀ nípa Jèhófà, a ti wá túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. (Òwe 4:18) Torí náà, máa walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Máa ṣàṣàrò lé ohun tó ò ń kà. Máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ Baba rẹ ọ̀run, wàá sì máa fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù nínú ayé burúkú yìí.​—Òwe 2:4-7.

^ ìpínrọ̀ 5 Baba ńlá Nóà tó ń jẹ́ Énọ́kù náà “ń bá a nìṣó ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́.” Àmọ́, “Ọlọ́run mú un lọ” ní nǹkan bí ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin [69] kí wọ́n tó bí Nóà.​—Jẹ́n. 5:​23, 24.

^ ìpínrọ̀ 19 Nóà náà lè fẹ́ ju ìyàwó kan lọ tó bá fẹ́, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì ni àwọn èèyàn ti ń fẹ́ ju ìyàwó kan lọ, síbẹ̀ ìyàwó kan ṣoṣo ló ní.​—Jẹ́n. 4:19.