Dáníẹ́lì 9:1-27

  • Dáníẹ́lì gbàdúrà ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ (1-19)

    • Jerúsálẹ́mù máa dahoro fún 70 ọdún (2)

  • Gébúrẹ́lì wá bá Dáníẹ́lì (20-23)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àádọ́rin ọ̀sẹ̀ (24-27)

    • Mèsáyà máa fara hàn lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ 69 (25)

    • Wọ́n máa pa Mèsáyà (26)

    • Ìlú náà àti ibi mímọ́ máa pa run (26)

9  Ní ọdún kìíní Dáríúsì+ ọmọ Ahasuérúsì, àtọmọdọ́mọ àwọn ará Mídíà, ẹni tí wọ́n fi jọba lórí ìjọba àwọn ará Kálídíà,+  ní ọdún kìíní ìjọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi òye mọ̀ látinú ìwé,* iye ọdún tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà pé Jerúsálẹ́mù fi máa wà ní ahoro,+ ìyẹn àádọ́rin (70) ọdún.+  Mo wá yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, mo bẹ̀ ẹ́ bí mo ṣe ń gbàdúrà sí i, pẹ̀lú ààwẹ̀,+ aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.  Mo gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run mi, mo jẹ́wọ́, mo sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá, tó yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+  a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe ohun tí kò dáa, a ti hùwà burúkú, a sì ti ṣọ̀tẹ̀;+ a ti kọ àwọn àṣẹ rẹ àti àwọn ìdájọ́ rẹ sílẹ̀.  A ò fetí sí àwọn wòlíì tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ,+ tí wọ́n bá àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa, àwọn baba ńlá wa àti gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ.  Jèhófà, tìrẹ ni òdodo, àmọ́ àwa ni ìtìjú bá, bó ṣe rí lónìí yìí, àwa èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn tó wà nítòsí àti lọ́nà jíjìn, ní gbogbo ilẹ̀ tí o fọ́n wọn ká sí torí pé wọn ò jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.+  “Jèhófà, àwa ni ìtìjú bá, àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa àti àwọn baba ńlá wa, torí pé a ti ṣẹ̀ ọ́.  Àánú àti ìdáríjì jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run wa,+ torí a ti ṣọ̀tẹ̀ sí i.+ 10  A ò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa nípa títẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀ tó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 11  Gbogbo Ísírẹ́lì ti tẹ Òfin rẹ lójú, wọ́n sì ti yà kúrò nínú rẹ̀ torí pé wọn ò ṣègbọràn sí ohùn rẹ, tí o fi da ègún àti ìbúra lé wa lórí, èyí tí wọ́n kọ sínú Òfin Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ torí pé a ti ṣẹ̀ Ẹ́. 12  Ó ti ṣe ohun tó sọ lòdì sí àwa+ àti àwọn alákòóso wa tí wọ́n jọba lé wa lórí,* torí ó mú kí àjálù ńlá ṣẹlẹ̀ sí wa; ohunkóhun ò ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ gbogbo ọ̀run bí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.+ 13  Bí a ṣe kọ ọ́ sínú Òfin Mósè, gbogbo àjálù yìí ti dé bá wa,+ síbẹ̀ a kò bẹ Jèhófà Ọlọ́run wa pé* kó ṣojúure sí wa, nípa yíyí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ ká sì fi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú òótọ́* rẹ. 14  “Torí náà, Jèhófà wà lójúfò, ó sì mú àjálù bá wa, torí Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ olódodo nínú gbogbo iṣẹ́ tó ti ṣe; síbẹ̀, a ò ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀.+ 15  “Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run wa, Ìwọ tí o fi ọwọ́ agbára mú àwọn èèyàn rẹ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ tí o sì ṣe orúkọ fún ara rẹ títí di òní yìí,+ a ti ṣẹ̀, a sì ti hùwà burúkú. 16  Jèhófà, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo ìṣe òdodo rẹ,+ jọ̀ọ́, dáwọ́ ìbínú àti ìrunú rẹ dúró lórí ìlú rẹ, Jerúsálẹ́mù, òkè mímọ́ rẹ; torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣìṣe àwọn baba ńlá wa, gbogbo àwọn tó yí wa ká ń gan Jerúsálẹ́mù àti àwọn èèyàn rẹ.+ 17  Ní báyìí, Ọlọ́run wa, fetí sílẹ̀ sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ tàn sára ibi mímọ́ rẹ+ tó ti di ahoro,+ torí tìẹ, Jèhófà. 18  Ọlọ́run mi, tẹ́tí sílẹ̀, kí o sì gbọ́! La ojú rẹ, kí o sì rí ìyà tó ń jẹ wá àti bí ìlú tí a fi orúkọ rẹ pè ṣe di ahoro; kì í ṣe torí àwọn ìṣe òdodo wa la ṣe ń bẹ̀ ọ́, torí àánú rẹ tó pọ̀ ni.+ 19  Jèhófà, jọ̀ọ́ tẹ́tí gbọ́. Jèhófà, jọ̀ọ́ dárí jì.+ Jèhófà, jọ̀ọ́ fiyè sí wa, kí o sì gbé ìgbésẹ̀! Má ṣe jẹ́ kó pẹ́, torí tìẹ, Ọlọ́run mi, torí orúkọ rẹ la fi pe ìlú rẹ àti àwọn èèyàn rẹ.”+ 20  Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, tí mò ń gbàdúrà, tí mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì, tí mo sì ń bẹ̀bẹ̀ fún ojúure Jèhófà Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ Ọlọ́run mi,+ 21  àní, bí mo ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, ọkùnrin náà Gébúrẹ́lì,+ ẹni tí mo ti rí nínú ìran tẹ́lẹ̀,+ wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí okun ti tán nínú mi pátápátá, nígbà tí àkókò ọrẹ alẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó. 22  Ó sì là mí lóye, ó sọ pé: “Ìwọ Dáníẹ́lì, mo wá láti fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye àti ìmọ̀. 23  Nígbà tí o bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀bẹ̀, ọ̀rọ̀ jáde lọ, mo sì wá ròyìn rẹ̀ fún ọ, torí o ṣeyebíye gan-an.*+ Torí náà, ro ọ̀rọ̀ náà, kí ìran náà sì yé ọ. 24  “A ti pinnu àádọ́rin (70) ọ̀sẹ̀* fún àwọn èèyàn rẹ àti ìlú mímọ́ rẹ,+ láti fòpin sí àṣìṣe, láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́,+ láti ṣe ètùtù torí ìṣìnà,+ láti mú òdodo tó máa wà títí láé wá,+ láti gbé èdìdì lé ìran náà àti àsọtẹ́lẹ̀*+ àti láti fòróró yan Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́.* 25  Mọ èyí, kó sì yé ọ pé látìgbà tí a bá ti pàṣẹ pé ká dá Jerúsálẹ́mù pa dà sí bó ṣe wà,+ ká sì tún un kọ́, títí di ìgbà Mèsáyà*+ Aṣáájú,+ ọ̀sẹ̀ méje máa wà àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta (62).+ Wọ́n máa mú kó pa dà sí bó ṣe wà, wọ́n sì máa tún un kọ́, ó máa ní ojúde ìlú, wọ́n sì máa gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká, àmọ́ á jẹ́ ní àkókò wàhálà. 26  “Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta (62) náà, wọ́n máa pa Mèsáyà,*+ láìṣẹ́ ohunkóhun kù fún ara rẹ̀.+ “Àwọn èèyàn aṣáájú tó ń bọ̀ máa pa ìlú náà àti ibi mímọ́ náà run.+ Àkúnya omi ló sì máa fòpin sí i. Ogun á sì máa jà títí dé òpin; a ti pinnu pé ó máa di ahoro.+ 27  “Ó máa mú kí májẹ̀mú náà wà lẹ́nu iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, fún ọ̀sẹ̀ kan; ní ìdajì ọ̀sẹ̀ náà, ó máa mú kí ẹbọ àti ọrẹ dópin.+ “Ẹni tó ń sọ nǹkan di ahoro máa wà lórí ìyẹ́ àwọn ohun ìríra;+ títí dìgbà ìparun, a máa da ohun tí a pinnu sórí ẹni tó ti di ahoro pẹ̀lú.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, àwọn ìwé mímọ́.
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Ní Héb., “àwọn adájọ́ wa tí wọ́n dá ẹjọ́ wa.”
Tàbí “a ò tu Jèhófà Ọlọ́run wa lójú pé.”
Tàbí “òdodo.”
Tàbí “fani mọ́ra gan-an; èèyàn pàtàkì ni ọ́.”
Ìyẹn, ọ̀sẹ̀ tó dúró fún ọdún.
Tàbí “Ibi Mímọ́ Jù Lọ.”
Ní Héb., “wòlíì.”
Tàbí “Ẹni Àmì Òróró.”
Tàbí “ké Mèsáyà kúrò.”