Sí Àwọn Ará Róòmù 1:1-32

  • Ìkíni (1-7)

  • Ó wu Pọ́ọ̀lù láti lọ sí Róòmù (8-15)

  • Ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo wà láàyè (16, 17)

  • Àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kò ní àwíjàre (18-32)

    • À ń rí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run nínú àwọn ohun tó dá (20)

1  Pọ́ọ̀lù, ẹrú Kristi Jésù, tí a pè láti jẹ́ àpọ́sítélì, tí a yà sọ́tọ̀ fún ìhìn rere Ọlọ́run,+  èyí tí òun ti ṣèlérí ṣáájú nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́,  nípa Ọmọ rẹ̀, tó jáde wá látinú ọmọ* Dáfídì+ nípa ti ara,  àmọ́ tí a kéde rẹ̀ ní Ọmọ Ọlọ́run+ pẹ̀lú agbára ẹ̀mí mímọ́ nípasẹ̀ àjíǹde láti inú ikú,+ bẹ́ẹ̀ ni, Jésù Kristi Olúwa wa.  Ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti iṣẹ́ àpọ́sítélì+ gbà, kí a lè máa ṣègbọràn nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè+ nítorí orúkọ rẹ̀,  láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí a ti pe ẹ̀yin náà láti di ti Jésù Kristi—  sí gbogbo àwọn tó wà ní Róòmù tí wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run, tí a sì pè láti jẹ́ ẹni mímọ́: Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa, wà pẹ̀lú yín.  Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi nípasẹ̀ Jésù Kristi lórí gbogbo yín, torí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ yín káàkiri ayé.  Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí mò ń fi ẹ̀mí mi ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún bí mo ṣe ń kéde ìhìn rere nípa Ọmọ rẹ̀, ni ẹlẹ́rìí mi bí mi ò ṣe ṣíwọ́ dídárúkọ yín nínú àdúrà mi nígbà gbogbo,+ 10  tí mò ń bẹ̀bẹ̀ pé tó bá ṣeé ṣe, kí n lè wá sọ́dọ̀ yín lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn tó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. 11  Nítorí àárò yín ń sọ mí, kí n lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, kí ẹ lè fìdí múlẹ̀; 12  àbí, ká kúkú sọ pé, ká jọ fún ara wa ní ìṣírí+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, tiyín àti tèmi. 13  Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ẹ̀yin ará, pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, àmọ́ a ò gbà mí láyè títí di báyìí, kí iṣẹ́ ìwàásù mi lè so èso rere láàárín yín bó ṣe rí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó kù. 14  Mo jẹ́ ajigbèsè sí àwọn Gíríìkì àti àwọn àjèjì,* sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn òmùgọ̀; 15  nítorí náà, ara mi wà lọ́nà láti kéde ìhìn rere fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Róòmù pẹ̀lú.+ 16  Nítorí ìhìn rere kò tì mí lójú;+ ní tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run tó ń mú kí gbogbo ẹni tó ní ìgbàgbọ́ rí ìgbàlà,+ àwọn Júù lákọ̀ọ́kọ́,+ lẹ́yìn náà àwọn Gíríìkì.+ 17  Nítorí inú rẹ̀ ni a ti ń fi òdodo Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti fún ìgbàgbọ́,+ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Àmọ́ ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo wà láàyè.”+ 18  Nítorí ìrunú Ọlọ́run+ ni à ń fi hàn láti ọ̀run sí gbogbo àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti àìṣòdodo àwọn èèyàn tí wọ́n ń tẹ òtítọ́ rì+ ní ọ̀nà àìṣòdodo, 19  torí pé ohun tó ṣeé mọ̀ nípa Ọlọ́run fara hàn kedere láàárín wọn, nítorí Ọlọ́run mú kó ṣe kedere sí wọn.+ 20  Nítorí àwọn ànímọ́* rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá,+ títí kan agbára ayérayé tó ní+ àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run,+ tó fi jẹ́ pé wọn ò ní àwíjàre. 21  Nítorí bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ Ọlọ́run, wọn ò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ìrònú wọn ò mọ́gbọ́n dání, ọkàn wọn tó ti kú tipiri sì ṣókùnkùn.+ 22  Bí wọ́n tiẹ̀ ń sọ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, wọ́n ya òmùgọ̀, 23  wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kò lè díbàjẹ́ pa dà sí ohun tó dà bí àwòrán èèyàn tó lè díbàjẹ́ àti àwọn ẹyẹ àti àwọn ẹ̀dá ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin pẹ̀lú àwọn ẹran tó ń fàyà fà.*+ 24  Torí náà, Ọlọ́run fi wọ́n sílẹ̀ fún ìwà àìmọ́, kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, kí wọ́n sì tàbùkù sí ẹran ara wọn. 25  Wọ́n fi irọ́ pààrọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run, wọ́n wá ń júbà,* wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún ẹ̀dá dípò Ẹlẹ́dàá, ẹni tí àwọn èèyàn ń yìn títí láé. Àmín. 26  Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi yọ̀ǹda wọn fún ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu,+ nítorí àwọn obìnrin wọn ti yí ìlò ara wọn pa dà sí èyí tó lòdì sí ti ẹ̀dá;+ 27  bákan náà, àwọn ọkùnrin fi ìlò obìnrin* lọ́nà ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọ́n sì jẹ́ kí ìfẹ́ ìbálòpọ̀ mú ara wọn gbóná janjan sí ara wọn, ọkùnrin sí ọkùnrin,+ wọ́n ń ṣe ohun ìbàjẹ́, wọ́n sì ń jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìyà* tó yẹ ìṣìnà wọn.+ 28  Bí wọn ò ṣe gbà pé ó yẹ kí àwọn ka Ọlọ́run sí,* Ọlọ́run yọ̀ǹda wọn fún èrò orí tí kò ní ìtẹ́wọ́gbà, láti máa ṣe àwọn ohun tí kò yẹ.+ 29  Ọwọ́ wọn wá kún fún gbogbo àìṣòdodo,+ ìwà ìkà, ojúkòkòrò,*+ ìwà búburú, wọ́n kún fún owú,+ ìpànìyàn,+ wàhálà, ẹ̀tàn,+ èrò ibi,+ wọ́n jẹ́ olófòófó,* 30  ẹni tó ń sọ̀rọ̀ ẹni láìdáa,+ ẹni tó kórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, afọ́nnu, ẹni tó ń pète ohun búburú,* aṣàìgbọràn sí òbí,+ 31  aláìlóye,+ olùyẹ àdéhùn, aláìní ìfẹ́ àdámọ́ni àti aláìláàánú. 32  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn yìí mọ àṣẹ òdodo Ọlọ́run dáadáa, pé ikú tọ́ sí àwọn tó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀,+ kì í ṣe pé wọn ò jáwọ́ nínú àwọn ìwà yẹn nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún ń gbóṣùbà fún àwọn tó ń ṣe wọ́n.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “èso.”
Tàbí “àwọn tí kì í ṣe Gíríìkì.” Ní Grk., “aláìgbédè.”
Ìyẹn, ìwà àti ìṣe.
Tàbí “àwọn ohun tó ń rákò.”
Tàbí “jọ́sìn.”
Tàbí “fi bíbá obìnrin lò pọ̀.”
Tàbí “èrè.”
Tàbí “Bí wọn ò ṣe ní ìmọ̀ tó péye nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.”
Tàbí “ìwọra.”
Ní Grk., “asọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́.”
Tàbí “hùmọ̀ ohun tó ń ṣeni léṣe.”