Jẹ́nẹ́sísì 2:1-25

  • Ọlọ́run sinmi ní ọjọ́ keje (1-3)

  • Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé (4)

  • Ọkùnrin àti obìnrin nínú ọgbà Édẹ́nì (5-25)

    • Ọlọ́run fi erùpẹ̀ mọ ọkùnrin (7)

    • Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ (15-17)

    • Ọlọ́run dá obìnrin (18-25)

2  Bí Ọlọ́run ṣe parí dídá ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn* nìyẹn.+  Nígbà tó fi máa di ọjọ́ keje, Ọlọ́run ti parí iṣẹ́ tó ti ń ṣe,* ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi ní ọjọ́ keje lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ tó ti ń ṣe.*+  Ọlọ́run wá bù kún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, torí ọjọ́ yẹn ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi lẹ́yìn gbogbo ohun tó ti dá, ìyẹn gbogbo ohun tó ní lọ́kàn.  Ìtàn ọ̀run àti ayé nìyí, ní àkókò tí Ọlọ́run dá wọn, ní ọjọ́ tí Jèhófà* Ọlọ́run dá ayé àti ọ̀run.+  Kò sí igbó kankan ní ayé nígbà yẹn, ewéko kankan ò sì tíì hù, torí Jèhófà Ọlọ́run ò tíì rọ òjò sórí ilẹ̀, kò sì sí ẹnì kankan tó máa ro ilẹ̀.  Àmọ́ omi máa ń sun látinú ilẹ̀, á sì rin gbogbo ilẹ̀.  Jèhófà Ọlọ́run fi erùpẹ̀+ ilẹ̀ mọ ọkùnrin, ó mí èémí ìyè+ sí ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì di alààyè.*+  Jèhófà Ọlọ́run wá gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì,+ ní apá ìlà oòrùn; ó sì fi ọkùnrin tó dá+ síbẹ̀.  Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí gbogbo igi tó dùn-ún wò, tó sì dára fún oúnjẹ hù látinú ilẹ̀, ó sì mú kí igi ìyè+ hù ní àárín ọgbà náà pẹ̀lú igi ìmọ̀ rere àti búburú.+ 10  Odò kan ń ṣàn jáde láti Édẹ́nì, tí omi rẹ̀ ń rin ọgbà náà, ó sì pín sí odò mẹ́rin* níbẹ̀. 11  Orúkọ odò àkọ́kọ́ ni Píṣónì; òun ló yí gbogbo ilẹ̀ Háfílà ká, níbi tí wúrà wà. 12  Wúrà ilẹ̀ náà dára. Gọ́ọ̀mù bídẹ́líọ́mù àti òkúta ónísì tún wà níbẹ̀. 13  Orúkọ odò kejì ni Gíhónì; òun ló yí gbogbo ilẹ̀ Kúṣì ká. 14  Orúkọ odò kẹta ni Hídẹ́kẹ́lì;*+ òun ló ṣàn lọ sí ìlà oòrùn Ásíríà.+ Odò kẹrin sì ni Yúfírétì.+ 15  Jèhófà Ọlọ́run mú ọkùnrin náà, ó sì fi sínú ọgbà Édẹ́nì kó lè máa ro ó, kó sì máa tọ́jú rẹ̀.+ 16  Jèhófà Ọlọ́run tún pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé: “O lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìí ní àjẹtẹ́rùn.+ 17  Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, torí ó dájú pé ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.”+ 18  Jèhófà Ọlọ́run wá sọ pé: “Kò dáa kí ọkùnrin náà máa dá wà. Màá ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tó máa jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀.”+ 19  Jèhófà Ọlọ́run dá gbogbo ẹranko látinú ilẹ̀ àti gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sọ́dọ̀ ọkùnrin náà láti wo orúkọ tó máa sọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; orúkọ tí ọkùnrin náà bá sì sọ ohun alààyè* kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ń jẹ́.+ 20  Ọkùnrin náà wá sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn lórúkọ àti gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run pẹ̀lú gbogbo ẹranko, àmọ́ kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan fún ọkùnrin náà tó máa jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀. 21  Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sun oorun àsùnwọra. Nígbà tó ń sùn, ó yọ ọ̀kan lára egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran bo ibẹ̀. 22  Jèhófà Ọlọ́run wá fi egungun ìhà tó yọ lára ọkùnrin náà mọ obìnrin, ó sì mú un wá fún ọkùnrin náà.+ 23  Ni ọkùnrin náà bá sọ pé: “Èyí gan-an ni egungun látinú egungun miÀti ẹran ara látinú ẹran ara mi. Obìnrin ni yóò máa jẹ́,Torí ara ọkùnrin ló ti wá.”+ 24  Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin á ṣe fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́* ìyàwó rẹ̀, wọ́n á sì di ara kan.+ 25  Ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀ sì wà ní ìhòòhò;+ síbẹ̀ ojú ò tì wọ́n.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “àti gbogbo ọmọ ogun wọn.”
Tàbí “àwọn ohun tó ti ń dá.”
Tàbí “gbogbo ohun tó ti ń dá.”
Orúkọ yìí, יהוה (YHWH), ni a fi ń dá Ọlọ́run tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tó fara hàn. Wo Àfikún A4.
Tàbí “alààyè ọkàn.” Lédè Hébérù, neʹphesh, èyí tó túmọ̀ sí “ẹ̀dá tó ń mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “ó sì di orí mẹ́rin.”
Tàbí “Tígírísì.”
Tàbí “alààyè ọkàn.”
Tàbí “wà pẹ̀lú.”