Lẹ́tà Júùdù 1:1-25

  • Ìkíni (1, 2)

  • Ìdájọ́ àwọn olùkọ́ èké dájú (3-16)

    • Máíkẹ́lì bá Èṣù fa ọ̀rọ̀ (9)

    • Àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù (14, 15)

  • Ẹ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run (17-23)

  • Kí ògo jẹ́ ti Ọlọ́run (24, 25)

 Júùdù, arákùnrin Jémíìsì,+ tí mo jẹ́ ẹrú Jésù Kristi, sí àwọn tí Ọlọ́run tó jẹ́ Baba wa pè,+ tó nífẹ̀ẹ́, tó sì pa mọ́ fún Jésù Kristi:+  Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ Ọlọ́run máa pọ̀ sí i fún yín.  Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, mo ti ń wá bí mo ṣe máa kọ̀wé sí yín nípa ìgbàlà tí gbogbo wa jọ ń jàǹfààní rẹ̀,+ àmọ́ mo rí i pé ó pọn dandan láti kọ̀wé sí yín, kí n lè rọ̀ yín pé kí ẹ máa jà fitafita torí ìgbàgbọ́+ tí Ọlọ́run fún àwọn ẹni mímọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo tí yóò sì wà títí láé.  Ìdí ni pé àwọn kan ti yọ́ wọlé sí àárín yín, àwọn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ tipẹ́tipẹ́ pé ìdájọ́ ń bọ̀ sórí wọn. Wọn ò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa ṣe àwáwí láti máa hu ìwà àìnítìjú,*+ wọ́n sì kọ Jésù Kristi, ẹnì kan ṣoṣo tó ni wá,* tó sì jẹ́ Olúwa wa.+  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mọ gbogbo èyí, mo fẹ́ rán yín létí pé lẹ́yìn tí Jèhófà* ti gba àwọn èèyàn kan là kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ó pa àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ run.+  Ní ti àwọn áńgẹ́lì tó fi ipò wọn àti ibi tó yẹ kí wọ́n máa gbé sílẹ̀,+ ó ti dè wọ́n títí láé sínú òkùnkùn biribiri, ó sì fi wọ́n pa mọ́ de ìdájọ́ ní ọjọ́ ńlá náà.+  Lọ́nà kan náà, Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ìlú tó yí wọn ká ṣe ìṣekúṣe* tó burú jáì, wọ́n ṣe ìfẹ́ tara tí kò bá ìwà ẹ̀dá mu.+ Ìdájọ́ ìparun* ayérayé tí wọ́n gbà jẹ́ àpẹẹrẹ láti kìlọ̀ fún wa.+  Láìka èyí sí, àwọn èèyàn yìí ń ro ìròkurò,* wọ́n ń sọ àwọn èèyàn di ẹlẹ́gbin, wọn ò ka àwọn aláṣẹ sí, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo láìdáa.+  Kódà nígbà tí Máíkẹ́lì+ olú áńgẹ́lì+ ń bá Èṣù fa ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń jiyàn nípa òkú Mósè,+ kò jẹ́ dá a lẹ́jọ́, kò sì sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí i,+ àmọ́ ó sọ fún un pé: “Kí Jèhófà* bá ọ wí.”+ 10  Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn yìí ń sọ ohun tí kò dáa nípa gbogbo ohun tí wọn kò mọ̀.+ Gbogbo ohun tí wọ́n mọ̀ bíi ti ẹranko tí kì í ronú,+ ni wọ́n fi ń sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin. 11  Ó mà ṣe o, wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kéènì.+ Láìronú, wọ́n ṣe ohun tí kò tọ́ bíi ti Báláámù+ torí ohun tí wọ́n máa rí gbà, ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀+ wọn sì mú kí wọ́n ṣègbé bíi ti Kórà!+ 12  Àwọn yìí máa ń wà níbi àsè tí ẹ fìfẹ́ pe ara yín sí,+ àmọ́ wọ́n dà bí àpáta tó fara pa mọ́ lábẹ́ omi. Olùṣọ́ àgùntàn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run ni wọ́n, ara wọn nìkan ni wọ́n ń bọ́.+ Wọ́n dà bí ìkùukùu* tí kò lómi tí atẹ́gùn ń gbá síbí sọ́hùn-ún.+ Wọ́n dà bí igi tí kò léso nígbà ìwọ́wé, tó ti kú pátápátá,* tí a ti hú tegbòtegbò; 13  wọ́n dà bí ìgbì òkun líle tí ń ru ìfófòó ìtìjú ara rẹ̀ sókè + àti bí ìràwọ̀ tí kò ní ọ̀nà tó ń tọ̀, tí yóò wà nínú òkùnkùn biribiri títí láé.+ 14  Kódà, Énọ́kù+ tó jẹ́ ẹnì keje nínú ìran Ádámù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé: “Wò ó! Jèhófà* dé pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye* àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,+ 15  láti ṣe ìdájọ́ gbogbo èèyàn+ àti láti dá gbogbo àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi torí gbogbo ìwà búburú wọn àti gbogbo ọ̀rọ̀ tó burú jáì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ti sọ sí i.”+ 16  Àwọn èèyàn yìí máa ń ráhùn,+ wọ́n máa ń ṣàròyé nípa bí nǹkan ṣe rí fún wọn, ìfẹ́ inú wọn ni wọ́n máa ń ṣe,+ wọ́n ń fọ́nnu, wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ dídùn pọ́n* àwọn ẹlòmíì torí àǹfààní tí wọ́n máa rí.+ 17  Àmọ́, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ rántí ọ̀rọ̀* tí àwọn àpọ́sítélì Olúwa wa Jésù Kristi ti sọ, 18  bí wọ́n ṣe máa ń sọ fún yín pé: “Ní àkókò ìkẹyìn, àwọn tó ń fini ṣe ẹlẹ́yà yóò wà, ohun tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu tó ń wù wọ́n ni wọ́n á máa ṣe.”+ 19  Àwọn yìí ló ń fa ìyapa,+ wọ́n ń hùwà bí ẹranko,* wọn ò ní ẹ̀mí Ọlọ́run.* 20  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ máa fún ara yín lókun látinú ìgbàgbọ́ mímọ́ jù lọ tí ẹ ní, ẹ sì jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí yín bí ẹ ti ń gbàdúrà,+ 21  kí ẹ lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run,+ bí ẹ ti ń retí àánú Olúwa wa Jésù Kristi tí yóò jẹ́ kí ẹ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 22  Bákan náà, ẹ máa ṣàánú+ àwọn tó ń ṣiyèméjì;+ 23  ẹ já wọn gbà kúrò nínú iná kí wọ́n lè ní ìgbàlà.+ Ẹ tún máa ṣàánú àwọn míì, àmọ́ kí ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì kórìíra aṣọ tí ara ti kó àbààwọ́n bá.+ 24  Ọlọ́run, ẹni tó lè ṣọ́ yín kí ẹ má bàa kọsẹ̀ tó sì lè mú kí ẹ ní ayọ̀ púpọ̀ bí ẹ ṣe ń dúró níwájú ògo rẹ̀* láìní àbààwọ́n,+ 25  Ọlọ́run kan ṣoṣo tó jẹ́ Olùgbàlà wa nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa, ni kí ògo, ọlá, agbára àti àṣẹ máa jẹ́ tirẹ̀ láti ayérayé àti nísinsìnyí àti títí láé. Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “tó jẹ́ ọ̀gá wa.”
Ní Grk., “iná.”
Tàbí “lá àlá.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Grk., “kú lẹ́ẹ̀mejì.”
Tàbí “ẹgbẹẹgbàárùn-ún.”
Tàbí “kan sáárá sí.”
Tàbí “àwọn àsọtẹ́lẹ̀.”
Tàbí “ẹni tí nǹkan tara gbà lọ́kàn.”
Tàbí “wọn kò sún mọ́ Ọlọ́run.”
Tàbí “dúró níbi tó wà tògotògo.”