Ẹ́kísódù 34:1-35

  • Ó gbẹ́ àwọn wàláà òkúta míì (1-4)

  • Mósè rí ògo Jèhófà (5-9)

  • Ọlọ́run tún àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà sọ (10-28)

  • Ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú Mósè (29-35)

34  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Kí ìwọ fúnra rẹ gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́,+ màá sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lórí àwọn wàláà àkọ́kọ́+ tí o fọ́ túútúú+ sára rẹ̀.  Múra sílẹ̀ de àárọ̀, torí ìwọ yóò gun Òkè Sínáì lọ ní àárọ̀, kí o sì dúró síbẹ̀ lórí òkè náà níwájú mi.+  Àmọ́ ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ bá ọ lọ, ẹnikẹ́ni ò sì gbọ́dọ̀ sí níbikíbi lórí òkè náà. Àwọn agbo ẹran tàbí ọ̀wọ́ ẹran pàápàá ò gbọ́dọ̀ jẹko níwájú òkè yẹn.”+  Mósè wá gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní àárọ̀ kùtù lọ sí Òkè Sínáì, bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un, ó sì gbé wàláà òkúta méjì náà dání.  Jèhófà sọ̀ kalẹ̀+ nínú ìkùukùu,* ó dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ níbẹ̀, ó sì kéde orúkọ Jèhófà.+  Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,  tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini,+ àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ, dórí ìran kẹta àti dórí ìran kẹrin.”+  Mósè sáré tẹrí ba, ó sì wólẹ̀.  Ó sọ pé: “Jèhófà, tí mo bá ti rí ojúure rẹ, jọ̀ọ́ Jèhófà, máa bá wa lọ kí o sì wà láàárín wa,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé alágídí* ni wá,+ kí o dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì,+ kí o sì mú wa bí ohun ìní rẹ.” 10  Ó fèsì pé: “Èmi yóò dá májẹ̀mú kan: Níṣojú gbogbo èèyàn rẹ, èmi yóò ṣe àwọn ohun àgbàyanu tí wọn ò ṣe* rí ní gbogbo ayé tàbí láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè,+ gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń gbé láàárín wọn yóò rí iṣẹ́ Jèhófà, torí ohun àgbàyanu ni màá ṣe fún yín.+ 11  “Ẹ fiyè sí ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín lónìí.+ Èmi yóò lé àwọn Ámórì kúrò níwájú yín àti àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+ 12  Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá májẹ̀mú,+ kó má bàa di ìdẹkùn fún yín.+ 13  Ṣùgbọ́n kí ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn túútúú, kí ẹ sì wó àwọn òpó òrìṣà* wọn lulẹ̀.+ 14  O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún ọlọ́run míì,+ torí Jèhófà máa ń fẹ́* kí a jọ́sìn òun nìkan.* Àní, ó jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa sin òun nìkan.+ 15  Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú, torí tí wọ́n bá ń bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn,+ ẹnì kan yóò pè ọ́ wá, wàá sì jẹ nínú ẹbọ rẹ̀.+ 16  Ó sì dájú pé ẹ máa mú lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,+ àwọn ọmọbìnrin wọn máa bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, wọ́n á sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe.+ 17  “O ò gbọ́dọ̀ fi irin rọ àwọn ọlọ́run.+ 18  “Kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.+ Ẹ jẹ búrẹ́dì aláìwú bí mo ṣe pa á láṣẹ fún yín; ọjọ́ méje ni kí ẹ fi ṣe é ní àkókò rẹ̀ nínú oṣù Ábíbù,*+ torí oṣù Ábíbù lẹ kúrò ní Íjíbítì. 19  “Tèmi ni gbogbo ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí,*+ pẹ̀lú gbogbo ẹran ọ̀sìn yín, yálà ó jẹ́ àkọ́bí akọ màlúù tàbí ti àgùntàn.+ 20  Kí ẹ fi àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pa dà. Àmọ́ tí ẹ ò bá rà á pa dà, kí ẹ ṣẹ́ ọrùn rẹ̀. Kí ẹ ra gbogbo àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin yín pa dà.+ Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wá síwájú mi lọ́wọ́ òfo. 21  “Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ẹ sinmi* ní ọjọ́ keje.+ Kódà, nígbà ìtúlẹ̀ àti ìkórè, kí ẹ sinmi. 22  “Kí ẹ fi àwọn èso yín tó kọ́kọ́ pọ́n nígbà ìkórè àlìkámà* ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ àti Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé* nígbà tí ọdún bá yí po.+ 23  “Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni kí gbogbo ọkùnrin* yín wá síwájú Jèhófà, Olúwa tòótọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 24  Torí màá lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú yín,+ màá sì mú kí ilẹ̀ yín fẹ̀, ilẹ̀ yín ò sì ní wọ ẹnikẹ́ni lójú nígbà tí ẹ bá ń gòkè lọ rí ojú Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún. 25  “O ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀jẹ̀ rúbọ sí mi pa pọ̀ pẹ̀lú ohun tó ní ìwúkàrà.+ Ẹbọ àjọyọ̀ Ìrékọjá ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ kù di àárọ̀.+ 26  “Kí o mú èyí tó dáa jù nínú àwọn èso tó kọ́kọ́ pọ́n ní ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ “O ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.”+ 27  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,+ torí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi yóò fi bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.”+ 28  Ó sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Kò jẹun rárá, kò sì mu omi.+ Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà sára àwọn wàláà náà, Òfin Mẹ́wàá.*+ 29  Mósè wá sọ̀ kalẹ̀ látorí Òkè Sínáì, àwọn wàláà Ẹ̀rí méjì náà sì wà lọ́wọ́ rẹ̀.+ Nígbà tó sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, Mósè ò mọ̀ pé ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú òun torí ó ti ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. 30  Nígbà tí Áárónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Mósè, wọ́n rí i pé ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú rẹ̀, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti sún mọ́ ọn.+ 31  Àmọ́ Mósè pè wọ́n, Áárónì àti gbogbo ìjòyè àpéjọ náà sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, Mósè sì bá wọn sọ̀rọ̀. 32  Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ ọn, ó sì sọ gbogbo àṣẹ tí Jèhófà pa fún un lórí Òkè Sínáì fún wọn.+ 33  Tí Mósè bá ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, á fi nǹkan bojú.+ 34  Àmọ́ tí Mósè bá fẹ́ wọlé lọ bá Jèhófà sọ̀rọ̀, á ṣí ìbòjú náà kúrò títí á fi jáde.+ Ó wá jáde, ó sì sọ àwọn àṣẹ tó gbà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 35  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rí i pé ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú Mósè; torí náà, Mósè lo ìbòjú náà títí ó fi wọlé lọ bá Ọlọ́run* sọ̀rọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “ìṣòtítọ́.”
Tàbí “inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”
Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
Ní Héb., “ọlọ́rùn líle.”
Tàbí “dá.”
Ní Héb., “torí orúkọ Jèhófà ní nínú.”
Tàbí “kò fẹ́ kí o ní ọlọ́run míì.”
Ní Héb., “gbogbo àkọ́bí tó ṣí ilé ọmọ kọ̀ọ̀kan.”
Tàbí “kí ẹ pa sábáàtì mọ́.”
Tàbí “wíìtì.”
Wọ́n tún máa ń pè é ní Àjọyọ̀ Àtíbàbà (Àgọ́ Ìjọsìn).
Tàbí “akọ.”
Ní Héb., “Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá.”
Ní Héb., “bá a.”