Jẹ́nẹ́sísì 5:1-32

  • Látorí Ádámù dórí Nóà (1-32)

    • Ádámù bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin (4)

    • Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn (21-24)

5  Ìwé ìtàn Ádámù nìyí. Ní ọjọ́ tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run.+  Ó dá wọn ní akọ àti abo.+ Ní ọjọ́ tó dá wọn,+ ó súre fún wọn, ó sì pè wọ́n ní Èèyàn.*  Ádámù pé ẹni àádóje (130) ọdún, ó wá bí ọmọkùnrin kan tó jọ ọ́, tó jẹ́ àwòrán rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì.+  Lẹ́yìn tó bí Sẹ́ẹ̀tì, Ádámù tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.  Gbogbo ọjọ́ ayé Ádámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé ọgbọ̀n (930) ọdún, ó sì kú.+  Sẹ́ẹ̀tì pé ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rùn-ún (105), ó wá bí Énọ́ṣì.+  Lẹ́yìn tó bí Énọ́ṣì, Sẹ́ẹ̀tì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún ó lé méje (807). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.  Gbogbo ọjọ́ ayé Sẹ́ẹ̀tì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú.  Énọ́ṣì pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, ó wá bí Kénánù. 10  Lẹ́yìn tó bí Kénánù, Énọ́ṣì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 11  Gbogbo ọjọ́ ayé Énọ́ṣì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú. 12  Kénánù pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, ó wá bí Máhálálélì.+ 13  Lẹ́yìn tó bí Máhálálélì, Kénánù tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé ogójì (840) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 14  Gbogbo ọjọ́ ayé Kénánù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú. 15  Máhálálélì pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin (65), ó wá bí Járédì.+ 16  Lẹ́yìn tó bí Járédì, Máhálálélì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé ọgbọ̀n (830) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 17  Gbogbo ọjọ́ ayé Máhálálélì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú. 18  Járédì pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́jọ (162), ó wá bí Énọ́kù.+ 19  Lẹ́yìn tó bí Énọ́kù, Járédì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 20  Gbogbo ọjọ́ ayé Járédì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti méjìlélọ́gọ́ta (962) ọdún, ó sì kú. 21  Énọ́kù pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin (65), ó wá bí Mètúsélà.+ 22  Lẹ́yìn tó bí Mètúsélà, Énọ́kù ń bá Ọlọ́run tòótọ́* rìn fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 23  Gbogbo ọjọ́ ayé Énọ́kù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínláàádọ́rin (365) ọdún. 24  Énọ́kù ń bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn. Nígbà tó yá, Énọ́kù ò sí mọ́, torí Ọlọ́run mú un lọ.+ 25  Mètúsélà pé ẹni ọgọ́sàn-án ọdún ó lé méje (187), ó wá bí Lámékì.+ 26  Lẹ́yìn tó bí Lámékì, Mètúsélà tún lo ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlélọ́gọ́rin (782) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 27  Gbogbo ọjọ́ ayé Mètúsélà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mọ́kàndínláàádọ́rin (969) ọdún, ó sì kú. 28  Lámékì pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́sàn-án (182), ó wá bí ọmọkùnrin kan. 29  Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Nóà,*+ ó sọ pé: “Ọmọ yìí á tù wá nínú* nídìí iṣẹ́ wa àti làálàá tí a ṣe torí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.”+ 30  Lẹ́yìn tó bí Nóà, Lámékì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ọdún ó dín márùn-ún (595). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 31  Gbogbo ọjọ́ ayé Lámékì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (777) ọdún, ó sì kú. 32  Lẹ́yìn tí Nóà pé ẹni ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún, ó bí Ṣémù,+ Hámù+ àti Jáfẹ́tì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ádámù; Aráyé.”
Ní Héb., “Ọlọ́run náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ìsinmi; Ìtùnú.”
Tàbí “tù wá lára.”