Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Obìnrin inú Bíbélì​—Kí La Rí Kọ́ Lára Wọn?

Àwọn Obìnrin inú Bíbélì​—Kí La Rí Kọ́ Lára Wọn?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ obìnrin tí ìgbé ayé wọn kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. (Róòmù 15:4; 2 Tímótì 3:16, 17) Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ṣókí nípa díẹ̀ lára àwọn obìnrin tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Ọ̀pọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tá a lè tẹ̀ lé. Àwọn yòókù sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa.—1 Kọ́ríńtì 10:11; Hébérù 6:12

   Ábígẹ́lì

 Ta ni Ábígẹ́lì? Ìyàwó ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Nábálì ni, àmọ́ ọkùnrin náà ti le koko jù. Ní ti Ábígẹ́lì, ó lẹ́wà, ó nírẹ̀lẹ̀, ó ń fòye báni lò, ó sì tún láwọn ànímọ́ míì tínú Jèhófà dùn sí.—1 Sámúẹ́lì 25:3.

 Kí ló ṣe? Ábígẹ́lì hùwà ọgbọ́n, ó sì lo ìfòyemọ̀ kí àjálù má bàa dé bá ìdílé rẹ̀. Agbègbè tí Dáfídì ọba lọ́la orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fara pa mọ́ sí ni Ábígẹ́lì àti Nábálì ń gbé. Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ ló sì ń dáàbò bo agbo àgùntàn Nábálì káwọn olè máa bàa kó wọn lọ. Àmọ́, nígbà táwọn ìránṣẹ́ Dáfídì lọ béèrè oúnjẹ lọ́wọ́ Nábálì, kò tiẹ̀ kà wọ́n sí débi tó máa fún wọn lóúnjẹ. Inú bí Dáfídì gan-an. Lòun àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá gbéra, wọ́n fẹ́ lọ pa Nábálì àti gbogbo ọkùnrin tó wà lágbo ilé rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 25:10-12, 22.

 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ábígẹ́lì gbé ìgbésẹ̀ nígbà tó gbọ́ ohun tí ọkọ rẹ̀ ṣe. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ó ti kó oúnjẹ rẹpẹtẹ jọ, ó sì ní káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ gbé e fún Dáfídì àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún tẹ̀ lé wọn kó lè bẹ Dáfídì. (1 Sámúẹ́lì 25:14-19, 24-31) Nígbà tí Dáfídì rí àwọn ohun tó kó wá àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní, tó sì tún fetí sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó fún un, ó gbà pé Ọlọ́run ló rán Ábígẹ́lì kóun máa bàa ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 25:32, 33) Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Nábálì kú tí Ábígẹ́lì sì di ìyàwó Dáfídì.—1 Sámúẹ́lì 25:37-41.

 Kí la rí kọ́ lára Ábígẹ́lì? Ábígẹ́lì ní ẹwà àti ọrọ̀, àmọ́ kò ro ara rẹ̀ ju bí ó ṣe yẹ lọ. Kí àlàáfíà lè jọba, ó ṣe tán láti tọrọ àforíjì fún ohun tí kì í ṣe ẹ̀bi rẹ̀. Ó fi sùúrù yanjú ìṣòro tó dojú kọ ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, ìgboyà àti ìdánúṣe.

   Dèbórà

 Ta ni Dèbórà? Wòlíì obìnrin ni, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì máa ń sọ àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ fún un. Ọlọ́run tún lò ó láti yanjú àwọn ìṣòro láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Àwọn Onídàájọ́ 4:4, 5.

 Kí ló ṣe? Dèbórà fi ìgboyà ti àwọn olùjọsìn Jèhófà lẹ́yìn. Ó ránṣẹ́ sí Bárákì pé kó ṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lọ gbéjà ko àwọn ará Kénáánì tó ń jẹ gàba lé wọn lórí. (Àwọn Onídàájọ́ 4:6, 7) Nígbà tí Bárákì ní kí Dèbórà tẹ̀ lé òun lọ sójú ogun, kò bẹ̀rù, tinútinú ló fi gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Àwọn Onídàájọ́ 4:8, 9.

 Lẹ́yìn tí Ọlọ́run jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn, Dèbórà àti Bárákì kọrin láti sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, Dèbórà sì wà lára àwọn tó kọ orin náà. Nínú orin yẹn, ó sọ ohun tí Jáẹ́lì obìnrin onígboyà náà ṣe tó mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ará Kénáánì.—Àwọn Onídàájọ́, orí 5.

 Kí la rí kọ́ lára Dèbórà? Dèbórà máa ń lo ara ẹ̀ fáwọn míì, ó sì ní ìgboyà. Ó gba àwọn èèyàn níyànjú láti ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run. Tí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ń gbóríyìn fún wọn.

  Dẹ̀lílà

 Ta ni Dẹ̀lílà? Òun ni obìnrin tí Sámúsìn ọ̀kan lára àwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì fẹ́.—Àwọn Onídàájọ́ 16:4, 5.

 Kí ló ṣe? Ó gba owó lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ Filísínì láti dalẹ̀ Sámúsìn, ẹni tí Ọlọ́run ń lò láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn Filísínì. Agbára àwọn Filísínì kò ká Sámúsìn nítorí Ọlọ́run ló fún un lágbára. (Àwọn Onídàájọ́ 13:5) Ìyẹn ló mú káwọn aláṣẹ Filísínì wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Dẹ̀lílà.

 Àwọn Filísínì fún Dẹ̀lílà ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti bá wọn wádìí orísun agbára Sámúsìn. Dẹ̀lílà gba owó náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ló gbìyànjú láti mọ orísun agbára Sámúsìn, nígbà tó yá, ó mọ̀ ọ́n. (Àwọn Onídàájọ́ 16:15-17) Ó sọ àṣírí náà fáwọn ará Filísínì, wọ́n mú Sámúsìn, wọ́n sì fi i sẹ́wọ̀n.—Àwọn Onídàájọ́ 16:18-21.

 Kí la rí kọ́ lára Dẹ̀lílà? Ìkìlọ̀ lọ̀rọ̀ Dẹ̀lílà jẹ́ fún wa. Ó jẹ́ kí ìwọra borí òun, ó sì hùwà ẹ̀tàn sí ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, ọ̀dàlẹ̀ ni, kò sì mọ̀ ju tara ẹ̀ nìkan.

  Ẹ́sítà

 Ta ni Ẹ́sítà? Ó jẹ́ obìnrin Júù kan tí Ahasuérúsì ọba Páṣíà fi ṣe olorì.

 Kí ló ṣe? Ẹ́sítà lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ọba láti dáwọ́ ìpakúpa tí wọ́n fẹ́ pa àwọn èèyàn rẹ̀ dúró. Ó gbọ́ pé ọba ti pàṣẹ pé kí wọ́n ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ láti pa gbogbo àwọn Júù tó ń gbé Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Hámánì, tó wà ní ipò gíga jù lọ ní ilẹ̀ ọba náà ló wà nídìí òtẹ̀ yìí. (Ẹ́sítà 3:13-15; 4:1, 5) Módékáì ìbátan rẹ̀ àgbà ràn án lọ́wọ́, Ẹ́sítà náà sì ṣe tán láti fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, ó lọ sọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe fún ọkọ rẹ̀ Ọba Ahasuérúsì. (Ẹ́sítà 4:10-16; 7:1-10) Ahasuérúsì wá gba Ẹ́sítà àti Módékáì láàyè láti gbé àṣẹ ọba tuntun mìíràn jáde tó fàyè gba àwọn Júù láti gbèjà ara wọn. Àwọn Júù sì rẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn pátápátá.—Ẹ́sítà 8:5-11; 9:16, 17.

 Kí la rí kọ́ lára Ẹ́sítà? Ẹ́sítà ayaba fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ torí pé ó ní ìgboyà, ìrẹ̀lẹ̀, ó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. (Sáàmù 31:24; Fílípì 2:3) Láìka ẹwà àti ipò rẹ̀ sí, ó béèrè fún ìmọ̀ràn àti ìrànlọ́wọ́. Nígbà tó ń bá ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó lo ọgbọ́n, ìgboyà, ó sì bọ̀wọ̀ fún un. Lásìkò tí wọ́n fẹ́ pa àwọn Júù run, kò bẹ̀rù láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Júù lòun náà.

  Éfà

 Ta ni Éfà? Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run dá, òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.

 Kí ló ṣe? Éfà ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run. Bíi ti Ádámù ọkọ rẹ̀, Ọlọ́run dá Éfà ní ẹni pípé pẹ̀lú òmìnira láti yan ohun tó fẹ́, ó sì tún lè ní irú àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní, irú bí ìfẹ́ àti ọgbọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Éfà mọ̀ pé Ọlọ́run ti sọ fún Ádámù pé táwọn bá jẹ nínú èso igi tí Ọlọ́run ní káwọn má jẹ, àwọn máa kú. Àmọ́, Sátánì tan Éfà jẹ, ó sọ fún un pé wọn ò ní kú tí wọ́n bá jẹ èso náà. Kódà, Sátánì mú kó gbà gbọ́ pé nǹkan máa sàn fún un tó bá rú òfin Ọlọ́run. Torí náà, ó jẹ èso yẹn, ó sì mú kí ọkọ ẹ̀ náà jẹ ẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; 1 Tímótì 2:14.

 Kí la rí kọ́ lára Éfà? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Éfà jẹ́ ká mọ̀ pé ó léwu téèyàn bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sí. Éfà jẹ́ kí nǹkan tí kì í ṣe tiẹ̀ wọ òun lójú, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà.—Jẹ́nẹ́sísì 3:6; 1 Jòhánù 2:16.

  Hánà

 Ta ni Hánà? Òun ni ìyàwó Ẹlikénà àti ìyá Sámúẹ́lì. Sámúẹ́lì sì di wòlíì olókìkí ní Ísírẹ́lì àtijọ́.—1 Sámúẹ́lì 1:1, 2, 4-7.

 Kí ló ṣe? Nígbà tí Hánà kò rí ọmọ bí, ó yíjú sí Ọlọ́run fún ìtùnú. Ìyàwó méjì ni ọkọ ẹ̀ ní. Pẹ̀nínà tó jẹ́ ìyàwó kejì ó láwọn ọmọ, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún ni Hánà kò fi rọ́mọ bí lẹ́yìn tó wọlé ọkọ. Pẹ̀nínà máa ń bú Hánà, àmọ́ Hánà máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó tu òun nínú. Ó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run pé tó bá fún òun ní ọmọkùnrin kan, òun á yọ̀ǹda ẹ̀ láti lọ sìn ní àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn àgọ́ kan tó ṣe é gbé kiri táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń lò fún ìjọsìn.—1 Sámúẹ́lì 1:11.

 Ọlọ́run dáhùn àdúrà Hánà, ó sì bí Sámúẹ́lì. Hánà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, nígbà tí Sámúẹ́lì wà ní kékeré, ó mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn láti máa sìn níbẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 1:27, 28) Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, ìyá rẹ̀ máa ń rán aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá, á sì mú u lọ fún un. Nígbà tó yá, Ọlọ́run fi ọmọ márùn-ún míì jíǹkí Hánà, ọkùnrin mẹ́ta àti obìnrin méjì.—1 Sámúẹ́lì 2:18-21

 Kí la rí kọ́ lára Hánà? Àdúrà àtọkànwá tí Hánà gbà ràn án lọ́wọ́ láti fara da ọ̀pọ̀ àdánwò. Àdúrà ìdúpẹ́ rẹ̀ tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 2:1-10 jẹ́ ká rí bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run ṣe jinlẹ̀ tó.

  Jáẹ́lì

 Ta ni Jáẹ́lì? Jáẹ́lì jẹ́ ìyàwó ọkùnrin kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, Hébà lorúkọ ẹ̀. Jáẹ́lì fi ìgboyà ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́.

  Kí ló ṣe? Jáẹ́lì hùwà ọgbọ́n nígbà tí Sísérà, olórí ogun àwọn ará Kénáánì wá sínú àgọ́ rẹ̀. Sísérà fìdí rẹmi nínú ogun tó jà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí i sá fún ẹ̀mí ẹ̀, ó sì ń wá ibi tó lè fara pa mọ́ sí. Jáẹ́lì wá pè é wá sí àgọ́ rẹ̀ pé kó wá fara pa mọ́, kó sì sinmi. Nígbà tó ń sùn lọ́wọ́, Jáẹ́lì fi ikú pa á.—Àwọn Onídàájọ́ 4:17-21.

 Ohun tí Jáẹ́lì ṣe mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Dèbórà ṣẹ pé: “Obìnrin ni Jèhófà máa fi Sísérà lé lọ́wọ́.” (Àwọn Onídàájọ́ 4:9) Torí ohun tí Jáẹ́lì ṣe yìí, wọ́n yìn ín, wọ́n sì pè é ní “ẹni tí a bù kún jù lọ nínú àwọn obìnrin.”—Àwọn Onídàájọ́ 5:24.

 Kí la rí kọ́ lára Jáẹ́lì? Jáẹ́lì lo ìdánúṣe àti ìgboyà. Ohun tó ṣe fi hàn pé Ọlọ́run lè yí ohunkóhun pa dà láti mú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ.

  Jésíbẹ́lì

 Ta ni Jésíbẹ́lì? Ìyàwó Ọba Áhábù tó jẹ́ ọba Ísírẹ́lì ni. Kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì bẹ́ẹ̀ ni kò jọ́sìn Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Báálì ọlọ́run àwọn ará Kénáánì ló ń jọ́sìn.

 Kí ló ṣe? Ajẹgàba ni Ayaba Jésíbẹ́lì, ìkà àti oníjàgídíjàgan sì ni. Ó gbé ìjọsìn Báálì lárugẹ pa pọ̀ pẹ̀lú ìṣekúṣe tí wọ́n máa ń ṣe nínú ìjọsìn Báálì. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún gbìyànjú láti fòpin sí ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́.—1 Àwọn Ọba 18:4, 13; 19:1-3.

 Jésíbẹ́lì máa ń parọ́, ó sì máa ń pa àwọn èèyàn kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ ohun tó fẹ́. (1 Àwọn Ọba 21:8-16) Bí Ọlọ́run ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ó kú ikú oró, kò sì sẹ́ni tó sin in.—1 Àwọn Ọba 21:23; 2 Àwọn Ọba 9:10, 32-37.

 Kí la rí kọ́ lára Jésíbẹ́lì? Ìkìlọ̀ ni àpẹẹrẹ Jésíbẹ́lì jẹ́. Ó máa ń hùwà pálapàla àti ìwàkiwà débi pé téèyàn bá gbọ́ orúkọ ẹ̀, ìwà àìnítìjú àti ìwà ìríra táwọn èèyàn ń hù ló máa ń gbé sí èèyàn lọ́kàn.

  Líà

 Ta ni Líà? Òun nìyàwó àkọ́kọ́ tí Jékọ́bù fẹ́. Àbúrò rẹ̀ Réṣẹ́lì sì nìyàwó kejì.—Jẹ́nẹ́sísì 29:20-29.

 Kí ló ṣe? Líà bí ọmọkùnrin mẹ́fà fún Jékọ́bù. (Rúùtù 4:11) Réṣẹ́lì ni Jékọ́bù ní lọ́kàn láti fẹ́, kì í ṣe Líà. Àmọ́, Lábánì, bàbá àwọn ọmọbìnrin yìí ṣètò pé kí Líà gbapò Réṣẹ́lì. Nígbà tí Jékọ́bù rí i pé wọ́n ti tan òun láti fẹ́ Líà, ó kojú Lábánì. Lábánì sọ fún un pé nínú àṣà àwọn, àbúrò obìnrin kì í ṣáájú ẹ̀gbọ́n ẹ̀ obìnrin lọ sílé ọkọ. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, Jékọ́bù fẹ́ Réṣẹ́lì.—Jẹ́nẹ́sísì 29:26-28.

 Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì ju Líà lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 29:30) Torí náà, ara ta Líà gan-an, ó sì jowú torí Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ àbúrò ẹ̀ jù ú lọ. Ọlọ́run rí bọ́rọ̀ ṣe rí lára Líà, ó sì fi ọmọ méje jíǹkí rẹ̀, ọkùnrin mẹ́fà àti obìnrin kan.—Jẹ́nẹ́sísì 29:31.

 Kí la rí kọ́ lára Líà? Líà gbára lé Ọlọ́run nínú àdúrà, kò sì jẹ́ kí ìṣòro ìdílé tó ní mú kó má rí bí Ọlọ́run ṣe ń ti òun lẹ́yìn. (Jẹ́nẹ́sísì 29:32-35; 30:20) Ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ fi hàn pé kíkó obìnrin jọ kì í sábà bímọọre bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fàyè gbà á fún àwọn àkókò kan. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí ọkùnrin ní ìyàwó kan, kí obìnrin náà sì ní ọkọ kan ṣoṣo.—Mátíù 19:4-6.

 •  Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa Líà, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Tí Wọn Ò Láyọ̀ Ló ‘Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì.’

 •  Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba pé káwọn èèyàn rẹ̀ àtijọ́ ní ju ìyàwó kan lọ, wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ìkóbìnrinjọ?

  Màtá

 Ta ni Màtá? Ó jẹ́ arábìnrin Lásárù àti Màríà, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì ń gbé ní Bẹ́tánì tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù.

 Kí ló ṣe? Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Jésù ni Màtá. Jésù “fẹ́ràn Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.” (Jòhánù 11:5) Màtá fẹ́ràn kó máa ṣe àlejò. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù máa ń lọ sọ́dọ̀ wọn, àmọ́ ìgbà kan wà tí Màríà dúró ti Jésù kó lè máa fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, àmọ́ iṣẹ́ ilé ni Màtá gbájú mọ́ ní tiẹ̀. Màtá bá fẹjọ́ Màríà sun Jésù pé kò ran òun lọ́wọ́. Jésù fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tún ojú ìwòye Màtá ṣe.—Lúùkù 10:38-42.

 Nígbà tí Lásárù ń ṣàìsàn, Màtá àti arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí Jésù, wọ́n sì gbà pé ó máa wo arákùnrin àwọn sàn. (Jòhánù 11:3, 21) Àmọ́ Lásárù kú. Ọ̀rọ̀ tí Màtá bá Jésù sọ fi hàn pé ó ní ìgbọ́kànlé nínú ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé àjíǹde àwọn òkú máa wà àti pé Jésù lágbára láti jí arákùnrin rẹ̀ dìde.—Jòhánù 11:20-27.

 Kí la rí kọ́ lára Màtá? Màtá sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣaájò àlejò. Tinútinú ló fi gba ìmọ̀ràn. Ó sì sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ àti ohun tó gbà gbọ́ ní gbangba.

 •  Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa Màtá, wo àpilẹ̀kọ náà ““Mo Ti Gbà Gbọ́.”

  Màríà (ìyá Jésù)

 Ta ni Màríà? Ọ̀dọ́bìnrin Júù kan ni, kò sì mọ ọkùnrin títí dìgbà tó fi bí Jésù, nítorí ọ̀nà ìyanu ló gbà lóyún ọmọ Ọlọ́run.

 Kí ló ṣe? Màríà fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó ti ń fẹ́ Jósẹ́fù sọ́nà nígbà tí áńgẹ́lì Ọlọ́run yọ sí i, tó sì sọ fún un pé á lóyún, á sì bí Mèsáyà tí àwọn èèyàn ti ń retí tipẹ́tipẹ́. (Lúùkù 1:26-33) Ó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà tinútinú. Lẹ́yìn tí Màríà bí Jésù, òun àti Jósẹ́fù bí ọmọkùnrin mẹ́rin àti ó kéré tán ọmọbìnrin méjì. Torí náà Màríà kì í ṣe wúńdíá mọ́. (Mátíù 13:55, 56) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe iṣẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, kò fìgbà kankan retí pé kí wọ́n máa yin òun tàbí kí wọ́n máa gbé òun gẹ̀gẹ̀, bóyá nígbà tí Jésù wà láyé tàbí nígbà tí Màríà wà nínú ìjọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.

 Kí la rí kọ́ lára Màríà? Obìnrin olóòótọ́ kan tó fi tinútinú gba ojúṣe pàtàkì ni Màríà. Ó mọ Ìwé Mímọ́ dunjú. Ó jọ pé nǹkan bí ogún (20) ìgbà ni Màríà fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó sọ nínú Lúùkù 1:46-55.

  Màríà (arábìnrin Màtá àti Lásárù)

 Ta ni Màríà? Màríà pẹ̀lú Lásárù arákùnrin rẹ̀ àti Màtá arábìnrin wọn jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún Jésù.

 Kí ló ṣe? Léraléra ló fi hàn pé òun mọyì bí Jésù ṣe jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run. Ohun tó sọ fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ pé ká ní Jésù wà níbẹ̀ ni, Lásárù arákùnrin òun ò ní kú, ó sì ṣojú rẹ̀ nígbà tí Jésù jí i dìde. Nígbà kan tí Jésù wà lọ́dọ̀ wọn, Màtá tó jẹ́ arábìnrin Màríà fẹjọ́ rẹ̀ sun torí pé ó jókòó láti gbọ́rọ̀ Jésù dípò kó lọ́ bá Màtá se oúnjẹ. Àmọ́, Jésù gbóríyìn fún Màríà torí pé nǹkan tẹ̀mí ló jẹ ẹ́ lógún.—Lúùkù 10:38-42.

 Ìgbà kan tún wà tí Màríà hùwà ọ̀làwọ́ tó jọni lójú sí Jésù nígbà tó da “òróró onílọ́fínńdà olówó iyebíye” sí orí àti ẹsẹ̀ Jésù. (Mátíù 26:6, 7) Àwọn míì tó wà níbẹ̀ fi ẹ̀sùn kan Màríà pé ó ń fi nǹkan ṣòfò. Àmọ́, Jésù gbèjà ẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Ibikíbi tí a bá ti ń wàásù ìhìn rere yìí ní gbogbo ayé, wọ́n á máa sọ ohun tí obìnrin yìí ṣe láti fi rántí rẹ̀.”—Mátíù 24:14; 26:8-13.

 Kí la rí kọ́ lára Màríà? Màríà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Ó fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú nǹkan tara. Kódà, ó fi ohun ìní ẹ̀ bọlá fún Jésù bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ná an lówó rẹpẹtẹ.

  Màríà Magidalénì

 Ta Ni Màríà Magidalénì? Ọmọlẹ́yìn Jésù kan tó jẹ́ olóòótọ́ ni.

 Kí ló ṣe? Màríà Magidalénì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó rin ìrìn àjò pẹ̀lú Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó fi àwọn ohun ìní ẹ̀ bójú tó ohun tí wọ́n nílò. (Lúùkù 8:1-3) Ó tẹ̀ lé Jésù títí tí Jésù fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n pa á. Ó ní àǹfààní láti wà lára àwọn tó kọ́kọ́ rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde.—Jòhánù 20:11-18.

 Kí la rí kọ́ lára Màríà Magidalénì? Màríà Magidalénì fi tinútinú ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lẹ́yìn, ó sì jẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.

  Míríámù

 Ta ni Míríámù? Ẹ̀gbọ́n Mósè àti Áárónì ni. Òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tí Bíbélì pè ní wòlíì.

 Kí ló ṣe? Torí pé wòlíì ni, ó máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run fàwọn èèyàn. Ó ní àwọn àǹfààní àkànṣe kan ní Ísírẹ́lì, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tó kọrin ìṣẹ́gun lẹ́yìn tí Ọlọ́run ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Íjíbítì nínú Òkun Pupa—Ẹ́kísódù 15:1, 20, 21.

 Nígbà tó yá, Míríámù àti Áárónì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Mósè. Ìgbéraga àti owú ló sì mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run “ń fetí sílẹ̀” sí wọn, ó sì bá Míríámù àti Áárónì wí. (Nọ́ńbà 12:1-9) Ọlọ́run fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọlu Míríámù, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí òun ló bẹ̀rẹ̀ ọ̀tẹ̀ yẹn. Mósè wá bẹ Ọlọ́run nítorí rẹ̀, Ọlọ́run sì wò ó sàn. Lẹ́yìn ọjọ́ méje tí wọ́n fi sé e mọ́ torí àìsàn náà, ó pa dà sí ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Nọ́ńbà 12:10-15.

 Bíbélì fi hàn pé Míríámù gba ìbáwí torí pé nígbà tí Ọlọ́run ń bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Ọlọ́run ó rán wọn létí pé: “Mo rán Mósè, Áárónì àti Míríámù sí yín.”—Míkà 6:4.

 Kí la rí kọ́ lára Míríámù? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Míríámù jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run máa ń kíyè sí ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ nípa àwọn míì. A tún kọ́ pé tá a bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, a gbọ́dọ̀ yẹra fún owú àti ìgbéraga torí pé àwọn nǹkan yìí lè ba orúkọ àwọn míì jẹ́.

  Réṣẹ́lì

 Ta ni Réṣẹ́lì? Òun ni ọmọbìnrin Lábánì àti ìyàwó tí Jékọ́bù fẹ́ràn jù.

 Kí ló ṣe? Réṣẹ́lì fẹ́ Jékọ́bù, ó sì bí ọmọkùnrin méjì fún un. Àwọn ọmọ yìí wà lára àwọn olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá (12) Ísírẹ́lì àtijọ́. Ìgbà tí Réṣẹ́lì ń da àgùntàn bàbá rẹ̀ ló pà dé ọkọ tó fẹ́ nígbà tó yá. (Jẹ́nẹ́sísì 29:9, 10) Réṣẹ́lì “wuni, ó sì rẹwà gan-an” ju Líà ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.—Jẹ́nẹ́sísì 29:17.

 Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì, ó sì gbà láti ṣiṣẹ́ fún ọdún méje kó lè fẹ́ ẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 29:18) Àmọ́, Lábánì tan Jékọ́bù jẹ kó lè kọ́kọ́ fẹ́ Líà, lẹ́yìn náà Lábánì gbà kí Jékọ́bù fẹ́ Réṣẹ́lì.—Jẹ́nẹ́sísì 29:25-27.

 Jékọ́bù fẹ́ràn Réṣẹ́lì àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì ju bó ṣe fẹ́ràn Líà àtàwọn ọmọ rẹ̀ lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 37:3; 44:20, 27-29) Torí náà, àárín àwọn obìnrin méjèèjì yìí ò gún.—Jẹ́nẹ́sísì 29:30; 30:1, 15.

 Kí la rí kọ́ lára Réṣẹ́lì? Réṣẹ́lì fara da ìṣòro ìdílé tó nira, kò sì sọ̀rètí nù pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà òun. (Jẹ́nẹ́sísì 30:22-24) Ìtàn rẹ̀ fi hàn pé ìnira ni ìkóbìnrinjọ kì í bímọ re. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Réṣẹ́lì jẹ́ ká rí ọgbọ́n tó wà nínú ètò tí Ọlọ́run ṣe látìbẹ̀rẹ̀ pé ọkùnrin kan ò gbọ́dọ̀ ní ju ìyàwó kan lọ.—Mátíù 19:4-6.

 •  Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa Réṣẹ́lì, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Tí Wọn Ò Láyọ̀ Ló ‘Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì.’

 •  Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba pé káwọn èèyàn rẹ̀ àtijọ́ ní ju ìyàwó kan lọ, wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ìkóbìnrinjọ?

  Ráhábù

 Ta ni Ráhábù? Aṣẹ́wó kan tó ń gbé ní ọ̀kan lára àwọn ìlú tó wà ní Jẹ́ríkò, nílẹ̀ Kénáánì. Nígbà ó yá, ó di olùjọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run.

 Kí ló ṣe? Ráhábù fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì tó wá ṣe amí ilẹ̀ náà pa mọ́. Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó ti gbọ́ ìròyìn nípa bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè ní Íjíbítì àti bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn Ámórì.

 Ráhábù ran àwọn amí yẹn lọ́wọ́, ó sì bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n dá ẹ̀mí òun àtàwọn ẹbí òun sí nígbà tí Ísírẹ́lì bá wá pa Jẹ́ríkò run. Wọ́n gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó láwọn nǹkan tóun náà gbọ́dọ̀ ṣe: Kò ní sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ìdí tí wọ́n fi wá. Yàtọ̀ síyẹn, inú ilé lòun àtàwọn ẹbí ẹ̀ gbọ́dọ̀ dúró sí, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fi aṣọ pupa sí ojú fèrèsé ilé náà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè dá ilé náà mọ̀ yàtọ̀. Ráhábù pa gbogbo ìtọ́ni yẹn mọ́, òun àti ìdílé rẹ̀ sì làá já nígbà tí Ísírẹ́lì pa Jẹ́ríkò run.

 Ráhábù pa dà fẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì kan, ó sì wá di ìyá ńlá fún Ọba Dáfídì àti Jésù Kristi.—Jóṣúà 2:1-24; 6:25; Mátíù 1:5, 6, 16.

 Kí la rí kọ́ lára Ráhábù? Bíbélì sọ pé ìgbàgbọ́ Ráhábù ta yọ. (Hébérù 11:30, 31; Jémíìsì 2:25) Ìtàn rẹ̀ fi hàn pé Ọlọ́run máa ń dárí jini, kì í sì ṣe ojúsàájú. Ó máa ń bù kún àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e láìka ibi tí wọ́n ti wá sí.

  Rèbékà

 Ta ni Rèbékà? Ìyàwó Ísákì ni, òun sì ni ìyá àwọn ìbejì tí wọ́n bí, ìyẹn Jékọ́bù àti Ísọ̀.

 Kí ló ṣe? Rèbékà ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kódà nígbà tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nira. Nígbà tó ń fa omi nínú kànga, ọkùnrin kan ní kó fún òun lómi mu. Ní kíá, Rèbékà fún un lómi mu, ó sì tún yọ̀ǹda láti fa omi fún àwọn ràkunmí ọkùnrin náà. (Jẹ́nẹ́sísì 24:15-20) Ìránṣẹ́ Ábúráhámù ni ọkùnrin yẹn, ó sì ti rin ìrìn àjò tó jìnnà láti wá ìyàwó fún Ísákì ọmọkùnrin Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 24:2-4) Ó sì ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́. Bó se rí i pé Rèbékà ń ṣiṣẹ́ kára àti pé ó lẹ́mìí aájò àlejò, ó fòye mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà òun, ó sì gbà pé Rèbékà ni Ọlọ́run yàn fún Ísákì.—Jẹ́nẹ́sísì 24:10-14, 21, 27.

 Nígbà tí Rèbékà gbọ́ ohun tí ìránsẹ́ náà wá fún, ó gbà láti bá a lọ, kó sì di ìyàwó Ísákì. (Jẹ́nẹ́sísì 24:57-59) Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín Rèbékà bí ọkùnrin méjì, ìbejì sì ni wọ́n. Ọlọ́run jẹ́ kí Rèbékà mọ̀ pé Ísọ̀ tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n máa sin àbúrò rẹ̀ Jékọ́bù. (Jẹ́nẹ́sísì 25:23) Nígbà tí Ísákì ṣètò láti súre fún Ísọ̀ tó jẹ́ àkọ́bí, Rèbékà rí i pé Jékọ́bù ni bàbá wọn súre fún dípò Ísọ̀ torí ó ti mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ nìyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 27:1-17.

 Kí la rí kọ́ lára Rèbékà? Rèbékà mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì nífẹ̀ẹ́ àtimáa ṣe àlejò. Àwọn ànímọ́ tó ní yìí ló jẹ́ kó di ìyàwó rere, ìyá tó mọ iṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ àti olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́.

  Rúùtù

 Ta ni Rúùtù? Obìnrin ará Móábù kan ni. Ó fi àwọn ọlọ́run rẹ̀ àti ìlú rẹ̀ sílẹ̀ láti di olùjọsìn Jèhófà ní ilẹ́ Ísírẹ́lì.

 Kí ló ṣe? Rúùtù fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí Náómì ìyá ọkọ ẹ̀. Náómì àti ọkọ ẹ̀ títí kan àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì lọ sí Móábù kí ìyàn tó wà ní Ísírẹ́lì má bàa pa wọ́n. Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, àwọn ọmọkùnrin wọn fẹ́ àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Móábù, Rúùtù àti Ópà lorúkọ wọn. Nígbà tó yá, ọkọ Náómì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì kú, wọ́n sì fi opó mẹ́ta sílẹ̀.

 Náómì pinnu láti pa dà sí Ísírẹ́lì, ó ṣe tán kò sí ìyàn mọ́ níbẹ̀. Rúùtù àti Ópà pinnu láti tẹ̀ lé e. Àmọ́, Náómì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Ópà pa dà ní ti ẹ̀. (Rúùtù 1:1-6, 15) Ṣùgbọ́n Rúùtù dúró ti ìyá ọkọ rẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ Náómì, ó sì ṣe tán láti sin Jèhófà Ọlọ́run tí Náómì ń sìn.—Rúùtù 1:16, 17; 2:11.

 Rúùtù ṣiṣẹ́ kára gan-an kó lè tọ́jú ìyá ọkọ rẹ̀, kò sì pẹ́ táwọn aládùúgbò fi gbọ́ nípa rẹ̀ nígbà tí wọ́n dé ìlú ìbílẹ̀ Náómì, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ọkùnrin onílé ọlọ́nà kan tó ń jẹ́ Bóásì mọrírì ohun tí Rúùtù ń ṣe gan-an, débi pé tinútinú ló fi pèsè oúnjẹ fún Rúùtù àti Náómì. (Rúùtù 2:5-7, 20) Nígbà tó yá, Rúùtù fẹ́ Bóásì, ó sì di ìyá ńlá fún Ọba Dáfídì àti Jésù Kristi.—Mátíù 1:5, 6, 16.

 Kí la rí kọ́ lára Rúùtù? Torí pé Rúùtù nífẹ̀ẹ́ Náómì àti Jèhófà gan-an, ó fi ìlú àti àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀. Ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, adúróṣinṣin sì ni kódà lójú àwọn ìṣòro tó le gan-an.

  Sérà

 Ta Ni Sérà? Òun ni ìyàwó Ábúráhámù àti ìyá Ísákì.

 Kí ló ṣe? Sérà fi ìgbé ayé tó rọ̀ ọ́ lọ́rùn sílẹ̀ nílùú ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Úrì. Ìdí sì ni pé ó nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù ọkọ rẹ̀. Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kó kúrò ní Úrì, kó kó lọ sí Kénánì. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa bù kún un, òun á sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-5) Ó ṣeé ṣe kí Sérà ti tó ẹni ọgọ́ta (60) ọdún nígbà yẹn. Láti ìgbà yẹn, inú àgọ́ ni Sérà àti ọkọ rẹ̀ ń gbé, wọ́n sì ń ṣí kiri láti ibì kan sí ibòmíì.

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó léwu pé kéèyàn máa ṣí kiri, síbẹ̀ Sérà dúró ti ọkọ ẹ̀ gbágbágbá bí Ábúráhámù ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 12:10, 15) Ọ̀pọ̀ ọdún ni Sérà ò fi rọ́mọ bí, ìyẹn sì kó ìbànújẹ́ bá a gan-an. Síbẹ̀, Ọlọ́run ti ṣélérí pé Òun máa bù kún àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 12:7; 13:15; 15:18; 16:1, 2, 15) Nígbà tó yá, Ọlọ́run jẹ́ kó dá Sérà àti Ábúráhámù lójú pé wọ́n máa bímọ fún ara wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti dàgbà kọjá ẹni tó le bímọ, ó ṣì bímọ náà. Ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún ni nígbà yẹn, ọkọ rẹ̀ sì jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún. (Jẹ́nẹ́sísì 17:17; 21:2-5) Wọ́n pe orúkọ ọmọ náà ní Ísákí.

 Kí la rí kọ́ lára Sérà? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sérà jẹ́ ká rí i pé a lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé ó máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, títí kan àwọn tó jọ pé kò lè ṣeé ṣe! (Hébérù 11:11) Àpẹẹrẹ tó dáa ló fi lélẹ̀ tó bá di pé kí ìyàwó bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ ẹ̀.—1 Pétérù 3:5, 6.

  Ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì

 Ta ni ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì? Arẹwà ọmọbìnrin kan tí ń gbé ní àrọko ni, òun ni ìwé Orin Sólómọ́nì dá lé lórí. Bíbélì kò sọ orúkọ rẹ̀.

 Kí ló ṣe? Omidan Ṣúlámáítì jẹ́ adúrósinsin sí ọ̀dọ́kùnrin olùsọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́. (Orin Sólómọ́nì 2:16) Ẹwà rẹ̀ tó sàrà ọ̀tọ̀ gba àfiyèsí Sólómọ́nì ọba, ó sì gbìyànjú láti fa ojú rẹ̀ mọ́ra. (Orin Sólómọ́nì 7:6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míì gbà á nímọ̀ràn pé kó fẹ́ Ọba Sólómọ́nì, ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì kọ̀ jálẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ olùṣọ́ àgùntàn yẹn bí kò tiẹ̀ lówó, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i.—Orin Sólómọ́nì 3:5; 7:10; 8:6.

 Kí la rí kọ́ lára ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì? Kò ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, láìka ẹwà rẹ̀ àti àfiyèsí tí ọba fi hàn sí i. Kò jẹ́ kí owó tàbí ìfẹ́ tí Ọba Sólómọ́nì fi hàn sí i wọ òun lójú. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ oníwà mímọ́, kò sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà gbòdì lára ẹ̀.

  Aya Lọ́ọ̀tì

 Ta ni aya Lọ́ọ̀tì? Bíbélì kò dárúkọ rẹ̀. Àmọ́, Bíbélì sọ fún wa pé ó ní ọmọbìnrin méjì, ìlú Sódómù lòun àti ìdílé rẹ̀ sì ń gbé.—Jẹ́nẹ́sísì 19:1, 15.

 Kí ló ṣe? Ó ṣàìgbọràn sí òfin Ọlọ́run. Torí pé àwọn tó ń gbé ní Sódómù àti àwọn ìlú tó yí i ká ń hùwà ìṣekúṣe tó burú jáì, Ọlọ́run pinnu pé òun máa pa wọ́n run. Àmọ́ torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ olódodo àti ìdílé ẹ̀, ó rán áńgẹ́lì méjì pé kí wọ́n mú wọn kúrò níbẹ̀ kí wọ́n má bàa fara pa.—Jẹ́nẹ́sísì 18:20; 19:1, 12, 13.

 Àwọn áńgẹ́lì náà sọ fún ìdílé Lọ́ọ̀tì pé kí wọ́n sá kúrò ní agbègbè náà, kí wọ́n má sì wo ẹ̀yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n máa kú ni o. (Jẹ́nẹ́sísì 19:17) Àmọ́, aya Lọ́ọ̀tì “bẹ̀rẹ̀ sí í wo ẹ̀yìn, ó sì di ọwọ̀n iyọ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 19:26.

 Kí la rí kọ́ lára aya Lọ́ọ̀tì? Ìtàn rẹ̀ jẹ́ ká rí ewu tó wà nínú kéèyàn fẹ́ràn ohun tara débi tó fi máa ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Jésù sọ pé aya Lọ́ọ̀tì jẹ́ àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ fún wa, ó ní: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì”.—Lúùkù 17:32.

 Àtẹ Ọjọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Àwọn Obìnrin inú Bíbélì

 1.   Éfà

 2.  Ìkún omi (2370 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni)

 3.  Sérà

 4.  Aya Lọ́ọ̀tì

 5.  Rèbékà

 6.  Líà

 7.  Réṣẹ́lì

 8.  Wọ́n Kúrò ní Íjíbítì (1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni)

 9.  Míríámù

 10.  Ráhábù

 11.  Rúùtù

 12.  Dèbórà

 13.  Jáẹ́lì

 14.  Dẹ̀lílà

 15.  Hánà

 16.  Ọba Ísírẹ́lì àkọ́kọ́ (1117 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni)

 17.  Ábígẹ́lì

 18.  Ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì

 19.  Jésíbẹ́lì

 20.  Ẹ́sítà

 21.  Màríà (ìyá Jésù)

 22.  Ìbatisí Jésù (29 Sànmánì Kristẹni)

 23.  Màtá

 24.  Màríà (arábìnrin Màtá àti Lásárù)

 25.  Màríà Magidalénì

 26.  Ikú Jésù (33 Sànmánì Kristẹni)