Orin Sólómọ́nì 8:1-14

  • Ọ̀dọ́bìnrin (1-4)

    • “Ká ní o dà bí arákùnrin mi ni” (1)

  • Àwọn arákùnrin ọ̀dọ́bìnrin náà (5a)

    • ‘Ta nìyí, tó fara ti olólùfẹ́ rẹ̀?’

  • Ọ̀dọ́bìnrin (5b-7)

    • “Ìfẹ́ lágbára bí ikú” (6)

  • Àwọn arákùnrin ọ̀dọ́bìnrin náà (8, 9)

    • “Tó bá jẹ́ ògiri, . . . àmọ́ tó bá jẹ́ ilẹ̀kùn, . . .” (9)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (10-12)

    • “Ògiri ni mí” (10)

  • Olùṣọ́ àgùntàn (13)

    • ‘Jẹ́ kí n gbọ́ ohùn rẹ’

  • Ọ̀dọ́bìnrin (14)

    • “Yára bí egbin”

8  “Ká ní o dà bí arákùnrin mi ni,Tó mu ọmú ìyá mi! Tí mo bá rí ọ níta, ṣe ni ǹ bá fi ẹnu kò ọ́ lẹ́nu,+Àwọn èèyàn ò sì ní fi ojú àbùkù wò mí.   Màá darí rẹ;Màá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi,+Ẹni tó kọ́ mi. Màá fún ọ ní wáìnì tó ń ta sánsán mu,Omi èso pómégíránétì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fún.   Ọwọ́ òsì rẹ̀ yóò wà lábẹ́ orí mi,Á sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbá mi mọ́ra.+   Mo mú kí ẹ búra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù: Pé kí ẹ má ṣe ta ìfẹ́ jí, ẹ má sì ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí á fi wá fúnra rẹ̀.”+   “Ta nìyí, tó ń bọ̀ látinú aginjù,Tó fara ti olólùfẹ́ rẹ̀?” “Mo jí ọ lábẹ́ igi ápù. Ibẹ̀ ni ìyá rẹ ti rọbí nígbà tó fẹ́ bí ọ. Ibẹ̀ ni ẹni tó bí ọ ti rọbí.   Gbé mi lé ọkàn rẹ bí èdìdì,Bí èdìdì ní apá rẹ,Torí ìfẹ́ lágbára bí ikú,+Ìṣòtítọ́ sì lágbára bí Isà Òkú.* Ọwọ́ iná rẹ̀ dà bí iná tó ń jó, ọwọ́ iná Jáà.*+   Omi tó ń ru gùdù ò lè paná ìfẹ́,+Odò kò sì lè gbé e lọ.+ Tí ọkùnrin kan bá fi gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀ fúnni torí ìfẹ́,Wọ́n á fojú àbùkù wò ó.”*   “A ní àbúrò obìnrin kan+Tí kò tíì ní ọmú. Kí la máa ṣe fún àbúrò waNí ọjọ́ tí wọ́n bá wá tọrọ rẹ̀?”   “Tó bá jẹ́ ògiri,A ó mọ odi fàdákà sórí rẹ̀,Àmọ́ tó bá jẹ́ ilẹ̀kùn,A ó fi pákó kédárì dí i pa.” 10  “Ògiri ni mí,Ọmú mi sì dà bí ilé gogoro. Lójú rẹ̀, mo ti wá dà bíẸni tó ní àlàáfíà. 11  Sólómọ́nì ní ọgbà àjàrà+ kan ní Baali-hámọ́nì. Ó gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn tí á máa tọ́jú rẹ̀. Kálukú wọn á máa mú ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà wá fún èso rẹ̀. 12  Mo ní ọgbà àjàrà tèmi. Sólómọ́nì, ìwọ lo ni ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà náà,Igba (200) sì ni ti àwọn tó ń bójú tó èso rẹ̀.” 13  “Ìwọ tí ò ń gbé inú àwọn ọgbà,+Àwọn ọ̀rẹ́ fẹ́ gbọ́ ohùn rẹ. Jẹ́ kí n gbọ́ ọ.”+ 14  “Tètè, olólùfẹ́ mi,Kí o sì yára bí egbin+Tàbí akọ ọmọ àgbọ̀nrínLórí àwọn òkè tó ní ewé tó ń ta sánsán.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí kó jẹ́, “wo ọkùnrin náà.”