Àkọsílẹ̀ Mátíù 26:1-75

  • Àwọn àlùfáà gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù (1-5)

  • Ó da òróró onílọ́fínńdà sára Jésù (6-13)

  • Ìrékọjá tó gbẹ̀yìn àti ẹni tó máa da Jésù (14-25)

  • Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀ (26-30)

  • Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun (31-35)

  • Jésù gbàdúrà ní Gẹ́tísémánì (36-46)

  • Wọ́n mú Jésù (47-56)

  • Wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (57-68)

  • Pétérù sẹ́ Jésù (69-75)

26  Nígbà tí Jésù sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tán, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé:  “Ẹ mọ̀ pé ní ọjọ́ méjì òní, Ìrékọjá máa wáyé,+ a sì máa fa Ọmọ èèyàn léni lọ́wọ́, kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.”+  Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà wá kóra jọ sínú àgbàlá àlùfáà àgbà, tí wọ́n ń pè ní Káyáfà,+  wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀+ kí wọ́n lè fi ọgbọ́n àrékérekè** Jésù, kí wọ́n sì pa á.  Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Kì í ṣe nígbà àjọyọ̀, kí ariwo má bàa sọ láàárín àwọn èèyàn.”  Nígbà tí Jésù wà ní Bẹ́tánì, ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀,+  obìnrin kan tó ní orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà olówó iyebíye sí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da òróró náà sí orí rẹ̀ nígbà tó ń jẹun.*  Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, inú bí wọn gan-an, wọ́n sì sọ pé: “Kí ló dé tó ń fi nǹkan ṣòfò báyìí?  Ṣe là bá tà á ní owó gọbọi, ká sì fún àwọn aláìní.” 10  Jésù mọ ohun tí wọ́n ń sọ, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fẹ́ máa yọ obìnrin yìí lẹ́nu? Ohun tó dáa gan-an ló ṣe sí mi. 11  Torí ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín,+ àmọ́ ìgbà gbogbo kọ́ ni màá wà láàárín yín.+ 12  Nígbà tí obìnrin yìí da òróró onílọ́fínńdà yìí sí ara mi, ó ṣe é kó lè múra mi sílẹ̀ fún ìsìnkú.+ 13  Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ibikíbi tí a bá ti ń wàásù ìhìn rere yìí ní gbogbo ayé, wọ́n á máa sọ ohun tí obìnrin yìí ṣe láti fi rántí rẹ̀.”+ 14  Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Méjìlá náà, tí wọ́n ń pè ní Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà,+ 15  ó sì sọ pé: “Kí lẹ máa fún mi, kí n lè fà á lé yín lọ́wọ́?”+ Wọ́n bá a ṣe àdéhùn ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà.+ 16  Torí náà, látìgbà yẹn lọ, ó ń wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́. 17  Ní ọjọ́ kìíní Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n bi í pé: “Ibo lo fẹ́ ká ṣètò fún ọ láti jẹ Ìrékọjá?”+ 18  Ó dáhùn pé: “Ẹ lọ sínú ìlú, kí ẹ lọ bá Lágbájá, kí ẹ sì sọ fún un pé, ‘Olùkọ́ sọ pé: “Àkókò tí a yàn fún mi ti sún mọ́lé; èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi máa ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá ní ilé rẹ.”’” 19  Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe ohun tí Jésù sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá. 20  Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́,+ òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá (12) jókòó* sídìí tábìlì.+ 21  Nígbà tí wọ́n ń jẹun, ó sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ọ̀kan nínú yín máa dà mí.”+ 22  Ọ̀rọ̀ yìí bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ gan-an, gbogbo wọn wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un lọ́kọ̀ọ̀kan pé: “Olúwa, èmi kọ́ o, àbí èmi ni?” 23  Ó fún wọn lésì pé: “Ẹni tí a jọ ń ki ọwọ́ bọ inú abọ́ ni ẹni tó máa dà mí.+ 24  Lóòótọ́, Ọmọ èèyàn ń lọ, bí a ṣe kọ ọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ ọkùnrin tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi Ọmọ èèyàn léni lọ́wọ́+ gbé!+ Ì bá sàn fún ọkùnrin náà ká ní wọn ò bí i.”+ 25  Júdásì, ẹni tó máa tó dà á, sọ pé: “Èmi kọ́ o, àbí èmi ni, Rábì?” Jésù sọ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́.” 26  Bí wọ́n ṣe ń jẹun, Jésù mú búrẹ́dì, lẹ́yìn tó súre, ó bù ú,+ ó sì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sọ pé: “Ẹ gbà, kí ẹ jẹ ẹ́. Èyí túmọ̀ sí ara mi.”+ 27  Ó mú ife kan, ó dúpẹ́, ó sì gbé e fún wọn, ó ní: “Gbogbo yín, ẹ mu nínú rẹ̀,+ 28  torí èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀+ májẹ̀mú’ mi,+ tí a máa dà jáde nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn,+ kí wọ́n lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.+ 29  Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ó dájú pé mi ò tún ní mu èyíkéyìí nínú àwọn ohun tí wọ́n fi àjàrà ṣe yìí, títí di ọjọ́ yẹn tí màá mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín nínú Ìjọba Baba mi.”+ 30  Níkẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n kọrin ìyìn,* wọ́n lọ sí Òkè Ólífì.+ 31  Jésù sọ fún wọn pé: “Gbogbo yín lẹ máa kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi lóru òní, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Màá kọ lu olùṣọ́ àgùntàn, àwọn àgùntàn inú agbo sì máa tú ká.’+ 32  Àmọ́ lẹ́yìn tí mo bá jíǹde, màá lọ sí Gálílì ṣáájú yín.”+ 33  Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn pé: “Tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó dájú pé èmi ò ní kọsẹ̀ láé!”+ 34  Jésù sọ fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, lóru òní, kí àkùkọ tó kọ, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ 35  Pétérù sọ fún un pé: “Àní tó bá tiẹ̀ gba pé kí n kú pẹ̀lú rẹ pàápàá, ó dájú pé mi ò ní sẹ́ ọ.”+ Gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù sọ ohun kan náà. 36  Lẹ́yìn náà, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ wá sí ibi tí wọ́n ń pè ní Gẹ́tísémánì,+ ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ jókòó síbí, mo fẹ́ lọ sí ọ̀hún yẹn lọ gbàdúrà.”+ 37  Ó mú Pétérù àti àwọn ọmọ Sébédè méjèèjì dání, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ní ẹ̀dùn ọkàn, ìdààmú sì bá a gan-an.+ 38  Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi* gan-an, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”+ 39  Ó lọ síwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé:+ “Baba mi, tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife+ yìí ré mi kọjá. Síbẹ̀, kì í ṣe bí mo ṣe fẹ́, àmọ́ bí ìwọ ṣe fẹ́.”+ 40  Ó pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, ó wá sọ fún Pétérù pé: “Ṣé ẹ ò wá lè ṣọ́nà pẹ̀lú mi fún wákàtí kan péré ni?+ 41  Ẹ máa ṣọ́nà,+ kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo,+ kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.+ Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́,* àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.”+ 42  Ó tún lọ gbàdúrà lẹ́ẹ̀kejì, ó sọ pé: “Baba mi, tí kò bá ṣeé ṣe kí èyí kọjá lọ àfi tí mo bá mu ún, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.”+ 43  Ó tún pa dà wá, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, torí oorun ń kùn wọ́n gan-an. 44  Ó wá fi wọ́n sílẹ̀, ó tún lọ gbàdúrà lẹ́ẹ̀kẹta, ó sì sọ ohun kan náà lẹ́ẹ̀kan sí i. 45  Nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sọ fún wọn pé: “Ní irú àkókò yìí, ẹ̀ ń sùn, ẹ sì ń sinmi! Ẹ wò ó! Wákàtí náà ti dé tán tí wọ́n máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 46  Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ. Ẹ wò ó! Ẹni tó máa dà mí ti dé tán.” 47  Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! Júdásì, ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà dé pẹ̀lú èrò rẹpẹtẹ tí wọ́n kó idà àti kùmọ̀ dání, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà ló rán wọn wá.+ 48  Ẹni tó fẹ́ dà á ti fún wọn ní àmì kan, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; kí ẹ mú un.” 49  Ó wá lọ tààràtà sọ́dọ̀ Jésù, ó sọ pé: “Mo kí ọ o, Rábì!” ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 50  Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Ọ̀gbẹ́ni, kí lo wá ṣe níbí?”+ Ni wọ́n bá wá síwájú, wọ́n gbá Jésù mú, wọ́n sì mú un sọ́dọ̀. 51  Àmọ́ wò ó! ọ̀kan lára àwọn tó wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ dà nù.+ 52  Jésù wá sọ fún un pé: “Dá idà rẹ pa dà sí àyè rẹ̀,+ torí gbogbo àwọn tó bá yọ idà máa ṣègbé nípasẹ̀ idà.+ 53  Àbí o rò pé mi ò lè bẹ Baba mi pé kó fún mi ní àwọn áńgẹ́lì tó ju líjíónì méjìlá (12) lọ ní ìṣẹ́jú yìí?+ 54  Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ báyìí ṣe máa ṣẹ?” 55  Ní wákàtí yẹn, Jésù sọ fún àwọn èrò náà pé: “Ṣé èmi lẹ wá fi idà àti kùmọ̀ mú bí olè? Ojoojúmọ́ ni mò ń jókòó nínú tẹ́ńpìlì,+ tí mò ń kọ́ni, àmọ́ ẹ ò mú mi.+ 56  Ṣùgbọ́n gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun* tí àwọn wòlíì kọ sílẹ̀ lè ṣẹ.” Gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá fi í sílẹ̀,+ wọ́n sì sá lọ.+ 57  Àwọn tó mú Jésù wá mú un lọ sọ́dọ̀ Káyáfà+ tó jẹ́ àlùfáà àgbà, níbi tí àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà kóra jọ sí.+ 58  Àmọ́ Pétérù ń tẹ̀ lé e ní òkèèrè, títí dé àgbàlá àlùfáà àgbà, lẹ́yìn tó sì wọlé, ó jókòó sọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ilé náà kó lè mọ ibi tọ́rọ̀ yẹn máa já sí.+ 59  Àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sàhẹ́ndìrìn ń wá ẹ̀rí èké tí wọ́n máa fi mú Jésù kí wọ́n lè pa á.+ 60  Àmọ́ wọn ò rí ìkankan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí èké ló jáde wá.+ Nígbà tó yá, àwọn méjì wá síwájú, 61  wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó tẹ́ńpìlì Ọlọ́run palẹ̀, kí n sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ.’”+ 62  Ni àlùfáà àgbà bá dìde, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé o ò ní fèsì rárá ni? Ẹ̀rí tí àwọn èèyàn yìí jẹ́ lòdì sí ọ yìí ńkọ́?”+ 63  Àmọ́ Jésù ò sọ̀rọ̀.+ Àlùfáà àgbà wá sọ fún un pé: “Mo fi ọ́ sábẹ́ ìbúra níwájú Ọlọ́run alààyè pé kí o sọ fún wa bóyá ìwọ ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run!”+ 64  Jésù sọ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́. Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Láti ìsinsìnyí lọ, ẹ máa rí Ọmọ èèyàn+ tó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára,+ tó sì ń bọ̀ lórí àwọn àwọsánmà* ojú ọ̀run.”+ 65  Àlùfáà àgbà fa aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ ya, ó ní: “Ó ti sọ̀rọ̀ òdì! Kí la tún fẹ́ fi àwọn ẹlẹ́rìí ṣe? Ẹ wò ó! Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì náà. 66  Kí lèrò yín?” Wọ́n fèsì pé: “Ikú ló tọ́ sí i.”+ 67  Wọ́n wá tutọ́ sí i lójú,+ wọ́n sì gbá a ní ẹ̀ṣẹ́.+ Àwọn míì gbá a lójú,+ 68  wọ́n ní: “Sọ tẹ́lẹ̀ fún wa, ìwọ Kristi. Ta ló gbá ọ?” 69  Pétérù jókòó síta nínú àgbàlá, ìránṣẹ́bìnrin kan sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ìwọ náà wà pẹ̀lú Jésù ará Gálílì!”+ 70  Àmọ́ ó sẹ́ níwájú gbogbo wọn, ó ní: “Mi ò mọ ohun tí ò ń sọ.” 71  Nígbà tó jáde lọ sí ilé ẹnu ọ̀nà, ọmọbìnrin míì tún kíyè sí i, ó sì sọ fún àwọn tó wà níbẹ̀ pé: “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ará Násárẹ́tì.”+ 72  Ló bá tún sẹ́, ó sì búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin náà!” 73  Lẹ́yìn tó ṣe díẹ̀, àwọn tó dúró sí àyíká wá, wọ́n sì sọ fún Pétérù pé: “Ó dájú pé ìwọ náà wà lára wọn, torí ká sòótọ́, èdè ẹnu rẹ* tú ọ fó.” 74  Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gégùn-ún, ó sì ń búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin náà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ kọ. 75  Pétérù wá rántí ohun tí Jésù sọ, pé: “Kí àkùkọ tó kọ, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ Ló bá bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ẹ̀tàn.”
Tàbí “fàṣẹ ọba mú.”
Tàbí “ìgò.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “kọ orin ìjọsìn; kọ sáàmù.”
Tàbí “bá ọkàn mi.”
Tàbí “ó wu ẹ̀mí.”
Tàbí “ìwé mímọ́.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “bí o ṣe ń sọ̀rọ̀.”