Orin Sólómọ́nì 2:1-17

  • Ọ̀dọ́bìnrin (1)

    • “Mo dà bí òdòdó sáfúrónì”

  • Olùṣọ́ àgùntàn (2)

    • ‘Olólùfẹ́ mi dà bí òdòdó lílì’

  • Ọ̀dọ́bìnrin (3-14)

    • ‘Ẹ má ṣe ru ìfẹ́ sókè títí á fi wá fúnra rẹ̀’ (7)

    • Ohun tí olùṣọ́ àgùntàn sọ (10b-14)

      • “Arẹwà mi, tẹ̀ lé mi ká lọ” (10b, 13)

  • Àwọn arákùnrin ọ̀dọ́bìnrin náà (15)

    • “Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀”

  • Ọ̀dọ́bìnrin (16, 17)

    • “Èmi ni mo ni olólùfẹ́ mi, òun ló sì ni mí” (16)

2  “Mo dà bí òdòdó sáfúrónì tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ etíkun,Bí òdòdó lílì tó wà ní àfonífojì.”+  2  “Bí òdòdó lílì láàárín àwọn ẹ̀gún,Ni olólùfẹ́ mi rí láàárín àwọn ọmọbìnrin.”  3  “Bí igi ápù láàárín àwọn igi inú igbó,Ni olólùfẹ́ mi rí láàárín àwọn ọmọkùnrin. Ó wù mí tọkàntọkàn pé kí n jókòó sábẹ́ ibòji rẹ̀,Èso rẹ̀ sì ń dùn mọ́ mi lẹ́nu.  4  Ó mú mi wá sínú ilé àsè,* Ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ bò mí.  5  Ẹ fún mi ní ìṣù àjàrà gbígbẹ+ kí ara lè tù mí;Ẹ fún mi ní èso ápù kí n lè lókun,Torí òjòjò ìfẹ́ ń ṣe mí.  6  Ọwọ́ òsì rẹ̀ wà lábẹ́ orí mi,Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbá mi mọ́ra.+  7  Mo mú kí ẹ búra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù,Kí ẹ fi àwọn egbin+ àti àwọn abo àgbọ̀nrín inú pápá búra: Pé kí ẹ má ṣe ta ìfẹ́ jí, ẹ má sì ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí á fi wá fúnra rẹ̀.+  8  Mo gbọ́ ìró olólùfẹ́ mi! Wò ó! Òun ló ń bọ̀ yìí,Ó ń gun àwọn òkè ńlá, ó ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún lórí àwọn òkè kéékèèké.  9  Olólùfẹ́ mi dà bí egbin, bí akọ ọmọ àgbọ̀nrín.+ Òun nìyẹn, ó dúró sí ẹ̀yìn ògiri wa,Ó ń yọjú lójú fèrèsé,* Ó ń yọjú níbi àwọn fèrèsé tó ní asẹ́ onígi. 10  Olólùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé: ‘Dìde, ìfẹ́ mi,Arẹwà mi, tẹ̀ lé mi ká lọ. 11  Wò ó! Ìgbà òtútù* ti kọjá. Òjò ò rọ̀ mọ́, ó ti dáwọ́ dúró. 12  Òdòdó ti yọ ní ilẹ̀ wa,+Àkókò ti tó láti rẹ́wọ́ ọ̀gbìn,+A sì gbọ́ orin tí ẹyẹ oriri ń kọ ní ilẹ̀ wa.+ 13  Àwọn èso tó kọ́kọ́ yọ lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ ti pọ́n;+ Àwọn àjàrà ti yọ òdòdó, wọ́n sì ń ta sánsán. Dìde, olólùfẹ́ mi, máa bọ̀. Arẹwà mi, tẹ̀ lé mi ká lọ. 14  Ìwọ àdàbà mi, tí o wà nínú ihò àpáta,+Níbi kọ́lọ́fín òkè tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́,Jẹ́ kí n rí ọ, kí n sì gbọ́ ohùn rẹ,+Torí ohùn rẹ dùn, ìrísí rẹ sì dára gan-an.’”+ 15  “Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tó ń ba àwọn ọgbà àjàrà jẹ́,Torí àwọn ọgbà àjàrà wa ti yọ òdòdó.” 16  “Èmi ni mo ni olólùfẹ́ mi, òun ló sì ni mí.+ Ó ń tọ́jú àwọn àgùntàn+ láàárín àwọn òdòdó lílì.+ 17  Títí afẹ́fẹ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́,* tí òjìji kò sì ní sí mọ́,Tètè pa dà, ìwọ olólùfẹ́ mi,Bí egbin+ tàbí akọ ọmọ àgbọ̀nrín+ lórí àwọn òkè tó yà wá sọ́tọ̀.*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Ní Héb., “ilé wáìnì.”
^ Tàbí “wíńdò.”
^ Tàbí “Ìgbà òjò.”
^ Ní Héb., “Títí ọjọ́ á fi bẹ̀rẹ̀ sí í mí.”
^ Tàbí kó jẹ́, “àwọn òkè tó ní àlàfo.” Tàbí “àwọn òkè Bétérì.”