Ẹ́kísódù 15:1-27

  • Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọrin ìṣẹ́gun (1-19)

  • Míríámù fi orin dáhùn pa dà (20, 21)

  • Omi tó korò wá dùn (22-27)

15  Nígbà yẹn, Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orin yìí sí Jèhófà:+ “Jẹ́ kí n kọrin sí Jèhófà, torí ó ti di ẹni àgbéga.+ Ó taari ẹṣin àti ẹni tó gùn ún sínú òkun.+   Jáà* ni okun àti agbára mi, torí ó ti wá gbà mí là.+ Ọlọ́run mi nìyí, màá yìn ín;+ Ọlọ́run bàbá mi,+ màá gbé e ga.+   Jagunjagun tó lágbára ni Jèhófà.+ Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.+   Ó ti ju àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sínú òkun,+ Àwọn tó dára jù nínú àwọn jagunjagun rẹ̀ sì ti rì sínú Òkun Pupa.+   Alagbalúgbú omi bò wọ́n; wọ́n rì sí ìsàlẹ̀ ibú omi bí òkúta.+   Ọwọ́ ọ̀tún rẹ mà lágbára o, Jèhófà;+ Jèhófà, ọwọ́ ọ̀tún rẹ lè fọ́ ọ̀tá túútúú.   Nínú ọlá ńlá rẹ, o lè bi àwọn tó bá dìde sí ọ ṣubú;+ O mú kí ìbínú rẹ tó ń jó fòfò jẹ wọ́n run bí àgékù pòròpórò.   Èémí tó ti ihò imú rẹ jáde mú kí omi wọ́ jọ; Omi náà dúró, kò pa dà; Alagbalúgbú omi dì láàárín òkun.   Ọ̀tá sọ pé: ‘Màá lépa wọn! Màá lé wọn bá! Màá pín ẹrù ogun wọn títí yóò fi tẹ́ mi* lọ́rùn! Màá fa idà mi yọ! Ọwọ́ mi yóò ṣẹ́gun wọn!’+  10  O fẹ́ èémí rẹ jáde, òkun sì bò wọ́n;+ Wọ́n rì sínú alagbalúgbú omi bí òjé.  11  Jèhófà, ta ló dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run?+ Ta ló dà bí rẹ, ìwọ tí o fi hàn pé ẹni mímọ́ jù lọ ni ọ́?+ Ẹni tó yẹ ká máa bẹ̀rù, ká máa fi orin yìn, Ẹni tó ń ṣe ohun ìyanu.+  12  O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ sì gbé wọn mì.+  13  O fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ṣamọ̀nà àwọn èèyàn tí o rà pa dà;+ Ìwọ yóò fi agbára rẹ darí wọn lọ sí ibùgbé rẹ mímọ́.  14  Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ gbọ́,+ jìnnìjìnnì á bò wọ́n; Àwọn tó ń gbé Filísíà máa jẹ̀rora.*  15  Ní àkókò yẹn, ẹ̀rù yóò ba àwọn séríkí* Édómù, Àwọn alágbára tó ń ṣàkóso Móábù* yóò gbọ̀n rìrì.+ Ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ní Kénáánì yóò domi.+  16  Ìbẹ̀rù àti jìnnìjìnnì yóò bò wọ́n.+ Ọwọ́ ńlá rẹ yóò mú kí wọ́n dúró sójú kan bí òkúta Títí àwọn èèyàn rẹ yóò fi kọjá, Jèhófà, Títí àwọn èèyàn tí o mú jáde+ yóò fi kọjá.+  17  Ìwọ yóò mú wọn wá, ìwọ yóò sì gbìn wọ́n sí òkè ogún rẹ,+ Ibi tó fìdí múlẹ̀ tí o ti pèsè kí ìwọ fúnra rẹ lè máa gbé, Jèhófà, Ibi mímọ́ tí o fi ọwọ́ rẹ ṣe, Jèhófà.  18  Jèhófà yóò máa jọba títí láé àti láéláé.+  19  Nígbà tí àwọn ẹṣin Fáráò àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀ wọnú òkun,+ Jèhófà mú kí omi òkun pa dà, ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,+ Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba orí ilẹ̀ kọjá láàárín òkun.”+ 20  Míríámù wòlíì obìnrin, ẹ̀gbọ́n Áárónì wá mú ìlù tanboríìnì, gbogbo obìnrin sì ń jó tẹ̀ lé e pẹ̀lú ìlù tanboríìnì. 21  Míríámù fi orin dá àwọn ọkùnrin lóhùn pé: “Ẹ kọrin sí Jèhófà, torí ó ti di ẹni àgbéga.+ Ó taari ẹṣin àti ẹni tó gùn ún sínú òkun.”+ 22  Lẹ́yìn náà, Mósè darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Òkun Pupa, wọ́n sì lọ sí aginjù Ṣúrì. Wọ́n rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù, àmọ́ wọn ò rí omi. 23  Wọ́n dé Márà,*+ àmọ́ wọn ò lè mu omi tó wà ní Márà torí ó korò. Ìdí nìyẹn tó fi pè é ní Márà. 24  Àwọn èèyàn náà wá ń kùn sí Mósè+ pé: “Kí la máa mu báyìí?” 25  Ó bá ké pe Jèhófà,+ Jèhófà sì darí rẹ̀ síbi igi kan. Nígbà tó jù ú sínú omi, omi náà wá dùn. Ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé òfin àti ìlànà ìdájọ́ kalẹ̀ fún wọn, Ó sì dán wọn wò níbẹ̀.+ 26  Ó sọ pé: “Tí ẹ bá ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín délẹ̀délẹ̀, tí ẹ ṣe ohun tó tọ́ ní ojú rẹ̀, tí ẹ pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀ lé gbogbo ìlànà rẹ̀,+ mi ò ní mú kí ìkankan ṣe yín nínú àwọn àrùn tí mo mú kó ṣe àwọn ará Íjíbítì,+ torí èmi Jèhófà ló ń mú yín lára dá.”+ 27  Lẹ́yìn náà, wọ́n dé Élímù, níbi tí ìsun omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) igi ọ̀pẹ wà. Wọ́n sì pàgọ́ síbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “ọkàn mi.”
Ní Héb., “jẹ̀rora ìbímọ.”
Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.
Tàbí “Àwọn olórí tó ń ṣi agbára lò ní Móábù.”
Ó túmọ̀ sí “Ìkorò.”