Jẹ́nẹ́sísì 18:1-33

  • Áńgẹ́lì mẹ́ta wá sọ́dọ̀ Ábúráhámù (1-8)

  • Ó ṣèlérí pé Sérà yóò bímọ; Sérà rẹ́rìn-ín (9-15)

  • Ábúráhámù ń bẹ̀bẹ̀ torí Sódómù (16-33)

18  Lẹ́yìn náà, Jèhófà+ fara hàn án láàárín àwọn igi ńlá tó wà ní Mámúrè+ nígbà tó jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ní àkókò tí ojú ọjọ́ gbóná gan-an.  Ó wòkè, ó sì rí ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n dúró ní ọ̀ọ́kán.+ Nígbà tó rí wọn, ó sáré láti ẹnu ọ̀nà àgọ́ lọ pàdé wọn, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀.  Ó wá sọ pé: “Jèhófà, tó bá jẹ́ pé mo ti rí ojúure rẹ, jọ̀ọ́, má kọjá ìránṣẹ́ rẹ.  Jọ̀ọ́, jẹ́ ká bu omi díẹ̀ wá, ká lè fọ+ ẹsẹ̀ yín; kí ẹ wá jókòó lábẹ́ igi.  Ní báyìí tí ẹ ti wá sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ yín, ẹ jẹ́ kí n fún yín ní búrẹ́dì, kí ara lè tù yín.* Lẹ́yìn ìyẹn, ẹ lè máa lọ.” Torí náà, wọ́n sọ pé: “Ó dáa. O lè ṣe ohun tí o sọ.”  Ábúráhámù wá sáré lọ bá Sérà nínú àgọ́, ó sì sọ pé: “Yára! Mú òṣùwọ̀n* ìyẹ̀fun tó kúnná mẹ́ta. Pò ó, kí o sì fi ṣe búrẹ́dì.”  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù sáré lọ síbi tí agbo ẹran wà, ó sì mú akọ ọmọ màlúù kan tó dára, tí ara rẹ̀ sì rọ̀. Ó fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì yára lọ sè é.  Ó mú bọ́tà àti wàrà àti akọ ọmọ màlúù tó ti sè, ó sì gbé oúnjẹ náà fún wọn. Ó wá dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn lábẹ́ igi bí wọ́n ṣe ń jẹun.+  Wọ́n bi í pé: “Ibo ni Sérà+ ìyàwó rẹ wà?” Ó fèsì pé: “Ó wà nínú àgọ́ níbí.” 10  Torí náà, ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “Màá pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní àkókò yìí lọ́dún tó ń bọ̀. Wò ó! Sérà ìyàwó rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin+ kan.” Àmọ́ Sérà wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ tó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà, ó ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. 11  Ábúráhámù àti Sérà ti darúgbó, wọ́n ti lọ́jọ́ lórí.+ Sérà ti dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ.*+ 12  Sérà wá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín sínú, ó ń sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti gbó tán, tí olúwa mi sì ti darúgbó, ṣé mo ṣì lè nírú ayọ̀ yẹn?”+ 13  Jèhófà wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Kí ló dé tí Sérà ń rẹ́rìn-ín, tó sì sọ pé, ‘Èmi tí mo ti darúgbó yìí, ṣé mo ṣì lè bímọ?’ 14  Ǹjẹ́ a rí ohun tó pọ̀ jù fún Jèhófà+ láti ṣe? Màá pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní àkókò yìí lọ́dún tó ń bọ̀, Sérà yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” 15  Àmọ́ Sérà sẹ́ nítorí ẹ̀rù bà á, ó sọ pé, “Mi ò rẹ́rìn-ín o!” Ó wá fèsì pé: “Àní o rẹ́rìn-ín!” 16  Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti kúrò níbẹ̀, tí wọ́n sì wo apá ibi tí Sódómù+ wà, Ábúráhámù ń bá wọn lọ kó lè sìn wọ́n sọ́nà. 17  Jèhófà sọ pé: “Ṣé màá fi ohun tí mo fẹ́ ṣe+ pa mọ́ fún Ábúráhámù ni? 18  Ó dájú pé Ábúráhámù máa di orílẹ̀-èdè ńlá tó máa lágbára, gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóò rí ìbùkún gbà* nípasẹ̀ rẹ̀.+ 19  Torí mo ti wá mọ̀ ọ́n, kó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ àti agbo ilé rẹ̀ pé kí wọ́n máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà nípa ṣíṣe ohun tó dáa, tó sì tọ́,+ kí Jèhófà bàa lè mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ.” 20  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ pé: “Igbe àwọn tó ń ráhùn nípa Sódómù àti Gòmórà ti pọ̀ gidigidi,+ ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì wúwo gan-an.+ 21  Èmi yóò lọ wò ó bóyá ohun tí mò ń gbọ́ nípa wọn náà ni wọ́n ń ṣe. Tí kò bá sì rí bẹ́ẹ̀, màá lè mọ̀.”+ 22  Àwọn ọkùnrin náà kúrò níbẹ̀, wọ́n sì forí lé ọ̀nà Sódómù, àmọ́ Jèhófà+ wà pẹ̀lú Ábúráhámù. 23  Ábúráhámù wá sún mọ́ ọn, ó sì sọ pé: “Ṣé o máa pa olódodo run pẹ̀lú ẹni burúkú+ ni? 24  Ká sọ pé àádọ́ta (50) olódodo wà nínú ìlú náà. Ṣé o ṣì máa pa wọ́n run? Ṣé o ò ní dárí ji ìlú náà nítorí àádọ́ta (50) olódodo tó wà níbẹ̀? 25  Ó dájú pé o ò ní hùwà báyìí, pé kí o pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú, tó fi jẹ́ pé ohun kan náà+ ló máa ṣẹlẹ̀ sí olódodo àti ẹni burúkú! Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.+ Ṣé Onídàájọ́ gbogbo ayé kò ní ṣe ohun tó tọ́ ni?”+ 26  Jèhófà wá sọ pé: “Tí mo bá rí àádọ́ta (50) olódodo ní ìlú Sódómù, màá dárí ji gbogbo ìlú náà nítorí wọn.” 27  Àmọ́ Ábúráhámù tún sọ pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, èmi tí mo jẹ́ erùpẹ̀ àti eérú kò lẹ́tọ̀ọ́ láti bá ọ sọ̀rọ̀. 28  Ká sọ pé àádọ́ta (50) olódodo náà dín márùn-ún, ṣé wàá pa gbogbo ìlú náà run nítorí àwọn márùn-ún náà?” Ó fèsì pé: “Mi ò ní pa á run tí mo bá rí márùndínláàádọ́ta (45)+ níbẹ̀.” 29  Àmọ́, ó tún sọ fún un pé: “Ká sọ pé ogójì (40) lo rí níbẹ̀.” Ó dáhùn pé: “Mi ò ní pa á run nítorí ogójì (40).” 30  Àmọ́ ó tún sọ pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, má bínú+ sí mi, jẹ́ kí n máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ: Ká sọ pé ọgbọ̀n (30) péré lo rí níbẹ̀.” Ó fèsì pé: “Mi ò ní pa á run tí mo bá rí ọgbọ̀n (30) níbẹ̀.” 31  Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, má bínú pé mo gbójúgbóyà láti bá ọ sọ̀rọ̀: Ká sọ pé ogún (20) péré lo rí níbẹ̀.” Ó fèsì pé: “Mi ò ní pa á run nítorí ogún (20).” 32  Níkẹyìn, ó sọ pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, má bínú sí mi, jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i: Ká sọ pé olódodo mẹ́wàá péré lo rí níbẹ̀.” Ó fèsì pé: “Mi ò ní pa á run nítorí mẹ́wàá.” 33  Nígbà tí Jèhófà bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ tán, ó kúrò níbẹ̀,+ Ábúráhámù sì pa dà sí ibi tó ń gbé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “kí ọkàn yín lè lókun.”
Ní Héb., “òṣùwọ̀n síà.” Síà kan jẹ́ Lítà 7.33. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “Sérà ò ṣe ohun tí obìnrin ń ṣe mọ́.”
Tàbí “gba ìbùkún fún ara wọn.”