Jẹ́nẹ́sísì 37:1-36

  • Àwọn àlá Jósẹ́fù (1-11)

  • Jósẹ́fù àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ òjòwú (12-24)

  • Wọ́n ta Jósẹ́fù sí oko ẹrú (25-36)

37  Jékọ́bù ń gbé ilẹ̀ Kénáánì nìṣó, ibi tí bàbá rẹ̀ gbé bí àjèjì.+  Ìtàn Jékọ́bù nìyí. Nígbà tí Jósẹ́fù+ wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), ọ̀dọ́kùnrin náà pẹ̀lú àwọn ọmọ Bílíhà+ àti àwọn ọmọ Sílípà+ tí wọ́n jẹ́ ìyàwó bàbá rẹ̀ jọ ń bójú tó agbo ẹran.+ Jósẹ́fù wá ròyìn ohun búburú tí wọ́n ṣe fún bàbá wọn.  Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jósẹ́fù ju gbogbo àwọn ọmọ+ rẹ̀ yòókù lọ torí pé ìgbà tó darúgbó ló bí i, ó sì ṣe aṣọ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀* fún un.  Nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rí i pé bàbá àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ju gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra rẹ̀, wọn kì í sì í fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀.  Nígbà tó yá, Jósẹ́fù lá àlá kan, ó sì rọ́ ọ fún àwọn arákùnrin+ rẹ̀, èyí mú kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀.  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fetí sí àlá tí mo lá.  Ó ṣẹlẹ̀ pé à ń di ìtí ọkà ní àárín oko, ni ìtí tèmi bá dìde, ó nàró, àwọn ìtí tiyín sì tò yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì tẹrí ba fún un.”+  Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé o wá fẹ́ jọba lé wa lórí ni, kí o wá máa pàṣẹ fún wa?”+ Ìyẹn wá mú kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀, torí àwọn àlá tó lá àti ohun tó sọ.  Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún lá àlá míì, ó sì rọ́ ọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, ó ní: “Mo tún lá àlá míì. Lọ́tẹ̀ yìí, oòrùn àti òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá (11) ń tẹrí ba fún mi.”+ 10  Ó rọ́ ọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, bàbá rẹ̀ sì bá a wí, ó ní: “Kí ni ìtúmọ̀ àlá tí o lá yìí? Ṣé èmi àti ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ yóò wá máa tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún ọ ni?” 11  Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú rẹ̀,+ àmọ́ bàbá rẹ̀ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn. 12  Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kó agbo ẹran bàbá wọn lọ jẹko lẹ́bàá Ṣékémù.+ 13  Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Ṣebí tòsí Ṣékémù làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ti ń bójú tó agbo ẹran, àbí? Wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.” Ó fèsì pé: “Ó ti yá!” 14  Ó wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, lọ wò ó bóyá àlàáfíà ni àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ wà. Wo bí agbo ẹran náà ṣe ń ṣe sí, kí o sì pa dà wá jíṣẹ́ fún mi.” Ló bá rán an lọ láti àfonífojì* Hébúrónì,+ ó sì forí lé Ṣékémù. 15  Nígbà tó yá, ọkùnrin kan rí i bó ṣe ń rìn kiri nínú oko. Ọkùnrin náà bi í pé: “Kí lò ń wá?” 16  Ó fèsì pé: “Mò ń wá àwọn ẹ̀gbọ́n mi ni. Ẹ jọ̀ọ́, ǹjẹ́ ẹ mọ ibi tí wọ́n ti ń da agbo ẹran?” 17  Ọkùnrin náà fèsì pé: “Wọ́n ti ṣí kúrò níbí, torí mo gbọ́ tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ ká lọ sí Dótánì.’” Torí náà, Jósẹ́fù wá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní Dótánì. 18  Wọ́n rí Jósẹ́fù tó ń bọ̀ ní ọ̀ọ́kán, àmọ́ kó tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbìmọ̀ pọ̀ kí wọ́n lè pa á. 19  Wọ́n wá ń sọ fún ara wọn pé: “Wò ó! Alálàá+ yẹn ló ń bọ̀ yìí. 20  Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká pa á, ká sì jù ú sínú ọ̀kan nínú àwọn kòtò omi, ká sì sọ pé ẹranko burúkú kan ló pa á jẹ. Ká wá wo bí àwọn àlá rẹ̀ ṣe máa ṣẹ.” 21  Nígbà tí Rúbẹ́nì+ gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ ká pa á.”*+ 22  Rúbẹ́nì sọ fún wọn pé: “Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ẹ jù ú sínú kòtò omi yìí nínú aginjù, àmọ́ ẹ má ṣe é léṣe.”*+ Ó ní in lọ́kàn láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn kó lè dá a pa dà sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. 23  Gbàrà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, wọ́n bọ́ aṣọ rẹ̀, ìyẹn aṣọ àrà ọ̀tọ̀ tó wọ̀,+ 24  wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò omi. Kòtò náà ṣófo nígbà yẹn; kò sí omi nínú rẹ̀. 25  Wọ́n wá jókòó láti jẹun. Nígbà tí wọ́n wòkè, wọ́n rí àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì+ tó ń rìnrìn àjò tí wọ́n ń bọ̀ láti Gílíádì. Àwọn ràkúnmí wọn ru gọ́ọ̀mù lábídánọ́mù, básámù àti èèpo+ igi olóje, wọ́n ń lọ sí Íjíbítì. 26  Ni Júdà bá sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá pa àbúrò wa, tí a sì bo ẹ̀jẹ̀+ rẹ̀ mọ́lẹ̀? 27  Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká tà á  + fún àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, ẹ má sì jẹ́ ká fọwọ́ kàn án. Ó ṣe tán, àbúrò wa ni, ara kan náà ni wá.” Wọ́n sì gbọ́ ohun tí arákùnrin wọn sọ. 28  Nígbà tí àwọn oníṣòwò tí wọ́n jẹ́ ọmọ Mídíánì+ ń kọjá lọ, wọ́n fa Jósẹ́fù jáde látinú kòtò omi náà, wọ́n sì tà á fún àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì ní ogún (20) ẹyọ fàdákà.+ Ni àwọn ọkùnrin yìí bá mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì. 29  Nígbà tí Rúbẹ́nì wá pa dà dé ibi kòtò omi náà, tó sì rí i pé Jósẹ́fù ò sí nínú rẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ ara rẹ̀ ya. 30  Nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ àwọn àbúrò rẹ̀, ó pariwo pé: “Ọmọ náà ti lọ! Kí ni màá ṣe báyìí?” 31  Wọ́n wá mú aṣọ Jósẹ́fù, wọ́n pa òbúkọ kan, wọ́n sì ti aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 32  Lẹ́yìn náà, wọ́n fi aṣọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ náà ránṣẹ́ sí bàbá wọn, wọ́n sì sọ pé: “Ohun tí a rí nìyí. Jọ̀ọ́, yẹ̀ ẹ́ wò bóyá aṣọ ọmọ rẹ ni tàbí òun kọ́.”+ 33  Ó sì yẹ̀ ẹ́ wò, ló bá kígbe pé: “Aṣọ ọmọ mi ni! Ẹranko burúkú ti pa á jẹ! Ó dájú pé ẹranko náà ti fa Jósẹ́fù ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ!” 34  Ni Jékọ́bù bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sán aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ ìbàdí, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. 35  Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń gbìyànjú láti tù ú nínú, àmọ́ kò gbà, ó ń sọ pé: “Màá ṣọ̀fọ̀ ọmọ mi wọnú Isà Òkú!”*+ Bàbá rẹ̀ sì ń sunkún torí rẹ̀. 36  Àwọn ọmọ Mídíánì ta Jósẹ́fù fún Pọ́tífárì, òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò+ àti olórí ẹ̀ṣọ́,+ ní Íjíbítì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “aṣọ gígùn kan tó rẹwà.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “pa ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “ẹ má fọwọ́ kàn án.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.