Rúùtù 2:1-23

  • Rúùtù pèéṣẹ́ ní oko Bóásì (1-3)

  • Rúùtù àti Bóásì pàdé (4-16)

  • Rúùtù sọ fún Náómì bí Bóásì ṣe ṣojúure sí òun (17-23)

2  Mọ̀lẹ́bí ọkọ Náómì kan wà tó ní ọrọ̀ gan-an, Bóásì+ ni orúkọ rẹ̀, ìdílé Élímélékì ló sì ti wá.  Rúùtù ará Móábù sọ fún Náómì pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí oko, kí n lè pèéṣẹ́*+ lára ṣírí ọkà lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni tó bá ṣojúure sí mi.” Torí náà, Náómì sọ fún un pé: “Lọ, ọmọ mi.”  Lẹ́yìn náà, ó lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pèéṣẹ́ lẹ́yìn àwọn olùkórè. Láìmọ̀, ó dé oko Bóásì+ tó wá láti ìdílé Élímélékì.+  Ìgbà yẹn ni Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sì sọ fún àwọn olùkórè náà pé: “Kí Jèhófà wà pẹ̀lú yín.” Wọ́n sì dáhùn pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ.”  Lẹ́yìn náà, Bóásì bi ọkùnrin tó ń bójú tó àwọn olùkórè pé: “Ilé ibo ni obìnrin yìí ti wá?”  Ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ará Móábù+ ni, òun ló tẹ̀ lé Náómì wá láti ilẹ̀ Móábù.+  Ó bi mí pé, ‘Ẹ jọ̀ọ́, ṣé mo lè pèéṣẹ́+ kí n sì kó àwọn ṣírí* ọkà tí àwọn olùkórè bá fi sílẹ̀?’ Ó sì ti ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀, kódà ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jókòó sí abẹ́ àtíbàbà kó lè sinmi díẹ̀ ni.”  Bóásì wá sọ fún Rúùtù pé: “Gbọ́, ọmọ mi. Má lọ pèéṣẹ́ nínú oko míì, má sì lọ sí ibòmíì, tòsí àwọn òṣìṣẹ́ mi obìnrin+ ni kí o máa wà.  Ibi tí wọ́n ti ń kórè ni kí o máa wò, kí o sì máa tẹ̀ lé wọn. Mo ti sọ fún àwọn ọkùnrin tó ń bá mi ṣiṣẹ́ pé wọn kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn ọ́.* Tí òùngbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ síbi ìṣà omi, kí o sì mu nínú omi tí àwọn òṣìṣẹ́ mi pọn.” 10  Torí náà, Rúùtù kúnlẹ̀, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀, ó wá sọ fún un pé: “Kí nìdí tí o fi ṣojúure sí mi, kí sì nìdí tí o fi kíyè sí mi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjèjì+ ni mí?” 11  Bóásì dá a lóhùn pé: “Gbogbo ohun tí o ṣe fún ìyá ọkọ rẹ lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ ni wọ́n ti ròyìn fún mi àti bí o ṣe fi bàbá àti ìyá rẹ àti ìlú ìbílẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tí ìwọ kò mọ̀ rí.+ 12  Kí Jèhófà san ẹ̀san ohun tí o ṣe fún ọ,+ kí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí o wá ààbò wá sábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀+ sì fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.” 13  Ó fèsì pé: “Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí n rí ojúure rẹ torí o ti tù mí nínú, ọ̀rọ̀ rẹ sì ti fi ìránṣẹ́ rẹ lọ́kàn balẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò sí lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ.” 14  Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Bóásì sọ fún un pé: “Máa bọ̀ níbí, wá jẹ búrẹ́dì, kí o sì ki èyí tí o bá bù bọ inú ọtí kíkan.” Torí náà, ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olùkórè. Lẹ́yìn náà, Bóásì fún un ní ọkà yíyan, ó jẹ, ó yó, oúnjẹ rẹ̀ sì ṣẹ́ kù. 15  Nígbà tó dìde láti pèéṣẹ́,+ Bóásì pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kó ṣà lára àwọn ṣírí* ọkà tó bọ́ sílẹ̀ pàápàá, ẹ má sì ni ín lára.+ 16  Kí ẹ sì rí i pé ẹ yọ ṣírí ọkà díẹ̀ sílẹ̀ fún un lára èyí tí ẹ ti dì, kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ kó lè ṣà wọ́n, ẹ má ṣe bá a sọ ohunkóhun láti dá a dúró.” 17  Torí náà, ó ń pèéṣẹ́ nínú oko títí di ìrọ̀lẹ́.+ Nígbà tó lu ọkà bálì tó kó jọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kún òṣùwọ̀n eéfà* kan. 18  Lẹ́yìn náà, ó gbé e, ó pa dà sínú ìlú, ìyá ọkọ rẹ̀ sì rí ohun tó pèéṣẹ́. Rúùtù tún gbé oúnjẹ tó ṣẹ́ kù+ lẹ́yìn tó jẹun yó lọ́hùn-ún wá sílé, ó sì gbé e fún ìyá ọkọ rẹ̀. 19  Lẹ́yìn náà, ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Ibo lo ti pèéṣẹ́ lónìí? Ibo lo sì ti ṣiṣẹ́? Kí Ọlọ́run bù kún ẹni tó ṣojúure sí ọ.”+ Torí náà, ó sọ ọ̀dọ̀ ẹni tó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀, ó ní: “Bóásì ni orúkọ ẹni tí mo ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí.” 20  Náómì wá sọ fún ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé: “Ìbùkún ni fún un látọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí àwọn alààyè àti òkú.”+ Náómì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mọ̀lẹ́bí wa ni ọkùnrin náà.+ Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùtúnrà* wa.”+ 21  Nígbà náà ni Rúùtù ará Móábù sọ pé: “Ó tún sọ fún mi pé, ‘Ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ mi ni kí o wà títí wọ́n á fi parí gbogbo ìkórè oko mi.’”+ 22  Náómì sọ fún Rúùtù ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé: “Ọmọ mi, ó dáa kí o wà lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ obìnrin ju kí o lọ sí oko ẹlòmíì tí wọ́n á ti máa dà ọ́ láàmú.” 23  Torí náà, ó wà lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ Bóásì, ó ń pèéṣẹ́ títí ìkórè ọkà bálì+ àti àlìkámà* fi parí. Ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀ ló sì ń gbé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.
Tàbí kó jẹ́, “ìtí.”
Tàbí “yọ ọ́ lẹ́nu.”
Tàbí kó jẹ́, “ìtí.”
Nǹkan bíi Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Tàbí “mọ̀lẹ́bí wa tó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní wa pa dà.”
Tàbí “wíìtì.”