Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | RÁHÁBÙ

A “Polongo Rẹ̀ Ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀”

A “Polongo Rẹ̀ Ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀”

BÍ OJÚMỌ́ ṣe mọ́, Ráhábù yọjú lójú fèrèsé rẹ̀, ó rí gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò tó ti mọ́lẹ̀ kedere. Ó tún rí àwọn ọmọ ogun tó kóra jọ síbẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì ni. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í yan yíká ìlú náà, bí wọ́n ti ń ṣe láti ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, bí wọ́n ṣe ń yan, ńṣe ni eruku ń kù làù, ariwo ìwo tàbí fèrè tí wọ́n ń fọn sì ń ròkè lálá.

Ilẹ̀ Jẹ́ríkò ni wọ́n bí Ráhábù sí, ó sì mọ àwọn ilé àti gbogbo òpópónà tó wà ní ilẹ̀ náà títí kan àwọn ilé ìtajà àti ṣọ́ọ̀bù tó wà níbẹ̀. Ó tún mọ àwọn èèyàn ibẹ̀ dáadáa, ó sì mọ̀ pé bí nǹkan ṣe ń lọ yìí, gbogbo aráàlú á ti kú sára nítorí ìbẹ̀rù àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tó ti ń yan yíká ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́. Àmọ́, bí ariwo fèrè ti ń dún káàkiri gbogbo òpópónà àti gbàgede Jẹ́ríkò tó, Ráhábù kò fòyà rárá, kò sì dààmú bíi tàwọn aráàlú rẹ̀.

Ráhábù ń wo àwọn ọmọ ogun náà bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí yan yíká ìlú náà ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ keje. Láàárín àwọn ọmọ ogun yẹn, ó rí àwọn àlùfáà wọn tí wọ́n ń fọn ìwo tàbí fèrè, tí wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí dání. Àpótí yìí jẹ́ àpẹẹrẹ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà pẹ̀lú wọn. Fojú inú wò ó pé Ráhábù di okùn rírẹ̀dòdò kan mú lójú fèrèsé rẹ̀ tó kọjú síta látara odi ńlá Jẹ́ríkò. Okùn tí Ráhábù gbá mú yìí ló ń jẹ́ kó rántí pé òun àti ìdílé òun máa la ìparun ìlú náà já. Ṣé kì í ṣe pé ọ̀dàlẹ̀ ni Ráhábù? Ojú tí Jèhófà fi wò ó kọ́ nìyẹn, obìnrin tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Ráhábù jẹ́ lójú Ọlọ́run. Jẹ́ ká sọ ìtàn Ráhábù láti ìbẹ̀rẹ̀, ká sì wo ohun tí a lè kọ́ lára rẹ̀.

RÁHÁBÙ AṢẸ́WÓ

Iṣẹ́ aṣẹ́wó ni Ráhábù ń ṣe. Òkodoro òtítọ́ yìí máa ń ya àwọn tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lẹ́nu, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ pé olùtọ́jú ilé èrò ni. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ ṣe kedere, kò fi òótọ́ bò rárá. (Jóṣúà 2:1; Hébérù 11:31; Jákọ́bù 2:25) Nílẹ̀ Kénáánì, wọn ò ka irú iṣẹ́ tí Ráhábù ń ṣe yìí sí ohun tó burú. Àmọ́, bí àṣà ìbílẹ̀ kò bá tiẹ̀ dẹ́bi fún iṣẹ́ kan, ẹ̀rí ọkàn tí Jèhófà ti fún oníkálukú wa máa ń gún wa ní kẹ́ṣẹ́ tó bá kan ọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Róòmù 2:14, 15) Ó ṣeé ṣe kí Ráhábù fúnra rẹ̀ ti mọ̀ pé iṣẹ́ ìtìjú ni òun ń ṣe. Àmọ́, bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí táwọn náà ń ṣe irú iṣẹ́ tí Ráhábù ń ṣe nígbà yẹn, ó lè jẹ́ pé irú èrò tó wà lọ́kàn wọn ni Ráhábù náà ní. Ráhábù lè máa wò ó pé òun ti há, pé kò tún sí ọ̀nà míì tí òun lè máa fi gbọ́ bùkátà ìdílé òun, àfi iṣẹ́ aṣẹ́wó yìí.

Láìsí àní-àní, ìgbé ayé tó dára ló wu Ráhábù. Àmọ́, oríṣiríṣi ìwà ipá àti ìṣekúṣe ló kún ìlú rẹ̀, títí kan ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan àtàwọn tó ń bá ẹranko lò pọ̀. (Léfítíkù 18:3, 6, 21-24) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ̀sìn gan-an ni olórí ohun tó jẹ́ kí irú àwọn ìwà abèṣe bẹ́ẹ̀ gbòde kan nílùú yẹn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fàyè gba iṣẹ́ aṣẹ́wó nínú àwọn tẹ́ńpìlì wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké, irú bí òrìṣà Báálì àti Mólékì, ń sọ àwọn ọmọ wọn sínú iná lóòyẹ̀ láti fi rúbọ.

Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Kénáánì yìí ò kúkú pa mọ́ lójú Jèhófà. Nítorí gbogbo ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù yìí ni Jèhófà fi kéde pé: “Ilẹ̀ náà jẹ́ aláìmọ́, èmi yóò sì mú ìyà wá sórí rẹ̀ nítorí ìṣìnà rẹ̀, ilẹ̀ náà yóò sì pọ àwọn olùgbé rẹ̀ jáde.” (Léfítíkù 18:25) Kí ni “ìyà” tó ń bọ̀ lórí wọn nítorí “ìṣìnà” wọn ní nínú? Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì ti àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí kúrò níwájú rẹ díẹ̀díẹ̀.” (Diutarónómì 7:22) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Jèhófà ti ṣèlérí pé ìdílé Ábúráhámù ni yóò jogún ilẹ̀ náà. Àwa náà sì mọ̀ pé “Ọlọ́run. . . kò lè purọ́.”—Títù 1:2; Jẹ́nẹ́sísì 12:7.

Àmọ́, àwọn ìlú kan tún wà tí Jèhófà ti pàṣẹ pé kí wọ́n pa run ráúráú. (Diutarónómì 7:1, 2) Torí pé Jèhófà jẹ́ olódodo àti “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé,” ó ti mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn pé wọ́n ti jingíri sínú ìwà ibi àti ìwàkiwà tí wọ́n ń hù, wọn kò sì fẹ́ jáwọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 18:25; 1 Kíróníkà 28:9) Ṣé ẹ tí wá rí i báyìí pé ìlú tó kún fọ́fọ́ fún ìwà abèṣe ni Ráhábù ń gbé. Báwo ni àwọn ohun tó gbọ́ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rí lára rẹ̀? Ó ti gbọ́ nípa bí ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rí màbo nígbà tí wọ́n ń ṣẹrú àti bí Ọlọ́run wọn ṣe tì wọ́n lẹ́yìn, tó sì mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Íjíbítì tó lágbára jù láyé ìgbà yẹn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti dé báyìí láti wá gbéjà ko Jẹ́ríkò! Síbẹ̀ àwọn aráàlú yìí ò jáwọ́ nínú ìwà ibi wọn. Abájọ tí Bíbélì fi pe àwọn ọmọ Kénáánì, ìyẹn àwọn aráàlú Ráhábù ní “àwọn tí ó ṣe àìgbọràn.”—Hébérù 11:31.

Ṣùgbọ́n Ráhábù yàtọ̀ ní tiẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ló ti ń ronú lórí àwọn ìròyìn tó gbọ́ nípa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Jèhófà Ọlọ́run wọn. Á ti mọ̀ pé Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ọlọ́run ilẹ̀ Kénáánì tí kò ní láárí. Jèhófà kì í fìtínà àwọn èèyàn rẹ̀, ńṣe ló ń gbèjà wọn, dípò kó sọ wọ́n di eléèérí, ó kọ́ wọn níwà tó mú kí wọ́n dá yàtọ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ wọ́n dẹni ẹ̀yẹ. Àwọn obìnrin ṣeyebíye lójú Jèhófà, kì í ṣe wọ́n báṣubàṣu, kò kà wọ́n sí ẹni tí kò wúlò fún nǹkan kan ju ìbálòpọ̀ lọ tàbí ohun téèyàn ń tà tàbí rà tàbí fi ṣe ìṣekúṣe nídìí ìjọsìn tó ń ríni lára. Nígbà tí Ráhábù gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ti pabùdó sí ẹ̀bá Jọ́dánì, tí wọ́n sì ti gbára dì láti gbógun ja ìlú náà, ìdààmú lè ti bá a gan-an lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rẹ̀. Ǹjẹ́ Jèhófà kíyèsí Ráhábù, ṣé ó sì mọyì ẹ̀mí rere tó ní?

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló dà bíi Ráhábù. Wọ́n máa ń rò pé àwọn ti há sínú ìgbé ayé tí kò jẹ́ kí àwọn láyọ̀, wọn kò sì níyì lójú ara wọn mọ́, wọ́n gbà pé kò sí ẹni tó rí tàwọn rò tàbí mọyì àwọn. Àmọ́, ìtùnú ni ìtàn Ráhábù jẹ́ torí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run kà wá sí, kò sì gbàgbé ẹnì kankan. Bó ti wù ká ro ara wa pin tó, “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Jèhófà kò ta kété sí wa, ó fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń lo ìgbàgbọ́ nínú òun ní ìrètí tó dájú. Ǹjẹ́ Ráhábù lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run?

Ó GBA ÀWỌN AMÍ

Lọ́jọ́ kan, ṣáájú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó bẹ̀rẹ̀ sí í yan yíká ìlú Jẹ́ríkò, àwọn ọkùnrin méjì kan tí Ráhábù kò mọ̀ rí wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ńṣe ni wọ́n dọ́gbọ́n ya ibẹ̀ láì fu ẹni kankan lára, àmọ́ ara gbogbo aráàlú kò balẹ̀ mọ́, wọ́n wà lójúfò, wọ́n sì ń ṣọ́nà kí ọwọ́ wọn lè tẹ ẹnikẹ́ni tó bá wá ṣe amí láti Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí Ráhábù ti fura pé amí ni àwọn ọkùnrin náà. Lóòótọ́ àwọn ọkùnrin àjèjì máa ń wá a wá, àmọ́ kì í ṣe ìṣekúṣe ni àwọn amí yìí bá wá sọ́dọ̀ọ́ rẹ̀, wọ́n kàn fẹ́ kí ó bá wọn wá ibi tí wọ́n lè sùn ni.

Lóòótọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wá ṣe amí ni àwọn ọkùnrin yìí. Ọ̀gágun wọn Jóṣúà ló rán wọn lọ fimú fínlẹ̀ kí wọ́n lè mọ bí àwọn aráàlú yẹn ṣe wà lójúfò tó àti ibi tí àwọn lè gbà wọlé sí wọn lára. Ìlú yìí ni àkọ́kọ́ lára àwọn ilẹ̀ Kénáánì tí Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n pa run, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìlú yìí ló lágbára jù nínú gbogbo ìlú tó wà nílẹ̀ Kénáánì. Torí náà, Jóṣúà fẹ́ mọ ohun tí òun àtàwọn ọmọ ogun òun máa kojú táwọn bá dé inú ìlú náà. Kò sí iyèméjì pé àwọn amí yẹn mọ̀ọ́mọ̀ ya ilé Ráhábù ni. Wọ́n ti lè wò ó pé ilé aṣẹ́wó kúkú ni, àwọn èèyàn lè máà fura sí àjèjì tó bá wọ ibẹ̀. Ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n ti gbèrò pé oríṣiríṣi èèyàn ló ń wá sílé aṣẹ́wó àti pé ìsọfúnni tí àwọn ń wá lè ta sí àwọn létí táwọn tó wà níbẹ̀ bá ń tàkúrọ̀sọ.

Bíbélì sọ pé Ráhábù “gba àwọn ońṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò.” (Jákọ́bù 2:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara fu ú sí àwọn ọkùnrin náà nípa ohun tí wọ́n bá wá àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́, síbẹ̀ ó gbà wọ́n sínú ilé rẹ̀. Bóyá ó ti ní i lọ́kàn pé òun á fi ìyẹn mọ púpọ̀ sí i nípa Jèhófà Ọlọ́run wọn.

Àmọ́, ká tó wí ká tó fọ̀, àwọn oníṣẹ́ ọba ìlú Jẹ́ríkò ti dé! Torí wọ́n ti gbọ́ pé àwọn amí láti Ísírẹ́lì ti wọlé wá sọ́dọ̀ Ráhábù. Ǹjẹ́ Ráhábù ò ti dáràn báyìí? Kí ni kó ṣe? Tó bá fi àwọn àjèjì méjì yìí pa mọ́ sílé rẹ̀, ǹjẹ́ kò ní kó ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sínú wàhálà? Tí àwọn aráàlú rẹ̀ bá mọ̀ pé ó fi àwọn ọ̀tá pa mọ́ sínú ilé rẹ̀, ǹjẹ́ wọn ò ní pa òun àtàwọn amí yẹn? Àmọ́, kò sí iyèméjì mọ́ pé Ráhábù ti mọ ẹni tí àwọn ọkùnrin méjì yìí jẹ́. Níwọ̀n bí Ráhábù ti mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run lágbára fíìfíì ju ọlọ́run tí òun ń sìn lọ, ǹjẹ́ àǹfààní kò ti ṣí sílẹ̀ fún un báyìí láti sá di Jèhófà?

Àkókò ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tó fún Ráhábù láti ronú lórí gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ onílàákàyè ni, kò jáfara rárá, kíá ló wá nǹkan ṣe. Ńṣe ló fi àwọn amí méjì yẹn pa mọ́ sáàárín ìtí pòròpórò ọ̀gbọ̀ tí ó sá sórí òrùlé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó lọ pàdé àwọn oníṣẹ́ ọba lẹ́nu ọ̀nà, ó sì wí fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ mi ní tòótọ́, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n ti wá. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí àkókò ti ń tó láti ti ẹnubodè nígbà tí ilẹ̀ ṣú ni àwọn ọkùnrin náà jáde lọ. Èmi kò sáà mọ ibi tí àwọn ọkùnrin náà lọ. Ẹ tètè lépa wọn, nítorí ẹ óò bá wọn.” (Jóṣúà 2:4,  5) Ẹ wo bí àyà Ráhábù á ṣe máa lù kìkì bó ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí níwájú àwọn oníṣẹ́ ọba yẹn. Ǹjẹ́ kò ní máa bẹ̀rù pé wọ́n lè fura sí òun?

Ráhábù fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu bó ṣe fi àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà méjì pa mọ́ sáàárín ìtí pòròpórò ọ̀gbọ̀

Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn oníṣẹ́ ọba ti forí lé apá ọ̀nà Jọ́dánì níbi odò pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ tí Ráhábù sọ pé kí wọ́n lépa àwọn amí náà gbà. Bí ọgbọ́n arúmọjẹ tó lò fún wọn ṣe ṣiṣẹ́ nìyẹn! (Jóṣúà 2:7) Ọkàn Ráhábù ṣẹ̀ṣẹ̀ wá balẹ̀ wàyí. Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ló fi darí àwọn oníṣẹ́ ọba gba ibòmíì, torí pé wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ òtítọ́. Bí ó ṣe gba ẹ̀mí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà là nìyẹn.

Kété lẹ́yìn náà ni Ráhábù pa dà síbi òrùlé rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn amí náà nípa gbogbo ohun tí òun ṣe. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹ̀rù ń ba àwọn aráàlú òun, ìdààmú sì ti bá wọn torí wọ́n ti gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bọ̀ wá kógun jà wọ́n. Ohun táwọn amí yìí fẹ́ gbọ́ gan-an nìyẹn. Inú wọ́n dùn láti mọ̀ pé jìnnìjìnnì Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bo àwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì yìí! Ọ̀rọ̀ tí Ráhábù wá sọ tẹ̀ lé e jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì kan. Ó sọ fún àwọn amí náà pé: “Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run nínú ọ̀run lókè àti lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.” (Jóṣúà 2:11) Àṣé gbogbo ohun tó gbọ́ nípa Jèhófà ti wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ó wá wò ó pé ó yẹ kí òun gbára lé Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn, ó lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.

Ọkàn Ráhábù balẹ̀ pé bí iná ń jó bí ìjì ń jà, Jèhófà yóò ṣẹ́gun fún àwọn èèyàn tirẹ̀. Torí náà, ó bẹ àwọn amí náà pé kí wọ́n ṣàánú òun, kí wọ́n dá ẹ̀mí òun àti ìdílé òun sí. Àwọn amí náà gbà, àmọ́ wọ́n kìlọ̀ fún Ráhábù pé kó ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí, wọ́n tún ní kó so okùn fọ́nrán òwú rírẹ̀dòdò kan mọ́ fèrèsé rẹ̀. Tí àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì bá ti rí okùn yìí lára ilé rẹ̀, wọ́n á dá ẹ̀mí òun àti ìdílé rẹ̀ sí.—Jóṣúà 2:12-14,  18.

Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ ni Ráhábù jẹ́ fún gbogbo wa! Bí Bíbélì ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí, pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Ráhábù tí gbọ́ lẹ́nu àwọn tó ṣeé fọkàn tán pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run alágbára, ó sì kórìíra ìrẹ́jẹ, èyí ló mú kí òun náà gba Jèhófà gbọ́ tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Lónìí, ìmọ̀ nípa Jèhófà pọ̀, ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ti kọ́ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ǹjẹ́ àwa náà ṣe tán láti mọ Jèhófà, ká sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?

ODI ŃLÁ JẸ́RÍKÒ WÓ LULẸ̀ BẸẸRẸBẸ

Àwọn amí yẹn ta okùn kan wálẹ̀ láti ojú fèrèsé Ráhábù gba ẹ̀yìn odi ìlú, wọ́n sì yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wọ àárín àwọn òkè ńlá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ihò inú àpáta ló wà níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó wà lápá àríwá ìlú Jẹ́ríkò tí àwọn amí yìí lè sá sí títí di ìgbà tí ewu á fi ré kọjá, tí wọ́n á lè pa dà síbi tí àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì pàgọ́ sí, kí wọ́n sì sọ ìròyìn ayọ̀ tí wọ́n gbọ́ lọ́dọ̀ Ráhábù fún wọn.

Ráhábù lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì

Ó dájú pé jìnnìjìnnì á ti bo àwọn aráàlú Jẹ́ríkò nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jèhófà kò jẹ́ kí odò Jọ́dánì ṣàn mọ́, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè rìn kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ. (Jóṣúà 3:14-17) Àmọ́, ńṣe ni ìròyìn yìí túbọ̀ ki Ráhábù láyà pé ìgbàgbọ́ òun nínú Jèhófà kò ní já sí asán.

Láti ọjọ́ mẹ́fà sẹ́yìn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń yan yíká ìlú Jẹ́ríkò ní ẹ̀ẹ̀kan lóòjọ́. Ọjọ́ keje ti pé wàyí, ohun tí wọ́n sì fẹ́ ṣe máa yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n ti ń ṣe bọ̀. Bá a ṣe sọ ṣáájú, àárọ̀ kùtùkùtù ni àwọn ọmọ ogun náà bẹ̀rẹ̀ sí í yan yíká ìlú náà, lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣeé lẹ́ẹ̀kan, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í yan yípo Jẹ́ríkò léraléra. (Jóṣúà 6:15) A lè máa ronú pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe yìí?

Ní ọjọ́ keje, ẹ̀ẹ̀méje ni wọ́n yan yípo. Bó ṣe di ìgbà keje báyìí ni gbogbo àwọn ọmọ ogun náà bá dúró jẹ́ẹ́. A ò gbọ́ ariwo ìwo tàbí fèrè mọ́. Ibi gbogbo wá pa rọ́rọ́. Ní gbogbo àkókò yìí, ọkàn àwọn aráàlú Jẹ́ríkò ti pami. Lójijì, Jóṣúà ṣẹ́wọ́ sí àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, ni gbogbo wọn bá kígbe ni ohùn rara, ariwo náà sì rinlẹ̀ gan-an. Ẹnu ya àwọn aṣọ́bodè ìlú Jẹ́ríkò tó lé téńté sórí odi ìlú bí wọ́n ṣe ń wo àwọn tó ń kígbe yìí. Wọ́n á máa ṣe kàyéfì pé ṣé igbe lásán làwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì fẹ́ fi bá àwọn já ni? Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń ro gbogbo èyí, ọṣẹ́ ti ṣe. Gbogbo ibi tí wọ́n dúró sí bẹ̀rẹ̀ sí í mì tìtì. Lójijì, ògiri ńlá náà sán, gbogbo rẹ̀ sì ya lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ! Nígbà tí eruku fẹ́ kúrò, ó yani lẹ́nu pé apá kan ògiri yẹn ṣì dúró digbí. Ilé Ráhábù ni ibi kan ṣoṣo tó ṣì dúró digbí yìí. Ìgbàgbọ́ Ráhábù ni kò jẹ́ kí idílé rẹ̀ bá ìparun náà lọ. Téèyàn bá ń gẹṣin nínú Ráhábù lọ́jọ́ náà, kò lè kọsẹ̀! * Ayọ̀ rẹ̀ kún torí pé Jèhófà dá òun àti ìdílé rẹ̀ sí!—Jóṣúà 6:10, 16, 20, 21.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàápàá kan sárá sí Ráhábù torí ìgbàgbọ́ tó ní. Bí àwọn náà ṣe rí i pé ilé kan ṣoṣo ló ṣì dúró láàárín gbogbo àwókù yẹn, wọ́n á ti mọ̀ pé Jèhófà ló pa obìnrin náà mọ́. Obìnrin rere yìí àti ìdílé rẹ̀ la ìparun búburú náà já. Lẹ́yìn tí ogun yẹn parí, wọ́n gba Ráhábù láyè kó máa gbé nítòsí ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Ráhábù di ara àwọn júù, ó sì fẹ́ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sálímọ́nì. Wọ́n bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bóásì, ìgbàgbọ́ tirẹ̀ náà ṣàrà ọ̀tọ̀. Nígbà tó yá, Bóásì fẹ́ ọmọ Móábù kan tó ń jẹ́ Rúùtù. * (Rúùtù 4:13, 22) Ìlà ìdílé Ráhábù yìí ni Dáfídì Ọba àti Jésù Kristi tó di Mèsáyà, ti ṣẹ̀ wá. Àwòfiṣàpẹẹrẹ ni wọ́n nínú ìdílé yẹn.—Jóṣúà 6:22-25; Mátíù 1:5, 6, 16.

Ìtàn Ráhábù kọ́ gbogbo wa pé kò sẹ́ni tí kò já mọ́ nǹkan kan lójú Jèhófà. Ó rí gbogbo wa, ó ń wo ohun tó wà lọkàn wa, ó sì máa ń láyọ̀ tó bá ríi pé a ní ìgbàgbọ́ bíi ti Ráhábù, kódà bí kò bá tiẹ̀ tó nǹkan lójú tiwa, ó mọyì rẹ̀. Ìgbàgbọ́ tí Ráhábù ní ló jẹ́ kó ṣe gbogbo ohun tó ṣe. Ó bá ohun tí Bíbélì sọ mu gẹ́lẹ́ pé a polongo rẹ̀ ní “olódodo nípa àwọn iṣẹ́” rẹ̀. (Jákọ́bù 2:25) Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká fara wé àpẹẹrẹ àtàtà Ráhábù.

^ ìpínrọ̀ 27 Ó ní láti jẹ́ pé Jèhófà fọwọ́ sí àdéhùn tí àwọn amí náà ṣe fún Ráhábù.

^ ìpínrọ̀ 28 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Rúùtù àti Bóásì, ka àwọn àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” nínú Ilé Ìṣọ́ July 1 àti October 1, 2012.