Ìwé Kìíní sí Tímótì 2:1-15

  • Gbàdúrà nítorí onírúurú èèyàn (1-7)

    • Ọlọ́run kan, alárinà kan (5)

    • Ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí fún gbogbo èèyàn (6)

  • Àwọn ìtọ́ni fún tọkùnrin tobìnrin (8-15)

    • Múra lọ́nà tó bójú mu (9, 10)

2  Torí náà, mò ń pàrọwà fún yín ṣáájú ohun gbogbo pé kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ máa dúpẹ́, kí ẹ sì máa bẹ̀bẹ̀ torí onírúurú èèyàn,  kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ torí àwọn ọba àti gbogbo àwọn tó wà ní ipò gíga,*+ ká lè máa gbé ìgbé ayé tó pa rọ́rọ́ nìṣó pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn, bí a ti ń fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run, tí a sì ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan.+  Èyí dáa, ó sì ní ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run, Olùgbàlà wa,+  ẹni tó fẹ́ ká gba onírúurú èèyàn là,+ kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.  Torí Ọlọ́run kan ló wà+ àti alárinà kan+ láàárín Ọlọ́run àtàwọn èèyàn,+ ọkùnrin kan, Kristi Jésù,+  ẹni tó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí fún gbogbo èèyàn*+—ohun tí a máa jẹ́rìí sí nìyí tí àkókò rẹ̀ bá tó.  Torí ìjẹ́rìí yìí  + ni a ṣe yàn mí láti jẹ́ oníwàásù àti àpọ́sítélì+—òótọ́ ni mò ń sọ, mi ò parọ́—olùkọ́ àwọn orílẹ̀-èdè+ ní ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.  Nítorí náà, ní ibi gbogbo mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́* sókè,+ láìsí ìbínú+ àti fífa ọ̀rọ̀.+  Bákan náà, kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tó bójú mu* ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀,* kì í ṣe dídi irun lọ́nà àrà àti lílo wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ olówó ńlá,+ 10  àmọ́ kó jẹ́ lọ́nà tó yẹ àwọn obìnrin tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn,+ ìyẹn nípa àwọn iṣẹ́ rere. 11  Kí obìnrin kẹ́kọ̀ọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́* kó sì máa tẹrí ba délẹ̀délẹ̀.+ 12  Mi ò fọwọ́ sí kí obìnrin kọ́ni tàbí kó pàṣẹ lé ọkùnrin lórí, àmọ́ kí ó dákẹ́.*+ 13  Torí Ádámù ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, kó tó wá dá Éfà.+ 14  Bákan náà, a kò tan Ádámù jẹ, àmọ́ a tan obìnrin náà jẹ pátápátá,+ ó sì di arúfin. 15  Síbẹ̀, ọmọ bíbí máa dáàbò bò ó,+* bá rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ àti ìjẹ́mímọ́ àti àròjinlẹ̀.*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ipò àṣẹ.”
Tàbí “gbogbo onírúurú èèyàn.”
Ní Grk., “ọwọ́ ìdúróṣinṣin.”
Tàbí “tó buyì kúnni.”
Tàbí “làákàyè; òye.”
Tàbí “láìsọ̀rọ̀; fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́.”
Tàbí “máa fara balẹ̀; máa wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.”
Ní Grk., “tí wọ́n.”
Tàbí “làákàyè; òye.”